Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Léfítíkù 1:1-17

1  Jèhófà sì bẹ̀rẹ̀ sí pe Mósè, ó sì bá a sọ̀rọ̀ láti inú àgọ́ ìpàdé,+ pé:  “Bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀,+ kí o sì wí fún wọn pé, ‘Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ẹnì kan nínú yín mú ọrẹ ẹbọ wá fún Jèhófà láti inú àwọn ẹran agbéléjẹ̀, kí ẹ mú ọrẹ ẹbọ yín wá láti inú ọ̀wọ́ ẹran àti láti inú agbo ẹran.  “‘Bí ọrẹ ẹbọ rẹ̀ bá jẹ́ ọrẹ ẹbọ sísun+ láti inú ọ̀wọ́ ẹran, akọ, èyí tí ara rẹ̀ dá ṣáṣá,+ ni kí ó mú wá. Ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé ni kí ó ti mú un wá síwájú Jèhófà láti inú ìfẹ́ àtinúwá rẹ̀.+  Kí ó sì gbé ọwọ́ rẹ̀ lé orí ọrẹ ẹbọ sísun náà, kí ó sì fi ojú rere tẹ́wọ́ gbà á,+ kí ó le ṣe ètùtù fún un.+  “‘Lẹ́yìn náà, kí a pa akọ màlúù náà níwájú Jèhófà; kí àwọn ọmọkùnrin Áárónì, àwọn àlùfáà,+ sì gbé ẹ̀jẹ̀ náà wá, kí wọ́n sì wọ́n ẹ̀jẹ̀ náà sórí pẹpẹ yíká-yíká,+ èyí tí ó wà ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé.  Kí a sì bó ọrẹ ẹbọ sísun náà láwọ, kí a sì gé e sí àwọn apá rẹ̀ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.+  Kí àwọn ọmọkùnrin Áárónì, àwọn àlùfáà, sì fi iná sórí pẹpẹ,+ kí wọ́n sì to igi sórí iná náà.+  Kí àwọn ọmọkùnrin Áárónì, àwọn àlùfáà, sì to àwọn ègé náà,+ pẹ̀lú orí àti ọ̀rá líle, sórí igi tí ó wà lórí iná tí ó wà lórí pẹpẹ.  Ìfun rẹ̀+ àti tete rẹ̀ ni a ó fi omi fọ̀; kí àlùfáà sì mú gbogbo rẹ̀ rú èéfín lórí pẹpẹ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ sísun, ọrẹ ẹbọ àfinásun, ti òórùn amáratuni sí Jèhófà.+ 10  “‘Bí ọrẹ ẹbọ rẹ̀ fún ọrẹ ẹbọ sísun bá wá láti inú agbo ẹran,+ láti inú àwọn ẹgbọrọ àgbò tàbí àwọn ewúrẹ́, akọ,+ èyí tí ara rẹ̀ dá ṣáṣá, ni kí ó mú wá.+ 11  Kí a sì pa á lẹ́gbẹ̀ẹ́ pẹpẹ níhà àríwá níwájú Jèhófà, kí àwọn ọmọkùnrin Áárónì, àwọn àlùfáà, sì wọ́n ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sórí pẹpẹ yíká-yíká.+ 12  Kí ó sì gé e sí àwọn apá rẹ̀ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ àti sí orí rẹ̀ àti sí ọ̀rá rẹ̀ líle, kí àlùfáà sì tò wọ́n sórí igi tí ó wà lórí iná tí ó wà lórí pẹpẹ.+ 13  Yóò sì fi omi fọ ìfun+ àti tete;+ kí àlùfáà sì mú gbogbo rẹ̀ wá, kí ó sì mú un rú èéfín+ lórí pẹpẹ. Ọrẹ ẹbọ sísun ni, ọrẹ ẹbọ àfinásun, ti òórùn amáratuni sí Jèhófà.+ 14  “‘Àmọ́ ṣá o, bí ọrẹ ẹbọ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ sísun sí Jèhófà bá wá láti inú ẹ̀dá abìyẹ́, nígbà náà, kí ó mú ọrẹ ẹbọ rẹ̀ wá láti inú àwọn oriri+ tàbí àwọn ọmọ ẹyẹlé.+ 15  Kí àlùfáà sì mú un wá sí ibi pẹpẹ, kí ó sì já+ a ní orí, kí ó sì mú un rú èéfín lórí pẹpẹ, ṣùgbọ́n kí a ro ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sí ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ. 16  Kí ó sì yọ àpò oúnjẹ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìyẹ́ rẹ̀ kúrò, kí ó sì kó o sẹ́gbẹ̀ẹ́ pẹpẹ náà, níhà ìlà-oòrùn, sí ibi eérú ọlọ́ràá.+ 17  Kí ó sì ya á níbi àwọn ìyẹ́ apá rẹ̀. Kò gbọ́dọ̀ pín in.+ Lẹ́yìn náà, kí àlùfáà mú un rú èéfín lórí pẹpẹ, lórí igi tí ó wà lórí iná. Ọrẹ ẹbọ sísun ni,+ ọrẹ ẹbọ àfinásun, ti òórùn amáratuni sí Jèhófà.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé