Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Jeremáyà 9:1-26

9  Ì bá ṣe pé orí mi jẹ́ omi, tí ojú mi sì jẹ́ orísun omijé!+ Nígbà náà, èmi ì bá máa sunkún tọ̀sán-tòru fún ọmọbìnrin àwọn ènìyàn mi tí a pa.+  Ì bá ṣe pé mo ní ibi tí àwọn arìnrìn-àjò ń wọ̀ sí ní aginjù!+ Nígbà náà, èmi ì bá fi àwọn ènìyàn mi sílẹ̀ láti lọ kúrò lọ́dọ̀ wọn, nítorí panṣágà ni gbogbo wọn,+ àpéjọ ọ̀wọ̀ ti àwọn olùṣe àdàkàdekè;+  wọ́n sì ń fa ahọ́n wọn bí ọrun wọn nínú èké;+ ṣùgbọ́n kì í ṣe fún ìṣòtítọ́ ni wọ́n jẹ́ alágbára ńlá ní ilẹ̀ náà. “Nítorí láti orí ìwà búburú sí orí ìwà búburú ni wọ́n ti jáde lọ, wọ́n sì fi èmi pàápàá dá àgunlá,”+ ni àsọjáde Jèhófà.  “Kí olúkúlùkù yín ṣọ́ra lọ́dọ̀ alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀,+ ẹ má sì gbẹ́kẹ̀ yín lé arákùnrin rárá.+ Nítorí, àní olúkúlùkù arákùnrin yóò fèrú gbapò dájúdájú,+ olúkúlùkù alábàákẹ́gbẹ́ pàápàá yóò sì máa rìn ká bí afọ̀rọ̀-èké-banijẹ́ lásán-làsàn,+  olúkúlùkù sì ń fi alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ ṣeré;+ wọn kò sì sọ òtítọ́ rárá. Wọ́n ti kọ́ ahọ́n wọn láti ṣe èké.+ Wọ́n ti ṣe àìtọ́ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí àárẹ̀ fi mú wọn.+  “Ìjókòó rẹ wà ní àárín ẹ̀tàn.+ Nípa ẹ̀tàn, wọ́n ti kọ̀ láti mọ̀ mí,”+ ni àsọjáde Jèhófà.  Nítorí náà, èyí ni ohun tí Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wí: “Kíyè sí i, èmi yóò yọ́ wọn, èmi yóò sì wádìí wọn wò dájúdájú,+ nítorí bí kò bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, báwo ni mo ṣe lè gbé ìgbésẹ̀ ní tìtorí ọmọbìnrin àwọn ènìyàn mi?+  Ọfà tí ń gúnni pa ni ahọ́n wọn.+ Ẹ̀tàn ni ohun tí ó ń sọ. Ní ẹnu rẹ̀, àlàáfíà ni ènìyàn kan ń bá alábàákẹ́gbẹ́ tirẹ̀ sọ; ṣùgbọ́n nínú ara rẹ̀, ó ba ní ibùba.”+  “Nítorí nǹkan wọ̀nyí, kò ha yẹ kí n béèrè ìjíhìn lọ́wọ́ wọn?” ni àsọjáde Jèhófà. “Tàbí ọkàn mi kì yóò ha gbẹ̀san lára orílẹ̀-èdè tí ó rí bí èyí?+ 10  Èmi yóò gbé ohùn ẹkún sísun àti ìdárò sókè nítorí àwọn òkè ńlá,+ àti orin arò nítorí àwọn ilẹ̀ ìjẹko aginjù; nítorí a ó ti fi iná sun wọ́n+ tí kì yóò fi sí ènìyàn kankan tí ó ń gba ibẹ̀ kọjá, àwọn ènìyàn kì yóò sì gbọ́ ìró ohun ọ̀sìn rárá.+ Ẹ̀dá tí ń fò ní ojú ọ̀run àti ẹranko yóò ti sá lọ; wọn yóò ti lọ.+ 11  Dájúdájú, èmi yóò sì sọ Jerúsálẹ́mù di ìtòjọpelemọ òkúta,+ ibùgbé àwọn akátá;+ èmi yóò sì sọ ìlú ńlá Júdà di ahoro, láìní olùgbé.+ 12  “Ta ni ọkùnrin tí ó gbọ́n, kí ó lè lóye èyí, àní ẹni tí ẹnu Jèhófà bá sọ̀rọ̀, kí ó lè sọ ọ́?+ Ní tìtorí kí ni ilẹ̀ náà yóò fi ṣègbé ní ti gidi, tí yóò fi di èyí tí a fi iná sun ní ti gidi bí aginjù láìsí ẹnì kankan tí ó ń gba ibẹ̀ kọjá?”+ 13  Jèhófà sì tẹ̀ síwájú láti wí pé: “Ní tìtorí fífi tí wọ́n fi òfin mi sílẹ̀, tí mo gbé kalẹ̀ níwájú wọn, àti nítorí pé wọn kò ṣègbọràn sí ohùn mi, tí wọn kò sì rìn nínú rẹ̀,+ 14  ṣùgbọ́n wọ́n ń tọ agídí ọkàn-àyà wọn+ lẹ́yìn,+ wọ́n sì ń tọ àwọn ère Báálì lẹ́yìn, èyí tí àwọn baba wọn ti kọ́ wọn;+ 15  nítorí náà, èyí ni ohun tí Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí, ‘Kíyè sí i, èmi yóò mú, èyíinì ni, àwọn ènìyàn yìí, jẹ iwọ,+ dájúdájú, èmi yóò sì mú wọn mu omi onímájèlé;+ 16  ṣe ni èmi yóò tú wọn ká sáàárín àwọn orílẹ̀-èdè tí àwọn tàbí àwọn baba wọn kò mọ̀,+ dájúdájú, èmi yóò sì rán idà tọ̀ wọ́n lẹ́yìn títí èmi yóò fi pa wọ́n run pátápátá.’+ 17  “Èyí ni ohun tí Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wí, ‘Ẹ fi òye hùwà, ẹ sì pe àwọn obìnrin tí ń kọ orin arò,+ kí wọ́n lè wá; ẹ sì ránṣẹ́ sí àwọn ọ̀jáfáfá obìnrin pàápàá, kí wọ́n lè wá,+ 18  kí wọ́n sì lè ṣe wéré, kí wọ́n sì gbé ohùn ìdárò sókè lórí wa. Kí omijé sì ṣàn wálẹ̀ ní ojú wa, kí ojú wa tí ń tàn yanran sì sun omi.+ 19  Nítorí ohùn ìdárò ni a gbọ́ ní Síónì:+ “Ẹ wo bí a ti fi wá ṣe ìjẹ!+ Ẹ wo bí ojú ti tì wá tó! Nítorí a ti fi ilẹ̀ náà sílẹ̀; nítorí wọ́n ti gbé ibùgbé wa sọnù.”+ 20  Ṣùgbọ́n, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà, ẹ̀yin obìnrin, kí etí yín sì gba ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀. Lẹ́yìn náà, ẹ kọ́ àwọn ọmọbìnrin yín ní ìdárò,+ kí olúkúlùkù obìnrin sì kọ́ alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ ní orin arò.+ 21  Nítorí ikú ti gba ojú fèrèsé wa gòkè wá; ó ti dé inú ilé gogoro ibùgbé wa, láti ké ọmọ kúrò ní ojú pópó, láti ké àwọn ọ̀dọ́kùnrin kúrò ní àwọn ojúde ìlú.’+ 22  “Sọ pé, ‘Èyí ni àsọjáde Jèhófà: “Òkú aráyé yóò sì ṣubú pẹ̀lú bí ajílẹ̀ lórí pápá àti bí ẹsẹ ọkà tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ gé lẹ́yìn akárúgbìn, láìsí ẹnì kankan láti ṣe kíkójọpọ̀.”’”+ 23  Èyí ni ohun tí Jèhófà wí: “Kí ọlọ́gbọ́n má ṣe fọ́nnu nípa ara rẹ̀ nítorí ọgbọ́n rẹ̀,+ kí alágbára ńlá má sì fọ́nnu nípa ara rẹ̀ nítorí agbára ńlá rẹ̀.+ Kí ọlọ́rọ̀ má ṣe fọ́nnu nípa ara rẹ̀ nítorí ọrọ̀ rẹ̀.”+ 24  “Ṣùgbọ́n kí ẹni tí ń fọ́nnu nípa ara rẹ̀ fọ́nnu nípa ara rẹ̀ nítorí ohun yìí gan-an, níní tí ó ní ìjìnlẹ̀ òye+ àti níní tí ó ní ìmọ̀ mi, pé èmi ni Jèhófà,+ Ẹni tí ń ṣe inú-rere-onífẹ̀ẹ́, ìdájọ́ òdodo àti òdodo ní ilẹ̀ ayé;+ nítorí nǹkan wọ̀nyí ni mo ní inú dídùn sí,”+ ni àsọjáde Jèhófà. 25  “Wò ó! Àwọn ọjọ́ ń bọ̀,” ni àsọjáde Jèhófà, “dájúdájú, èmi yóò sì béèrè ìjíhìn lọ́wọ́ olúkúlùkù ẹni tí a dádọ̀dọ́ rẹ̀ ṣùgbọ́n tí ó wà ní ipò àìdádọ̀dọ́ síbẹ̀,+ 26  lórí Íjíbítì+ àti lórí Júdà+ àti lórí Édómù+ àti lórí àwọn ọmọ Ámónì+ àti lórí Móábù+ àti lórí gbogbo àwọn tí a gé irun wọn mọ́lẹ̀ ní ẹ̀bátí, tí wọ́n ń gbé ní aginjù;+ nítorí gbogbo orílẹ̀-èdè náà jẹ́ aláìdádọ̀dọ́, gbogbo ilé Ísírẹ́lì sì jẹ́ aláìdádọ̀dọ́ ọkàn-àyà.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé