Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Léfítíkù 17:1-16

17  Jèhófà sì ń bá a lọ láti bá Mósè sọ̀rọ̀, pé:  “Bá Áárónì àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ àti gbogbo ọmọ Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀, kí o sì wí fún wọn pé, ‘Èyí ni ohun tí Jèhófà pa láṣẹ, pé:  “‘“Ní ti ọkùnrin èyíkéyìí ní ilé Ísírẹ́lì tí ó bá pa akọ màlúù tàbí ẹgbọrọ àgbò tàbí ewúrẹ́ nínú ibùdó tàbí tí ó bá pa á ní òde ibùdó  tí kò sì mú un wá sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé+ ní ti gidi láti mú un wá gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ fún Jèhófà níwájú àgọ́ ìjọsìn Jèhófà, ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ ni kí a kà sí ọkùnrin yẹn lọ́rùn. Ó ti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀, ọkùnrin náà ni kí a ké kúrò láàárín àwọn ènìyàn rẹ̀,+  kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bàa lè mú ẹbọ wọn wá, èyí tí wọ́n ń rú nínú pápá gbalasa,+ kí wọ́n sì mú wọn wá fún Jèhófà ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé, sọ́dọ̀ àlùfáà,+ kí wọ́n sì fi ìwọ̀nyí rúbọ gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ìdàpọ̀ sí Jèhófà.+  Kí àlùfáà sì wọ́n ẹ̀jẹ̀ náà sórí pẹpẹ+ Jèhófà ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé, kí ó sì mú ọ̀rá+ náà rú èéfín gẹ́gẹ́ bí òórùn amáratuni sí Jèhófà.+  Nítorí náà, kí wọ́n má ṣe rú ẹbọ wọn mọ́ sí ẹ̀mí èṣù onírìísí ewúrẹ́,+ èyí tí wọn ń bá ní ìbádàpọ̀ oníṣekúṣe.+ Èyí yóò jẹ́ ìlànà àgbékalẹ̀ fún yín fún àkókò tí ó lọ kánrin, jálẹ̀ ìran-ìran yín.”’  “Kí o sì sọ fún wọn pé, ‘Ní ti ọkùnrin èyíkéyìí ní ilé Ísírẹ́lì tàbí àtìpó kan tí ó lè máa ṣe àtìpó ní àárín yín tí ó bá rú ọrẹ ẹbọ sísun+ tàbí ẹbọ,  tí kò sì mú un wá sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé láti fi í rúbọ sí Jèhófà,+ ọkùnrin náà ni kí a ké kúrò nínú àwọn ènìyàn rẹ̀.+ 10  “‘Ní ti ọkùnrin èyíkéyìí ní ilé Ísírẹ́lì tàbí àtìpó kan tí ń ṣe àtìpó ní àárín yín tí ó bá jẹ ẹ̀jẹ̀+ èyíkéyìí, dájúdájú, èmi yóò dojú mi kọ ọkàn+ tí ó bá jẹ ẹ̀jẹ̀, ní tòótọ́, èmi yóò sì ké e kúrò láàárín àwọn ènìyàn rẹ̀. 11  Nítorí ọkàn ara ń bẹ nínú ẹ̀jẹ̀,+ èmi tìkára mi sì ti fi sórí pẹpẹ fún yín láti ṣe ètùtù+ fún ọkàn yín, nítorí pé ẹ̀jẹ̀+ ni ó ń ṣe ètùtù+ nípasẹ̀ ọkàn tí ń bẹ nínú rẹ̀. 12  Ìdí nìyẹn tí mo fi sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Ọkàn kankan lára yín kò gbọ́dọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀, àtìpó kankan tí ń ṣe àtìpó ní àárín+ yín kò sì gbọ́dọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀.”+ 13  “‘Ní ti ọkùnrin èyíkéyìí lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tàbí àtìpó kan tí ń ṣe àtìpó ní àárín yín, ẹni tí ó jẹ́ pé nígbà tí ó ń ṣọdẹ, ó mú ẹranko ìgbẹ́ tàbí ẹ̀dá abìyẹ́ tí a lè jẹ, bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, kí ó da ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ jáde,+ kí ó sì fi ekuru bò ó.+ 14  Nítorí ọkàn gbogbo onírúurú ẹran ara ni ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ nípasẹ̀ ọkàn tí ń bẹ nínú rẹ̀. Nítorí náà, mo wí fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Ẹ kò gbọ́dọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀ ẹran ara èyíkéyìí, nítorí pé ọkàn gbogbo onírúurú ẹran ara ni ẹ̀jẹ̀ rẹ̀.+ Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ ẹ́ ni a óò ké kúrò.”+ 15  Ní ti ọkàn èyíkéyìí tí ó jẹ òkú ẹran tàbí ohun kan tí ẹranko ẹhànnà fà ya,+ yálà ọmọ ìbílẹ̀ tàbí àtìpó, bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, kí ó fọ ẹ̀wù rẹ̀, kí ó sì wẹ̀ nínú omi, kí ó sì jẹ́ aláìmọ́ títí di alẹ́;+ kí ó sì mọ́. 16  Ṣùgbọ́n bí òun kò bá ní fọ̀ wọ́n, tí kò sì ní wẹ̀ ara rẹ̀, nígbà náà, kí ó dáhùn fún ìṣìnà rẹ̀.’”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé