Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Léfítíkù 20:1-27

20  Jèhófà sì ń bá a lọ láti bá Mósè sọ̀rọ̀, pé:  “Ìwọ yóò sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, ‘Ọkùnrin èyíkéyìí nínú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, àti àtìpó èyíkéyìí tí ń ṣe àtìpó ní Ísírẹ́lì, tí ó bá fi èyíkéyìí nínú àwọn ọmọ rẹ̀ fún Mólékì,+ kí a fi ikú pa á láìkùnà. Kí àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà sọ ọ́ ní òkúta pa.  Ní tèmi, èmi yóò dojú mi kọ ọkùnrin yẹn, èmi yóò sì ké e kúrò láàárín àwọn ènìyàn rẹ̀,+ nítorí pé ó ti fi àwọn kan lára àwọn ọmọ rẹ̀ fún Mólékì fún ète sisọ ibi mímọ́+ mi di ẹlẹ́gbin àti láti sọ orúkọ mímọ́ mi di aláìmọ́.+  Bí àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà bá sì mọ̀ọ́mọ̀ fi ojú wọn pa mọ́ kúrò lọ́dọ̀ ọkùnrin yẹn nígbà tí ó ń fi èyíkéyìí lára àwọn ọmọ rẹ̀ fún Mólékì tí wọn kò sì fi ikú pa á,+  nígbà náà, èmi, ní tèmi, yóò dojú mi kọ ọkùnrin yẹn àti ìdílé rẹ̀,+ òun àti gbogbo àwọn tí ó bá ní ìbádàpọ̀ oníṣekúṣe nínú níní ìbádàpọ̀ oníṣekúṣe+ pẹ̀lú Mólékì ni èmi yóò sì ké kúrò láàárín àwọn ènìyàn wọn ní tòótọ́.  “‘Ní ti ọkàn tí ó yíjú sí àwọn abẹ́mìílò+ àti àwọn olùsàsọtẹ́lẹ̀ ìṣẹ̀lẹ̀+ láti ní ìbádàpọ̀ oníṣekúṣe pẹ̀lú wọn, dájúdájú, èmi yóò dojú mi kọ ọkàn yẹn, èmi yóò sì ké e kúrò láàárín àwọn ènìyàn rẹ̀.+  “‘Kí ẹ sọ ara yín di mímọ́, kí ẹ sì jẹ́ mímọ́,+ nítorí èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín.  Kí ẹ sì máa pa àwọn ìlànà àgbékalẹ̀ mi mọ́, kí ẹ sì máa tẹ̀ lé wọn.+ Èmi ni Jèhófà tí ń sọ yín di mímọ́.+  “‘Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ọkùnrin èyíkéyìí wà tí ó pe ibi wá sórí baba rẹ̀ àti ìyá rẹ̀,+ kí a fi ikú pa á láìkùnà.+ Ó pe ibi wá sórí baba rẹ̀ àti ìyá rẹ ni. Ẹ̀jẹ̀ òun fúnra rẹ̀ wà lórí ara rẹ̀.+ 10  “‘Wàyí o, ọkùnrin tí ó ṣe panṣágà pẹ̀lú aya ọkùnrin mìíràn ni ẹni tí ó ṣe panṣágà pẹ̀lú aya ọmọnìkejì rẹ̀.+ Kí a fi ikú pa á láìkùnà, àti panṣágà ọkùnrin náà àti panṣágà obìnrin náà.+ 11  Ọkùnrin kan tí ó sì sùn ti aya baba rẹ̀ ti tú ìhòòhò baba rẹ̀.+ Kí a fi ikú pa àwọn méjèèjì láìkùnà. Ẹ̀jẹ̀ wọ́n wà lórí wọn. 12  Bí ọkùnrin kan bá sì sùn ti aya ọmọ rẹ̀, àwọn méjèèjì ni kí a fi ikú pa láìkùnà.+ Wọ́n ti rú ìlànà ohun tí ó bá ìwà ẹ̀dá mu. Ẹ̀jẹ̀ wọ́n wà lórí wọn.+ 13  “‘Nígbà tí ọkùnrin kan bá sì sùn ti ọkùnrin bí ẹní sùn ti obìnrin, àwọn méjèèjì ti ṣe ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí.+ Kí a fi ikú pa wọ́n láìkùnà. Ẹ̀jẹ̀ wọ́n wà lórí wọn. 14  “‘Bí ọkùnrin kan bá sì fẹ́ obìnrin kan àti ìyá rẹ̀, ìwà àìníjàánu ni.+ Kí wọ́n sun òun àti àwọn nínú iná,+ kí ìwà àìníjàánu+ má bàa máa bá a lọ ní àárín yín. 15  “‘Bí ọkùnrin kan bá sì fi àtọ̀ tí ó dà lára rẹ̀ fún ẹranko,+ kí a fi ikú pa á láìkùnà, kí ẹ sì pa ẹranko náà. 16  Nígbà tí obìnrin kan bá sì sún mọ́ ẹranko èyíkéyìí láti bá a ní ìdàpọ̀,+ kí o pa obìnrin náà àti ẹranko náà. Kí a fi ikú pa wọ́n láìkùnà. Ẹ̀jẹ̀ wọ́n wà lórí wọn. 17  “‘Bí ọkùnrin kan bá sì fẹ́ arábìnrin rẹ̀, ọmọbìnrin baba rẹ̀ tàbí ọmọbìnrin ìyá rẹ̀, tí ó sì rí ìhòòhò rẹ̀, tí obìnrin náà sì rí ìhòòhò ọkùnrin náà, ìtìjú ni.+ Nítorí náà, kí a ké wọn kúrò lójú àwọn ọmọ ènìyàn wọn. Ìhòòhò arábìnrin rẹ̀ ni ó tú. Kí ó dáhùn fún ìṣìnà rẹ̀. 18  “‘Bí ọkùnrin kan bá sì sùn ti obìnrin kan tí ń ṣe nǹkan oṣù tí ó sì tú ìhòòhò rẹ̀, ó ti fi orísun obìnrin náà hàn síta, obìnrin náà fúnra rẹ̀ sì ti tú orísun ẹ̀jẹ̀ ara rẹ̀ sí borokoto.+ Nítorí náà, kí a ké àwọn méjèèjì kúrò láàárín àwọn ènìyàn wọn. 19  “‘Ìhòòhò arábìnrin ìyá rẹ+ àti ti arábìnrin baba rẹ+ ni ìwọ kò sì gbọ́dọ̀ tú, nítorí pé ẹbí rẹ̀ ni onítọ̀hún ṣí.+ Kí wọ́n dáhùn fún ìṣìnà wọn. 20  Ọkùnrin tí ó bá sì sùn ti aya arákùnrin òbí rẹ̀ ti tú ìhòòhò arákùnrin òbí rẹ̀.+ Kí wọ́n dáhùn fún ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Kí wọ́n kú láìbímọ.+ 21  Nígbà tí ọkùnrin kan bá sì fẹ́ aya arákùnrin rẹ̀, ohun ìkórìíra tẹ̀gàntẹ̀gàn ni.+ Ìhòòhò arákùnrin rẹ̀ ni ó tú. Kí wọ́n di aláìbímọ. 22  “‘Kí ẹ máa pa gbogbo ìlànà àgbékalẹ̀ mi+ àti gbogbo ìpinnu ìdájọ́+ mi mọ́, kí ẹ sì máa tẹ̀ lé wọn, kí ilẹ̀ tí èmi yóò mú yín wá sí láti máa gbé má bàa pọ̀ yín jáde.+ 23  Ẹ kò sì gbọ́dọ̀ rìn nínú ìlànà àgbékalẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè tí èmi yóò lé jáde kúrò níwájú yín,+ nítorí pé wọ́n ti ṣe gbogbo nǹkan wọ̀nyí, mo sì fi tẹ̀gàntẹ̀gàn kórìíra wọn.+ 24  Nítorí bẹ́ẹ̀ ni mo ṣe wí fún yín pé:+ “Ẹ̀yin, ní tiyín, yóò gba ilẹ̀ wọn, àti èmi, ní tèmi, yóò fi í fún yín láti gbà á, ilẹ̀ tí ń ṣàn fún wàrà àti oyin.+ Jèhófà Ọlọ́run yín ni èmi, ẹni tí ó ti yà yín sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn ènìyàn.”+ 25  Kí ẹ sì fi ìyàtọ̀ sáàárín ẹranko tí ó mọ́ àti èyí tí ó jẹ́ aláìmọ́ àti sáàárín ẹ̀dá abìyẹ́ tí ó mọ́ àti èyí tí ó jẹ́ aláìmọ́;+ ẹ kò sì gbọ́dọ̀ sọ ọkàn yín di ohun ìkórìíra tẹ̀gbintẹ̀gbin+ nípasẹ̀ ẹranko àti ẹ̀dá abìyẹ́ àti ohunkóhun tí ń rìn lórí ilẹ̀ tí mo ti yà sọ́tọ̀ fún yín ní pípolongo wọn ní aláìmọ́. 26  Kí ẹ sì jẹ́ mímọ́ lójú mi,+ nítorí pé èmi Jèhófà jẹ́ mímọ́;+ mó sì bẹ̀rẹ̀ sí yà yín sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn ènìyàn láti di tèmi.+ 27  “‘Ní ti ọkùnrin kan tàbí obìnrin kan tí agbára ìbẹ́mìílò tàbí ẹ̀mí ìsàsọtẹ́lẹ̀+ bá wà nínú rẹ̀, kí a fi ikú pa wọ́n láìkùnà.+ Kí wọ́n sọ wọ́n ní òkúta pa. Ẹ̀jẹ̀ wọ́n wà lórí wọn.’”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé