Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Léfítíkù 19:1-37

19  Jèhófà sì wí fún Mósè síwájú sí i, pé:  “Bá gbogbo àpéjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pátá sọ̀rọ̀, kí o sì wí fún wọn pé, ‘Kí ẹ jẹ́ mímọ́,+ nítorí pé èmi Jèhófà Ọlọ́run yín jẹ́ mímọ́.+  “‘Kí olúkúlùkù yín bẹ̀rù ìyá rẹ̀ àti baba rẹ̀,+ kí ẹ sì máa pa àwọn sábáàtì mi mọ́.+ Èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín.  Ẹ má ṣe yíjú sí àwọn ọlọ́run tí kò ní láárí,+ ẹ kò sì gbọ́dọ̀ ṣe àwọn ọlọ́run dídà fún ara yín.+ Èmi ni Jèhófà Ọlọ́run.  “‘Wàyí o, bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ẹ rú ẹbọ ìdàpọ̀ sí Jèhófà,+ kí ẹ rú u láti rí ìtẹ́wọ́gbà fún ara yín.+  Ní ọjọ́ ẹbọ yín àti ọjọ́ kejì  rẹ̀ gan-an ni kí a jẹ ẹ́, ṣùgbọ́n ohun tí ó bá ṣẹ́ kù títí di ọjọ́ kẹta ni kí a fi iná sun.+  Ṣùgbọ́n, bí ó bá jẹ́ pé a jẹ ẹ́ rárá ní ọjọ́ kẹta, o ti di ohun àìmọ́.+ A kì yóò fi ojú rere tẹ́wọ́ gbà á.+  Ẹni tí ó sì jẹ ẹ́ yóò dáhùn fún ìṣìnà rẹ̀,+ nítorí pé ó ti sọ ohun mímọ́ Jèhófà di aláìmọ́; ọkàn yẹn ni kí a sì ké kúrò nínú àwọn ènìyàn rẹ̀.  “‘Nígbà tí ẹ bá sì kórè ilẹ̀ yín, ìwọ kò gbọ́dọ̀ kárúgbìn eteetí pápá rẹ pátápátá, ìwọ kò sì gbọ́dọ̀ pèéṣẹ́ ìkórè rẹ.+ 10  Pẹ̀lúpẹ̀lù, ìwọ kò gbọ́dọ̀ kó àṣẹ́kùsílẹ̀+ inú ọgbà àjàrà rẹ, ìwọ kò sì gbọ́dọ̀ ṣa àwọn èso àjàrà tí ó fọ́n ká nínú ọgbà àjàrà rẹ. Kí o fi wọ́n sílẹ̀ fún ẹni tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́ àti àtìpó.+ Èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín. 11  “‘Ẹ kò gbọ́dọ̀ jalè,+ ẹ kò sì gbọ́dọ̀ tanni jẹ,+ ẹ kò sì gbọ́dọ̀ ṣèké, ẹnikẹ́ni sí ẹlẹgbẹ́ rẹ̀.+ 12  Ẹ kò sì gbọ́dọ̀ búra ní orúkọ mi lórí irọ́,+ kí o má bàa sọ orúkọ Ọlọ́run rẹ di aláìmọ́. Èmi ni Jèhófà. 13  Ìwọ kò gbọ́dọ̀ lu ọmọnìkejì  rẹ ní jì bìtì,+ ìwọ kò sì gbọ́dọ̀ jalè.+ Owó ọ̀yà lébìrà tí a háyà kò gbọ́dọ̀ wà lọ́dọ̀ rẹ ní gbogbo òru títí di òwúrọ̀.+ 14  “‘Ìwọ kò gbọ́dọ̀ pe ibi wá sórí adití, ìwọ kò sì gbọ́dọ̀ fi ohun ìdìgbòlù+ síwájú afọ́jú; kí o sì máa bẹ̀rù Ọlọ́run rẹ.+ Èmi ni Jèhófà. 15  “‘Ẹ kò gbọ́dọ̀ ṣe àìṣèdájọ́ òdodo nínú ìdájọ́. Ìwọ kò gbọ́dọ̀ fi ojúsàájú+ bá ẹni rírẹlẹ̀ lò, ìwọ kò sì gbọ́dọ̀ ṣe ojúsàájú ẹni ńlá.+ Ìdájọ́ òdodo ni kí o fi ṣe ìdájọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ. 16  “‘Ìwọ kò gbọ́dọ̀ máa lọ káàkiri láàárín àwọn ènìyàn rẹ láti fọ̀rọ̀ èké bani jẹ́.+ Ìwọ kò gbọ́dọ̀ dìde sí ẹ̀jẹ̀+ ọmọnìkejì  rẹ. Èmi ni Jèhófà. 17  “‘Ìwọ kò gbọ́dọ̀ kórìíra arákùnrin rẹ nínú ọkàn-àyà rẹ.+ Kí o rí í pé o fi ìbáwí tọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ sọ́nà,+ kí o má bàa ru ẹ̀ṣẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀. 18  “‘Ìwọ kò gbọ́dọ̀ gbẹ̀san+ tàbí kí o di kùnrùngbùn sí ọmọ àwọn ènìyàn rẹ;+ kí ìwọ sì nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì  rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.+ Èmi ni Jèhófà. 19  “‘Kí ẹ máa pa àwọn ìlànà àgbékalẹ̀ mi mọ́: Ìwọ kò gbọ́dọ̀ mú ẹran agbéléjẹ̀ rẹ oríṣi méjì  bá ara wọn dà pọ̀. Ìwọ kò gbọ́dọ̀ gbin oríṣi+ irúgbìn méjì  sínú pápá rẹ, ìwọ kò sì gbọ́dọ̀ fi ẹ̀wù tí ó ní oríṣi fọ́nrán òwú méjì  tí a hun pọ̀ wọ ara rẹ.+ 20  “‘Wàyí o, bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ọkùnrin kan sùn ti obìnrin kan tí ó sì da àtọ̀, nígbà tí ó jẹ́ ìránṣẹ́bìnrin tí a yàn sọ́tọ̀ fún ọkùnrin mìíràn, tí a kò sì tíì tún un rà padà ní ọ̀nà èyíkéyìí tàbí tí a kò tíì fún un ní òmìnira, ohun tí ó yẹ fún ìyà ni. A kò gbọ́dọ̀ fi ikú pa wọn, nítorí pé a kò dá obìnrin náà sílẹ̀ lómìnira. 21  Kí ọkùnrin náà sì mú ọrẹ ẹbọ ẹ̀bi rẹ̀ wá fún Jèhófà ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé, àgbò ọrẹ ẹbọ ẹ̀bi.+ 22  Kí àlùfáà sì fi àgbò ọrẹ ẹbọ ẹ̀bi ṣe ètùtù fún un níwájú Jèhófà nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ tí ó dá; a ó sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ tí ó dá jì  í.+ 23  “‘Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ẹ dé ilẹ̀ náà, tí ẹ sì gbin igi èyíkéyìí fún oúnjẹ, kí ẹ ka èso rẹ̀ sí ohun ìdọ̀tí gẹ́gẹ́ bí “adọ̀dọ́” rẹ̀. Fún ọdún mẹ́ta ni kí ó fi wà ní aláìdádọ̀dọ́ fún yín. Kí a má ṣe jẹ ẹ́. 24  Ṣùgbọ́n ní ọdún kẹrin gbogbo èso+ rẹ̀ yóò di ohun mímọ́ fún ayọ̀ ńláǹlà ti àjọyọ̀ sí Jèhófà.+ 25  Ní ọdún karùn-ún, ẹ lè jẹ èso rẹ̀, kí èso rẹ̀ lè pọ̀ sí i fún ara yín.+ Èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín. 26  “‘Ẹ kò gbọ́dọ̀ jẹ ohunkóhun tòun ti ẹ̀jẹ̀.+ “‘Ẹ kò gbọ́dọ̀ wá àwọn àmì ìṣẹ̀lẹ̀,+ ẹ kò sì gbọ́dọ̀ pidán.+ 27  “‘Ẹ kò gbọ́dọ̀ gé kànnàǹgó yín kúrú yí ká, ìwọ kò sì gbọ́dọ̀ ba ìpẹ̀kun irùngbọ̀n rẹ jẹ́.+ 28  “‘Ẹ kò sì gbọ́dọ̀ kọ ara yín lábẹ nítorí ọkàn tí ó ti di olóògbé,+ ẹ kò sì gbọ́dọ̀ fín àmì sí ara yín. Èmi ni Jèhófà. 29  “‘Má ṣe sọ ọmọbìnrin rẹ di aláìmọ́ nípa sísọ ọ́ di kárùwà,+ kí ilẹ̀ náà má bàa ṣe iṣẹ́ kárùwà tí ilẹ̀ náà yóò fi kún fún ìwà àìníjàánu ní ti gidi.+ 30  “‘Àwọn sábáàtì mi ni kí ẹ máa pa mọ́,+ kí ẹ sì ní ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀ fún ibùjọsìn mi.+ Èmi ni Jèhófà. 31  “‘Ẹ má ṣe yíjú sí àwọn abẹ́mìílò,+ ẹ má sì ṣe wádìí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ àwọn olùsàsọtẹ́lẹ̀ ìṣẹ̀lẹ̀,+ láti di aláìmọ́ nípasẹ̀ wọn. Èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín. 32  “‘Kí o dìde dúró níwájú orí ewú,+ kí o sì fi ìgbatẹnirò hàn fún arúgbó,+ kí o sì máa bẹ̀rù Ọlọ́run rẹ.+ Èmi ni Jèhófà. 33  “‘Bí ó bá sì ṣẹlẹ̀ pé àtìpó kan ń ṣe àtìpó lọ́dọ̀ rẹ ní ilẹ̀ yín, ẹ kò gbọ́dọ̀ fojú rẹ̀ gbolẹ̀.+ 34  Kí àtìpó tí ń ṣe àtìpó lọ́dọ̀ yín dà bí ọmọ ìbílẹ̀ yín; kí ìwọ sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ,+ nítorí ẹ di àtìpó ní ilẹ̀ Íjíbítì.+ Èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín. 35  “‘Ẹ kò gbọ́dọ̀ ṣe àìṣèdájọ́ òdodo nínú ìdájọ́ ṣíṣe,+ nínú ìdíwọ̀n, nínú wíwọ̀n,+ tàbí nínú dídíwọ̀n àwọn ohun olómi. 36  Kí ẹ ní òṣùwọ̀n pípéye,+ ìwọ̀n pípéye, òṣùwọ̀n eéfà pípéye àti òṣùwọ̀n hínì pípéye. Jèhófà Ọlọ́run yín ni èmi, ẹni tí ó mú yín jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì. 37  Nítorí náà, kí ẹ máa pa gbogbo ìlànà àgbékalẹ̀ mi àti gbogbo ìpinnu ìdájọ́ mi mọ́, kí ẹ sì máa tẹ̀ lé wọn.+ Èmi ni Jèhófà.’”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé