Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Léfítíkù 2:1-16

2  “‘Wàyí o, bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ọkàn kan mú ọrẹ ẹbọ ọkà+ wá gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ sí Jèhófà, kí ọrẹ ẹbọ rẹ̀ jẹ́ ìyẹ̀fun kíkúnná;+ kí ó sì da òróró sórí rẹ̀, kí ó sì fi oje igi tùràrí sórí rẹ̀.  Kí ó sì mú un wá fún àwọn ọmọkùnrin Áárónì, àwọn àlùfáà, kí àlùfáà sì bu ẹ̀kúnwọ́ rẹ̀ láti inú ìyẹ̀fun rẹ̀ kíkúnná àti òróró rẹ̀ pa pọ̀ pẹ̀lú gbogbo oje igi tùràrí rẹ̀; kí ó sì mú un rú èéfín gẹ́gẹ́ bí ohun ìránnilétí+ rẹ̀ lórí pẹpẹ, gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ àfinásun, ti òórùn amáratuni sí Jèhófà.  Ohun tí ó sì ṣẹ́ kù lára ọrẹ ẹbọ ọkà jẹ́ ti Áárónì àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀,+ gẹ́gẹ́ bí ohun mímọ́ jù lọ+ láti inú àwọn ọrẹ ẹbọ tí a fi iná sun sí Jèhófà.  “‘Bí ó bá sì ṣẹlẹ̀ pé ìwọ yóò mú ọrẹ ẹbọ ọkà wá gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ tí ó jẹ́ ohun kan tí a yan nínú ààrò, kí ó jẹ́ ìyẹ̀fun kíkúnná, àkàrà aláìwú tí ó ní ìrísí òrùka,+ tí a fi òróró rin fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́ tàbí àdíngbẹ àkàrà aláìwú+ tí ó rí pẹlẹbẹ tí a fi òróró pa.+  “‘Bí ọrẹ ẹbọ rẹ bá sì jẹ́ ọrẹ ẹbọ ọkà láti inú agbada,+ kí ó jẹ́ ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi òróró rin fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́, tí ó jẹ́ aláìwú.  Kí a bù ú sí wẹ́wẹ́, kí o sì da òróró sórí rẹ̀.+ Ọrẹ ẹbọ ọkà ni.  “‘Bí ọrẹ ẹbọ rẹ bá sì jẹ́ ọrẹ ẹbọ ọkà láti inú kẹ́tùrù jíjinnú, ìyẹ̀fun kíkúnná pẹ̀lú òróró ni kí a fi ṣe é.  Kí o sì mú ọrẹ ẹbọ ọkà tí a fi ìwọ̀nyí ṣe wá fún Jèhófà; kí a sì fi fún àlùfáà, kí ó sì mú un sún mọ́ pẹpẹ.  Kí àlùfáà sì mú lára ọrẹ ẹbọ ọkà gẹ́gẹ́ bí ohun ìránnilétí rẹ̀,+ kí ó sì mú un rú èéfín lórí pẹpẹ, gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ àfinásun, ti òórùn amáratuni sí Jèhófà.+ 10  Ohun tí ó bá sì ṣẹ́ kù lára ọrẹ ẹbọ ọkà náà jẹ́ ti Áárónì àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ohun mímọ́ jù lọ láti inú àwọn ọrẹ ẹbọ tí a fi iná sun sí Jèhófà.+ 11  “‘Ọrẹ ẹbọ ọkà tí ẹ óò mú wá fún Jèhófà ni ẹ kò gbọ́dọ̀ ṣe ní ìwúkàrà,+ nítorí tí ẹ kò gbọ́dọ̀ mú ìyẹ̀fun àpòrọ́ kíkan, ẹ kò sì gbọ́dọ̀ mú oyin rú èéfín rárá gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ àfinásun sí Jèhófà. 12  “‘Gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ àkọ́so,+ ẹ óò mú wọn wá fún Jèhófà, wọn kò sì gbọ́dọ̀ wá sórí pẹpẹ fún òórùn amáratuni. 13  “‘Gbogbo ọrẹ ẹbọ ti ọrẹ ẹbọ ọkà rẹ ni kí o fi iyọ̀ dùn;+ ìwọ kò sì gbọ́dọ̀ jẹ́ kí iyọ̀ májẹ̀mú+ Ọlọ́run rẹ ṣàìsí lórí ọrẹ ẹbọ ọkà rẹ. Kí o máa mú iyọ̀ wá pa pọ̀ pẹ̀lú gbogbo ọrẹ ẹbọ rẹ. 14  “‘Bí ìwọ yóò bá mú ọrẹ ẹbọ ọkà ti àkọ́pọ́n èso wá fún Jèhófà, kí o mú ṣírí tútù tí a fi iná yan gbẹ, èbó ọkà tuntun, wá, gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ ọkà ti àkọ́pọ́n èso rẹ.+ 15  Kí o sì fi òróró sórí rẹ̀, kí o sì fi oje igi tùràrí sórí rẹ̀. Ọrẹ ẹbọ ọkà ni.+ 16  Kí àlùfáà sì mú ohun ìránnilétí+ rẹ̀ rú èéfín, èyíinì ni, díẹ̀ lára èbó àti òróró rẹ̀, pa pọ̀ pẹ̀lú gbogbo oje igi tùràrí rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ àfinásun sí Jèhófà.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé