Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Jeremáyà 6:1-30

6  Ẹ wá ibi ààbò, ẹ̀yin ọmọ Bẹ́ńjámínì, kúrò ní àárín Jerúsálẹ́mù; ẹ sì fun ìwo+ ní Tékóà.+ Ẹ sì gbé àmì àfiyèsí tí ó jẹ́ iná sókè lórí Bẹti-hákérémù;+ nítorí pé ìyọnu àjálù pàápàá ti bojú wolẹ̀ láti àríwá, àní ìfọ́yángá ńláǹlà.+  Ní tòótọ́, ọmọbìnrin Síónì jọ obìnrin dídára rèǹtè-rente àti ẹlẹ́wà oge.+  Ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni àwọn olùṣọ́ àgùntàn àti agbo ẹran ọ̀sìn wọn bẹ̀rẹ̀ sí wá. Wọ́n pa àgọ́ wọn tì í yí ká.+ Olúkúlùkù wọn jẹko ní apá tirẹ̀.+  Wọ́n ti sọ ogun di mímọ́ lòdì sí i:+ “Dìde, sì jẹ́ kí a gòkè lọ ní ọjọ́kanrí!”+ “A gbé, nítorí ọjọ́ ti rọ̀, nítorí òjìji ìrọ̀lẹ́ ń fa ara rẹ̀ gùn síwájú!”  “Dìde, sì jẹ́ kí a gòkè lọ ní òru, kí a sì run àwọn ilé gogoro ibùgbé rẹ̀.”+  Nítorí, èyí ni ohun tí Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wí: “Gé igi lulẹ̀+ kí o sì yára kọ́ ohun àfiṣe-odi ìsàgatì ti Jerúsálẹ́mù.+ Ìlú ńlá tí a gbọ́dọ̀ béèrè ìjíhìn lọ́wọ́ rẹ̀ ni.+ Ìnilára gbáà ni ó jẹ́ láàárín rẹ̀.+  Bí ìkùdu tí ń mú omi rẹ̀ tutù, bẹ́ẹ̀ ni ó ti mú ìwà búburú rẹ̀ tutù. Ìwà ipá àti ìfiṣèjẹ ni a gbọ́ nínú rẹ̀;+ àìsàn àti ìyọnu àjàkálẹ̀ wà níwájú mi nígbà gbogbo.  Gba ìtọ́sọ́nà,+ ìwọ Jerúsálẹ́mù, kí ọkàn mi má bàa ṣí kúrò lọ́dọ̀ rẹ nínú ìríra;+ kí n má bàa ṣe ọ ní ahoro, ilẹ̀ tí kò ní olùgbé.”+  Èyí ni ohun tí Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wí: “Láìkùnà, wọn yóò pèéṣẹ́ àṣẹ́kù Ísírẹ́lì gan-an gẹ́gẹ́ bí àjàrà.+ Dá ọwọ́ rẹ padà bí ẹni tí ń kó èso àjàrà jọ lórí ọwọ́ àjàrà.” 10  “Ta ni èmi yóò bá sọ̀rọ̀, tí èmi yóò sì fún ní ìkìlọ̀, kí wọ́n lè gbọ́? Wò ó! A kò dádọ̀dọ́ etí wọn, tí wọn kò fi lè fiyè sílẹ̀.+ Wò ó! àní Ọ̀rọ̀ Jèhófà ti di ẹ̀gàn sí wọn,+ ọ̀rọ̀ tí wọn kò lè ní inú dídùn sí.+ 11  Mo sì ti kún fún ìhónú Jèhófà. Àárẹ̀ mú mi láti mú un mọ́ra.”+ “Dà á sórí àwọn ọmọ ní ojú pópó+ àti sórí àwùjọ tímọ́tímọ́ àwọn ọ̀dọ́kùnrin lẹ́sẹ̀ kan náà; nítorí a óò mú àwọn náà pẹ̀lú, ọkùnrin pa pọ̀ pẹ̀lú aya rẹ̀, arúgbó pa pọ̀ pẹ̀lú ẹni tí ó kún fún ọjọ́.+ 12  Dájúdájú, ilé wọn ni a ó sì fi lé àwọn mìíràn lọ́wọ́ ní ìní, àwọn pápá àti aya lẹ́sẹ̀ kan náà.+ Nítorí èmi yóò na ọwọ́ mi lòdì sí àwọn olùgbé ilẹ̀ náà,” ni àsọjáde Jèhófà.+ 13  “Nítorí láti orí ẹni kíkéré jù lọ nínú wọn àní títí dórí ẹni títóbi jù lọ nínú wọn, olúkúlùkù ń jẹ èrè tí kò bá ìdájọ́ òdodo mu fún ara rẹ̀;+ àti láti orí wòlíì àní títí dórí àlùfáà, olúkúlùkù ń ṣe èké.+ 14  Wọ́n sì ń gbìyànjú láti mú ìwópalẹ̀ àwọn ènìyàn mi lára dá fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́,+ pé, ‘Àlàáfíà wà! Àlàáfíà wà!’ nígbà tí kò sí àlàáfíà.+ 15  Ojú ha tì wọ́n nítorí pé ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí ni wọ́n ṣe bí?+ Ní ọwọ́ kan, ojú kò tì wọ́n rárá; ní ọwọ́ kejì, wọn kò mọ bí a tilẹ̀ ṣe ń mọ ìtẹ́lógo lára.+ Nítorí náà, wọn yóò ṣubú láàárín àwọn tí ń ṣubú;+ ní àkókò tí èmi yóò béèrè ìjíhìn lọ́wọ́ wọn, wọn yóò kọsẹ̀,” ni Jèhófà wí. 16  Èyí ni ohun tí Jèhófà wí: “Ẹ dúró jẹ́ẹ́ ní ọ̀nà, kí ẹ sì rí, ẹ béèrè fún àwọn òpópónà ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn, ibi tí ọ̀nà tí ó dára wà nísinsìnyí;+ ẹ sì máa rìn ín,+ kí ẹ sì rí ìdẹ̀rùn fún ọkàn yín.”+ Ṣùgbọ́n wọ́n ń wí pé: “Àwa kì yóò rìn.”+ 17  “Mo sì gbé àwọn olùṣọ́ lé yín lórí,+ ‘Ẹ fiyè sí ìró ìwo!’”+ Ṣùgbọ́n wọ́n ń wí pé: “Àwa kì yóò fiyè sílẹ̀.”+ 18  “Nítorí náà, ẹ gbọ́, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè! Sì mọ̀, ìwọ àpéjọ, ohun tí yóò wà láàárín wọn. 19  Fetí sílẹ̀, ìwọ ilẹ̀ ayé! Kíyè sí i, èmi yóò mú ìyọnu àjálù wá sórí àwọn ènìyàn yìí+ gẹ́gẹ́ bí èso ìrònú wọn,+ nítorí wọn kò fiyè sí ọ̀rọ̀ tèmi gan-an; àti òfin mi—wọ́n ń kọ̀ ọ́ ṣáá pẹ̀lú.”+ 20  “Kí ni èyí jámọ́ fún mi pé ẹ ń mú oje igi tùràrí pàápàá láti Ṣébà+ àti ewéko onípòròpórò dídára wá láti ilẹ̀ jíjìnnàréré? Àwọn odindi ọrẹ ẹbọ sísun yín kò mú ìdùnnú wá,+ àwọn ẹbọ yín gan-an kò sì mú inú mi dùn.”+ 21  Nítorí náà, èyí ni ohun tí Jèhófà wí: “Kíyè sí i, èmi yóò gbé àwọn ohun ìkọ̀sẹ̀ kalẹ̀ fún àwọn ènìyàn yìí,+ dájúdájú, wọ́n yóò sì kọsẹ̀ lára wọn, baba pa pọ̀ pẹ̀lú ọmọ; aládùúgbò àti alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀—wọn yóò ṣègbé.”+ 22  Èyí ni ohun tí Jèhófà wí: “Wò ó! Àwọn ènìyàn kan ń bọ̀ láti ilẹ̀ àríwá, orílẹ̀-èdè títóbi kan ni a ó sì jí lójú oorun láti apá jíjìnnàréré jù lọ ní ilẹ̀ ayé.+ 23  Ọrun àti ẹ̀ṣín ni wọn yóò dì mú.+ Ìkà ni, wọn kì yóò sì ní ojú àánú. Ohùn wọn yóò dún lọ rére gan-an gẹ́gẹ́ bí òkun,+ ẹṣin ni wọn yóò sì gùn.+ Ó tẹ́ ìtẹ́gun bí ọkùnrin ogun láti bá ọ jagun, ìwọ ọmọbìnrin Síónì.”+ 24  A ti gbọ́ ìròyìn nípa rẹ̀. Ọwọ́ wa ti rọ jọwọrọ.+ Àní wàhálà ti bá wa, ìrora ìrọbí bí ti obìnrin tí ó fẹ́ bímọ.+ 25  Má ṣe jáde lọ sínú pápá, má sì ṣe rìn, àní lójú ọ̀nà; nítorí idà kan wà tí ó jẹ́ ti ọ̀tá, jìnnìjìnnì wà ní gbogbo àyíká.+ 26  Ìwọ ọmọbìnrin àwọn ènìyàn mi, sán aṣọ àpò ìdọ̀họ,+ sì yíràá nínú eérú.+ Jẹ́ kí ọ̀fọ̀ rẹ jẹ́ bí èyí tí a ń ṣe fún ọmọkùnrin kan ṣoṣo, ìpohùnréré ìkorò;+ nítorí lójijì ni afiniṣèjẹ yóò dé sórí wa.+ 27  “Mo ti fi ọ́ ṣe ohun ìṣàyẹ̀wò irin láàárín àwọn ènìyàn mi, ẹni tí ń ṣe àyẹ̀wò fínnífínní; ìwọ yóò fiyè sí, ìwọ yóò sì wádìí ọ̀nà wọn wò.+ 28  Gbogbo wọn jẹ́ alágídí jù lọ,+ wọ́n ń rìn káàkiri bí afọ̀rọ̀-èké-banijẹ́+—bàbà àti irin. Gbogbo wọn jẹ́ apanirun.+ 29  A ti jó ẹwìrì wọn gbẹ.+ Òjé ní ń jáde láti inú iná wọn.+ Lásán ni ènìyàn kàn ń ṣe ìyọ́mọ́ kíkankíkan, a kò sì tíì ya àwọn tí ó burú sọ́tọ̀.+ 30  Dájúdájú, fàdákà tí a kọ̀ ni àwọn ènìyàn yóò pè wọ́n,+ nítorí Jèhófà ti kọ̀ wọ́n.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé