Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Jeremáyà 7:1-34

7  Ọ̀rọ̀ tí ó tọ Jeremáyà wá láti ọ̀dọ̀ Jèhófà, pé:  “Dúró ní ẹnubodè ilé Jèhófà, kí o sì pòkìkí ọ̀rọ̀ yìí níbẹ̀,+ kí o sì wí pé, ‘Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà, gbogbo ẹ̀yin ti Júdà, tí ń wọ ẹnubodè wọ̀nyí láti tẹrí ba fún Jèhófà.  Èyí ni ohun tí Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí: “Ẹ ṣe àwọn ọ̀nà yín àti àwọn ìbálò yín ní rere, dájúdájú, èmi yóò sì mú yín máa gbé ibí yìí.+  Ẹ má ṣe gbẹ́kẹ̀ yín lé àwọn ọ̀rọ̀ èké,+ pé, ‘Tẹ́ńpìlì Jèhófà, tẹ́ńpìlì Jèhófà, tẹ́ńpìlì Jèhófà ni wọ́n!’  Nítorí bí ẹ óò bá ṣe àwọn ọ̀nà yín àti àwọn ìbálò yín ní rere dájúdájú, bí ẹ óò bá ṣe ìdájọ́ òdodo láàárín ènìyàn àti alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀,+  bí ẹ kò bá ni àtìpó, ọmọdékùnrin aláìníbaba àti opó lára,+ tí ẹ kò sì ta ẹ̀jẹ̀ aláìmọwọ́-mẹsẹ̀ sílẹ̀ ní ibí yìí,+ tí ẹ kò sì tọ àwọn ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn sí ìyọnu àjálù yín,+  èmi, ẹ̀wẹ̀, yóò mú yín máa gbé ibí yìí dájúdájú, ní ilẹ̀ tí mo fún àwọn baba ńlá yín, láti àkókò tí ó lọ kánrin àní dé àkókò tí ó lọ kánrin.”’”+  “Kíyè sí i, ẹ gbẹ́kẹ̀ yín lé ọ̀rọ̀ èké—dájúdájú, kì yóò ṣàǹfààní rárá.+  Jíjalè,+ ìṣìkàpànìyàn+ àti ṣíṣe panṣágà+ àti bíbúra lọ́nà èké+ àti rírú èéfín ẹbọ sí Báálì+ àti títọ àwọn ọlọ́run mìíràn tí ẹ kò mọ̀ lẹ́yìn ha lè wà,+ 10  ó ha sì yẹ kí ẹ wá, kí ẹ sì wá dúró níwájú mi nínú ilé yìí tí a fi orúkọ mi pè,+ kí ẹ sì wí pé, ‘Dájúdájú, a óò dá wa nídè,’ pẹ̀lú ṣíṣe gbogbo ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí wọ̀nyí? 11  Ilé yìí tí a fi orúkọ mi pè+ ha ti di kìkì hòrò àwọn ọlọ́ṣà ní ojú yín bí?+ Kíyè sí i, èmi fúnra mi ti rí i pẹ̀lú,” ni àsọjáde Jèhófà.+ 12  “‘Bí ó ti wù kí ó rí, nísinsìnyí, ẹ lọ sí àyè mi tí ó wà ní Ṣílò,+ níbi tí mo mú kí orúkọ mi wà ní ìbẹ̀rẹ̀pàá,+ sì wo ohun tí mo ṣe sí i nítorí ìwà búburú àwọn ènìyàn mi, Ísírẹ́lì.+ 13  Wàyí o, nítorí tí ẹ ń bá a nìṣó ní ṣíṣe gbogbo iṣẹ́ wọ̀nyí,’ ni àsọjáde Jèhófà, ‘tí mo sì ń bá yín sọ̀rọ̀ ṣáá, mo ń dìde ní kùtùkùtù, tí mo sì ń sọ̀rọ̀,+ ṣùgbọ́n ẹ kò fetí sílẹ̀,+ mo sì ń pè yín ṣáá, ṣùgbọ́n ẹ kò dá mi lóhùn,+ 14  gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣe sí Ṣílò,+ bákan náà ni èmi yóò ṣe dájúdájú sí ilé tí a fi orúkọ mi pè,+ èyí tí ẹ gbẹ́kẹ̀ lé,+ àti sí ibi tí mo fi fún yín àti fún àwọn baba ńlá yín. 15  Dájúdájú, èmi yóò sọ yín síta kúrò níwájú mi,+ gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti sọ gbogbo àwọn arákùnrin yín síta, gbogbo àwọn ọmọ Éfúráímù.’+ 16  “Àti ní tìrẹ, má ṣe gbàdúrà nítorí àwọn ènìyàn yìí, má sì ṣe gbé ohùn igbe ìpàrọwà sókè tàbí àdúrà tàbí kí o fi taratara bẹ̀ mí nítorí wọn,+ nítorí èmi kì yóò fetí sí ọ.+ 17  Ìwọ kò ha rí ohun tí wọ́n ń ṣe ní àwọn ìlú ńlá Júdà àti ní àwọn ojú pópó Jerúsálẹ́mù?+ 18  Àwọn ọmọ ń ṣa ìṣẹ́pẹ́ igi, àwọn baba sì ń dá iná, àwọn aya sì ń po àpòrọ́ ìyẹ̀fun láti fi ṣe àwọn àkàrà ìrúbọ sí ‘ọbabìnrin ọ̀run’;+ dída àwọn ọrẹ ẹbọ ohun mímu+ sí ọlọ́run mìíràn sì wà, kí wọ́n bàa lè mú mi bínú.+ 19  ‘Èmi ha ni wọ́n ń mú bínú bí?’ ni àsọjáde Jèhófà.+ ‘Kì í ha ṣe àwọn fúnra wọn, kí ojú bàa lè tì wọ́n?’+ 20  Nítorí náà, èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí, ‘Wò ó! Ìbínú mi àti ìhónú mi ni a óò tú jáde sórí ibí yìí,+ sórí aráyé àti sórí ẹran agbéléjẹ̀, àti sórí igi pápá+ àti sórí èso ilẹ̀; yóò sì jóná, a kì yóò sì paná rẹ̀.’+ 21  “Èyí ni ohun tí Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí, ‘Ẹ fi odindi ọrẹ ẹbọ sísun yín wọnnì kún ẹbọ yín kí ẹ sì jẹ ẹran.+ 22  Nítorí èmi kò bá àwọn baba ńlá yín sọ̀rọ̀, bẹ́ẹ̀ sì ni èmi kò pàṣẹ fún wọn ní ọjọ́ tí mo ń mú wọn jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì ní ti àwọn ọ̀ràn odindi ọrẹ ẹbọ sísun àti ẹbọ.+ 23  Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ yìí ni mo pa ní àṣẹ fún wọn, pé: “Ẹ ṣègbọràn sí ohùn mi,+ èmi yóò sì di Ọlọ́run yín,+ ẹ̀yin alára yóò sì di ènìyàn mi; kí ẹ sì máa rìn ní gbogbo ọ̀nà+ tí èmi yóò pa láṣẹ fún yín, kí nǹkan lè máa lọ dáadáa fún yín.”’+ 24  Ṣùgbọ́n wọn kò fetí sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ sì ni wọn kò dẹ etí wọn sílẹ̀,+ ṣùgbọ́n wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí rìn nínú ìmọ̀ràn, nínú agídí ọkàn-àyà búburú wọn,+ tí wọ́n fi padà sí ìhà ẹ̀yìn, kì í ṣe iwájú,+ 25  láti ọjọ́ tí àwọn baba ńlá yín ti jáde wá láti ilẹ̀ Íjíbítì títí di òní yìí;+ mo sì ń rán gbogbo àwọn ìránṣẹ́ mi wòlíì sí yín ṣáá, mo ń dìde lójoojúmọ́ ní kùtùkùtù mo sì ń rán wọn.+ 26  Ṣùgbọ́n wọn kò fetí sí mi, wọn kò sì dẹ etí wọn sílẹ̀,+ ṣùgbọ́n wọ́n ń mú ọrùn wọn le ṣáá.+ Wọ́n ṣe búburú ju àwọn baba ńlá wọn!+ 27  “Kí o sì sọ gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fún wọn,+ ṣùgbọ́n wọn kì yóò fetí sí ọ; kí o sì pè wọ́n, ṣùgbọ́n wọn kì yóò dá ọ lóhùn.+ 28  Kí o sì wí fún wọn pé, ‘Èyí ni orílẹ̀-èdè náà tí àwọn ènìyàn rẹ̀ kò ṣègbọràn sí ohùn Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀,+ tí kò sì tẹ́wọ́ gba ìbáwí.+ Ìṣòtítọ́ ti ṣègbé, a sì ti ké e kúrò ní ẹnu wọn.’+ 29  “Rẹ́ irun rẹ tí a kò gé kúrò, kí o sì sọ ọ́ nù,+ sì gbé ohùn orin arò sókè lórí òkè kékeré dídán borokoto, gbé orin arò sókè,+ nítorí pé Jèhófà ti kọ+ ìran tí ó bínú sí kíkankíkan, òun yóò sì kọ̀ ọ́ tì.+ 30  ‘Nítorí àwọn ọmọ Júdà ti ṣe ohun tí ó burú ní ojú mi,’ ni àsọjáde Jèhófà. ‘Wọ́n ti gbé àwọn ohun ìríra wọn kalẹ̀ sínú ilé tí a fi orúkọ mi pè, láti sọ ọ́ di ẹlẹ́gbin.+ 31  Wọ́n sì ti kọ́ àwọn ibi gíga Tófétì,+ èyí tí ó wà ní àfonífojì ọmọ Hínómù,+ láti sun àwọn ọmọkùnrin wọn àti àwọn ọmọbìnrin wọn nínú iná,+ ohun tí èmi kò pa láṣẹ tí kò sì wá sínú ọkàn-àyà mi.’+ 32  “‘Nítorí náà, wò ó! àwọn ọjọ́ ń bọ̀,’ ni àsọjáde Jèhófà, ‘nígbà tí a kì yóò tún pè é ní Tófétì àti àfonífojì ọmọ Hínómù mọ́, bí kò ṣe àfonífojì ìpànìyàn;+ ṣe ni wọn yóò sì máa sìnkú ní Tófétì láìsí àyè tí ó tó.+ 33  Òkú àwọn ènìyàn yìí yóò sì di oúnjẹ fún àwọn ẹ̀dá tí ń fò ní ojú ọ̀run àti fún àwọn ẹranko orí ilẹ̀, láìsí ẹnikẹ́ni tí yóò mú wọn wárìrì.+ 34  Dájúdájú, èmi yóò mú kí ohùn ayọ̀ ńláǹlà àti ohùn ayọ̀ yíyọ̀, ohùn ọkọ ìyàwó àti ohùn ìyàwó kásẹ̀ nílẹ̀ ní àwọn ìlú ńlá Júdà àti ní àwọn ojú pópó Jerúsálẹ́mù;+ nítorí ilẹ̀ náà yóò di ibi ìparundahoro pátápátá.’”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé