Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Jeremáyà 52:1-34

52  Ẹni ọdún mọ́kànlélógún ni Sedekáyà+ nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ sí jọba,+ ọdún mọ́kànlá sì ni ó fi jọba ní Jerúsálẹ́mù.+ Orúkọ ìyá rẹ̀ sì ni Hámútálì+ ọmọbìnrin Jeremáyà ti Líbínà.+  Ó sì ń bá a lọ ní ṣíṣe ohun tí ó burú ní ojú Jèhófà,+ ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo ohun tí Jèhóákímù+ ti ṣe.  Nítorí pé, ní tìtorí ìbínú Jèhófà ni ó fi ṣẹlẹ̀ ní Jerúsálẹ́mù àti Júdà, títí ó fi gbá wọn dànù kúrò níwájú rẹ̀.+ Sedekáyà sì tẹ̀ síwájú láti ṣọ̀tẹ̀ sí ọba Bábílónì.+  Níkẹyìn, ó ṣẹlẹ̀ ní ọdún kẹsàn-án tí ó jẹ ọba,+ ní oṣù kẹwàá, ní ọjọ́ kẹwàá oṣù náà, pé Nebukadirésárì ọba Bábílónì dé, òun àti gbogbo ẹgbẹ́ ológun rẹ̀, láti gbéjà ko Jerúsálẹ́mù,+ wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí dó tì í, wọ́n sì mọ odi ìsàgatì yí i ká.+  Nítorí náà, ìlú ńlá náà wà lábẹ́ ìsàgatì títí di ọdún kọkànlá Sedekáyà+ Ọba.  Ní oṣù kẹrin, ní ọjọ́ kẹsàn-án oṣù náà,+ ìyàn sì mú gidigidi ní ìlú ńlá náà, kò wá sí oúnjẹ kankan fún àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà.+  Níkẹyìn, wọ́n ya wọ ìlú ńlá náà;+ àti ní ti gbogbo ọkùnrin ogun, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí fẹsẹ̀ fẹ,+ wọ́n sì jáde kúrò nínú ìlú ńlá náà ní òru gba ti ẹnubodè tí ó wà láàárín ògiri onílọ̀ọ́po-méjì tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọgbà ọba,+ nígbà tí àwọn ará Kálídíà ká ìlú ńlá náà mọ́; wọ́n sì ń gba ọ̀nà Árábà lọ.+  Ẹgbẹ́ ológun àwọn ará Kálídíà sì bẹ̀rẹ̀ sí lépa ọba,+ wọ́n sì lé Sedekáyà+ bá ní àwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀ aṣálẹ̀ ti Jẹ́ríkò; gbogbo ẹgbẹ́ ológun rẹ̀ sì tú ká kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀.+  Nígbà náà ni wọ́n gbá ọba mú, wọ́n sì mú un gòkè wá sọ́dọ̀ ọba Bábílónì+ ní Ríbúlà+ ní ilẹ̀ Hámátì,+ kí ó lè kéde àwọn ìpinnu ìdájọ́ lé e lórí.+ 10  Ọba Bábílónì sì tẹ̀ síwájú láti pa àwọn ọmọ Sedekáyà lójú rẹ̀,+ gbogbo àwọn ọmọ aládé Júdà ni ó sì pa pẹ̀lú ní Ríbúlà.+ 11  Ó sì fọ́ ojú Sedekáyà,+ lẹ́yìn èyí, ọba Bábílónì fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ bàbà dè é, ó sì mú un wá sí Bábílónì,+ ó sì fi í sínú ilé ìhámọ́ títí di ọjọ́ ikú rẹ̀. 12  Àti ní oṣù karùn-ún, ní ọjọ́ kẹwàá oṣù náà, èyíinì ni, ní ọdún kọkàndínlógún Nebukadirésárì+ Ọba, tí í ṣe ọba Bábílónì, Nebusárádánì+ olórí ẹ̀ṣọ́, tí ń dúró níwájú ọba Bábílónì, wá sí Jerúsálẹ́mù. 13  Ó sì tẹ̀ síwájú láti fi iná sun ilé Jèhófà+ àti ilé ọba àti gbogbo ilé ní Jerúsálẹ́mù;+ gbogbo ilé ńlá ni ó sì fi iná sun.+ 14  Àti gbogbo ògiri Jerúsálẹ́mù, yíká-yíká, ni gbogbo ẹgbẹ́ ológun àwọn ará Kálídíà tí ó wà pẹ̀lú olórí ẹ̀ṣọ́ bì wó.+ 15  Àwọn kan lára àwọn ẹni rírẹlẹ̀ nínú àwọn ènìyàn náà àti ìyókù àwọn ènìyàn tí a fi sílẹ̀ sí ìlú ńlá náà+ àti àwọn olùyalọ tí ó ya lọ sọ́dọ̀ ọba Bábílónì àti ìyókù àwọn àgbà òṣìṣẹ́ ni Nebusárádánì olórí ẹ̀ṣọ́ kó lọ sí ìgbèkùn.+ 16  Àwọn kan lára àwọn ẹni rírẹlẹ̀ ilẹ̀ náà sì ni Nebusárádánì olórí ẹ̀ṣọ́ jẹ́ kí ó ṣẹ́ kù bí olùrẹ́wọ́ àjàrà àti lébìrà àpàpàǹdodo.+ 17  Àti àwọn ọwọ̀n bàbà+ tí ó jẹ́ ti ilé Jèhófà àti àwọn kẹ̀kẹ́ ẹrù+ àti òkun bàbà+ tí ó wà ní ilé Jèhófà ni àwọn ará Kálídíà fọ́ sí wẹ́wẹ́, wọ́n sì kó gbogbo bàbà rẹ̀ lọ sí Bábílónì.+ 18  Àti àwọn garawa àti àwọn ṣọ́bìrì+ àti àwọn àlùmọ́gàjí fìtílà+ àti àwọn àwokòtò+ àti àwọn ife àti gbogbo nǹkan èlò bàbà tí wọ́n fi ń ṣiṣẹ́ ni wọ́n kó.+ 19  Àti àwọn bàsíà+ àti àwọn ìkóná àti àwọn àwokòtò+ àti àwọn garawa àti àwọn ọ̀pá fìtílà+ àti àwọn ife àti àwọn àwokòtò tí ó jẹ́ ojúlówó wúrà,+ àti àwọn tí ó jẹ́ ojúlówó fàdákà,+ ni olórí ẹ̀ṣọ́ kó.+ 20  Àti ọwọ̀n méjèèjì,+ òkun kan ṣoṣo yẹn,+ àti akọ màlúù méjìlá tí a fi bàbà ṣe+ tí ó wà lábẹ́ òkun náà, àwọn kẹ̀kẹ́ ẹrù, tí Sólómọ́nì Ọba ṣe fún ilé Jèhófà.+ A kò ṣírò ìwọ̀n gbogbo bàbà wọn—gbogbo ohun èlò wọ̀nyí.+ 21  Àti ní ti àwọn ọwọ̀n náà, ìgbọ̀nwọ́ méjìdínlógún ni gíga ọwọ̀n kọ̀ọ̀kan,+ fọ́nrán òwú ìgbọ̀nwọ́ méjìlá yóò sì lọ yí ká rẹ̀;+ nínípọn rẹ̀ sì jẹ́ ìbú-ìka mẹ́rin, ó jinnú. 22  Ọpọ́n tí ó wà lórí rẹ̀ sì jẹ́ bàbà,+ gíga ọpọ́n kan sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún;+ àti ní ti àsokọ́ra bí àwọ̀n àti pómégíránétì tí ó wà lára ọpọ́n náà, yí ká,+ gbogbo rẹ̀ jẹ́ bàbà; ọwọ̀n kejì sì ní irú nǹkan wọ̀nyí gẹ́lẹ́, àti àwọn pómégíránétì pẹ̀lú.+ 23  Àwọn pómégíránétì náà sì wá jẹ́ mẹ́rìn-dín-lọ́gọ́rùn-ún, lẹ́gbẹ̀ẹ̀gbẹ́, gbogbo pómégíránétì jẹ́ ọgọ́rùn-ún lórí àsokọ́ra bí àwọ̀n yíká-yíká.+ 24  Síwájú sí i, olórí ẹ̀ṣọ́ mú Seráyà+ olórí àlùfáà àti Sefanáyà+ àlùfáà kejì àti àwọn olùṣọ́nà mẹ́ta,+ 25  àti láti inú ìlú ńlá náà, ó mú òṣìṣẹ́ kan láàfin tí ó jẹ́ kọmíṣọ́nnà lórí àwọn ọkùnrin ogun, àti ọkùnrin méje nínú àwọn tí ó ní àǹfààní láti dé ọ̀dọ̀ ọba,+ àwọn tí a rí nínú ìlú ńlá náà, àti akọ̀wé olórí ẹgbẹ́ ọmọ ogun, ẹni tí ń pe àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà jọ, àti ọgọ́ta ọkùnrin lára àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà, tí a rí nínú ìlú ńlá náà.+ 26  Nítorí náà, àwọn wọ̀nyí ni Nebusárádánì+ olórí ẹ̀ṣọ́ kó, ó sì kó wọn lọ sọ́dọ̀ ọba Bábílónì ní Ríbúlà.+ 27  Àwọn wọ̀nyí sì ni ọba Bábílónì ṣá balẹ̀,+ ó sì fi ikú pa wọ́n ní Ríbúlà+ ní ilẹ̀ Hámátì.+ Bí Júdà ṣe lọ sí ìgbèkùn kúrò lórí ilẹ̀ rẹ̀ nìyẹn.+ 28  Ìwọ̀nyí ni àwọn ènìyàn tí Nebukadirésárì kó lọ sí ìgbèkùn: ní ọdún keje, ẹgbẹ̀ẹ́dógún ó lé mẹ́tàlélógún àwọn Júù.+ 29  Ní ọdún kejìdínlógún Nebukadirésárì, láti Jerúsálẹ́mù, ẹgbẹ̀rin ọkàn ó lé méjìlélọ́gbọ̀n ni ó kó. 30  Ní ọdún kẹtàlélógún Nebukadirésárì,+ Nebusárádánì olórí ẹ̀ṣọ́ kó àwọn Júù lọ sí ìgbèkùn, òjì-lé-lẹ́ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin ó lé márùn-ún ọkàn.+ Gbogbo ọkàn náà jẹ́ ẹgbẹ̀tàlélógún. 31  Níkẹyìn, ó ṣẹlẹ̀ ní ọdún kẹtàdínlógójì ìgbèkùn Jèhóákínì+ ọba Júdà, ní oṣù kejìlá, ní ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n oṣù náà, pé Efili-méródákì ọba Bábílónì, ní ọdún tí ó di ọba, gbé orí Jèhóákínì ọba Júdà sókè,+ ó sì tẹ̀ síwájú láti mú un jáde kúrò nínú ilé ẹ̀wọ̀n. 32  Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí bá a sọ ohun rere, ó sì gbé ìtẹ́ rẹ̀ ga ju ìtẹ́ àwọn ọba yòókù tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ ní Bábílónì.+ 33  Ó sì bọ́ ẹ̀wù ẹ̀wọ̀n rẹ̀,+ ó sì ń jẹ oúnjẹ+ níwájú rẹ̀ nígbà gbogbo ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀.+ 34  Àti ní ti ohun tí a yọ̀ǹda fún un, ohun tí a yọ̀ǹda ni a ń fi fún un nígbà gbogbo láti ọ̀dọ̀ ọba Bábílónì, lójoojúmọ́ bí ó ti yẹ, títí di ọjọ́ ikú rẹ̀,+ ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé