Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Kólósè 1:1-29

1  Pọ́ọ̀lù, àpọ́sítélì Kristi Jésù nípasẹ̀ ìfẹ́ Ọlọ́run,+ àti Tímótì+ arákùnrin wa  sí àwọn ẹni mímọ́ àti àwọn olùṣòtítọ́ arákùnrin ní ìrẹ́pọ̀+ pẹ̀lú Kristi ní Kólósè: Kí ẹ ní inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí àti àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Baba wa Ọlọ́run.+  Àwa ń dúpẹ́+ lọ́wọ́ Ọlọ́run Baba Olúwa wa Jésù Kristi nígbà gbogbo tí a bá ń gbàdúrà fún yín,+  níwọ̀n bí a ti gbọ́ nípa ìgbàgbọ́ yín ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Kristi Jésù àti ìfẹ́ tí ẹ ní fún gbogbo ẹni mímọ́+  nítorí ìrètí+ tí a fi pa mọ́ dè yín ní ọ̀run.+ Ìrètí yìí ni ẹ gbọ́ nípa rẹ̀ ṣáájú nípa sísọ òtítọ́ ìhìn rere yẹn,+  èyí tí ó ti fi ara rẹ̀ hàn yín, àní gẹ́gẹ́ bí ó ti ń so èso,+ tí ó sì ń bí sí i+ ní gbogbo ayé+ gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti ń ṣe láàárín yín pẹ̀lú, láti ọjọ́ tí ẹ ti gbọ́, tí ẹ sì ti mọ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí+ Ọlọ́run lọ́nà pípéye ní òtítọ́.+  Èyíinì ni ohun tí ẹ ti kẹ́kọ̀ọ́ láti ọ̀dọ̀ Epafírásì+ olùfẹ́ ọ̀wọ́n tí í ṣe ẹrú ẹlẹgbẹ́ wa, ẹni tí ó jẹ́ olùṣòtítọ́ òjíṣẹ́ fún Kristi nítorí wa,  ẹni tí ó tún sọ ìfẹ́+ yín lọ́nà ti ẹ̀mí di mímọ̀ fún wa.  Ìdí tún nìyẹn tí ó fi jẹ́ pé, láti ọjọ́ tí a ti gbọ́ nípa rẹ̀, àwa kò ṣíwọ́ gbígbàdúrà fún yín+ àti bíbéèrè pé kí ẹ lè kún fún ìmọ̀ pípéye+ nípa ìfẹ́ rẹ̀ nínú ọgbọ́n+ gbogbo àti ìfinúmòye ti ẹ̀mí,+ 10  kí ẹ lè máa rìn lọ́nà tí ó yẹ+ Jèhófà+ fún ète wíwù ú ní kíkún bí ẹ ti ń bá a lọ ní síso èso nínú iṣẹ́ rere gbogbo,+ tí ẹ sì ń pọ̀ sí i nínú ìmọ̀ pípéye+ nípa Ọlọ́run, 11  tí a ń sọ yín di alágbára pẹ̀lú gbogbo agbára dé ìwọ̀n agbára ńlá rẹ̀ ológo+ kí ẹ bàa lè fara dà+ á ní kíkún, kí ẹ sì máa ní ìpamọ́ra pẹ̀lú ìdùnnú, 12  kí ẹ máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Baba tí ó mú yín yẹ fún ìkópa yín nínú ogún+ àwọn ẹni mímọ́+ nínú ìmọ́lẹ̀.+ 13  Ó dá wa nídè kúrò lọ́wọ́ ọlá àṣẹ+ òkùnkùn, ó sì ṣí wa nípò lọ+ sínú ìjọba+ Ọmọ ìfẹ́+ rẹ̀, 14  nípasẹ̀ ẹni tí a gba ìtúsílẹ̀ wa nípa ìràpadà, ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa.+ 15  Òun ni àwòrán+ Ọlọ́run tí a kò lè rí,+ àkọ́bí+ nínú gbogbo ìṣẹ̀dá; 16  nítorí pé nípasẹ̀ rẹ̀+ ni a dá gbogbo ohun mìíràn ní ọ̀run àti lórí ilẹ̀ ayé, àwọn ohun tí a lè rí àti àwọn ohun tí a kò lè rí, yálà wọn ì báà ṣe ìtẹ́ tàbí ipò olúwa tàbí ìjọba tàbí ọlá àṣẹ.+ Gbogbo ohun mìíràn ni a dá nípasẹ̀ rẹ̀+ àti fún un. 17  Pẹ̀lúpẹ̀lù, ó wà ṣáájú gbogbo ohun+ mìíràn, nípasẹ̀ rẹ̀ sì ni a gbà mú kí gbogbo ohun mìíràn wà,+ 18  òun sì ni orí fún ara, èyíini ni ìjọ.+ Òun ni ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀, àkọ́bí láti inú òkú,+ kí ó lè di ẹni tí ó jẹ́ àkọ́kọ́+ nínú ohun gbogbo; 19  nítorí Ọlọ́run rí i pé ó dára pé kí ẹ̀kún+ gbogbo máa gbé inú rẹ̀, 20  àti láti tún tipasẹ̀ rẹ̀ mú gbogbo ohun+ mìíràn padà rẹ́+ pẹ̀lú ara rẹ̀ nípa mímú àlàáfíà wá+ nípasẹ̀ ẹ̀jẹ̀+ tí ó ta sílẹ̀ lórí òpó igi oró,+ yálà wọn ì báà ṣe àwọn ohun tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé tàbí àwọn ohun tí ń bẹ ní ọ̀run. 21  Ní tòótọ́, ẹ̀yin tí a sọ di àjèjì+ àti ọ̀tá nígbà kan rí nítorí tí èrò inú yín wà lórí àwọn iṣẹ́ tí ó burú,+ 22  ni ó tún ti mú padà rẹ́+ nísinsìnyí nípasẹ̀ ẹran ara ẹni yẹn nípasẹ̀ ikú rẹ̀,+ kí ó lè mú yín wá ní mímọ́ àti ní àìlábààwọ́n+ àti ní àìfi àyè sílẹ̀ fún ẹ̀sùn+ kankan níwájú rẹ̀, 23  àmọ́ ṣá o, kìkì bí ẹ bá ń bá a lọ nínú ìgbàgbọ́,+ tí ẹ fìdí múlẹ̀ lórí ìpìlẹ̀ náà,+ tí ẹ sì fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin,+ tí a kò sì ṣí yín nípò kúrò nínú ìrètí ìhìn rere yẹn tí ẹ gbọ́,+ tí a sì wàásù+ nínú gbogbo ìṣẹ̀dá+ tí ń bẹ lábẹ́ ọ̀run. Ìhìn rere yìí ni èmi Pọ́ọ̀lù di òjíṣẹ́+ fún. 24  Mo ń yọ̀ nísinsìnyí nínú àwọn ìjìyà mi fún yín,+ èmi, ní tèmi ẹ̀wẹ̀, sì ń ṣe ẹ̀kún ohun tí ó kù nínú àwọn ìpọ́njú+ Kristi nínú ẹran ara mi nítorí ti ara rẹ̀, èyí tí í ṣe ìjọ.+ 25  Mo di òjíṣẹ́+ ìjọ yìí ní ìbámu pẹ̀lú iṣẹ́ ìríjú+ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, èyí tí a fi fún mi fún ire yín láti wàásù ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní kíkún, 26  àṣírí ọlọ́wọ̀+ tí a fi pa mọ́ láti àwọn ètò àwọn nǹkan tí ó ti kọjá+ àti láti àwọn ìran tí ó ti kọjá. Ṣùgbọ́n nísinsìnyí a ti fi í hàn kedere+ fún àwọn ẹni mímọ́ rẹ̀, 27  àwọn tí ó wu Ọlọ́run láti sọ ohun tí ó jẹ́ ọrọ̀ ológo+ nípa àṣírí ọlọ́wọ̀+ yìí di mímọ̀ fún láàárín àwọn orílẹ̀-èdè. Kristi+ ní í ṣe ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú yín, ìrètí ògo rẹ̀.+ 28  Òun ni ẹni tí a ń kéde,+ tí a ń ṣí olúkúlùkù ènìyàn létí, tí a sì ń kọ́ olúkúlùkù ènìyàn nínú ọgbọ́n+ gbogbo, kí a lè mú olúkúlùkù ènìyàn wá ní pípé pérépéré+ ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Kristi. 29  Fún ète yìí ni èmi ń ṣiṣẹ́ kára ní tòótọ́, mo ń tiraka+ ní ìbámu pẹ̀lú ìṣiṣẹ́+ rẹ̀, èyí tí ń fi agbára+ ṣiṣẹ́ nínú mi.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé