Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Jeremáyà 5:1-31

5  Ẹ lọ káàkiri àwọn ojú pópó Jerúsálẹ́mù, kí ẹ sì rí i, wàyí, kí ẹ sì mọ̀, kí ẹ sì wá àwọn ojúde rẹ̀ fúnra yín bóyá ẹ lè rí ènìyàn kan,+ bóyá ẹnikẹ́ni wà tí ń ṣe ìdájọ́ òdodo,+ ẹnikẹ́ni tí ń wá ìṣòtítọ́,+ èmi yóò sì dárí jì í.  Bí wọ́n bá tilẹ̀ wí pé: “Bí Jèhófà tí ń bẹ láàyè!” wọn yóò tipa báyìí máa búra sí kìkìdá èké.+  Jèhófà, ojú rẹ wọnnì kò ha wà lára ìṣòtítọ́?+ Ìwọ ti kọlù wọ́n,+ ṣùgbọ́n wọn kò ṣàmódi.+ Ìwọ pa wọ́n run pátápátá.+ Wọ́n kọ̀ láti gba ìbáwí.+ Wọ́n mú ojú wọn le ju àpáta gàǹgà lọ.+ Wọ́n kọ̀ láti yí padà.+  Àní èmi fúnra mi ti wí pé: “Dájúdájú, wọ́n jẹ́ ìsọ̀rí àwọn ẹni rírẹlẹ̀. Wọ́n hùwà òmùgọ̀, nítorí wọ́n ti fi ọ̀nà Jèhófà dá àgunlá, àní ìdájọ́ Ọlọ́run wọn.+  Dájúdájú, èmi yóò bá ọ̀nà mi lọ sọ́dọ̀ àwọn ẹni ńlá, èmi yóò sì bá wọn sọ̀rọ̀;+ nítorí àwọn fúnra wọn gbọ́dọ̀ ti ṣàkíyèsí ọ̀nà Jèhófà, ìdájọ́ Ọlọ́run wọn.+ Dájúdájú, àwọn fúnra wọn lápapọ̀ gbọ́dọ̀ ti ṣẹ́ àjàgà; wọ́n gbọ́dọ̀ ti fa ọ̀já já.”+  Ìdí nìyẹn tí kìnnìún láti inú igbó fi kọlù wọ́n, àní ìkookò láti pẹ̀tẹ́lẹ̀ aṣálẹ̀ ń fi wọ́n ṣe ìjẹ,+ àmọ̀tẹ́kùn ń wà lójúfò ní àwọn ìlú ńlá wọn.+ Olúkúlùkù ẹni tí ń jáde lọ láti ọ̀dọ̀ wọn ni a fà ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ. Nítorí ìrélànàkọjá wọn ti di púpọ̀; ìwà àìṣòótọ́ wọn ti di púpọ̀ níye.+  Báwo ni mo ṣe lè dárí jì ọ́ lórí ohun yìí gan-an? Àwọn ọmọ tìrẹ ti fi mí sílẹ̀, wọ́n sì ń fi ohun tí kì í ṣe Ọlọ́run+ búra.+ Mo sì ń tẹ́ wọn lọ́rùn ṣáá,+ ṣùgbọ́n wọ́n ń bá a lọ láti ṣe panṣágà,+ ilé obìnrin kárùwà ni wọ́n sì ń wọ́ tìrítìrí lọ.  Wọ́n ti di àwọn ẹṣin tí ìgbónára fún ìbálòpọ̀ takọtabo gbá mú, tí wọ́n ní kórópọ̀n líle. Olúkúlùkù wọn ń yán sí aya alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀.+  “Kò ha yẹ kí n béèrè ìjíhìn nítorí nǹkan wọ̀nyí?” ni àsọjáde Jèhófà.+ “Tàbí ọkàn mi kì yóò ha gbẹ̀san lára orílẹ̀-èdè tí ó rí bí èyí?”+ 10  “Ẹ gòkè wá lòdì sí ẹsẹ oko àjàrà rẹ̀, kí ẹ sì fa ìparun,+ ṣùgbọ́n ẹ má ṣe ìparun pátápátá gan-an.+ Ẹ mú àwọn ọ̀mùnú rẹ̀ tí ó gbẹ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀ kúrò, nítorí wọn kì í ṣe ti Jèhófà.+ 11  Nítorí ilé Ísírẹ́lì àti ilé Júdà ti ṣe àdàkàdekè sí mi dájúdájú,” ni àsọjáde Jèhófà.+ 12  “Wọ́n ti sẹ́ Jèhófà, wọ́n sì ń sọ ṣáá pé, ‘Kò sí.+ Ìyọnu àjálù kankan kì yóò sì já lù wá, àwa kì yóò sì rí idà tàbí ìyàn kankan.’+ 13  Àwọn wòlíì pàápàá sì di ẹ̀fúùfù, ọ̀rọ̀ náà kò sì sí nínú wọn.+ Bẹ́ẹ̀ ni a ó ṣe sí wọn.” 14  Nítorí náà, èyí ni ohun tí Jèhófà, Ọlọ́run àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wí: “Nítorí ìdí náà pé ẹ ń sọ nǹkan yìí, kíyè sí i, èmi yóò sọ ọ̀rọ̀ mi tí ó wà ní ẹnu rẹ di iná,+ àwọn ènìyàn yìí yóò sì jẹ́ igi, yóò sì jẹ wọ́n run dájúdájú.”+ 15  “Kíyè sí i, èmi yóò mú orílẹ̀-èdè kan láti ibi jíjìnnàréré wá sórí yín,+ ilé Ísírẹ́lì,” ni àsọjáde Jèhófà. “Orílẹ̀-èdè tí ó ti wà tipẹ́tipẹ́ ni.+ Orílẹ̀-èdè ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn ni, orílẹ̀-èdè tí ìwọ kò mọ èdè rẹ̀, ìwọ kò sì lè gbọ́ ohun tí wọ́n ń sọ ní àgbọ́yé. 16  Apó wọn dà bí ibi ìsìnkú ṣíṣí sílẹ̀; gbogbo wọn jẹ́ ọkùnrin alágbára ńlá.+ 17  Dájúdájú, wọn yóò jẹ ìkórè rẹ àti oúnjẹ rẹ pẹ̀lú.+ Àwọn ọkùnrin náà yóò jẹ àwọn ọmọkùnrin rẹ àti àwọn ọmọbìnrin rẹ. Wọn yóò jẹ àwọn agbo ẹran rẹ àti àwọn ọ̀wọ́ ẹran rẹ. Wọn yóò jẹ àjàrà rẹ àti igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ.+ Wọn yóò fi idà fọ́ ìlú ńlá olódi rẹ èyí tí ìwọ gbẹ́kẹ̀ lé túútúú.” 18  “Àní ní àwọn ọjọ́ wọnnì,” ni àsọjáde Jèhófà, “èmi kì yóò mú ìparun pátápátá dé bá yín.+ 19  Yóò sì ṣẹlẹ̀ pé, ẹ óò wí pé, ‘Nítorí òtítọ́ wo ni Jèhófà Ọlọ́run wa fi ṣe gbogbo nǹkan wọ̀nyí sí wa?’+ Ìwọ yóò sì wí fún wọn pé, ‘Gan-an gẹ́gẹ́ bí ẹ ti fi mí sílẹ̀ tí ẹ sì lọ ń sin ọlọ́run ilẹ̀ òkèèrè ní ilẹ̀ yín, bẹ́ẹ̀ ni ẹ ó sin àwọn àjèjì ní ilẹ̀ kan tí kì í ṣe tiyín.’”+ 20  Ẹ sọ èyí ní ilé Jékọ́bù, ẹ sì kéde rẹ̀ fáyé gbọ́ ní Júdà, pé: 21  “Wàyí o, ẹ gbọ́ èyí, ẹ̀yin aláìgbọ́n tí kò ní ọkàn-àyà:+ Wọ́n ní ojú, ṣùgbọ́n wọn kò lè ríran;+ wọ́n ní etí, ṣùgbọ́n wọn kò lè gbọ́ràn.+ 22  ‘Ṣe ẹ kò bẹ̀rù èmi pàápàá,’+ ni àsọjáde Jèhófà, ‘tàbí kẹ̀, ṣé ẹ kò jẹ ìrora mímúná nítorí èmi,+ ẹni tí ó fi iyanrìn pa ààlà òkun, ìlànà tí ó wà fún àkókò tí ó lọ kánrin tí kò lè ré kọjá? Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, àwọn ìgbì rẹ̀ ń bi ara wọn síwá-sẹ́yìn, síbẹ̀, wọn kò lè borí; bí ó sì tilẹ̀ jẹ́ pé wọn di aláriwo líle, síbẹ̀, wọn kò lè ré e kọjá.+ 23  Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn yìí gan-an ní ọkàn-àyà agídí àti ọ̀tẹ̀; wọ́n ti yà sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan, wọ́n sì ń rìn lọ ní ipa ọ̀nà wọn.+ 24  Ṣùgbọ́n wọn kò sọ ní ọkàn-àyà wọn pé: “Wàyí o, ẹ jẹ́ kí a bẹ̀rù Jèhófà Ọlọ́run wa,+ Ẹni tí ń fúnni ní eji wọwọ àti òjò ìgbà ìkórè àti òjò ìgbà ìrúwé ní àsìkò rẹ̀,+ Ẹni tí ń ṣọ́, àní àwọn ọ̀sẹ̀ tí a lànà sílẹ̀ fún ìkórè nítorí wa.”+ 25  Àwọn ìṣìnà yín ti yí nǹkan wọ̀nyí padà, àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín sì ti fawọ́ ohun rere sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ yín.+ 26  “‘Nítorí a ti rí àwọn ènìyàn burúkú láàárín àwọn ènìyàn mi.+ Wọ́n ń yọjú, bí ìgbà tí àwọn pẹyẹpẹyẹ bá lúgọ.+ Wọ́n ti dẹ pańpẹ́ ìparun. Ènìyàn ni wọ́n ń mú. 27  Bí àgò ti ń kún fún àwọn ẹ̀dá tí ń fò, bẹ́ẹ̀ ni ilé wọn kún fún ẹ̀tàn.+ Ìdí nìyẹn ti wọ́n fi di ńlá tí wọ́n sì jèrè ọrọ̀.+ 28  Wọ́n ti sanra;+ wọ́n wá ń dán. Pẹ̀lúpẹ̀lù, ohun búburú ti kún inú wọn ní àkúnwọ́sílẹ̀. Wọn kò gba ẹjọ́ kankan rò,+ àní ẹjọ́ ọmọdékùnrin aláìníbaba,+ kí wọ́n bàa kẹ́sẹ járí;+ ìdájọ́ àwọn òtòṣì ni wọn kò sì dá sí.’” 29  “Kò ha yẹ kí n béèrè fún ìjíhìn nítorí nǹkan wọ̀nyí bí,” ni àsọjáde Jèhófà, “tàbí kò ha yẹ kí ọkàn mi gbẹ̀san lórí orílẹ̀-èdè tí ó rí bí èyí?+ 30  Ipò yíyanilẹ́nu, kódà ohun ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀, ni a ti mú kí ó ṣẹlẹ̀ ní ilẹ̀ náà:+ 31  Àwọn wòlíì pàápàá ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ èké ní ti gidi;+ àti ní ti àwọn àlùfáà, wọ́n ń tẹni lórí ba ní ìbámu pẹ̀lú agbára wọn.+ Àwọn ènìyàn mi sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ bẹ́ẹ̀;+ kí sì ni ẹ ó ṣe ní paríparí rẹ̀?”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé