Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Kólósè 2:1-23

2  Nítorí mo fẹ́ kí ẹ mọ bí ìjàkadì+ tí mo ń ní nítorí yín ti pọ̀ tó àti nítorí àwọn tí ń bẹ ní Laodíkíà+ àti nítorí gbogbo àwọn tí kò tíì rí ojú mi nínú ara,  kí a lè tu ọkàn-àyà wọn nínú,+ kí a lè so wọ́n pọ̀ ní ìṣọ̀kan nínú ìfẹ́+ àti pẹ̀lú níní gbogbo ọrọ̀ tí ó jẹ́ ti ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìdánilójú òye+ wọn lọ́kàn, pẹ̀lú níní lọ́kàn ìmọ̀ pípéye nípa àṣírí ọlọ́wọ̀ Ọlọ́run, èyíinì ni, Kristi.+  Inú rẹ̀ ni a rọra fi gbogbo ìṣúra ọgbọ́n àti ti ìmọ̀+ pa mọ́ sí.  Èyí ni mo ń wí, kí ènìyàn kankan má bàa fi àwọn ìjiyàn tí ń yíni lérò padà+ mọ̀ọ́mọ̀ ṣì yín lọ́nà.  Nítorí bí èmi kò tilẹ̀ sí lọ́dọ̀ yín nínú ara, síbẹ̀síbẹ̀ mo wà lọ́dọ̀ yín nínú ẹ̀mí,+ tí mo ń yọ̀, tí mo sì ń wo wíwà létòletò yín+ àti ìfìdímúlẹ̀ ìgbàgbọ́+ yín nínú Kristi.  Nítorí náà, bí ẹ ti tẹ́wọ́ gba Kristi Jésù Olúwa, ẹ máa bá a lọ ní rírìn ní ìrẹ́pọ̀+ pẹ̀lú rẹ̀,  kí ẹ ta gbòǹgbò,+ kí a sì máa gbé yín ró+ nínú rẹ̀, kí ẹ sì fẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú ìgbàgbọ́,+ gan-an gẹ́gẹ́ bí a ti kọ́ yín, kí ẹ máa kún fún ìgbàgbọ́ ní àkúnwọ́sílẹ̀ nínú ìdúpẹ́.+  Ẹ máa ṣọ́ra: bóyá ẹnì kan lè wà tí yóò gbé+ yín lọ gẹ́gẹ́ bí ẹran ọdẹ rẹ̀ nípasẹ̀ ìmọ̀ ọgbọ́n orí+ àti ẹ̀tàn òfìfo+ ní ìbámu pẹ̀lú òfin àtọwọ́dọ́wọ́ ènìyàn, ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ohun àkọ́bẹ̀rẹ̀+ ayé, tí kò sì sí ní ìbámu pẹ̀lú Kristi;  nítorí pé nínú rẹ̀ ni ẹ̀kúnrẹ́rẹ́+ ànímọ́+ Ọlọ́run+ ń gbé gẹ́gẹ́ bí ara kan. 10  Àti nítorí náà, ẹ ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìní nípasẹ̀ rẹ̀, ẹni tí ó jẹ́ orí gbogbo ìjọba àti ọlá àṣẹ.+ 11  Nípa ìbátan+ pẹ̀lú rẹ̀, a tún dádọ̀dọ́+ yín pẹ̀lú ìdádọ̀dọ́ tí a kò fi ọwọ́ ṣe nípa bíbọ́ ara ti ẹran ara kúrò,+ nípa ìdádọ̀dọ́ tí ó jẹ́ ti Kristi, 12  nítorí a sin yín pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ nínú ìbatisí rẹ̀,+ àti pé nípa ìbátan pẹ̀lú rẹ̀, a tún gbé yín dìde+ pa pọ̀ nípasẹ̀ ìgbàgbọ́+ yín nínú ìṣiṣẹ́+ Ọlọ́run, ẹni tí ó gbé e dìde kúrò nínú òkú.+ 13  Síwájú sí i, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ ti kú nínú àwọn àṣemáṣe yín àti nínú ipò àìdádọ̀dọ́ ẹran ara yín, Ọlọ́run sọ yín di ààyè pa pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀.+ Ó fi inú rere dárí gbogbo àṣemáṣe wa+ jì wá, 14  ó sì pa ìwé àfọwọ́kọ+ tí ó lòdì sí wa rẹ́,+ èyí tí ó ní àwọn àṣẹ àgbékalẹ̀ nínú,+ tí ó sì wà ní ìlòdìsí wa;+ Ó sì ti mú un kúrò lójú ọ̀nà nípa kíkàn+ án níṣòó mọ́ òpó igi oró.+ 15  Ní títú àwọn alákòóso àti àwọn aláṣẹ+ sí borokoto, ó fi wọ́n hàn ní gbangba gẹ́gẹ́ bí àwọn tí a ti ṣẹ́gun,+ ó ń ṣamọ̀nà wọn nínú ìtọ́wọ̀ọ́rìn aláyọ̀ ìṣẹ́gun+ nípasẹ̀ rẹ̀. 16  Nítorí náà, ẹ má ṣe jẹ́ kí ènìyàn kankan ṣèdájọ́+ yín nínú jíjẹ àti mímu+ tàbí ní ti àjọyọ̀+ kan tàbí ní ti ààtò àkíyèsí òṣùpá tuntun+ tàbí ní ti sábáàtì;+ 17  nítorí nǹkan wọnnì jẹ́ òjìji+ àwọn nǹkan tí ń bọ̀, ṣùgbọ́n ohun gidi+ náà jẹ́ ti Kristi.+ 18  Ẹ má ṣe jẹ́ kí ènìyàn kankan fi ẹ̀bùn eré ìje+ náà dù+ yín, ẹni tí ń ní inú dídùn sí ìrẹ̀lẹ̀ ẹlẹ́yà àti ọ̀nà ìjọsìn àwọn áńgẹ́lì, “tí ń mú ìdúró rẹ̀ lórí” àwọn ohun tí ó rí, tí ipò èrò inú rẹ̀ nípa ti ara ń mú un wú fùkẹ̀ láìsí ìdí tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu, 19  nígbà tí ó jẹ́ pé kò di orí náà mú ṣinṣin,+ ipasẹ̀ ẹni tí gbogbo ara, tí a ń pèsè fún, tí a sì so pọ̀ ní ìṣọ̀kan+ nípasẹ̀ àwọn oríkèé àti àwọn iṣan adeegunpọ̀ rẹ̀, gbà ń bá a lọ ní dídàgbà pẹ̀lú ìdàgbà tí Ọlọ́run ń fi fúnni.+ 20  Bí ẹ bá ti kú+ pa pọ̀ pẹ̀lú Kristi sí àwọn ohun àkọ́bẹ̀rẹ̀+ ayé,+ èé ṣe tí ẹ̀yin, bí ẹni pé ẹ ń gbé nínú ayé, ṣe tún ń fi ara yín sábẹ́ àwọn àṣẹ àgbékalẹ̀+ náà: 21  “Má ṣe fọwọ́ dì mú, tàbí tọ́ wò,+ tàbí fara kàn,”+ 22  ní ti gbogbo ohun tí a ti yàn tẹ́lẹ̀ fún ìparun nípa lílò wọ́n tán, ní ìbámu pẹ̀lú àwọn àṣẹ àti àwọn ẹ̀kọ́ ènìyàn?+ 23  Ohun wọnnì gan-an, ní tòótọ́, ní ìrísí ọgbọ́n nínú ọ̀nà ìjọsìn àdábọwọ́ ara ẹni àti ìrẹ̀lẹ̀ ẹlẹ́yà, ìfìyàjẹ ara;+ ṣùgbọ́n wọn kò níye lórí rárá nínú gbígbógunti títẹ́ ẹran ara+ lọ́rùn.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé