Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Jeremáyà 8:1-22

8  “Ní àkókò yẹn,” ni àsọjáde Jèhófà, “àwọn ènìyàn yóò sì kó egungun àwọn ọba Júdà àti egungun àwọn ọmọ aládé rẹ̀ àti egungun àwọn àlùfáà àti egungun àwọn wòlíì àti egungun àwọn olùgbé Jerúsálẹ́mù jáde wá láti inú sàréè wọn.+  Ní ti gidi, wọn yóò sì tàn wọ́n kálẹ̀ sí oòrùn àti sí òṣùpá àti sí gbogbo ẹgbẹ́ ọmọ ogun ọ̀run tí wọ́n nífẹ̀ẹ́, tí wọ́n sì ti sìn, tí wọ́n sì ti tọ̀ lẹ́yìn,+ tí wọ́n sì ti wá, tí wọ́n sì ti tẹrí ba fún.+ A kì yóò kó wọn jọ, bẹ́ẹ̀ ni a kì yóò sin wọ́n. Bí ajílẹ̀ lórí ilẹ̀ ni wọn yóò dà.”+  “Dájúdájú, ikú yóò sì di yíyàn dípò ìyè,+ níhà ọ̀dọ̀ gbogbo àṣẹ́kù àwọn tí ó ṣẹ́ kù nínú ìdílé búburú yìí ní gbogbo ibi tí àwọn tí ó ṣẹ́ kù bá wà, níbi tí èmi yóò fọ́n wọn ká sí,”+ ni àsọjáde Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun.  “Ìwọ yóò sì wí fún wọn pé, ‘Èyí ni ohun tí Jèhófà wí: “Wọn yóò ha ṣubú láìdìde mọ́ bí?+ Bí ọ̀kan bá yí padà, èkejì kì yóò ha yí padà pẹ̀lú bí?+  Èé ṣe tí àwọn ènìyàn yìí, Jerúsálẹ́mù, fi jẹ́ aláìṣòótọ́ pẹ̀lú àìṣòótọ́ tí ó ti wà tipẹ́tipẹ́? Wọ́n ti di àgálámàṣà mú;+ wọ́n ti kọ̀ láti yí padà.+  Mo ti fiyè sílẹ̀,+ mo sì ń fetí sílẹ̀.+ Ọ̀nà tí wọ́n gbà ń sọ̀rọ̀ kò tọ́. Kò sí ènìyàn kankan tí ó ronú pìwà dà lórí ìwà búburú rẹ̀,+ pé, ‘Kí ni mo ṣe?’ Olúkúlùkù ń padà lọ sí ipa ọ̀nà gbígbajúmọ̀,+ bí ẹṣin tí ń já lọ fìà-fìà síbi ìjà ogun.  Àní ẹyẹ àkọ̀ ní ojú ọ̀run—ó mọ àkókò rẹ̀ tí a yàn kalẹ̀ dáadáa;+ àti oriri+ àti ẹyẹ olófèéèré àti ọ̀pẹ́ẹ̀rẹ́—dáadáa ni wọ́n ń ṣàkíyèsí àkókò tí olúkúlùkù wọn ń wọlé wá. Ṣùgbọ́n ní ti àwọn ènìyàn mi, wọn kò mọ ìdájọ́ Jèhófà”’+  “‘Báwo ni ẹ ṣe lè wí pé: “Ọlọ́gbọ́n ni wá, òfin Jèhófà sì wà pẹ̀lú wa”?+ Ó dájú pé, nísinsìnyí, kálàmù èké+ tí ó jẹ́ ti akọ̀wé ti ṣiṣẹ́ kìkìdá èké.  Ojú ti àwọn ọlọ́gbọ́n.+ Àyà wọn já, a ó sì mú wọn. Wò ó! Àní wọ́n ti kọ ọ̀rọ̀ Jèhófà, ọgbọ́n wo sì ni wọ́n ní?+ 10  Nítorí náà, èmi yóò fi àwọn aya wọn fún àwọn ọkùnrin mìíràn, àwọn pápá wọn fún àwọn tí yóò gbà wọ́n;+ nítorí, láti orí ẹni kíkéré jù lọ nínú wọn àní títí dórí ẹni títóbi jù lọ, olúkúlùkù ń jẹ èrè tí kò bá ìdájọ́ òdodo mu;+ láti orí wòlíì àní títí dórí àlùfáà, olúkúlùkù ń ṣe èké.+ 11  Wọ́n sì ń gbìyànjú láti mú ìwópalẹ̀ ọmọbìnrin àwọn ènìyàn mi lára dá fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́,+ pé: “Àlàáfíà wà! Àlàáfíà wà!” nígbà tí kò sí àlàáfíà.+ 12  Ojú ha tì wọ́n nítorí wọ́n ti ṣe àní ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí?+ Ní ọwọ́ kan, ojú kò lè tì wọ́n rárá; ní ọwọ́ kejì, wọn kò tilẹ̀ mọ bí a ṣe ń mọ ìtẹ́lógo lára.+ “‘Nítorí náà, wọn yóò ṣubú láàárín àwọn tí ń ṣubú. Ní àkókò tí a óò fún wọn ní àfiyèsí,+ wọn yóò kọsẹ̀,’ ni Jèhófà wí.+ 13  “‘Nígbà tí mo bá ń ṣe ìkójọ, èmi yóò mú wọn wá sí òpin wọn,’ ni àsọjáde Jèhófà.+ ‘Kì yóò sí èso àjàrà kankan lórí àjàrà,+ kì yóò sì sí ọ̀pọ̀tọ́ kankan lórí igi ọ̀pọ̀tọ́, àwọn ẹ̀ka eléwé pàápàá yóò sì rọ dájúdájú. Àwọn ohun tí mo sì fún wọn yóò kọjá wọn.’” 14  “Èé ṣe tí a fi jókòó jẹ́ẹ́? Ẹ kó ara yín jọpọ̀, ẹ sì jẹ́ kí a wọnú àwọn ìlú ńlá olódi,+ kí a sì dákẹ́ jẹ́ẹ́ níbẹ̀. Nítorí Jèhófà Ọlọ́run wa fúnra rẹ̀ ti pa wá lẹ́nu mọ́,+ ó sì fún wa ni omi onímájèlé mu,+ nítorí pé a ti ṣẹ̀ sí Jèhófà. 15  Ríretí àlàáfíà wà, ṣùgbọ́n ohun rere kankan kò sí;+ fún àkókò ìmúláradá, ṣùgbọ́n, wò ó! ìpayà!+ 16  A ti gbọ́ imú fífọn àwọn ẹṣin rẹ̀ láti Dánì.+ Nítorí ìró yíyán àwọn akọ ẹṣin rẹ̀, gbogbo ilẹ̀ náà ti bẹ̀rẹ̀ sí mì jìgìjìgì.+ Wọ́n sì wọlé wá, wọ́n sì jẹ ilẹ̀ náà àti ohun tí ó kún inú rẹ̀ run, ìlú ńlá náà àti àwọn olùgbé rẹ̀.” 17  “Nítorí, kíyè sí i, èmi yóò rán àwọn ejò, àwọn ejò olóró,+ sí àárín yín, èyí tí kì yóò ṣe é tù lójú,+ dájúdájú, wọn yóò sì bù yín ṣán,” ni àsọjáde Jèhófà. 18  Ẹ̀dùn-ọkàn tí ó ré kọjá wíwòsàn ti wá sínú mi.+ Ọkàn-àyà mi ń ṣàmódi. 19  Ìró igbe fún ìrànlọ́wọ́ rèé láti ọ̀dọ̀ ọmọbìnrin àwọn ènìyàn mi láti ilẹ̀ jíjìnnàréré:+ “Ṣé Jèhófà kò sí ní Síónì ni?+ Tàbí kẹ̀, ṣé ọba rẹ̀ kò sí nínú rẹ̀ ni?”+ “Èé ṣe tí wọ́n fi mú mi bínú pẹ̀lú ère fífín wọn, pẹ̀lú àwọn ọlọ́run asán wọn tí ó jẹ́ ti ilẹ̀ òkèèrè?”+ 20  “Ìkórè ti kọjá, ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn ti wá sí òpin; ṣùgbọ́n ní tiwa, a kò tíì rí ìgbàlà!”+ 21  Nítorí ìwópalẹ̀+ ọmọbìnrin àwọn ènìyàn mi, mo ti di ẹni tí a fọ́ túútúú.+ Inú mi ti bàjẹ́. Ìyàlẹ́nu tí ó peléke ti gbá mi mú.+ 22  Ṣé básámù kò sí ní Gílíádì ni?+ Ṣé kò sí amúniláradá níbẹ̀ ni?+ Kí wá ni ìdí rẹ̀, tí ìkọ́fẹ+ ọmọbìnrin àwọn ènìyàn mi kò fi tíì dé?+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé