Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Jeremáyà 51:1-64

51  Èyí ni ohun tí Jèhófà wí: “Kíyè sí i, èmi yóò rú ẹ̀fúùfù tí ń pani run sókè sí Bábílónì+ àti sí àwọn olùgbé Lẹbu-kámáì;+  ṣe ni èmi yóò sì rán àwọn olùfẹ́kà sí Bábílónì, àwọn tí yóò fẹ́ ẹ dájúdájú tí yóò sì sọ ilẹ̀ rẹ̀ di òfìfo;+ nítorí wọn yóò wá dojú kọ ọ́ ní ti gidi láti ìhà gbogbo ní ọjọ́ ìyọnu àjálù.+  “Kí ẹni tí ń fa ọrun má fà á mọ́.+ Kí ẹnikẹ́ni má sì nà ró nínú ẹ̀wù rẹ̀ tí a fi àdàrọ irin ṣe.+ “Ẹ má sì fi ìyọ́nú hàn fún àwọn ọ̀dọ́kùnrin rẹ̀. Ẹ ya gbogbo ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ sọ́tọ̀ fún ìparun.+  Wọn yóò sì ṣubú ní òkú ní ilẹ̀ àwọn ará Kálídíà,+ a ó sì gún wọn ní àgúnyọ ní àwọn ojú pópó rẹ̀.+  “Nítorí a kò sọ Ísírẹ́lì àti Júdà+ di opó lọ́dọ̀ Ọlọ́run wọn, lọ́dọ̀ Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun.+ Nítorí ilẹ̀ àwọn wọnnì ti kún fún ẹ̀bi lójú Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì.+  “Ẹ sá lọ kúrò nínú Bábílónì,+ kí olúkúlùkù sì pèsè àsálà fún ọkàn rẹ̀.+ Kí ẹ má di ẹni tí a sọ di aláìlẹ́mìí nítorí ìṣìnà rẹ̀.+ Nítorí ó jẹ́ àkókò ẹ̀san tí ó jẹ́ ti Jèhófà.+ Ìlòsíni kan wà tí yóò san padà fún un.+  Bábílónì ti jẹ́ ife wúrà ní ọwọ́ Jèhófà,+ ó ń mú kí gbogbo ilẹ̀ ayé mu àmupara.+ Àwọn orílẹ̀-èdè ti mu nínú ọtí wáìní rẹ̀.+ Ìdí nìyẹn tí àwọn orílẹ̀-èdè fi ń ṣe bí ayírí ṣáá.+  Lójijì, Bábílónì ti ṣubú, ó sì ṣẹ́.+ Ẹ hu fún un.+ Ẹ mú básámù fún ìrora rẹ̀.+ Bóyá a óò mú un lára dá.”  “À bá ti mú Bábílónì lára dá, ṣùgbọ́n a kò tíì mú un lára dá. Ẹ fi í sílẹ̀,+ kí olúkúlùkù wa sì lọ sí ilẹ̀ tirẹ̀.+ Nítorí títí dé ọ̀run ni ìdájọ́ rẹ̀, a sì ti gbé e sókè dé sánmà ṣíṣú dẹ̀dẹ̀.+ 10  Jèhófà ti mú àwọn iṣẹ́ òdodo jáde fún wa.+ Ẹ wá, ẹ sì jẹ́ kí a ròyìn iṣẹ́ Jèhófà Ọlọ́run wa lẹ́sẹẹsẹ ní Síónì.”+ 11  “Ẹ dán ọfà.+ Ẹ kún apata bìrìkìtì. Jèhófà ti ru ẹ̀mí àwọn ọba ará Mídíà dìde,+ nítorí èrò-ọkàn rẹ̀ jẹ́ ní ìlòdìsí Bábílónì,+ láti run ún. Nítorí ẹ̀san Jèhófà ni, ẹ̀san nítorí tẹ́ńpìlì rẹ̀.+ 12  Gbé àmì àfiyèsí sókè lòdì sí àwọn ògiri Bábílónì.+ Sọ ìṣọ́ di alágbára.+ Yan àwọn olùṣọ́ sẹ́nu iṣẹ́.+ Pèsè àwọn olùba ní ibùba sílẹ̀. Nítorí Jèhófà ti hùmọ̀ èrò-ọkàn náà, dájúdájú, yóò ṣe ohun tí ó ti sọ lòdì sí àwọn olùgbé Bábílónì.”+ 13  “Ìwọ obìnrin tí ń gbé lórí omi púpọ̀ gidigidi,+ tí ó ní ọ̀pọ̀ yanturu ìṣúra,+ òpin rẹ ti dé, òṣùwọ̀n+ èrè jíjẹ rẹ.+ 14  Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun ti fi ọkàn tirẹ̀ búra pé,+ ‘Ṣe ni èmi yóò fi ènìyàn kún inú rẹ, bí eéṣú,+ dájúdájú, wọn yóò sì fi igbe kọrin lórí rẹ.’+ 15  Òun ni Olùṣẹ̀dá ilẹ̀ ayé nípasẹ̀ agbára rẹ̀,+ Ẹni tí ó fìdí ilẹ̀ eléso múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in+ nípasẹ̀ ọgbọ́n rẹ̀,+ àti Ẹni tí ó na àwọn ọ̀run+ nípasẹ̀ òye rẹ̀.+ 16  Nígbà tí ohùn rẹ̀ bá dún, òun a fúnni ní ìdàwìtìwìtì omi ní ojú ọ̀run, a sì mú kí oruku ròkè láti ìkángun ilẹ̀ ayé.+ Ó tilẹ̀ ti ṣe ọ̀ṣọ̀ọ̀rọ̀ fún òjò,+ ó sì ń mú ẹ̀fúùfù jáde wá láti inú ilé ìtọ́jú nǹkan pa mọ́ rẹ̀. 17  Olúkúlùkù ènìyàn ti hùwà àìnírònú tó bẹ́ẹ̀ tí wọ́n kò fi mọ̀.+ Olúkúlùkù oníṣẹ́ irin ni ojú yóò tì dájúdájú nítorí ère gbígbẹ́;+ nítorí ère dídà rẹ̀ jẹ́ èké,+ kò sì sí ẹ̀mí kankan nínú wọn.+ 18  Asán ni wọ́n,+ iṣẹ́ àfiṣẹlẹ́yà.+ Wọn yóò ṣègbé ní àkókò tí a bá fún wọn ní àfiyèsí.+ 19  “Ìpín Jékọ́bù kò rí bí nǹkan wọ̀nyí,+ nítorí òun ni Aṣẹ̀dá ohun gbogbo,+ àní ọ̀pá ogún rẹ̀.+ Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun ni orúkọ rẹ̀.”+ 20  “Ọ̀gọ ni o jẹ́ fún mi, bí ohun ìjà ogun,+ nípasẹ̀ rẹ, dájúdájú, èmi yóò fọ́ àwọn orílẹ̀-èdè túútúú, àti nípasẹ̀ rẹ, èmi yóò run àwọn ìjọba. 21  Àti nípasẹ̀ rẹ, ṣe ni èmi yóò fọ́ ẹṣin àti ẹni tí ó gùn ún túútúú, àti nípasẹ̀ rẹ, èmi yóò fọ́ kẹ̀kẹ́ ẹṣin ogun àti ẹni tí ó gùn ún túútúú.+ 22  Àti nípasẹ̀ rẹ, ṣe ni èmi yóò fọ́ ọkùnrin àti obìnrin túútúú, àti nípasẹ̀ rẹ, èmi yóò fọ́ àgbà ọkùnrin àti ọmọdékùnrin túútúú, àti nípasẹ̀ rẹ, èmi yóò fọ́ ọ̀dọ́kùnrin àti wúńdíá túútúú. 23  Àti nípasẹ̀ rẹ, ṣe ni èmi yóò fọ́ olùṣọ́ àgùntàn àti agbo ẹran ọ̀sìn rẹ̀ túútúú, àti nípasẹ̀ rẹ, èmi yóò fọ́ àgbẹ̀ àti àdìpọ̀ méjì-méjì ẹran rẹ̀ túútúú, àti nípasẹ̀ rẹ, èmi yóò fọ́ àwọn gómìnà àti àwọn ajẹ́lẹ̀ túútúú. 24  Dájúdájú, èmi yóò san gbogbo ìwà búburú tí wọ́n ti hù ní Síónì lójú yín padà fún Bábílónì àti fún gbogbo àwọn olùgbé Kálídíà,”+ ni àsọjáde Jèhófà. 25  “Kíyè sí i, mo dojú ìjà kọ ọ́,+ ìwọ òkè ńlá tí ń fa ìparun,”+ ni àsọjáde Jèhófà, “ìwọ tí ń run gbogbo ilẹ̀ ayé;+ ṣe ni èmi yóò na ọwọ́ mi lòdì sí ọ, èmi yóò sì yí ọ kúrò lórí àwọn àpáta gàǹgà, èmi yóò sì sọ ọ́ di òkè ńlá jíjóná ráúráú.”+ 26  “Àwọn ènìyàn kì yóò sì mú òkúta fún igun ilé tàbí òkúta fún ìpìlẹ̀ nínú rẹ,+ nítorí pé ahoro fún àkókò tí ó lọ kánrin ni ìwọ yóò dà,”+ ni àsọjáde Jèhófà. 27  “Ẹ gbé àmì àfiyèsí sókè ní ilẹ̀ náà.+ Ẹ fun ìwo láàárín àwọn orílẹ̀-èdè. Ẹ sọ àwọn orílẹ̀-èdè di mímọ́+ lòdì sí i. Ẹ fi ọlá àṣẹ pe àwọn ìjọba Árárátì,+ Mínì àti Áṣíkénásì+ láti wá gbéjà kò ó. Ẹ fàṣẹ yan agbanisíṣẹ́ ogun láti wá gbéjà kò ó. Ẹ jẹ́ kí àwọn ẹṣin+ gòkè wá bí eéṣú onírun gàn-ùn gàn-ùn. 28  Ẹ sọ àwọn orílẹ̀-èdè di mímọ́ lòdì sí i, àwọn ọba Mídíà,+ àwọn gómìnà rẹ̀ àti gbogbo àwọn ajẹ́lẹ̀ rẹ̀ àti gbogbo ilẹ̀ àgbègbè ìṣàkóso ti olúkúlùkù. 29  Ẹ sì jẹ́ kí ilẹ̀ ayé mì jìgìjìgì kí ó sì jẹ ìrora mímúná,+ nítorí pé ìrònú Jèhófà ti dìde sí Bábílónì láti sọ ilẹ̀ Bábílónì di ohun ìyàlẹ́nu, láìní olùgbé.+ 30  “Àwọn alágbára ńlá Bábílónì ti ṣíwọ́ ìjà. Wọ́n jókòó pa sí àwọn ibi tí ó lágbára. Agbára ńlá wọn ti gbẹ.+ Wọ́n ti di obìnrin.+ A ti dáná ran àwọn ibùgbé rẹ̀. A ti ṣẹ́ àwọn ọ̀pá ìdábùú rẹ̀.+ 31  “Sárésáré kan sáré láti lọ pàdé sárésáré mìíràn, oníròyìn kan láti lọ pàdé oníròyìn mìíràn,+ láti ròyìn fún ọba Bábílónì pé a ti gba ìlú ńlá rẹ̀ ní ìhà gbogbo,+ 32  àti pé a ti gba ibi pẹ́ṣẹ́pẹ́ṣẹ́ odò rẹ̀,+ ọkọ̀ ojú omi tí a fi òrépèté ṣe ni a sì ti fi iná sun, ìyọlẹ́nu sì ti bá àwọn ọkùnrin ogun pàápàá.”+ 33  Nítorí èyí ni ohun tí Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, wí: “Ọmọbìnrin Bábílónì dà bí ilẹ̀ ìpakà.+ Ó tó àkókò láti tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀ di líle. Síbẹ̀, ní ìgbà díẹ̀ sí i, àkókò ìkórè yóò sì dé fún un.”+ 34  “Nebukadirésárì ọba Bábílónì ti jẹ mí run;+ ó ti kó mi sínú ìdàrúdàpọ̀. Ó ti gbé mi kalẹ̀ bí òfìfo ohun èlò. Ó ti gbé mi mì bí ejò ńlá;+ ó ti fi àwọn ohun àdídùn mi kún inú ara rẹ̀. Ó ti ṣàn mí nù. 35  ‘Kí ìwà ipá tí a hù sí mi àti sí ẹ̀yà ara mi wà lórí Bábílónì!’ ni obìnrin olùgbé Síónì yóò wí.+ ‘Kí ẹ̀jẹ̀ mi sì wà lórí àwọn olùgbé Kálídíà!’ ni Jerúsálẹ́mù yóò wí.”+ 36  Nítorí náà, èyí ni ohun tí Jèhófà wí: “Kíyè sí i, èmi yóò bá ọ dá ẹjọ́ rẹ,+ dájúdájú, èmi yóò sì gbẹ̀san fún ọ.+ Ṣe ni èmi yóò sì mú òkun rẹ̀ gbẹ, èmi yóò sì mú kí àwọn kànga rẹ̀ gbẹ.+ 37  Bábílónì yóò sì di ìtòjọpelemọ òkúta,+ ibùgbé àwọn akátá,+ ohun ìyàlẹ́nu àti ohun ìsúfèé sí, láìní olùgbé.+ 38  Lápapọ̀, gbogbo wọn yóò ké ramúramù gẹ́gẹ́ bí ẹgbọrọ kìnnìún onígọ̀gọ̀. Dájúdájú, wọn yóò kùn hùn-ùn bí ọmọ kìnnìún.” 39  “Nígbà tí ara wọn bá móoru èmi yóò gbé àkànṣe àsè kalẹ̀ fún wọn, ṣe ni èmi yóò sì mú kí wọ́n mu àmupara, kí wọ́n lè yọ ayọ̀ ńláǹlà;+ wọn yóò sì sun oorun àsùn-lọ-kánrin, nínú èyí tí wọn kì yóò jí,”+ ni àsọjáde Jèhófà. 40  “Èmi yóò mú wọn sọ̀ kalẹ̀ bí akọ àgùntàn tí a fà kalẹ̀ fún pípa, bí àwọn àgbò pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn òbúkọ.”+ 41  “Ẹ wo bí a ṣe kó Ṣéṣákì lẹ́rú,+ ẹ sì wo bí a ti gbá Ìyìn gbogbo ilẹ̀ ayé mú!+ Ẹ wo bí Bábílónì ṣe di ohun ìyàlẹ́nu lásán-làsàn láàárín àwọn orílẹ̀-èdè!+ 42  Òkun ti wá àní sórí Bábílónì. Nípa ògìdìgbó ìgbì rẹ̀, a ti bò ó mọ́lẹ̀.+ 43  Àwọn ìlú ńlá rẹ̀ ti di ohun ìyàlẹ́nu, ilẹ̀ aláìlómi àti pẹ̀tẹ́lẹ̀ aṣálẹ̀.+ Bí ilẹ̀, kò sí ènìyàn kankan tí yóò gbé orí rẹ̀, kò sì sí ọmọ aráyé kankan tí yóò gba ibẹ̀ kọjá.+ 44  Dájúdájú, èmi yóò yí àfiyèsí mi sí Bélì+ ní Bábílónì, èmi yóò sì mú ohun tí ó ti gbé mì jáde ní ẹnu rẹ̀.+ Àwọn orílẹ̀-èdè kì yóò sì wọ́ tìrítìrí lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ mọ́.+ Pẹ̀lúpẹ̀lù, àní ògiri Bábílónì yóò ṣubú.+ 45  “Ẹ jáde kúrò nínú rẹ̀, ẹ̀yin ènìyàn mi,+ kí olúkúlùkù yín sì pèsè àsálà+ fún ọkàn rẹ̀ lọ́wọ́ jíjófòfò ìbínú Jèhófà.+ 46  Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ojora yóò mú ọkàn-àyà yín,+ àyà yóò sì fò yín nítorí ìròyìn tí a óò gbọ́ ní ilẹ̀ náà. Ní ọdún kan ni ìròyìn náà yóò sì wá ní ti gidi, àti lẹ́yìn náà ní ọdún mìíràn, ìròyìn àti ìwà ipá ní ilẹ̀ ayé yóò wà, olùṣàkóso yóò sì dojú ìjà kọ olùṣàkóso. 47  Nítorí náà, wò ó! àwọn ọjọ́ ń bọ̀, ṣe ni èmi yóò sì yí àfiyèsí sí àwọn ère fífín Bábílónì;+ ìtìjú yóò sì bá gbogbo ilẹ̀ rẹ̀, gbogbo àwọn tirẹ̀ tí a pa yóò sì ṣubú ní àárín rẹ̀.+ 48  “Dájúdájú, àwọn ọ̀run àti ilẹ̀ ayé àti gbogbo ohun tí ó wà nínú wọn yóò sì fi ìdùnnú ké jáde lórí Bábílónì,+ nítorí pé láti àríwá, àwọn afiniṣèjẹ yóò wá sọ́dọ̀ rẹ̀,”+ ni àsọjáde Jèhófà. 49  “Kì í ṣe kìkì pé Bábílónì ni ó mú kí àwọn tí a pa ní Ísírẹ́lì ṣubú nìkan ni+ ṣùgbọ́n ní Bábílónì pẹ̀lú ni gbogbo àwọn tí a pa ní ilẹ̀ ayé ti ṣubú.+ 50  “Ẹ̀yin olùsálà lọ́wọ́ idà, ẹ sáà máa lọ. Ẹ má ṣe dúró jẹ́ẹ́.+ Láti ibi jíjìnnàréré, ẹ rántí Jèhófà,+ kí Jerúsálẹ́mù alára sì wá sínú ọkàn-àyà yín.”+ 51  “A ti kó ìtìjú bá wa,+ nítorí a ti gbọ́ ẹ̀gàn.+ Ìtẹ́lógo ti bo ojú wa,+ nítorí àwọn àjèjì ti wá gbéjà ko àwọn ibi mímọ́ ilé Jèhófà.”+ 52  “Nítorí náà, wò ó! àwọn ọjọ́ ń bọ̀,” ni àsọjáde Jèhófà, “ṣe ni èmi yóò sì yí àfiyèsí mi sí ère fífín rẹ̀,+ ẹni tí a gún yóò sì kérora jákèjádò ilẹ̀ rẹ̀.”+ 53  “Bí Bábílónì tilẹ̀ gòkè re ọ̀run,+ àní bí ó tilẹ̀ sọ ibi gíga okun rẹ̀ di aláìṣeédé,+ láti ọ̀dọ̀ mi ni àwọn afiniṣèjẹ yóò ti wá sọ́dọ̀ rẹ̀,”+ ni àsọjáde Jèhófà. 54  “Ẹ fetí sílẹ̀! Igbe ẹkún kan ń bẹ láti Bábílónì,+ àti ìfọ́yángá ńláǹlà láti ilẹ̀ àwọn ará Kálídíà,+ 55  nítorí Jèhófà ń fi Bábílónì ṣe ìjẹ, dájúdájú, òun yóò sì pa ohùn ńlá run kúrò nínú rẹ̀,+ dájúdájú, ìgbì wọn yóò jẹ́ aláriwo líle bí omi púpọ̀.+ Ariwo ohùn wọn ni a ó sì gbé jáde dájúdájú. 56  Nítorí afiniṣèjẹ yóò dé sórí rẹ̀, sórí Bábílónì,+ àwọn alágbára ńlá rẹ̀ ni a óò sì kó lẹ́rú.+ Ọrun wọn ni a óò ṣẹ́ sí wẹ́wẹ́,+ nítorí Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run tí ń sanni ní èrè iṣẹ́.+ Láìkùnà, òun yóò san án padà.+ 57  Ṣe ni èmi yóò sì mú kí àwọn ọmọ aládé rẹ̀ àti àwọn ọlọ́gbọ́n rẹ̀, àwọn gómìnà rẹ̀ àti àwọn ajẹ́lẹ̀ rẹ̀ àti àwọn alágbára ńlá rẹ̀ mu àmupara,+ wọn yóò sì sun oorun àsùn-lọ-kánrin, nínú èyí tí wọn kì yóò jí,”+ ni àsọjáde Ọba,+ ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun.+ 58  Èyí ni ohun tí Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wí: “Ògiri Bábílónì, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó fẹ̀ ni a óò wó palẹ̀ láìkùnà;+ àti àwọn ẹnubodè rẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ga ni a ó fi iná mú jó lala.+ Àwọn ènìyàn náà yóò sì ṣe làálàá lásán,+ àti àwọn àwùjọ orílẹ̀-èdè yóò sì ṣe làálàá fún kìkì iná;+ wọn yóò sì wulẹ̀ kó àárẹ̀ bá ara wọn.” 59  Ọ̀rọ̀ tí Jeremáyà wòlíì pa láṣẹ fún Seráyà ọmọkùnrin Neráyà+ ọmọkùnrin Maseáyà+ nígbà tí ó bá Sedekáyà ọba Júdà lọ sí Bábílónì ní ọdún kẹrin tí ó jẹ́ ọba; Seráyà sì ni olórí ibùdó. 60  Jeremáyà sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ gbogbo ìyọnu àjálù tí yóò já lu Bábílónì sínú ìwé kan,+ àní gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí tí a kọ lòdì sí Bábílónì. 61  Síwájú sí i, Jeremáyà wí fún Seráyà pé: “Gbàrà tí o bá dé Bábílónì, tí o sì rí i ní tòótọ́, kí o ka gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sókè pẹ̀lú.+ 62  Kí o sì wí pé, ‘Jèhófà, ìwọ fúnra rẹ ti sọ̀rọ̀ lòdì sí ibí yìí, láti ké e kúrò tí kò fi ní sí olùgbé kankan nínú rẹ̀,+ yálà ènìyàn tàbí ẹran agbéléjẹ̀ pàápàá, ṣùgbọ́n kí ó lè di ahoro lásán-làsàn fún àkókò tí ó lọ kánrin.’ 63  Yóò sì ṣẹlẹ̀ pé, nígbà tí o bá ti parí kíka ìwé yìí, kí o so ó mọ́ òkúta kan, kí o sì gbé e sọ sí àárín Yúfírétì.+ 64  Kí o sì wí pé, ‘Báyìí ni Bábílónì yóò ṣe rì wọlẹ̀, tí kì yóò sì dìde mọ́ nítorí ìyọnu àjálù tí èmi yóò mú wá sórí rẹ̀;+ dájúdájú, wọn yóò sì kó àárẹ̀ bá ara wọn.’”+ Títí dé ìhín ni àwọn ọ̀rọ̀ Jeremáyà.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé