Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Léfítíkù 14:1-57

14  Jèhófà sì ń bá a lọ láti bá Mósè sọ̀rọ̀, pé:  “Èyí ni yóò di òfin adẹ́tẹ̀+ ní ọjọ́ tí a bá fi ìdí ìwẹ̀mọ́gaara rẹ̀ múlẹ̀, nígbà tí a bá mú un wá sọ́dọ̀ àlùfáà.+  Kí àlùfáà sì jáde lọ sí òde ibùdó, kí àlùfáà sì wò ó; bí a bá sì ti wo àrùn ẹ̀tẹ̀ sàn+ lára adẹ́tẹ̀ náà,  nígbà náà, kí àlùfáà pa àṣẹ; kí ó sì mú ààyè ẹyẹ+ méjì  tí ó mọ́ àti igi kédárì+ àti òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò ti kòkòrò kókọ́sì+ àti hísópù+ fún wíwẹ ara rẹ̀ mọ́.  Kí àlùfáà sì pa àṣẹ, kí a sì pa ẹyẹ kan lórí omi tí ó ṣeé mu+ tí ó wà nínú ohun èlò amọ̀.  Ní ti ààyè ẹyẹ náà, kí ó mú un àti igi kédárì àti òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò ti kòkòrò kókọ́sì àti ewéko hísópù, kí ó sì tẹ àwọn àti ààyè ẹyẹ náà bọ ẹ̀jẹ̀ ẹyẹ tí a pa lórí omi.  Nígbà náà ni kí ó wọ́n ọn ṣẹ̀rẹ̀ṣẹ̀rẹ̀+ ní ìgbà méje+ sára ẹni tí ń wẹ ara rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ẹ̀tẹ̀, kí ó sì pè é ní ẹni tí ó mọ́,+ kí ó sì rán ààyè ẹyẹ náà lọ lórí pápá gbalasa.+  “Kí ẹni náà tí ń wẹ ara rẹ̀ mọ́ sì fọ ẹ̀wù rẹ̀,+ kí ó sì fá gbogbo irun rẹ̀, kí ó sì wẹ̀+ nínú omi, kí ó sì mọ́, lẹ́yìn ìgbà náà, ó lè wá sínú ibùdó. Kí ó sì gbé òde àgọ́ rẹ̀ fún ọjọ́ méje.+  Kí ó sì ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ keje pé kí ó fá gbogbo irun rẹ̀ tí ó wà ní orí rẹ̀+ àti àgbọ̀n rẹ̀ àti ìgbéǹgbéréjú rẹ̀ kúrò. Bẹ́ẹ̀ ni, kí ó fá gbogbo irun rẹ̀ kúrò, kí ó sì fọ ẹ̀wù rẹ̀, kí ó sì wẹ̀ ara rẹ̀ nínú omi; kí ó sì mọ́. 10  “Ní ọjọ́ kẹjọ+ kí ó mú ẹgbọrọ àgbò méjì  tí ara wọn dá ṣáṣá àti abo ọ̀dọ́ àgùntàn+ kan tí ara rẹ̀ dá ṣáṣá, tí ó wà ní ọdún rẹ̀ àkọ́kọ́, àti ìdá mẹ́ta nínú mẹ́wàá òṣùwọ̀n eéfà ìyẹ̀fun kíkúnná gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ ọkà+ tí a fi òróró rin fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́ àti òróró òṣùwọ̀n lọ́ọ̀gì kan;+ 11  kí àlùfáà tí ó pè é ní ẹni tí ó mọ́ mú ẹni tí ń wẹ ara rẹ̀ mọ́ náà, àti àwọn ohun náà, wá síwájú Jèhófà ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé. 12  Kí àlùfáà sì mú ẹgbọrọ àgbò kan, kí ó sì fi í rú ọrẹ ẹbọ ẹ̀bi+ pa pọ̀ pẹ̀lú òróró òṣùwọ̀n lọ́ọ̀gì+ náà, kí ó sì fì wọ́n síwá-sẹ́yìn gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ fífì+ níwájú Jèhófà. 13  Kí ó sì pa ẹgbọrọ àgbò náà ní ibi+ tí a ti ń pa ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti ọrẹ ẹbọ sísun déédéé, ní ibi mímọ́,+ nítorí pé, gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, ọrẹ ẹbọ ẹ̀bi jẹ́ ti àlùfáà.+ Ohun mímọ́ jù lọ ni. 14  “Kí àlùfáà sì mú lára ẹ̀jẹ̀ ọrẹ ẹbọ ẹ̀bi, kí àlùfáà sì fi í sí ìsàlẹ̀ etí ọ̀tún ẹni tí ń wẹ ara rẹ̀ mọ́ náà àti sí àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ àti sí àtàǹpàkò ẹsẹ̀ ọ̀tún rẹ̀.+ 15  Kí àlùfáà sì mú lára òróró òṣùwọ̀n lọ́ọ̀gì+ náà, kí ó sì dà á sí àtẹ́lẹwọ́ òsì àlùfáà. 16  Kí àlùfáà sì tẹ ìka ọ̀tún rẹ̀ bọ òróró tí ó wà ní àtẹ́lẹwọ́ òsì rẹ̀, kí ó sì fi ìka rẹ̀ wọ́n lára òróró náà ṣẹ̀rẹ̀ṣẹ̀rẹ̀ ní ìgbà méje+ níwájú Jèhófà. 17  Kí àlùfáà sì fi lára ìyókù òróró tí ó wà ní àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀ sí ìsàlẹ̀ etí ọ̀tún ẹni náà tí ń wẹ ara rẹ̀ mọ́ àti sí àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ àti sí àtàǹpàkò ẹsẹ̀ ọ̀tún rẹ̀ lórí ẹ̀jẹ̀ ọrẹ ẹbọ ẹ̀bi.+ 18  Ohun tí ó sì ṣẹ́ kù lára òróró tí ó wà ní àtẹ́lẹwọ́ àlùfáà ni yóò fi sí orí ẹni náà tí ń wẹ ara rẹ̀ mọ́, kí àlùfáà sì ṣe ètùtù+ fún un níwájú Jèhófà. 19  “Kí àlùfáà sì rú ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀,+ kí ó sì ṣe ètùtù fún ẹni náà tí ń wẹ ara rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ohun ìdọ̀tí rẹ̀, lẹ́yìn ìgbà náà, òun yóò pa ọrẹ ẹbọ sísun. 20  Kí àlùfáà sì rú ọrẹ ẹbọ sísun àti ọrẹ ẹbọ ọkà+ lórí pẹpẹ, kí àlùfáà+ sì ṣe ètùtù fún un;+ kí ó sì mọ́.+ 21  “Àmọ́ ṣá o, bí ó bá jẹ ẹni rírẹlẹ̀+ tí kò sì ní lọ́wọ́ tó bẹ́ẹ̀,+ nígbà náà, kí ó mú ẹgbọrọ àgbò gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ ẹ̀bi fún ọrẹ ẹbọ fífì láti ṣe ètùtù fún un àti ìdá mẹ́wàá òṣùwọ̀n eéfà ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi òróró rin fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ ọkà àti òróró òṣùwọ̀n lọ́ọ̀gì kan, 22  àti oriri méjì + tàbí ọmọ ẹyẹlé méjì , gẹ́gẹ́ bí ó ṣe ní lọ́wọ́ sí, kí ọ̀kan sì jẹ́ ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, kí èkejì  sì jẹ́ ọrẹ ẹbọ sísun. 23  Ní ọjọ́ kẹjọ,+ kí ó mú wọn wá sọ́dọ̀ àlùfáà láti fi ìdí ìwẹ̀mọ́gaara+ rẹ̀ múlẹ̀ ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé+ níwájú Jèhófà. 24  “Kí àlùfáà sì mú ẹgbọrọ àgbò ọrẹ ẹbọ ẹ̀bi+ àti òróró òṣùwọ̀n lọ́ọ̀gì náà, kí àlùfáà sì fì wọ́n síwá-sẹ́yìn gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ fífì níwájú Jèhófà.+ 25  Kí ó sì pa ẹgbọrọ àgbò ọrẹ ẹbọ ẹ̀bi náà, kí àlùfáà sì mú lára ẹ̀jẹ̀ ọrẹ ẹbọ ẹ̀bi, kí ó sì fi í sí ìsàlẹ̀ etí ọ̀tún ẹni náà tí ń wẹ ara rẹ̀ mọ́ àti sí àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ àti sí àtàǹpàkò ẹsẹ̀ ọ̀tún rẹ̀.+ 26  Kí àlùfáà sì dà lára òróró náà sí àtẹ́lẹwọ́ òsì+ àlùfáà. 27  Kí àlùfáà sì fi ìka ọ̀tún rẹ̀ wọ́n lára òróró tí ó wà ní àtẹ́lẹwọ́ òsì rẹ̀ ṣẹ̀rẹ̀ṣẹ̀rẹ̀+ ní ìgbà méje níwájú Jèhófà. 28  Kí àlùfáà sì fi lára òróró tí ó wà ní àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀ sí ìsàlẹ̀ etí ọ̀tún ẹni náà tí ń wẹ ara rẹ̀ mọ́ àti sí àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ àti sí àtàǹpàkò ẹsẹ̀ ọ̀tún rẹ̀ lórí ibi ẹ̀jẹ̀ ọrẹ ẹbọ ẹ̀bi.+ 29  Ohun tí ó sì ṣẹ́ kù lára òróró tí ó wà ní àtẹ́lẹwọ́ àlùfáà ni yóò fi sí orí+ ẹni náà tí ń wẹ ara rẹ̀ mọ́ láti ṣe ètùtù fún un níwájú Jèhófà. 30  “Kí ó sì fi ọ̀kan lára àwọn oriri náà rúbọ tàbí lára àwọn ọmọ ẹyẹlé èyí tí ọwọ́ rẹ̀ bá ká,+ 31  ọ̀kan lára wọn tí ọwọ́ rẹ̀ bá ká gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀+ àti èkejì  gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ sísun+ pa pọ̀ pẹ̀lú ọrẹ ẹbọ ọkà; kí àlùfáà sì ṣe ètùtù+ fún ẹni náà ti ń wẹ ara rẹ̀ mọ́ níwájú Jèhófà. 32  “Èyí ni òfin fún ẹni tí àrùn ẹ̀tẹ̀ wà lára rẹ̀ tí ó lè má ní lọ́wọ́ tó nígbà tí ó bá ń fi ìdí ìwẹ̀mọ́gaara rẹ̀ múlẹ̀.” 33  Jèhófà sì tẹ̀ síwájú láti bá Mósè àti Áárónì sọ̀rọ̀, pé: 34  “Nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ Kénáánì,+ tí èmi yóò fi fún yín gẹ́gẹ́ bí ohun ìní,+ tí mo sì fi àrùn ẹ̀tẹ̀ sí ilé kan ní ilẹ̀ ìní yín,+ 35  nígbà náà, kí ẹni tí ilé náà jẹ́ tirẹ̀ wá, kí ó sì sọ fún àlùfáà pé, ‘Ohun kan tí ó dà bí àrùn hàn sí mí nínú ilé.’ 36  Kí àlùfáà sì pa àṣẹ ìtọ́ni, kí wọ́n sì kó ohun gbogbo jáde kúrò nínú ilé náà kí àlùfáà tó wọlé láti wo àrùn náà, kí ó má bàa polongo ohun gbogbo tí ó wà nínú ilé náà ní aláìmọ́; lẹ́yìn ìyẹn, àlùfáà yóò wọlé láti wo ilé náà. 37  Nígbà tí ó bá ti rí àrùn náà, nígbà náà, bí àrùn náà bá wà lára ògiri ilé náà, tí ó ní ìtẹ̀wọnú aláwọ̀ ewéko àdàpọ̀-mọ́-yẹ́lò tàbí aláwọ̀ pupa rúsúrúsú, tí ìrísí wọn sì jì n sínú ara ògiri, 38  nígbà náà, kí àlùfáà jáde kúrò nínú ilé náà lọ sí ẹnu ọ̀nà ilé náà, kí ó sì sé ilé náà mọ́ nítorí àrùn+ fún ọjọ́ méje. 39  “Kí àlùfáà sì padà ní ọjọ́ keje láti wò ó;+ bí àrùn náà bá sì ti gbèèràn lára ògiri ilé náà, 40  nígbà náà, kí àlùfáà pa àṣẹ ìtọ́ni, kí wọ́n sì yọ+ àwọn òkúta tí àrùn náà wà lára wọn kúrò, kí wọ́n sì sọ wọ́n sí òde ìlú ńlá náà, sí ibi àìmọ́. 41  Kí ó sì mú kí a ha inú ilé náà yíká-yíká, kí wọ́n sì da ọ̀rọ̀-ìmọlé tí a fi amọ̀ ṣe tí wọ́n gbẹ́ kúrò sí òde ìlú ńlá náà, sí ibi àìmọ́. 42  Kí wọ́n sì kó àwọn òkúta mìíràn, kí wọ́n sì fi wọ́n sí ipò àwọn òkúta ìṣáájú; kí ó sì mú kí a kó àpòrọ́ mìíràn tí a fi amọ̀ ṣe, kí ó sì mú kí a rẹ́ ilé náà. 43  “Ṣùgbọ́n, bí àrùn náà bá padà tí ó sì sọ jáde nínú ilé náà lẹ́yìn tí a ti yọ àwọn òkúta náà kúrò àti lẹ́yìn tí a ti gbẹ́ ara ilé náà kúrò, tí a sì rẹ́ ẹ, 44  nígbà náà, kí àlùfáà+ wọlé, kí ó sì wò ó; bí àrùn náà bá sì ti gbèèràn nínú ilé náà, ẹ̀tẹ̀ afòòró-ẹ̀mí+ inú ilé ni. Aláìmọ́ ni. 45  Kí ó sì mú kí a fa ilé náà lulẹ̀ tòun ti àwọn òkúta rẹ̀ àti àwọn ẹ̀là gẹdú àti gbogbo ọ̀rọ̀-ìmọlé tí a fi amọ̀ ṣe, tí ó jẹ ti ilé náà, kí a sì kó o lọ sí òde ìlú ńlá náà, sí ibi àìmọ́.+ 46  Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá wá sínú ilé náà ní èyíkéyìí nínú àwọn ọjọ́ tí a sé e mọ́ nítorí àrùn,+ yóò jẹ́ aláìmọ́ títí di alẹ́;+ 47  ẹnikẹ́ni tí ó bá sì dùbúlẹ̀ nínú ilé náà, kí ó fọ ẹ̀wù+ rẹ̀, ẹnikẹ́ní tí ó bá sì jẹun nínú ilé náà, kí ó fọ ẹ̀wù rẹ̀. 48  “Àmọ́ ṣá o, bí àlùfáà bá wá rárá, tí ó sì wò ó, sì kíyè sí i ní báyìí, àrùn náà kò gbèèràn nínú ilé náà lẹ́yìn tí a ti rẹ́ ilé náà, nígbà náà, kí àlùfáà pe ilé náà ni ohun tí ó mọ́, nítorí pé àrùn náà ti sàn.+ 49  Láti wẹ ilé náà mọ́ gaara kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀, kí ó mú ẹyẹ méjì + àti igi kédárì+ àti òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò ti kòkòrò kókọ́sì+ àti ewéko hísópù. 50  Kí ó sì pa ẹyẹ kan lórí omi tí ó ṣeé mu+ tí ó wà nínú ohun èlò amọ̀. 51  Kí ó sì mú igi kédárì àti ewéko hísópù+ àti òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò ti kòkòrò kókọ́sì àti ààyè ẹyẹ, kí ó sì tẹ̀ wọ́n bọ ẹ̀jẹ̀ ẹyẹ tí a pa àti omi náà, kí ó sì wọ́n ọn ṣẹ̀rẹ̀ṣẹ̀rẹ̀+ sára ilé náà ní ìgbà méje.+ 52  Kí ó sì fi ẹ̀jẹ̀ ẹyẹ àti omi àti ààyè ẹyẹ àti igi kédárì àti ewéko hísópù àti òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò ti kòkòrò kókọ́sì wẹ ilé náà mọ́ gaara kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀. 53  Kí ó sì rán ààyè ẹyẹ náà lọ sí òde ìlú ńlá náà sínú pápá gbalasa, kí ó sì ṣe ètùtù+ fún ilé náà; kí ilé náà sì mọ́. 54  “Èyí ni òfin nípa àrùn ẹ̀tẹ̀+ èyíkéyìí àti nípa irun ríre lódìlódì+ 55  àti nípa ẹ̀tẹ̀ ẹ̀wù+ àti ti inú ilé, 56  àti nípa àwúfọ́ àti ẹ̀yi àti àmì àbààwọ́n,+ 57  láti fúnni ní ìtọ́ni+ nígbà tí ohun kan bá jẹ́ aláìmọ́ àti nígbà tí ohun kan bá mọ́. Èyí ni òfin nípa ẹ̀tẹ̀.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé