Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Léfítíkù 11:1-47

11  Jèhófà sì tẹ̀ síwájú láti bá Mósè àti Áárónì sọ̀rọ̀, ó wí fún wọn pé:  “Ẹ sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, pé, ‘Èyí ni ẹ̀dá alààyè tí ẹ lè jẹ+ nínú gbogbo ẹranko tí ó wà lórí ilẹ̀:  Gbogbo ẹ̀dá tí ó la pátákò tí ó sì ní àlàfo ní pátákò tí ó sì ń jẹ àpọ̀jẹ nínú àwọn ẹranko, ìyẹn ni èyí tí ẹ lè jẹ.+  “‘Kì kì èyí ni ohun tí ẹ kò gbọ́dọ̀ jẹ nínú àwọn tí ń jẹ àpọ̀jẹ àti àwọn tí ó la pátákò: ràkúnmí, nítorí èyí tí ń jẹ àpọ̀jẹ ni, ṣùgbọ́n kò la pátákò. Aláìmọ́ ni fún yín.+  Àti gárá orí àpáta pẹ̀lú,+ nítorí èyí tí ń jẹ àpọ̀jẹ ni, ṣùgbọ́n kò la pátákò. Aláìmọ́ ni fún yín.  Àti ehoro pẹ̀lú,+ nítorí èyí tí ń jẹ àpọ̀jẹ ni, ṣùgbọ́n kò la pátákò. Aláìmọ́ ni fún yín.  Àti ẹlẹ́dẹ̀ pẹ̀lú,+ nítorí tí ó la pátákò tí ó sì ní àlàfo ní pátákò, ṣùgbọ́n kì í jẹ àpọ̀jẹ. Aláìmọ́ ni fún yín.  Ẹ kò gbọ́dọ̀ jẹ́ èyíkéyìí nínú ẹran wọn, ẹ kò sì gbọ́dọ̀ fara kan òkú wọn.+ Aláìmọ́ ni wọ́n fún yín.+  “‘Èyí ni ohun tí ẹ lè jẹ nínú gbogbo ohun tí ó wà nínú omi:+ Ohun gbogbo tí ó ní lẹ́bẹ́ àti ìpẹ́+ nínú omi, nínú òkun àti nínú ọ̀gbàrá, àwọn wọ̀nyẹn ni ẹ lè jẹ. 10  Àti gbogbo ohun tí ó wà nínú òkun àti ọ̀gbàrá tí kò ní lẹ́bẹ́ àti ìpẹ́, láti inú gbogbo ẹ̀dá agbáyìn-ìn inú omi àti gbogbo alààyè ọkàn tí ó wà nínú omi, wọ́n jẹ́ ohun ìkórìíra tẹ̀gbintẹ̀gbin fún yín. 11  Bẹ́ẹ̀ ni, wọn yóò máa jẹ́ ohun ìkórìíra tẹ̀gbintẹ̀gbin fún yín. Ẹ kò gbọ́dọ̀ jẹ èyíkéyìí nínú ẹran wọn,+ kí ẹ sì kórìíra òkú wọn tẹ̀gbintẹ̀gbin. 12  Ohun gbogbo tí ó wà nínú omi tí kò ní lẹ́bẹ́ àti ìpẹ́ jẹ́ ohun ìkórìíra tẹ̀gbintẹ̀gbin fún yín. 13  “‘Àwọn wọ̀nyí ni ohun tí ẹ ó sì máa kórìíra tẹ̀gbintẹ̀gbin láàárín ẹ̀dá tí ń fò.+ A kò gbọ́dọ̀ jẹ wọ́n. Ohun ìkórìíra tẹ̀gbintẹ̀gbin ni wọ́n: idì+ àti idì ajẹja àti igún dúdú, 14  àti àwòdì pupa àti àwòdì dúdú+ ní irú tirẹ̀, 15  àti gbogbo ẹyẹ ìwò+ ní irú tirẹ̀, 16  àti ògòǹgò+ àti òwìwí àti ẹyẹ àkẹ̀ àti àṣáǹwéwé ní irú tirẹ̀, 17  àti òwìwí kékeré àti ẹyẹ àgò àti òwìwí elétí gígùn,+ 18  àti ògbùgbú àti ẹyẹ òfú àti igún,+ 19  àti ẹyẹ àkọ̀, ẹyẹ wádòwádò ní irú tirẹ̀, àti àgbìgbò àti àdán.+ 20  Gbogbo ẹ̀dá agbáyìn-ìn abìyẹ́lápá tí ń fi mẹ́rẹ̀ẹ̀rin rìn jẹ ohun ìkórìíra tẹ̀gbintẹ̀gbin fún yín.+ 21  “‘Kì kì èyí ni ohun tí ẹ lè jẹ nínú gbogbo ẹ̀dá agbáyìn-ìn abìyẹ́lápá tí ń fi mẹ́rẹ̀ẹ̀rin rìn, àwọn tí wọ́n ní tete lókè ẹsẹ̀ wọn láti fi tọ lórí ilẹ̀. 22  Ìwọ̀nyí ni àwọn tí ó wà nínú wọn tí ẹ lè jẹ: eéṣú aṣíkiri+ ní irú tirẹ̀, àti eéṣú tí ó ṣeé jẹ+ ní irú tirẹ̀, àti ìrẹ̀ ní irú tirẹ̀, àti tata+ ní irú tirẹ̀. 23  Gbogbo ẹ̀dá agbáyìn-ìn abìyẹ́lápá yòókù tí ó ní ẹsẹ̀ mẹ́rin sì jẹ́ ohun ìkórìíra tẹ̀gbintẹ̀gbin+ fún yín. 24  Nítorí náà, nípa ìwọ̀nyí ni ẹ ó sọ ara yín di aláìmọ́. Gbogbo ẹni tí ó bá fara kan òkú wọn yóò jẹ́ aláìmọ́ títí di alẹ́. 25  Àti gbogbo ẹni tí ó bá gbé èyíkéyìí lára òkú wọn yóò fọ+ ẹ̀wù rẹ̀, kí ó sì jẹ́ aláìmọ́ títí di alẹ́.+ 26  “‘Ní ti ẹranko èyíkéyìí tí ó la pátákò, ṣùgbọ́n tí kò ní àlàfo ní pátákò, tí kì í sì í ṣe èyí tí ń jẹ àpọ̀jẹ, aláìmọ́ ni wọ́n jẹ́ fún yín. Gbogbo ẹni tí ó bá fara kàn wọ́n yóò di aláìmọ́.+ 27  Ní ti gbogbo ẹ̀dá tí ń fi àtẹ́sẹ̀ rẹ̀ rìn nínú gbogbo ẹ̀dá alààyè tí ń fi mẹ́rẹ̀ẹ̀rin rìn, aláìmọ́ ni wọ́n jẹ́ fún yín. Gbogbo ẹni tí ó bá fara kan òkú wọn yóò jẹ́ aláìmọ́ títí di alẹ́. 28  Ẹni tí ó bá sì gbé òkú wọn+ yóò fọ ẹ̀wù rẹ̀,+ kí ó sì jẹ́ aláìmọ́ títí di alẹ́. Aláìmọ́ ni wọ́n jẹ́ fún yín. 29  “‘Èyí sì ni aláìmọ́ fún yín láàárín àwọn ẹ̀dá agbáyìn-ìn tí ń gbá yìn-ìn lórí ilẹ̀:+ ẹ̀lírí àti eku àgó+ àti aláǹgbá ní irú tirẹ̀, 30  àti ọmọńlé ẹlẹ́sẹ̀-abẹ̀bẹ̀ àti awọ́nríwọ́n àti aláàmù àti ọlọ́yọ̀ọ́ǹbẹ́rẹ́ àti ọ̀gà. 31  Ìwọ̀nyí jẹ́ aláìmọ́ fún yín láàárín gbogbo ẹ̀dá agbáyìn-ìn.+ Gbogbo ẹni tí ó bá fara kàn wọ́n nígbà tí wọ́n ti kú yóò jẹ́ aláìmọ́ títí di alẹ́.+ 32  “‘Wàyí o, ohunkóhun tí èyíkéyìí nínú wọn nígbà tí ó bá ti kú bá já bọ́ lé lórí, yóò di aláìmọ́, yálà ó jẹ́ ohun èlò kan tí a fi igi ṣe+ tàbí ẹ̀wù tàbí awọ+ tàbí aṣọ àpò ìdọ̀họ.+ Ohun èlò èyíkéyìí tí a lò ni kí a fi sínú omi, yóò sì di aláìmọ́ títí di alẹ́, lẹ́yìn náá, yóò sì di ohun tí ó mọ́. 33  Ní ti èyíkéyìí nínú ohun èlò amọ̀+ tí èyìkéyìí nínú wọn bá já bọ́ sí, ohunkóhun tí ó bá wà nínú rẹ̀ yóò di aláìmọ́, kí ẹ sì fọ́ ọ túútúú.+ 34  Irú oúnjẹ èyíkéyìí tí a lè jẹ tí omi ara rẹ̀ bá kán sí, yóò di aláìmọ́, ohun mímu èyíkéyìí tí a bá sì mu nínú ohun èlò èyíkéyìí yóò di aláìmọ́. 35  Ohun gbogbo tí èyíkéyìí lára òkú wọn bá sì já bọ́ lé lórí yóò di aláìmọ́. Yálà ó jẹ́ ààrò tàbí ibi tí a ń gbé ìṣà lé, a óò fọ́ ọ túútúú ni. Aláìmọ́ ni wọ́n, wọn yóò sì di aláìmọ́ fún yín. 36  Kì kì ìsun àti kòtò ìwọ́jọpọ̀ omi ni yóò máa bá a lọ láti jẹ́ ohun tí ó mọ́, ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá fara kan òkú wọn yóò di aláìmọ́. 37  Bí èyíkéyìí lára òkú wọn bá sì já bọ́ sórí irúgbìn èyíkéyìí nínú ọ̀gbìn tí a óò fúnrúgbìn, ó mọ́. 38  Ṣùgbọ́n bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé omi wà lára irúgbìn, tí ohun kan lára òkú wọn sì já bọ́ sórì rẹ̀, aláìmọ́ ni fún yín. 39  “‘Wàyí o, bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ẹranko èyíkéyìí tí ó jẹ́ tiyín tí ó wà fún oúnjẹ bá kú, ẹni tí ó bá fara kan òkú rẹ̀ yóò jẹ́ aláìmọ́ títí di alẹ́.+ 40  Ẹni tí ó bá sì jẹ+ ohun èyíkéyìí lára òkú rẹ̀ yóò fọ ẹ̀wù rẹ̀, kí ó sì jẹ́ aláìmọ́ títí di alẹ́; ẹni tí ó bá sì gbé òkú rẹ̀, yóò fọ ẹ̀wù rẹ̀, kí ó sì jẹ́ aláìmọ́ títí di alẹ́. 41  Gbogbo ẹ̀dá agbáyìn-ìn tí ń gbá yìn-ìn lórí ilẹ̀ sì jẹ́ ohun ìkórìíra tẹ̀gbintẹ̀gbin.+ A kò gbọ́dọ̀ jẹ ẹ́. 42  Ní ti ẹ̀dá èyíkéyìí tí ń fi ikùn+ wọ́ àti ẹ̀dá èyíkéyìí tí ń fi mẹ́rẹ̀ẹ̀rin rìn tàbí èyíkéyìí tí ó ní ẹsẹ̀ púpọ̀ nínú gbogbo ẹ̀dá agbáyìn-ìn tí ń gbá yìn-ìn lórí ilẹ̀, ẹ kò gbọ́dọ̀ jẹ wọ́n, nítorí pé wọ́n jẹ́ ohun ìkórìíra tẹ̀gbintẹ̀gbin.+ 43  Ẹ kò gbọ́dọ̀ fi èyíkéyìí lára ẹ̀dá agbáyìn-ìn tí ń gbá yìn-ìn sọ ọkàn yín di ohun ìkórìíra tẹ̀gbintẹ̀gbin, ẹ kò sì gbọ́dọ̀ fi wọ́n sọ ara yín di aláìmọ́, ní títipasẹ̀ wọn di aláìmọ́+ ní ti tòótọ́. 44  Nítòrí èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín;+ kí ẹ sì sọ ara yín di mímọ́, kí ẹ sì jẹ́ mímọ́,+ nítorí pé èmi jẹ́ mímọ́.+ Nítorí náà, ẹ kò gbọ́dọ̀ fi èyíkéyìí lára ẹ̀dá agbáyìn-ìn tí ń rìn lórí ilẹ̀ sọ ọkàn yín di aláìmọ́. 45  Nítorí èmi ni Jèhófà tí ó mú yín gòkè kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì láti fi ara mi hàn ní Ọlọ́run fún yín;+ kí ẹ sì jẹ́ mímọ́,+ nítorí pé mo jẹ́ mímọ́.+ 46  “‘Èyí sì ni òfin nípa ẹranko àti ẹ̀dá tí ń fò àti gbogbo alààyè ọkàn tí ń lọ káàkiri nínú omi+ àti nípa gbogbo ọkàn tí ń gbá yìn-ìn lórí ilẹ̀, 47  láti fi ìyàtọ̀+ sáàárín aláìmọ́ àti èyí tí ó mọ́ àti sáàárín ẹ̀dá alààyè tí ó ṣée jẹ àti ẹ̀dá alààyè tí a kò gbọ́dọ̀ jẹ.’”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé