Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Kólósè 3:1-25

3  Bí ó ti wù kí ó rí, bí a bá ti gbé yín dìde+ pẹ̀lú Kristi, ẹ máa bá a lọ ní wíwá àwọn nǹkan ti òkè,+ níbi tí Kristi jókòó sí ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run.+  Ẹ máa gbé èrò inú yín ka àwọn nǹkan ti òkè,+ kì í ṣe àwọn nǹkan tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé.+  Nítorí ẹ ti kú,+ a sì ti fi ìwàláàyè yín+ pa mọ́ sọ́dọ̀ Kristi ní ìrẹ́pọ̀+ pẹ̀lú Ọlọ́run.  Nígbà tí a bá fi Kristi, ìyè wa,+ hàn kedere, nígbà náà ni a ó fi ẹ̀yin náà hàn kedere+ pẹ̀lú rẹ̀ nínú ògo.+  Nítorí náà, ẹ sọ àwọn ẹ̀yà ara+ yín tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé di òkú+ ní ti àgbèrè, ìwà àìmọ́, ìdálọ́rùn fún ìbálòpọ̀ takọtabo,+ ìfẹ́-ọkàn tí ń ṣeni lọ́ṣẹ́, àti ojúkòkòrò,+ tí í ṣe ìbọ̀rìṣà.  Ní tìtorí nǹkan wọnnì ni ìrunú Ọlọ́run fi ń bọ̀.+  Nínú nǹkan wọnnì gan-an ni ẹ̀yin, pẹ̀lú, ti rìn nígbà kan rí nígbà tí ẹ ṣì máa ń gbé nínú wọn.+  Ṣùgbọ́n nísinsìnyí ní ti gidi, ẹ mú gbogbo wọn kúrò lọ́dọ̀ yín,+ ìrunú, ìbínú, ìwà búburú, ọ̀rọ̀ èébú,+ àti ọ̀rọ̀ rírùn+ kúrò lẹ́nu yín.  Ẹ má ṣe máa purọ́ fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì.+ Ẹ bọ́ ògbólógbòó àkópọ̀ ìwà sílẹ̀+ pẹ̀lú àwọn àṣà rẹ̀, 10  ẹ sì fi àkópọ̀ ìwà tuntun+ wọ ara yín láṣọ, èyí tí a ń sọ di tuntun nípasẹ̀ ìmọ̀ pípéye ní ìbámu pẹ̀lú àwòrán+ Ẹni tí ó dá a, 11  níbi tí kò ti sí Gíríìkì tàbí Júù, ìdádọ̀dọ́ tàbí àìdádọ̀dọ́, ọmọ ilẹ̀ òkèèrè, Síkítíánì, ẹrú, òmìnira,+ ṣùgbọ́n Kristi ni ohun gbogbo, ó sì wà nínú ohun gbogbo.+ 12  Ní ìbámu pẹ̀lú èyí, gẹ́gẹ́ bí àyànfẹ́+ Ọlọ́run, mímọ́ àti olùfẹ́, ẹ fi ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ ti ìyọ́nú,+ inú rere, ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú,+ ìwà tútù,+ àti ìpamọ́ra+ wọ ara yín láṣọ. 13  Ẹ máa bá a lọ ní fífaradà á fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, kí ẹ sì máa dárí ji ara yín fàlàlà+ lẹ́nì kìíní-kejì bí ẹnikẹ́ni bá ní ìdí fún ẹjọ́+ lòdì sí ẹlòmíràn. Àní gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti dárí jì yín ní fàlàlà,+ bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin pẹ̀lú máa ṣe. 14  Ṣùgbọ́n, yàtọ̀ sí gbogbo nǹkan wọ̀nyí, ẹ fi ìfẹ́ wọ ara yín láṣọ,+ nítorí ó jẹ́ ìdè ìrẹ́pọ̀ pípé.+ 15  Pẹ̀lúpẹ̀lù, ẹ jẹ́ kí àlàáfíà+ Kristi máa ṣàkóso nínú ọkàn-àyà+ yín, nítorí, ní ti tòótọ́, a pè yín sínú rẹ̀ ní ara kan.+ Ẹ sì fi ara yín hàn ní ẹni tí ó kún fún ọpẹ́. 16  Ẹ jẹ́ kí ọ̀rọ̀ Kristi máa gbé inú yín lọ́pọ̀ jaburata nínú ọgbọ́n gbogbo.+ Ẹ máa bá a nìṣó ní kíkọ́+ ara yín àti ní ṣíṣí ara yín létí lẹ́nì kìíní-kejì pẹ̀lú àwọn sáàmù,+ àwọn ìyìn sí Ọlọ́run, àwọn orin tẹ̀mí+ pẹ̀lú oore ọ̀fẹ́, kí ẹ máa kọrin nínú ọkàn-àyà yín sí Jèhófà.+ 17  Ohun yòówù tí ẹ bá sì ń ṣe ní ọ̀rọ̀ tàbí ní iṣẹ́,+ ẹ máa ṣe ohun gbogbo ní orúkọ Jésù Olúwa,+ kí ẹ máa dúpẹ́+ lọ́wọ́ Ọlọ́run Baba nípasẹ̀ rẹ̀. 18  Ẹ̀yin aya, ẹ wà ní ìtẹríba+ fún àwọn ọkọ yín, gẹ́gẹ́ bí ó ti yẹ nínú Olúwa. 19  Ẹ̀yin ọkọ, ẹ máa bá a nìṣó ní nínífẹ̀ẹ́ àwọn aya yín,+ ẹ má sì bínú sí wọn lọ́nà kíkorò.+ 20  Ẹ̀yin ọmọ, ẹ jẹ́ onígbọràn+ sí àwọn òbí yín nínú ohun gbogbo, nítorí èyí dára gidigidi nínú Olúwa. 21  Ẹ̀yin baba, ẹ má ṣe máa dá àwọn ọmọ yín lágara,+ kí wọ́n má bàa soríkodò. 22  Ẹ̀yin ẹrú, ẹ jẹ́ onígbọràn nínú ohun gbogbo sí àwọn tí wọ́n jẹ́ ọ̀gá yín nípa ti ara,+ kì í ṣe pẹ̀lú àwọn ìṣe àrójúṣe, gẹ́gẹ́ bí olùwu ènìyàn,+ ṣùgbọ́n pẹ̀lú òtítọ́ ọkàn-àyà, pẹ̀lú ìbẹ̀rù Jèhófà.+ 23  Ohun yòówù tí ẹ bá ń ṣe, ẹ fi tọkàntọkàn+ ṣe é bí ẹni pé fún Jèhófà,+ kì í sì í ṣe fún ènìyàn, 24  nítorí ẹ mọ̀ pé láti ọ̀dọ̀ Jèhófà+ ni ẹ ó ti gba ẹ̀san yíyẹ ti ogún náà.+ Ẹ máa sìnrú fún Ọ̀gá náà, Kristi.+ 25  Dájúdájú, ẹni tí ń ṣe àìtọ́ yóò rí nǹkan tí ó ṣe lọ́nà àìtọ́ gbà padà,+ kò sì sí ojúsàájú kankan.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé