Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Léfítíkù 18:1-30

18  Jèhófà sì ń bá a lọ láti bá Mósè sọ̀rọ̀, pé:  “Bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀, kí o sì wí fún wọn pé, ‘Èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín.+  Bí ilẹ̀ Íjíbítì tí ẹ gbé inú rẹ̀ ti ṣe ni ẹ kò gbọ́dọ̀ ṣe;+ àti bí ilẹ̀ Kénáánì, inú èyí tí èmi yóò mu yín lọ ti ń ṣe ni ẹ kò gbọ́dọ̀ ṣe;+ ẹ kò sì gbọ́dọ̀ rìn nínú ìlànà àgbékalẹ̀ wọn.  Àwọn ìpinnu ìdájọ́ mi+ ni kí ẹ mú ṣẹ, àwọn ìlànà àgbékalẹ̀ mi+ ni kí ẹ sì máa pa mọ́ láti máa rìn nínú wọn.+ Èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín.  Kí ẹ sì máa pa àwọn ìlànà àgbékalẹ̀ mi àti àwọn ìpinnu ìdájọ́ mi mọ́, èyí tí ó jẹ́ pé, bí ènìyàn bá pa wọ́n mọ́, ẹni náà yóò sì wà láàyè nípasẹ̀ wọn.+ Èmi ni Jèhófà.+  “‘Ọkùnrin èyíkéyìí nínú yín kò gbọ́dọ̀ sún mọ́ ẹnikẹ́ni tí ó jẹ́ ìbátan rẹ̀ tímọ́tímọ́ nípa ti ara láti tú u sí ìhòòhò.+ Èmi ni Jèhófà.  Ìhòòhò baba rẹ+ àti ìhòòhò ìyá rẹ ni ìwọ kò gbọ́dọ̀ tú. Ìyá rẹ ni. Ìwọ kò gbọ́dọ̀ tú ìhòòhò rẹ̀.  “‘Ìhòòhò aya baba rẹ ni ìwọ kò gbọ́dọ̀ tú.+ Ìhòòhò baba rẹ ni.  “‘Ní ti ìhòòhò arábìnrin rẹ, ọmọbìnrin baba rẹ tàbí ọmọbìnrin ìyá rẹ, yálà tí a bí sínú agbo ilé kan náà tàbí tí a bí sí òde, ìwọ kò gbọ́dọ̀ tú ìhòòhò wọn.+ 10  “‘Ní ti ìhòòhò ọmọbìnrin tí ó jẹ́ ti ọmọkùnrin rẹ tàbí ọmọbìnrin tí ó jẹ́ ti ọmọbìnrin rẹ, ìwọ kò gbọ́dọ̀ tú ìhòòhò wọn, nítorí pé ìhòòhò rẹ ni wọ́n. 11  “‘Ní ti ìhòòhò ọmọbìnrin aya baba rẹ, ọmọ baba rẹ, nítorí tí ó jẹ́ arábìnrin rẹ, ìwọ kò gbọ́dọ̀ tú ìhòòhò rẹ̀. 12  “‘Ìhòòhò arábìnrin baba rẹ ni ìwọ kò gbọ́dọ̀ tú. Ẹbí baba rẹ ni.+ 13  “‘Ìhòòhò arábìnrin ìyá rẹ ni ìwọ kò gbọ́dọ̀ tú, nítorí pé ó jẹ́ ẹbí ìyá rẹ. 14  “‘Ìhòòhò arákùnrin baba rẹ ni ìwọ kò gbọ́dọ̀ tú. Ìwọ kò gbọ́dọ̀ sún mọ́ aya rẹ̀. Aya arákùnrin baba rẹ ni.+ 15  “‘Ìhòòhò aya ọmọkùnrin+ rẹ ni ìwọ kò gbọ́dọ̀ tú. Aya ọmọkùnrin rẹ ni. Ìwọ kò gbọ́dọ̀ tú ìhòòhò rẹ̀. 16  “‘Ìhòòhò aya arákùnrin rẹ+ ni ìwọ kò gbọ́dọ̀ tú. Ìhòòhò arákùnrin rẹ ni. 17  “‘Ìhòòhò obìnrin àti ọmọbìnrin rẹ̀ ni ìwọ kò gbọ́dọ̀ tú.+ Ọmọbìnrin tí ó jẹ́ ti ọmọkùnrin rẹ̀ àti ọmọbìnrin tí ó jẹ́ ti ọmọbìnrin rẹ̀ ni ìwọ kò gbọ́dọ̀ mú láti lè tú ìhòòhò rẹ̀. Ẹ̀jẹ̀ kan náà ni wọ́n. Ìwà àìníjàánu ni.+ 18  “‘Ìwọ kò sì gbọ́dọ̀ fẹ́ obìnrin kan ní àfikún sí arábìnrin rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí orogún+ láti tú ìhòòhò rẹ̀, èyíinì ni, ní àfikún sí arábìnrin rẹ̀ ní ìgbà ayé rẹ̀. 19  “‘Ìwọ kò sì gbọ́dọ̀ sún mọ́ obìnrin kan nígbà ṣíṣe nǹkan oṣù+ ohun ìdọ̀tí rẹ̀ láti tú ìhòòhò rẹ̀.+ 20  “‘Ìwọ kò sì gbọ́dọ̀ fi ohun tí ó dà jáde lára rẹ tí ó jẹ́ àtọ̀ fún aya ẹlẹgbẹ́ rẹ láti di aláìmọ́ nípasẹ̀ rẹ̀.+ 21  “‘Ìwọ kò sì gbọ́dọ̀ yọ̀ǹda fún yíya èyíkéyìí nínú àwọn ọmọ rẹ sọ́tọ̀+ fún Mólékì.+ Ìwọ kò gbọ́dọ̀ sọ orúkọ Ọlọ́run rẹ di aláìmọ́+ nípa bẹ́ẹ̀. Èmi ni Jèhófà.+ 22  “‘Ìwọ kò gbọ́dọ̀ sùn ti ọkùnrin+ bí ìwọ yóò ṣe sùn ti obìnrin.+ Ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí ni. 23  “‘Ìwọ kò sì gbọ́dọ̀ fi ohun tí ó dà jáde lára rẹ tí ó jẹ́ àtọ̀ fún ẹranko+ èyíkéyìí láti di aláìmọ́ nípasẹ̀ rẹ̀, obìnrin kò sì gbọ́dọ̀ dúró níwájú ẹranko láti ní ìdàpọ̀ pẹ̀lú rẹ̀.+ Rírú ìlànà ohun tí ó bá ìwà ẹ̀dá mu ni. 24  “‘Ẹ má ṣe sọ ara yín di aláìmọ́ nípa èyíkéyìí nínú nǹkan wọ̀nyí, nítorí pé nípa gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni àwọn orílẹ̀-èdè tí èmi yóò rán kúrò níwájú yín fi sọ ara wọn di aláìmọ́.+ 25  Nítorí náà, ilẹ̀ náà jẹ́ aláìmọ́, èmi yóò sì mú ìyà wá sórí rẹ̀ nítorí ìṣìnà rẹ̀, ilẹ̀ náà yóò sì pọ àwọn olùgbé rẹ̀ jáde.+ 26  Kí ẹ̀yin fúnra yín sì pa àwọn ìlànà àgbékalẹ̀ mi àti àwọn ìpinnu ìdájọ́ mi mọ́,+ kí ẹ má sì ṣe èyíkéyìí nínú gbogbo ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí wọ̀nyí, yálà ọmọ ìbílẹ̀ tàbí àtìpó tí ń ṣe àtìpó ní àárín yín.+ 27  Nítorí gbogbo ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí wọ̀nyí ni àwọn ènìyàn tí wọ́n ti wà ṣáájú yín nínú ilẹ̀ náà ti ṣe,+ tí ilẹ̀ náà fi jẹ́ aláìmọ́. 28  Nígbà náà, ilẹ̀ náà kì yóò pọ̀ yín jáde nítorí sísọ tí ẹ sọ ọ́ di ẹlẹ́gbin ní ọ̀nà kan náà tí yóò gbà pọ àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti wà ṣáájú yín jáde.+ 29  Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ẹnikẹ́ni ṣe èyíkéyìí nínú gbogbo ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí wọ̀nyí, nígbà náà, kí a ké àwọn ọkàn tí ó ṣe wọ́n kúrò láàárín àwọn ènìyàn wọn.+ 30  Kí ẹ sì pa iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe yín sí mi mọ́ láti má ṣe èyíkéyìí nínú àwọn àṣà ìṣe-họ́ọ̀-sí tí a ti ṣe ṣáájú yín,+ kí ẹ má bàa sọ ara yín di aláìmọ́ nípasẹ̀ wọn. Èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín.’”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé