Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Jeremáyà 50:1-46

50  Ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ nípa Bábílónì,+ nípa ilẹ̀ àwọn ará Kálídíà,+ nípasẹ̀ Jeremáyà wòlíì:  “Ẹ sọ ọ́ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè kí ẹ sì kéde rẹ̀ fáyé gbọ́.+ Ẹ sì gbé àmì àfiyèsí sókè;+ ẹ kéde rẹ̀ fáyé gbọ́. Ẹ má fi nǹkan kan pa mọ́. Ẹ wí pé, ‘A ti kó Bábílónì lẹ́rú.+ Ìtìjú ti bá Bélì.+ Àyà Méródákì ti já. Ìtìjú ti bá àwọn ère rẹ̀.+ Àyà àwọn òrìṣà ẹlẹ́bọ́tọ rẹ̀ ti já.’  Nítorí orílẹ̀-èdè kan ti gòkè wá láti àríwá láti gbéjà kò ó.+ Èyí tí ó sọ ilẹ̀ rẹ̀ di ohun ìyàlẹ́nu ni, tí kò fi sí ẹni tí ń gbé inú rẹ̀.+ Àti ènìyàn àti ẹran agbéléjẹ̀ ti fẹsẹ̀ fẹ.+ Wọ́n ti lọ.”+  “Ní àwọn ọjọ́ wọnnì àti ní àkókò yẹn,”+ ni àsọjáde Jèhófà, “àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, àwọn àti àwọn ọmọ Júdà pa pọ̀, yóò dé.+ Wọn yóò rìn, ní sísunkún bí wọ́n ti ń rìn,+ Jèhófà Ọlọ́run wọn ni wọn yóò sì máa wá.+  Wọn yóò máa béèrè ọ̀nà sí Síónì, pẹ̀lú ojú wọn ní ìhà yẹn,+ pé, ‘Ẹ wá, ẹ sì jẹ́ kí a dara pọ̀ mọ́ Jèhófà nínú májẹ̀mú tí ó wà fún àkókò tí ó lọ kánrin tí kò ṣeé gbàgbé.’+  Àwọn ènìyàn mi ti di agbo ẹ̀dá tí ń ṣègbé lọ.+ Àwọn olùṣọ́ àgùntàn wọn ti mú kí wọ́n rìn gbéregbère.+ Orí àwọn òkè ńláńlá ni wọ́n ti mú wọn lọ.+ Láti orí òkè ńlá dé orí òkè kékeré ni wọ́n ti lọ. Wọ́n ti gbàgbé ibi ìsinmi wọn.+  Gbogbo àwọn tí ó rí wọn ti jẹ wọ́n tán,+ àwọn elénìní wọn sì ti wí pé,+ ‘Àwa kì yóò jẹ̀bi,+ nítorí òtítọ́ náà pé wọ́n ti dẹ́ṣẹ̀ sí Jèhófà tí í ṣe ibi gbígbé òdodo+ àti ìrètí àwọn baba ńlá wọn,+ Jèhófà.’”  “Ẹ fẹsẹ̀ fẹ kúrò ní àárín Bábílónì, ẹ sì lọ àní kúrò ní ilẹ̀ àwọn ará Kálídíà,+ kí ẹ sì dà bí ẹran tí ń ṣe aṣíwájú níwájú agbo ẹran.+  Nítorí kíyè sí i, èmi yóò ru ìpéjọ àwọn orílẹ̀-èdè ńlá láti ilẹ̀ àríwá dìde,+ èmi yóò sì gbé wọn dìde láti gbéjà ko Bábílónì, dájúdájú, wọn yóò sì to ara wọn lẹ́sẹẹsẹ láti gbéjà kò ó.+ Níbẹ̀ ni a ó ti kó o lẹ́rú.+ Àwọn ọfà ẹni tí ó dà bí ti àwọn alágbára ńlá tí ń fa ìṣòfò ọmọ, tí kì í padà wá láìní ìyọrísí.+ 10  Kálídíà yóò sì di ohun ìfiṣèjẹ.+ Gbogbo àwọn tí ń fi í ṣe ìjẹ yóò tẹ́ ara wọn lọ́rùn,”+ ni àsọjáde Jèhófà. 11  “Nítorí ẹ ń yọ̀,+ nítorí ẹ ń yọ ayọ̀ ńláǹlà nígbà tí ẹ ń kó ogún mi ní ìkógun.+ Nítorí ẹ ń fi àtẹ́sẹ̀ talẹ̀ bí ẹgbọrọ abo màlúù nínú koríko tútù yọ̀yọ̀,+ ẹ sì ń yán bí akọ ẹṣin.+ 12  Ìtìjú ti bá ìyá yín gidigidi.+ Ìjákulẹ̀ ti bá ẹni tí ó bí yín lọ́mọ.+ Wò ó! Òun ni ìjẹ́pàtàkì rẹ̀ kéré jù lọ nínú àwọn orílẹ̀-èdè, aginjù aláìlómi àti pẹ̀tẹ́lẹ̀ aṣálẹ̀.+ 13  Nítorí ìkannú Jèhófà, a kì yóò gbé inú rẹ̀,+ yóò sì di ahoro látòkè délẹ̀.+ Ní ti ẹnikẹ́ni tí ń kọjá lọ lẹ́gbẹ̀ẹ́ Bábílónì, yóò wò sùn-ùn tìyàlẹ́nu-tìyàlẹ́nu, yóò sì súfèé ní tìtorí gbogbo ìyọnu àjàkálẹ̀ rẹ̀.+ 14  “Ẹ to ara yín lẹ́sẹẹsẹ lòdì sí Bábílónì láti ìhà gbogbo,+ gbogbo ẹ̀yin tí ń fa ọrun.+ Ẹ ta á lọ́fà.+ Ẹ má ṣe ṣẹ́ ọfà kankan kù, nítorí Jèhófà ni ó dẹ́ṣẹ̀ sí.+ 15  Ẹ kígbe ogun lòdì sí i láti ìhà gbogbo.+ Ó ti fi ọwọ́ rẹ̀ fúnni.+ Àwọn ọwọ̀n rẹ̀ ti ṣubú. A ti ya àwọn ògiri rẹ̀ lulẹ̀.+ Nítorí ẹ̀san Jèhófà ni.+ Ẹ gbẹ̀san lára rẹ̀. Gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe, ẹ ṣe bẹ́ẹ̀ sí i.+ 16  Ẹ ké afúnrúgbìn kúrò ní Bábílónì,+ àti ẹni tí ń lo dòjé ní àkókò ìkórè. Nítorí idà tí ń hanni léèmọ̀, wọn yóò yí padà, olúkúlùkù sí àwọn ènìyàn tirẹ̀, wọn yóò sì sá lọ, olúkúlùkù sí ilẹ̀ tirẹ̀.+ 17  “Àgùntàn tí ó tú ká ni Ísírẹ́lì.+ Àwọn kìnnìún ni ó fọ́n wọn ká.+ Ní ìgbà àkọ́kọ́, ọba Ásíríà ni ó jẹ ẹ́ run,+ àti ní ìgbà kejì yìí, Nebukadirésárì ọba Bábílónì ni ó jẹ egungun rẹ̀ díẹ̀díẹ̀.+ 18  Nítorí náà, èyí ni ohun tí Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí, ‘Kíyè sí i, èmi yóò yí àfiyèsí mi sí ọba Bábílónì àti sí ilẹ̀ rẹ̀ ní ọ̀nà kan náà tí mo yí àfiyèsí mi sí ọba Ásíríà.+ 19  Ó dájú pé èmi yóò mú Ísírẹ́lì padà wá sí ilẹ̀ ìjẹko rẹ̀,+ dájúdájú, yóò sì jẹko ní Kámẹ́lì+ àti ní Báṣánì;+ ọkàn rẹ̀ yóò sì ní ìtẹ́lọ́rùn ní ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá Éfúráímù+ àti ti Gílíádì,+ ọkàn rẹ̀ yóò ní ìtẹ́lọ́rùn.’” 20  “Àti ní àwọn ọjọ́ wọnnì àti ní àkókò yẹn,”+ ni àsọjáde Jèhófà, “a óò wá ìṣìnà Ísírẹ́lì káàkiri,+ ṣùgbọ́n kì yóò sí; àti àwọn ẹ̀ṣẹ̀ Júdà,+ a kì yóò sì rí wọn, nítorí èmi yóò dárí ji àwọn tí mo jẹ́ kí ó ṣẹ́ kù.”+ 21  “Gbéjà ko ilẹ̀ Mérátáímù—gòkè wá láti gbéjà kò ó+ àti láti gbéjà ko àwọn olùgbé Pékódù.+ Jẹ́ kí ìpakúpa wáyé, kí ìyàsọ́tọ̀ fún ìparun sì ká wọn mọ́,” ni àsọjáde Jèhófà, “sì ṣe gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí mo pa láṣẹ fún ọ.+ 22  Ìró ogun wà ní ilẹ̀ náà, àti ìwópalẹ̀ ńláǹlà.+ 23  Ẹ wo bí a ti ké ọmọ owú+ gbogbo ilẹ̀ ayé lulẹ̀ tí ó sì ṣẹ́!+ Ẹ wo bí Bábílónì ti di ohun ìyàlẹ́nu lásán-làsàn láàárín àwọn orílẹ̀-èdè!+ 24  Mo ti dẹkùn fún ọ, a sì ti mú ọ pẹ̀lú, ìwọ Bábílónì, ìwọ alára kò sì mọ̀.+ A rí ọ, a sì dì ọ́ mú pẹ̀lú, nítorí pé Jèhófà ni o ru ara rẹ sókè sí.+ 25  “Jèhófà ti ṣí ilé ìtọ́jú nǹkan pa mọ́ rẹ̀, ó sì mú àwọn ohun ìjà ìdálẹ́bi rẹ̀ jáde.+ Nítorí iṣẹ́ kan wà tí Olúwa Ọba Aláṣẹ,+ Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, ní ní ilẹ̀ àwọn ará Kálídíà.+ 26  Wọlé tọ̀ ọ́ wá láti ibi jíjìnnà jù lọ.+ Ṣí àká rẹ̀.+ Kọ bèbè rẹ̀, gan-an gẹ́gẹ́ bí àwọn tí ń kọbè,+ sì yà á sọ́tọ̀ fún ìparun.+ Kí ó má sì wá ní ẹnikẹ́ni tí ó ṣẹ́ kù.+ 27  Pa gbogbo ẹgbọrọ akọ màlúù rẹ̀ ní ìpakúpa.+ Kí wọ́n sọ̀ kalẹ̀ lọ fún ìfikúpa.+ Ègbé ni fún wọn, nítorí ọjọ́ wọn ti dé, àkókò láti fún wọn ní àfiyèsí!+ 28  “Ìró àwọn tí ń sá lọ ń bẹ, àti ti àwọn tí ń sá àsála láti ilẹ̀ Bábílónì,+ láti kéde ẹ̀san Jèhófà Ọlọ́run wa ní Síónì,+ ẹ̀san nítorí tẹ́ńpìlì rẹ̀.+ 29  “Ẹ fi ọlá àṣẹ pe àwọn tafàtafà láti gbéjà ko Bábílónì, gbogbo àwọn tí ń fa ọrun.+ Ẹ dó tì í yí ká. Kí olùsálà kankan má sì sí.+ Ẹ san án padà fún un gẹ́gẹ́ bí ìgbòkègbodò rẹ̀.+ Gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí ó ti ṣe, ẹ ṣe bẹ́ẹ̀ sí i.+ Nítorí pé ó ti fi ìkùgbù gbé ìgbésẹ̀ lòdì sí Jèhófà, lòdì sí Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì.+ 30  Nítorí náà, àwọn ọ̀dọ́kùnrin rẹ̀ yóò ṣubú ní àwọn ojúde ìlú rẹ̀,+ àní gbogbo ọkùnrin ogun rẹ̀ ni a ó pa lẹ́nu mọ́ ní ọjọ́ yẹn,”+ ni àsọjáde Jèhófà. 31  “Wò ó! Mo dojú ìjà kọ ọ́,+ ìwọ Ìkùgbù,”+ ni àsọjáde Olúwa Ọba Aláṣẹ,+ Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, “nítorí ọjọ́ rẹ gbọ́dọ̀ dé, àkókò tí èmi yóò fún ọ ní àfiyèsí. 32  Dájúdájú, Ìkùgbù yóò sì kọsẹ̀,+ yóò sì ṣubú, kì yóò sì ní ẹnikẹ́ni tí yóò mú kí ó dìde.+ Ṣe ni èmi yóò sì mú kí iná jó nínú àwọn ìlú ńlá rẹ̀, yóò sì jẹ gbogbo àyíká rẹ̀ run.”+ 33  Èyí ni ohun tí Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wí: “Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àti àwọn ọmọ Júdà ni a ń ni lára pa pọ̀, gbogbo àwọn tí ó sì ń mú wọn ní òǹdè ti dì wọ́n mú.+ Wọ́n kọ̀ láti jẹ́ kí wọ́n lọ.+ 34  Olùtúnnirà wọ́n lágbára,+ Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun ni orúkọ rẹ̀.+ Láìkùnà, yóò bá wọn dá ẹjọ́ wọn,+ kí ó lè fún ilẹ̀ náà ní ìsinmi,+ kí ó sì kó ṣìbáṣìbo bá àwọn olùgbé Bábílónì.”+ 35  “Idà kan wà lòdì sí àwọn ará Kálídíà,”+ ni àsọjáde Jèhófà, “àti lòdì sí àwọn olùgbé Bábílónì+ àti lòdì sí àwọn ọmọ aládé+ rẹ̀ àti lòdì sí àwọn ọlọ́gbọ́n rẹ̀.+ 36  Idà kan wà lòdì sí àwọn olùsọ òfìfo ọ̀rọ̀,+ wọn yóò sì hùwà òmùgọ̀ dájúdájú.+ Idà kan wà lòdì sí àwọn alágbára ńlá rẹ̀,+ àyà wọn yóò sì máa já ní ti gidi.+ 37  Idà kan wà lòdì sí àwọn ẹṣin wọn+ àti lòdì sí àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin ogun wọn àti lòdì sí gbogbo àwùjọ onírúurú ènìyàn tí ó wà ní àárín rẹ̀,+ dájúdájú, wọn yóò sì di obìnrin.+ Idà kan wà lòdì sí àwọn ìṣúra rẹ̀,+ ṣe ni a ó sì piyẹ́ wọn. 38  Ìparundahoro wà lórí omi rẹ̀,+ a ó gbẹ ẹ́ táútáú. Nítorí ilẹ̀ ère fífín ni,+ wọ́n sì ń ṣe bí ayírí nítorí àwọn ìran wọn tí ń da jìnnìjìnnì boni. 39  Nítorí náà, àwọn olùgbé ẹkùn ilẹ̀ aláìlómi yóò máa gbé pẹ̀lú àwọn ẹranko tí ń hu, inú rẹ̀ sì ni ògòǹgò yóò máa gbé;+ a kì yóò sì gbé inú rẹ̀ mọ́ láé, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí mọ́ láti ìran dé ìran.”+ 40  “Gan-an gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti bi Sódómù àti Gòmórà+ àti àwọn ìlú tí ó wà ní àdúgbò rẹ̀ ṣubú,”+ ni àsọjáde Jèhófà, “kò sí ènìyàn kankan tí yóò máa gbé ibẹ̀, kì yóò sì sí ọmọ aráyé kankan tí yóò máa ṣe àtìpó nínú rẹ̀.+ 41  “Wò ó! Àwọn ènìyàn kan ń wọlé bọ̀ láti àríwá; orílẹ̀-èdè ńlá+ àti àwọn atóbilọ́lá ọba+ ni a ó ru dìde láti àwọn apá jíjìnnàréré jù lọ ní ilẹ̀ ayé.+ 42  Ọrun àti ẹ̀ṣín ni wọ́n mú dání.+ Wọn níkà, wọn kì yóò sì fi àánú hàn.+ Ìró wọn dà bí ti òkun tí í ṣe aláriwo líle,+ ẹṣin ni wọn yóò gùn;+ tí a tò ní ẹsẹẹsẹ gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan ṣoṣo fún ogun lòdì sí ọ, ìwọ ọmọbìnrin Bábílónì.+ 43  “Ọba Bábílónì ti gbọ́ ìròyìn nípa wọn,+ ọwọ́ rẹ̀ sì ti rọ jọwọrọ.+ Wàhálà wà! Ìrora mímúná ti gbá a mú, gẹ́gẹ́ bí ti obìnrin tí ó fẹ́ bímọ.+ 44  “Wò ó! Ẹnì kan yóò jáde wá gẹ́gẹ́ bí kìnnìún láti inú ìgbòrò ràgàjì lẹ́bàá Jọ́dánì lọ sí ibi gbígbé alálòpẹ́,+ ṣùgbọ́n ní ìṣẹ́jú kan, dájúdájú, èmi yóò mú kí wọ́n fẹsẹ̀ fẹ kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀.+ Èmi yóò sì yan ẹni àyànfẹ́ sórí rẹ̀.+ Nítorí ta ni ó dà bí èmi,+ ta ni yóò sì pè mi níjà,+ ta sì wá ni olùṣọ́ àgùntàn tí ó lè dúró níwájú mi?+ 45  Nítorí náà, ẹ gbọ́ ìpinnu+ tí Jèhófà tí ṣe lòdì sí Bábílónì,+ àti ìrònú rẹ̀ tí ó ti gbìrò lòdì sí ilẹ̀ àwọn ará Kálídíà.+ Dájúdájú, àwọn èyí kéékèèké nínú agbo ẹran ni a óò wọ́ káàkiri.+ Dájúdájú, ní tìtorí wọn, òun yóò mú kí ibi gbígbé wọn di ahoro.+ 46  Nígbà ìró tí ó dún nígbà tí a gbá Bábílónì mú, dájúdájú, ilẹ̀ ayé ni a óò mú kí ó máa mì jìgìjìgì,+ àti láàárín àwọn orílẹ̀-èdè, a óò gbọ́ igbe ẹkún pàápàá.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé