Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Léfítíkù 16:1-34

16  Jèhófà sì tẹ̀ síwájú láti bá Mósè sọ̀rọ̀ lẹ́yìn ikú àwọn ọmọkùnrin Áárónì méjì nítorí sísún tí wọ́n sún mọ́ iwájú Jèhófà tí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ kú.+  Jèhófà sì tẹ̀ síwájú láti wí fún Mósè pé: “Bá Áárónì arákùnrin rẹ sọ̀rọ̀, pé kí ó má ṣe máa wá nígbà gbogbo sínú ibi mímọ́+ sínú aṣọ ìkélé,+ ní iwájú ìbòrí tí ó wà lórí Àpótí, kí ó má bàa kú;+ nítorí pé nínú àwọsánmà+ ni èmi yóò fara hàn lórí ìbòrí náà.+  “Kí Áárónì wá sínú ibi mímọ́+ pẹ̀lú àwọn ohun tí ó tẹ̀ lé e yìí: ọmọ akọ màlúù fún ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀+ àti àgbò fún ọrẹ ẹbọ sísun.+  Kí ó wọ aṣọ mímọ́ tí a fi ọ̀gbọ̀ ṣe,+ kí ó sì wọ ṣòkòtò àwọ̀tẹ́lẹ̀ tí a fi ọ̀gbọ̀ ṣe,+ kí ó sì fi ìgbàjá ọ̀gbọ̀+ di ara rẹ̀ lámùrè, kí ó sì fi láwàní ọ̀gbọ̀+ wé orí rẹ̀. Ẹ̀wù mímọ́ ni wọ́n.+ Kí ó sì wẹ ara rẹ nínú omi,+ kí ó sì gbé wọn wọ̀.  “Kí ó sì gba akọ ọmọ ewúrẹ́ méjì lọ́wọ́ àpéjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì+ fún ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀+ àti àgbò kan fún ọrẹ ẹbọ sísun.+  “Kí Áárónì sì mú akọ màlúù ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ wá, èyí tí ó jẹ́ tirẹ̀,+ kí ó sì ṣe ètùtù+ nítorí ara rẹ̀+ àti ilé  rẹ̀.+  “Kí ó sì mú ewúrẹ́ méjèèjì náà, kí ó sì mú wọn dúró síwájú Jèhófà ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé.  Kí Áárónì sì ṣẹ́ kèké+ lórí ewúrẹ́ méjèèjì , kèké kan fún Jèhófà àti kèké kejì fún Ásásélì.+  Ewúrẹ́ tí kèké+ yàn fún Jèhófà ni kí Áárónì sì mú wá, kí ó sì fi í ṣe ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀.+ 10  Ṣùgbọ́n ewúrẹ́ tí kèké yàn fún Ásásélì ni kí a mú dúró láàyè níwájú Jèhófà láti ṣe ètùtù fún un, láti rán+ an lọ sínú aginjù+ fún Ásásélì. 11  “Kí Áárónì sì mú akọ màlúù ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ wá, èyí tí ó jẹ́ tirẹ̀, kí ó sì ṣe ètùtù nítorí ara rẹ̀ àti ilé rẹ̀; kí ó sì pa akọ màlúù ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, èyí tí ó jẹ́ tirẹ̀.+ 12  “Kí ó sì mú ìkóná+ tí ó kún fún ẹyín iná tí ń jó láti orí pẹpẹ+ níwájú Jèhófà, kí ìtẹkòtò ọwọ́+ rẹ̀ méjèèjì sì kún fún àtàtà tùràrí onílọ́fínńdà,+ kí ó sì mú wọn wá sínú aṣọ ìkélé.+ 13  Kí ó sì fi tùràrí sínú iná níwájú Jèhófà,+ kí ìṣúdùdù èéfín tùràrí sì bo ìbòrí Àpótí,+ tí ó wà lórí Gbólóhùn Ẹ̀rí,+ kí ó má bàa kú. 14  “Kí ó sì mú lára ẹ̀jẹ̀+ akọ màlúù náà, kí ó sì fi ìka rẹ̀ wọ́n ọn ṣẹ̀rẹ̀ṣẹ̀rẹ̀ ní iwájú ìbòrí náà ní ìhà ìlà-oòrùn, yóò sì fi ìka rẹ̀ wọ́n lára ẹ̀jẹ̀ náà ṣẹ̀rẹ̀ṣẹ̀rẹ̀+ ní ìgbà méje níwájú ìbòrí náà.+ 15  “Kí ó sì pa ewúrẹ́ ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, tí ó jẹ́ ti àwọn ènìyàn,+ kí ó sì mú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wá sínú aṣọ ìkélé,+ kí ó sì fi ẹ̀jẹ̀+ rẹ̀ ṣe ohun kan náà tí ó fi ẹ̀jẹ̀ akọ màlúù náà ṣe; kí ó sì wọ́n ọn ṣẹ̀rẹ̀ṣẹ̀rẹ̀ síhà ìbòrí náà àti níwájú ìbòrí náà. 16  “Kí ó sì ṣe ètùtù fún ibi mímọ́ nítorí àìmọ́+ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àti nítorí ìdìtẹ̀ wọn nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wọn;+ bẹ́ẹ̀ ni kí ó sì ṣe fún àgọ́ ìpàdé, èyí tí ó wà pẹ̀lú wọn nínú àìmọ́ wọn. 17  “Kí ó má sì sí ẹnì kankan nínú àgọ́ ìpàdé nígbà tí ó bá wọlé láti ṣe ètùtù ní ibi mímọ́ títí yóò fi jáde; kí ó sì ṣe ètùtù nítorí ara rẹ̀+ àti nítorí ilé rẹ̀ àti nítorí gbogbo ìjọ Ísírẹ́lì pátá.+ 18  “Kí ó sì jáde wá sí ibi pẹpẹ,+ tí ó wà níwájú Jèhófà, kí ó sì ṣe ètùtù fún un, kí ó sì mú lára ẹ̀jẹ̀ akọ màlúù náà àti lára ẹ̀jẹ̀ ewúrẹ́ náà, kí ó sì fi í sára àwọn ìwo pẹpẹ yíká-yíká.+ 19  Kí ó tún fi ìka rẹ̀ wọ́n lára ẹ̀jẹ̀ náà ṣẹ̀rẹ̀ṣẹ̀rẹ̀+ sára rẹ̀ ní ìgbà méje, kí ó sì wẹ̀ ẹ́ mọ́, kí ó sì sọ ọ́ di mímọ́ kúrò nínú àìmọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. 20  “Nígbà tí ó bá párí ṣíṣe ètùtù+ fún ibi mímọ́ àti àgọ́ ìpàdé àti pẹpẹ, kí ó mú ààyè ewúrẹ́ náà wá pẹ̀lú.+ 21  Kí Áárónì sì gbé ọwọ́+ rẹ̀ méjèèjì lé orí ààyè ewúrẹ́ náà, kí ó sì jẹ́wọ́+ gbogbo ìṣìnà+ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àti gbogbo ìdìtẹ̀ wọn nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀+ wọn sórí rẹ̀, kí ó sì fi wọ́n lé orí ewúrẹ́+ náà, kí ó sì rán an lọ sínú aginjù+ nípa ọwọ́ ọkùnrin+ kan tí ó ti múra tán. 22  Kí ewúrẹ́ náà sì fi orí ara rẹ̀ ru gbogbo ìṣìnà+ wọn lọ sí ilẹ̀ aṣálẹ̀,+ kí ó sì rán ewúrẹ́ náà lọ sínú aginjù.+ 23  “Kí Áárónì sì wá sínú àgọ́ ìpàdé, kí ó sì bọ́ ẹ̀wù ọ̀gbọ̀ tí ó wọ̀ nígbà tí ó wọ ibi mímọ́, kí ó sì kó wọn lélẹ̀ níbẹ̀.+ 24  Kí ó sì wẹ ara rẹ̀ nínú omi+ ní ibi mímọ́,+ kí ó sì gbé ẹ̀wù+ rẹ̀ wọ̀, kí ó sì jáde, kí ó sì rú ọrẹ ẹbọ sísun+ rẹ̀ àti ọrẹ ẹbọ sísun+ àwọn ènìyàn náà, kí ó sì ṣe ètùtù nítorí ara rẹ̀ àti nítorí àwọn ènìyàn náà.+ 25  Òun yóò sì mú ọ̀rá ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ rú èéfín lórí pẹpẹ.+ 26  “Ní ti ẹni+ tí ó rán ewúrẹ́ lọ fún Ásásélì,+ kí ó fọ ẹ̀wù rẹ̀, kí ó sì wẹ ara rẹ̀ nínú omi,+ lẹ́yìn ìyẹn ó lè wá sínú ibùdó. 27  “Bí ó ti wù kí ó rí, akọ màlúù ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti ewúrẹ́ ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, tí a mú ẹ̀jẹ̀ wọn wọlé wá láti fi ṣe ètùtù ní ibi mímọ́, ni yóò mú kí a gbé jáde sí òde ibùdó; kí wọ́n sì fi iná sun+ awọ wọn àti ẹran wọn àti imí wọn. 28  Kí ẹni tí ó sì fi iná sun wọ́n fọ ẹ̀wù rẹ̀, kí ó sì wẹ ara rẹ̀ nínú omi, lẹ́yìn ìyẹn ó lè wá sínú ibùdó. 29  “Kí ó sì jẹ́ ìlànà àgbékalẹ̀ fún yín fún àkókò tí ó lọ kánrin:+ Ní oṣù keje ní ọjọ́ kẹwàá oṣù,+ kí ẹ ṣẹ́ ọkàn yín níṣẹ̀ẹ́,+ ẹ kò sì gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ èyíkéyìí,+ yálà ọmọ ìbílẹ̀ tàbí àtìpó tí ń ṣe àtìpó ní àárín yín. 30  Nítorí ní ọjọ́ yìí ni a ó ṣe ètùtù+ fún yín láti pè yín ní ẹni tí ó mọ́. Ẹ óò mọ́ kúrò nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ yín níwájú Jèhófà.+ 31  Sábáàtì+ ìsinmi pátápátá ni fún yín, kí ẹ sì ṣẹ́ ọkàn yín níṣẹ̀ẹ́. Ìlànà àgbékalẹ̀ fún àkókò tí ó lọ kánrin ni. 32  “Kí àlùfáà tí a ó fòróró yàn,+ tí a ó sì fi agbára kún ọwọ́ rẹ̀ láti ṣe àlùfáà+ gẹ́gẹ́ bí arọ́pò+ baba rẹ̀ sì ṣe ètùtù, kí ó sì gbé ẹ̀wù ọ̀gbọ̀ wọ̀.+ Ẹ̀wù mímọ́ ni wọ́n.+ 33  Kí ó sì ṣe ètùtù fún ibùjọsìn mímọ́,+ yóò sì ṣe ètùtù fún àgọ́+ ìpàdé àti fún pẹpẹ;+ yóò sì ṣe ètùtù+ fún àwọn àlùfáà àti fún gbogbo ènìyàn ìjọ náà. 34  Kí èyí sì jẹ́ ìlànà àgbékalẹ̀ fún yín fún àkókò tí ó lọ kánrin,+ láti ṣe ètùtù fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lẹ́ẹ̀kan lọ́dún nítorí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wọn.”+ Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ó ṣé gan-an gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti pàṣẹ fún Mósè.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé