Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Léfítíkù 10:1-20

10  Lẹ́yìn náà, àwọn ọmọkùnrin Áárónì, Nádábù àti Ábíhù,+ olúkúlùkù wọn mú ìkóná+ rẹ̀ wá, wọ́n sì fi iná sínú wọn, wọ́n sì fi tùràrí+ sórí rẹ̀, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí rú ẹbọ tí kò bá ìlànà mu+ níwájú Jèhófà, èyí tí òun kò lànà rẹ̀ sílẹ̀ fún wọn.  Látàrí èyí, iná jáde wá láti ọ̀dọ̀ Jèhófà, ó sì jó wọn run,+ tí ò fi jẹ́ pé wọ́n kú níwájú Jèhófà.+  Nígbà náà ni Mose wí fún Áárónì pé: “Èyí ni ohun tí Jèhófà sọ, pé, ‘Láàárín àwọn tí ó sún mọ́ mi,+ kí a sọ mí di mímọ́,+ àti ní ojú gbogbo ènìyàn, kí èmi di àyìnlógo.’”+ Áárónì sì dákẹ́ jẹ́ẹ́.  Nítorí náà, Mósè pe Míṣáẹ́lì àti Élísáfánì, àwọn ọmọkùnrin Úsíélì,+ arákùnrin òbí Áárónì, ó sì wí fún wọn pé: “Ẹ sún mọ́ tòsí, kí ẹ sì gbé àwọn arákùnrin yín kúrò ní iwájú ibi mímọ́ lọ sí òde ibùdó.”+  Ní ìbámu pẹ̀lú èyí, wọ́n sún mọ́ tòsí, wọ́n sì gbé wọn lọ ti àwọn ti aṣọ wọn, sí òde ibùdó, gan-an gẹ́gẹ́ bí Mósè ti sọ.  Lẹ́yìn náà, Mósè wí fún Áárónì àti Élíásárì àti Ítámárì, àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ yòókù pé: “Ẹ má ṣe jẹ́ kí orí yín wà láìtọ́jú,+ ẹ kò sì gbọ́dọ̀ ya ẹ̀wù yín, kí ẹ má bàa kú, kí ìkannú rẹ̀ má bàa ru sí gbogbo àpéjọ yìí;+ ṣùgbọ́n àwọn arákùnrin yín ní gbogbo ilé Ísírẹ́lì yóò sun ẹkún nítorí jíjó iná, tí Jèhófà mú kí ó jó.  Kí ẹ má sì jáde kúrò ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé, kí ẹ má bàa kú,+ nítorí òróró àfiyanni ti Jèhófà wà lára yín.”+ Nípa bẹ́ẹ̀, wọ́n ṣe gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Mósè.  Jèhófà sì tẹ̀ síwájú láti bá Áárónì sọ̀rọ̀, pé:  “Má ṣe mu wáìnì tàbí ọtí tí ń pani,+ ìwọ àti àwọn ọmọkùnrin rẹ pẹ̀lú rẹ, nígbà tí ẹ bá wá sínú àgọ́ ìpàdé, kí ẹ má bàa kú. Ìlànà àgbékalẹ̀ ni fún àkókò tí ó lọ kánrin fún ìran-ìran yín, 10  láti fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun mímọ́ àti ohun tí a ti sọ di àìmọ́ àti sáàárín ohun tí kò mọ́ àti ohun tí ó mọ́,+ 11  àti láti kọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì+ ní gbogbo ìlànà tí Jèhófà ti sọ fún wọn nípasẹ̀ Mósè.” 12  Nígbà náà ni Mósè bá Áárónì àti Élíásárì àti Ítámárì, àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ tí ó ṣẹ́ kù sọ̀rọ̀ pé: “Ẹ kó ọrẹ ẹbọ ọkà+ tí ó ṣẹ́ kù nínú àwọn ọrẹ ẹbọ tí a fi iná sun sí Jèhófà, kí ẹ sì jẹ ẹ́ ní aláìwú nítòsí pẹpẹ, nítorí pé ohun mímọ́ jù lọ ni.+ 13  Kí ẹ sì jẹ ẹ́ ní ibi mímọ́,+ nítorí pé ohun tí a yọ̀ǹda fún ọ ni àti ohun tí a yọ̀ǹda fún àwọn ọmọkùnrin rẹ láti inú àwọn ọrẹ ẹbọ tí a fi iná sun sí Jèhófà; nítorí pé, bẹ́ẹ̀ ni a pàṣẹ fún mi. 14  Ẹ ó sì jẹ igẹ̀+ ọrẹ ẹbọ fífì àti ẹsẹ̀ tí ó jẹ́ ìpín ọlọ́wọ̀+ ní ibi tí ó mọ́, ìwọ àti àwọn ọmọkùnrin rẹ àti àwọn ọmọbìnrin rẹ pẹ̀lú rẹ,+ nítorí pé a ti fi í fún yín gẹ́gẹ́ bí ohun tí a yọ̀ǹda fún ọ àti ohun tí a yọ̀ǹda fún àwọn ọmọkùnrin rẹ láti inú àwọn ẹbọ ìdàpọ̀ ti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. 15  Wọn yóò mú ẹsẹ̀ tí ó jẹ́ ìpín ọlọ́wọ̀ wá àti igẹ̀ ọrẹ ẹbọ fífì+ pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ọrẹ ẹbọ tí a fi iná sun, ti ọ̀rá, kí a lè fi ọrẹ ẹbọ fífì síwá-sẹ́yìn níwájú Jèhófà; kí ó sì jẹ́ ohun tí a yọ̀ǹda+ fún àkókò tí ó lọ kánrin fún ọ àti fún àwọn ọmọkùnrin rẹ pẹ̀lú rẹ, gan-an gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti pa á láṣẹ.” 16  Mósè sì wá ewúrẹ́ ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀+ náà káàkiri dáadáa, sì wò ó! a ti sun ún. Nítorí náà, ìkannú rẹ̀ ru sí Élíásárì àti Ítámárì, àwọn ọmọkùnrin Áárónì tí ó ṣẹ́ kù, ó wí pé: 17  “Èé ṣe tí ẹ kò fi jẹ ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ ní ibi tí ó jẹ́ mímọ́,+ níwọ̀n bí ó ti jẹ́ ohun mímọ́ jù lọ, tí ó sì ti fi í fún yín, kí ẹ lè dáhùn fún ìṣìnà àpéjọ náà láti ṣe ètùtù fún wọn níwájú Jèhófà?+ 18  Wò ó! Ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ ni a kò tíì mú wá sí àárín ibi mímọ́.+ Láìkùnà, ó yẹ kí ẹ ti jẹ ẹ́ ní ibi mímọ́, gan-an gẹ́gẹ́ bí a ti pàṣẹ fún mi.”+ 19  Látàrí èyí, Áárónì bá Mósè sọ̀rọ̀ pé: “Wò ó! Òní ni wọ́n mú ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ wọn àti ọrẹ ẹbọ sísun wọn wá síwájú Jèhófà,+ tí àwọn nǹkan bí ìwọ̀nyí sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣẹlẹ̀ sí mi; ká sì ní mo jẹ ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ lónìí ni, yóò ha já sí ìtẹ́lọ́rùn ní ojú Jèhófà bi?”+ 20  Nígbà tí Mósè gbọ́ ìyẹn, nígbà náà, ó já sí ìtẹ́lọ́rùn ní ojú rẹ̀.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé