Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Léfítíkù 15:1-33

15  Jèhófà sì ń bá a lọ láti bá Mósè àti Áárónì sọ̀rọ̀, pé:  “Ẹ bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀, kí ẹ sì wí fún wọn pé, ‘Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ẹnikẹ́ni ní àsunjáde láti ẹ̀yà ara ìbímọ rẹ̀, àsunjáde rẹ̀ jẹ́ aláìmọ́.  Èyí ni yóò sì di àìmọ́ rẹ̀ nípasẹ̀ àsunjáde+ rẹ̀: Yálà ẹ̀yà ara ìbímọ rẹ̀ sun àsunjáde tàbí a dènà ẹ̀yà ara ìbímọ rẹ̀ kí ó má ṣe sun àsunjáde rẹ̀, àìmọ́ rẹ̀ ni.  “‘Ibùsùn èyíkéyìí tí ẹni tí ó ní àsunjáde bá dùbúlẹ̀ lé yóò di aláìmọ́, ohun èlò èyíkéyìí tí ó bá sì jókòó lé yóò di aláìmọ́.  Ẹni tí ó bá sì fara kan ibùsùn rẹ̀, kí ó fọ ẹ̀wù rẹ̀, kí ó sì wẹ̀ nínú omi, kí ó sì jẹ́ aláìmọ́ títí di alẹ́.+  Ẹnì yòówù tí ó bá sì jókòó lórí ohun èlò tí ẹni tí ó ní àsunjáde ti jókòó lé, kí ó fọ+ ẹ̀wù rẹ̀, kí ó sì wẹ̀ nínú omi, kí ó sì jẹ́ aláìmọ́ títí di alẹ́.  Ẹnì yóòwù tí ó bá sì fara kan ara ẹni tí ó ní àsunjáde,+ kí ó fọ ẹ̀wù rẹ̀, kí ó sì wẹ̀ nínú omi, kí ó sì jẹ́ aláìmọ́ títí di alẹ́.+  Bí ó bá sì ṣẹlẹ̀ pé ẹni tí ó ní àsunjáde tutọ́ sára ẹni tí ó mọ́, kí ó sì fọ ẹ̀wù rẹ̀, kí ó sì wẹ̀ nínú omi, kí ó sì jẹ́ aláìmọ́ títí di alẹ́.  Gàárì+ èyíkéyìí tí ẹni tí ó ní àsunjáde ba ti gùn lé yóò jẹ́ aláìmọ́. 10  Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì fara kan ohunkóhun tí ó bá wà lábẹ́ rẹ̀ yóò jẹ́ aláìmọ́ títí di alẹ́; ẹni tí ó bà sì gbé wọn yóò fọ ẹ̀wù rẹ̀, kí ó sì wẹ̀ nínú omi, kí ó sì jẹ́ aláìmọ́ títí di alẹ́. 11  Ẹnikẹ́ni tí ẹni tí ó ní àsunjáde+ bá sì fara kàn nígbà tí kò tíì ṣan ọwọ́ rẹ̀ nínú omi, kí ó fọ ẹ̀wù rẹ̀, kí ó sì wẹ̀ nínú omi, kí ó sì jẹ́ aláìmọ́ títí di alẹ́. 12  Ohun èlò amọ̀ tí ẹni tí ó ní àsunjáde bá sì fara kàn ni kí a fọ́ túútúú;+ ohun èlò èyíkéyìí tí a sì fi igi ṣe+ ni kí a fi omi ṣàn. 13  “‘Wàyí ó, bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ẹni tí ó ní àsunjáde yóò mọ́ kúrò nínú àsunjáde rẹ̀, nígbà náà, kí ó ka ọjọ́ méje fún ara rẹ̀ fún ìwẹ̀mọ́gaara+ rẹ̀, kí ó sì fọ ẹ̀wù rẹ̀, kí ó sì wẹ ara rẹ̀ nínú omi;+ kí ó sì mọ́. 14  Ní ọjọ́ kẹjọ kí ó sì mú oriri méjì + tàbí ọmọ ẹyẹlé méjì fún ara rẹ̀, kí ó sì wá síwájú Jèhófà, sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé, kí ó sì fi wọ́n fún àlùfáà. 15  Kí àlùfáà sì fi wọ́n rúbọ, ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti èkejì gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ sísun;+ kí àlùfáà sì ṣe ètùtù fún un níwájú Jèhófà nítorí àsunjáde rẹ̀. 16  “‘Wàyí o, bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ọkùnrin kan da àtọ̀+ láti ara rẹ̀, nígbà náà, kí ó wẹ gbogbo ara rẹ̀ nínú omi, kí ó sì jẹ́ aláìmọ́ títí di alẹ́. 17  Ẹ̀wù èyíkéyìí àti awọ èyíkéyìí tí àtọ̀ bá dà sí ni kí a fi omi fọ̀, kí ó sì di aláìmọ́ títí di alẹ́.+ 18  “‘Ní ti obìnrin kan tí ọkùnrin kan sùn tì, tí àtọ̀ sì dà jáde, kí wọ́n wẹ̀ nínú omi, kí wọ́n sì jẹ́ aláìmọ́+ títí di alẹ́. 19  “‘Bí ó bá sì ṣẹlẹ̀ pé obìnrin kan ní àsunjáde, tí àsunjáde rẹ̀ ní ara rẹ̀ sì jẹ́ ẹ̀jẹ̀,+ kí ó máa bá a lọ fún ọjọ́ méje nínú ohun ìdọ̀tí+ nǹkan oṣù+ rẹ̀, ẹnikẹ́ni tí ó bá sì fara kàn án yóò jẹ́ aláìmọ́ títí di alẹ́. 20  Ohunkóhun tí ó bá sì dùbúlẹ̀ lé nígbà ohun ìdọ̀tí nǹkan oṣù rẹ̀ yóò jẹ́ aláìmọ́,+ ohun gbogbo tí ó bá sì jókòó lé yóò jẹ́ aláìmọ́. 21  Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì fara kan ibùsùn rẹ̀, kí ó fọ ẹ̀wù rẹ̀, kí ó sì wẹ̀ nínú omi, kí ó sì jẹ́ aláìmọ́ títí di alẹ́.+ 22  Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì fara kan ohun èlò èyíkéyìí tí obìnrin náà jókòó lé, kí ó fọ ẹ̀wù rẹ̀, kí ó sì wẹ̀ nínú omi, kí ó sì jẹ́ aláìmọ́ títí di alẹ́.+ 23  Bí ó bá sì jẹ́ orí ibùsùn tàbí ohun èlò mìíràn ni obìnrin náà jókòó lé, nítorí tí ẹnì náà fara kan+ nǹkan yẹn, ẹni náà yóò jẹ́ aláìmọ́ títí di alẹ́. 24  Bí ọkùnrin kan bá sì sùn tì í pẹ́nrẹ́n, tí ohun ìdọ̀tí nǹkan oṣù rẹ̀ sì wá wà lára ọkùnrin náà,+ nígbà náà, kí ọkùnrin náà jẹ́ aláìmọ́ fún ọjọ́ méje, ibùsùn èyíkéyìí tí ọkùnrin náà bá sì dùbúlẹ̀ lé yóò jẹ́ aláìmọ́. 25  “‘Ní ti obìnrin kan, bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé àsunjáde ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ ń ṣàn fún ọ̀pọ̀ ọjọ́+ nígbà tí kì í ṣe àkókò tí ó máa ń rí ohun ìdọ̀tí nǹkan oṣù+ rẹ̀, tàbí bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ìsun rẹ̀ sun pẹ́ ju ohun ìdọ̀tí nǹkan oṣù rẹ̀ lọ, gbogbo ọjọ́ àsunjáde àìmọ́ rẹ̀ yóò jẹ́ gẹ́gẹ́ bí ti ọjọ́ ohun ìdọ̀tí nǹkan oṣù rẹ̀. Ó jẹ́ aláìmọ́. 26  Ibùsùn èyíkéyìí tí ó bá dùbúlẹ̀ lé ní èyíkéyìí nínú àwọn ọjọ́ àsunjáde rẹ̀ yóò dà bí ti ibùsùn ohun ìdọ̀tí nǹkan oṣù+ rẹ̀, ohun èlò èyíkéyìí tí ó bá sì jókòó lé yóò di aláìmọ́ bí àìmọ́ ti ohun ìdọ̀tí nǹkan oṣù rẹ̀. 27  Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì fara kàn+ wọ́n yóò jẹ́ aláìmọ́, kí ó sì fọ ẹ̀wù rẹ̀, kí ó sì wẹ̀ nínú omi, kí ó sì jẹ́ aláìmọ́ títí di alẹ́. 28  “‘Àmọ́ ṣá o, bí obìnrin náà bá mọ́ kúrò nínú àsunjáde rẹ̀, kí ó ka ọjọ́ méje fún ara rẹ̀, lẹ́yìn ìgbà náà, òun yóò mọ́.+ 29  Ní ọjọ́ kẹjọ ni kí ó sì mú oriri méjì + tàbí ọmọ ẹyẹlé méjì fún ara rẹ̀, kí ó sì mú wọn wá fún àlùfáà ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé.+ 30  Kí àlùfáà sì fi ọ̀kan ṣe ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti èkejì ṣe ọrẹ ẹbọ sísun;+ kí àlùfáà sì ṣe ètùtù+ fún un níwájú Jèhófà nítorí àsunjáde àìmọ́ rẹ̀. 31  “‘Kí ẹ sì ya àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ́tọ̀ kúrò nínú àìmọ́ wọn, kí wọ́n má bàa kú nínú àìmọ́ wọn fún sísọ tí wọ́n sọ àgọ́ ìjọsìn mi di ẹlẹ́gbin, èyí tí ó wà ní àárín wọn.+ 32  “‘Èyí ni òfin nípa ọkùnrin tí ó ní àsunjáde+ àti ọkùnrin tí àtọ̀ dà+ lára rẹ̀ tí ó sì di aláìmọ́ nípasẹ̀ rẹ̀; 33  àti obìnrin tí ń ṣe nǹkan oṣù+ nínú àìmọ́ rẹ̀, àti ẹnikẹ́ni tí ó ní ìsun àsunjáde rẹ̀,+ yálà ó jẹ́ akọ tàbí abo, àti yálà ọkùnrin tí ó sùn ti aláìmọ́ obìnrin.’”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé