Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Léfítíkù 12:1-8

12  Jèhófà sì ń ba a lọ láti bá Mósè sọ̀rọ̀, pé:  “Bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀, pé, ‘Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé obìnrin kan lóyún,+ tí ó sì bí akọ, kí obìnrin náà jẹ́ aláìmọ́ fún ọjọ́ méje; gẹ́gẹ́ bí ti àwọn ọjọ́ ohun ìdọ̀tí nígbà tí ó ń ṣe nǹkan oṣù, òun yóò jẹ́ aláìmọ́.+  Ní ọjọ́ kẹjọ ni a ó sì dá adọ̀dọ́+ ọmọkùnrin náà.  Fún ọjọ́ mẹ́tàlélọ́gbọ̀n sí i, obìnrin náà yóò wà nínú ẹ̀jẹ̀ ìwẹ̀mọ́gaara. Òun kò gbọ́dọ̀ fara kan ohun mímọ́ èyíkéyìí, kò sì gbọ́dọ̀ wá sínú ibi mímọ́ títí di ìgbà tí àwọn ọjọ́ ìwẹ̀mọ́gaara rẹ̀ bá pé.+  “‘Wàyí o, bí ó bá bí abo, nígbà náà, kí ó jẹ́ aláìmọ́ fún ọjọ́ mẹ́rìnlá, gẹ́gẹ́ bí ti ìgbà nǹkan oṣù rẹ̀. Fún ọjọ́ mẹ́rìn-dín-láàádọ́rin sí i, òun yóò wà pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ ìwẹ̀mọ́gaara.  Lẹ́yìn náà, ní ìgbà tí àwọn ọjọ́ ìwẹ̀mọ́gaara rẹ̀ fún ọmọkùnrin tàbí fún ọmọbìnrin bá pé, òun yóò mú ẹgbọrọ àgbò tí ó wà ní ọdún rẹ̀ àkọ́kọ́ wá sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé fún ọrẹ ẹbọ sísun+ àti ọmọ ẹyẹlé tàbí oriri+ fún ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, fún àlùfáà.  Kí àlùfáà sì mú un wá síwájú Jèhófà, kí ó sì ṣe ètùtù fún obìnrin náà, kí obìnrin náà sì mọ́ kúrò nínú orísun ẹ̀jẹ̀ rẹ̀.+ Èyí ni òfin nípa obìnrin tí ó bí akọ tàbí abo.  Ṣùgbọ́n bí agbára rẹ̀ kò bá ká àgùntàn, nígba náà, kí ó mú oriri méjì  tàbí ọmọ ẹyẹlé méjì ,+ ọ̀kan fún ọrẹ ẹbọ sísun àti ọ̀kan fún ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, kí àlùfáà sì ṣe ètùtù+ fún un, kí obìnrin náà sì mọ́.’”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé