Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Jeremáyà 49:1-39

49  Sí àwọn ọmọ Ámónì,+ èyí ni ohun tí Jèhófà wí: “Kò ha sí àwọn ọmọ tí Ísírẹ́lì ní, tàbí kò ha sí ajogún tí ó ní? Èé ṣe tí Málíkámù+ fi gba Gádì,+ tí àwọn ènìyàn tirẹ̀ sì ti bẹ̀rẹ̀ sí gbé inú àwọn ìlú ńlá Ísírẹ́lì gan-an?”+  “‘Nítorí náà, wò ó! àwọn ọjọ́ ń bọ̀,’ ni àsọjáde Jèhófà, ‘ṣe ni èmi yóò sì mú kí a gbọ́ àmì àfiyèsí oníròó ìdágìrì ogun+ lòdì sí Rábà+ ti àwọn ọmọ Ámónì; dájúdájú, yóò sì di òkìtì ahoro,+ àwọn àrọko+ rẹ̀ pàápàá ni a óò sì mú kí ó jó lala nínú iná.’+ “‘Ní tòótọ́, Ísírẹ́lì yóò sì sọ àwọn tí ó fi í ṣe ohun ìní di ohun ìní,’+ ni Jèhófà wí.  “‘Hu,+ ìwọ Hẹ́ṣíbónì,+ nítorí a ti fi Áì ṣe ìjẹ! Ké jáde, ẹ̀yin àrọko Rábà. Ẹ sán aṣọ àpò ìdọ̀họ.+ Pohùn réré ẹkún, kí o sì lọ káàkiri láàárín àwọn ọgbà ẹran tí a fi òkúta ṣe, nítorí Málíkámù alára yóò lọ àní sí ìgbèkùn,+ àwọn àlùfáà rẹ̀ àti àwọn ọmọ aládé rẹ̀, gbogbo wọn pa pọ̀.+  Èé ṣe tí o fi ń fọ́nnu nípa àwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀ rírẹlẹ̀,+ pẹ̀tẹ́lẹ̀ rírẹlẹ̀ rẹ tí ń ṣàn, ìwọ aláìṣòótọ́ ọmọbìnrin, ìwọ ẹni tí ó gbẹ́kẹ̀ lé àwọn ìṣúra rẹ̀,+ pé: “Ta ni yóò wá bá mi?”’”+  “‘Kíyè sí i, èmi yóò mú ohun akún-fún-ìbẹ̀rùbojo wá bá ọ,’+ ni àsọjáde Olúwa Ọba Aláṣẹ,+ Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, ‘láti ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn tí ó wà yí ọ ká. A ó sì fọ́n yín ká dájúdájú, olúkúlùkù sí ìhà tirẹ̀,+ kì yóò sì sí ẹni tí ń kó àwọn tí ń fẹsẹ̀ fẹ jọpọ̀.’”  “‘Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ìgbà náà, èmi yóò kó òǹdè nínú àwọn ọmọ Ámónì+ jọ,’ ni àsọjáde Jèhófà.”  Sí Édómù, èyí ni ohun tí Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wí: “Kò ha tún sí ọgbọ́n+ mọ́ ní Témánì?+ Ìmọ̀ràn ha ti ṣègbé lọ́dọ̀ àwọn tí ó ní òye? Ọgbọ́n wọn ha ti dómùkẹ̀?+  Ẹ sá lọ!+ Kí ẹ bìlà! Ẹ lọ sí ibi jíjìn nísàlẹ̀ kí ẹ lè máa gbé níbẹ̀,+ ẹ̀yin olùgbé Dédánì!+ Nítorí àjálù Ísọ̀ ni èmi yóò mú wá sórí rẹ̀, àkókò tí èmi yóò yí àfiyèsí mi sí i.+  Bí àwọn olùkó èso àjàrà jọ pàápàá bá wọlé wá bá ọ ní ti gidi, wọn kì yóò ha jẹ́ kí èéṣẹ́ díẹ̀ ṣẹ́ kù? Bí àwọn olè bá wọlé wá ní òru, dájúdájú, kìkì ìwọ̀n ìparun tí wọ́n bá fẹ́ ni wọn yóò fà.+ 10  Ṣùgbọ́n ní tèmi, ṣe ni èmi yóò tú Ísọ̀ sí borokoto.+ Ṣe ni èmi yóò tú àwọn ibi ìlùmọ́ rẹ̀ síta,+ ènìyàn kì yóò sì lè fi ara rẹ̀ pa mọ́.+ Àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ àti àwọn aládùúgbò rẹ̀ ni a ó fi ṣe ìjẹ dájúdájú,+ kì yóò sì sí mọ́.+ 11  Fi àwọn ọmọdékùnrin rẹ aláìníbaba sílẹ̀.+ Èmi fúnra mi yóò pa wọ́n mọ́ láàyè, àwọn opó rẹ yóò sì ní ìgbẹ́kẹ̀lé àní nínú mi.”+ 12  Nítorí èyí ni ohun tí Jèhófà wí: “Wò ó! Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe àṣà wọn láti mu ife náà, wọn yóò mu ún láìkùnà.+ Àti ìwọ fúnra rẹ, a ó ha ṣàìjẹ ọ́ níyà rárá bí? A kì yóò ṣàìjẹ ọ́ níyà, nítorí láìkùnà, ìwọ yóò mu ún.”+ 13  “Nítorí mo ti fi ara mi búra,”+ ni àsọjáde Jèhófà, “pé kìkì ohun ìyàlẹ́nu,+ ẹ̀gàn, ìparundahoro àti ìfiré ni Bósírà+ yóò dà; gbogbo àwọn ìlú ńlá rẹ̀ yóò sì di ibi ìparundahoro fún àkókò tí ó lọ kánrin.”+ 14  Ìròyìn kan wà tí mo ti gbọ́ láti ọ̀dọ̀ Jèhófà, aṣojú kan sì wà tí a rán sáàárín àwọn orílẹ̀-èdè, pé: “Ẹ kó ara yín jọpọ̀, ẹ wá gbéjà kò ó, ẹ sì dìde sí ìjà ogun.”+ 15  “Nítorí, wò ó! mo ti sọ ọ́ di kékeré ní tòótọ́ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè, ohun ìtẹ́ńbẹ́lú láàárín aráyé.+ 16  Ìgbọ̀njìnnìjìnnì tí o fà ti tàn ọ́ jẹ, ìkùgbù ọkàn-àyà rẹ,+ ìwọ tí ń gbé ní ibi kọ́lọ́fín àpáta gàǹgà, tí o di ibi gíga òkè kékeré mú. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé o kọ́ ìtẹ́ rẹ sí òkè réré gẹ́gẹ́ bí idì,+ èmi yóò mú ọ sọ̀ kalẹ̀ láti ibẹ̀ wá,”+ ni àsọjáde Jèhófà. 17  “Édómù yóò sì di ohun ìyàlẹ́nu.+ Olúkúlùkù ẹni tí ń kọjá lọ lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ yóò wò sùn-ùn tìyàlẹ́nu-tìyàlẹ́nu, yóò sì súfèé ní tìtorí gbogbo ìyọnu àjàkálẹ̀ rẹ̀.+ 18  Gan-an gẹ́gẹ́ bí ìbìṣubú Sódómù àti Gòmórà àti àwọn ìlú àdúgbò rẹ̀,”+ ni Jèhófà wí, “kò sí ènìyàn kankan tí yóò máa gbé ibẹ̀, kì yóò sì sí ọmọ aráyé kankan tí yóò máa ṣe àtìpó nínú rẹ̀.+ 19  “Wò ó! Ẹnì kan yóò jáde wá bí kìnnìún+ láti inú ìgbòrò ràgàjì lẹ́bàá Jọ́dánì lọ sí ibi gbígbé alálòpẹ́,+ ṣùgbọ́n ní ìṣẹ́jú kan, ṣe ni èmi yóò mú kí ó fẹsẹ̀ fẹ kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀.+ Èmi yóò sì yan ẹni àyànfẹ́ sórí rẹ̀. Nítorí ta ni ó dà bí èmi,+ ta ni yóò sì pè mí níjà,+ ta sì wá ni olùṣọ́ àgùntàn tí ó lè dúró níwájú mi?+ 20  Nítorí náà, ẹ gbọ́ ìpinnu Jèhófà, èyí tí ó ṣe lòdì sí Édómù,+ àti ìrònú rẹ̀ tí ó ti gbìrò sí àwọn olùgbé Témánì:+ Dájúdájú, àwọn èyí kéékèèké nínú agbo ẹran ni a óò wọ́ káàkiri. Dájúdájú, ní tìtorí wọn, òun yóò sọ ibi gbígbé wọn di ahoro.+ 21  Nígbà ìró ṣíṣubú wọn, ilẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí mì jìgìjìgì.+ Igbe ẹkún wà!+ A ti gbọ́ ìró rẹ̀ àní ní Òkun Pupa.+ 22  Wò ó! Gan-an gẹ́gẹ́ bí idì, ẹnì kan yóò gòkè wá, yóò sì kù gìrì wálẹ̀,+ yóò sì na ìyẹ́ apá rẹ̀ sórí Bósírà;+ ní ọjọ́ yẹn, ṣe ni ọkàn-àyà àwọn alágbára ńlá Édómù yóò sì dà bí ọkàn-àyà aya tí ó ní wàhálà ìbímọ.”+ 23  Sí Damásíkù:+ “Ìtìjú ti bá Hámátì+ àti Áápádì,+ nítorí ìròyìn búburú ni wọ́n gbọ́. Wọ́n ti fọ́ kélekèle.+ Àníyàn ṣíṣe wà nínú òkun; kò lè wà láìní ìyọlẹ́nu.+ 24  Àárẹ̀-ọkàn ti mú Damásíkù. Ó ti yí padà láti sá lọ, kìkìdá ẹ̀rù jìnnìjìnnì ti gbá a mú.+ Wàhálà àti ìroragógó ìbímọ pàápàá ti gbá a mú, bí ti obìnrin tí ó fẹ́ bímọ.+ 25  Èé ṣe tí a kò fi pa ìlú ńlá ìyìn tì, ìlú ayọ̀ ńláǹlà?+ 26  “Nítorí náà, àwọn ọ̀dọ́kùnrin rẹ̀ yóò ṣubú ní àwọn ojúde rẹ̀, gbogbo àwọn ọkùnrin ogun ni a ó sì pa lẹ́nu mọ́ ní ọjọ́ yẹn,”+ ni àsọjáde Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun. 27  “Ṣe ni èmi yóò mú kí iná jó lára ògiri Damásíkù, dájúdájú, yóò sì jẹ àwọn ilé gogoro ibùgbé Bẹni-hádádì+ run.” 28  Sí Kídárì+ àti àwọn ìjọba Hásórì,+ èyí tí Nebukadirésárì ọba Bábílónì ṣá balẹ̀,+ èyí ni ohun tí Jèhófà wí: “Ẹ dìde, ẹ gòkè lọ sí Kídárì, kí ẹ sì fi àwọn ọmọ Ìlà-Oòrùn ṣe ìjẹ.+ 29  Àgọ́ wọn+ àti àwọn agbo ẹran+ wọn ni a óò kó, aṣọ àgọ́+ wọn àti gbogbo ohun èlò wọn. Àwọn ràkúnmí+ wọn sì ni a óò kó lọ lọ́dọ̀ wọn. Dájúdájú, wọn yóò sì ké jáde sí wọn pé, ‘Jìnnìjìnnì wà ní gbogbo àyíká!’”+ 30  “Ẹ sá lọ, ẹ fẹsẹ̀ fẹ jìnnà réré; ẹ lọ sí ibi jíjìn nísàlẹ̀ kí ẹ lè máa gbé níbẹ̀, ẹ̀yin olùgbé Hásórì,”+ ni àsọjáde Jèhófà. “Nítorí Nebukadirésárì ọba Bábílónì+ ti ṣe ìpinnu kan àní lòdì sí yín, ó sì ti gbìrò ìrònú kan sí yín.” 31  “Ẹ dìde, ẹ gòkè lọ láti gbéjà ko orílẹ̀-èdè tí ó wà ní ìdẹ̀rùn,+ tí ń gbé nínú ààbò!”+ ni àsọjáde Jèhófà. “Kò ní ilẹ̀kùn bẹ́ẹ̀ ni kò ní ọ̀pá ìdábùú. Wọ́n ń gbé ní àwọn nìkan.+ 32  Ràkúnmí+ wọn yóò sì di ohun tí a piyẹ́, ògìdìgbó ohun ọ̀sìn wọn yóò sì di ohun ìfiṣèjẹ. Dájúdájú, èmi yóò tú wọn ká sí gbogbo ẹ̀fúùfù,+ àwọn tí a gé irun wọn mọ́lẹ̀ ní ẹ̀bátí;+ láti gbogbo àwọn ẹkùn ilẹ̀ tí ó sún mọ́ ọn ni èmi yóò sì ti mú àjálù wọn wá,” ni àsọjáde Jèhófà. 33  “Hásórì+ yóò sì di ibùgbé akátá,+ ahoro fún àkókò tí ó lọ kánrin. Ènìyàn kankan kì yóò gbé ibẹ̀, ọmọ aráyé kankan kì yóò sì ṣe àtìpó nínú rẹ̀.”+ 34  Èyí ni ohun tí ó tọ Jeremáyà wòlíì wá gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Jèhófà nípa Élámù+ ní ìbẹ̀rẹ̀ ìgbà àkóso Sedekáyà+ ọba Júdà, pé: 35  “Èyí ni ohun tí Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wí, ‘Kíyè sí i, èmi yóò ṣẹ́ ọrun Élámù,+ ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ agbára ńlá wọn. 36  Dájúdájú, èmi yóò mú ẹ̀fúùfù mẹ́rin láti ìkángun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ọ̀run wá sórí Élámù.+ Ṣe ni èmi yóò sì tú wọn ká sí gbogbo ẹ̀fúùfù wọ̀nyí,+ kì yóò sì sí orílẹ̀-èdè kankan tí àwọn tí a fọ́n ká+ láti Élámù kì yóò dé.’” 37  “Dájúdájú, èmi yóò fọ́ àwọn ọmọ Élámù túútúú níwájú àwọn ọ̀tá wọn àti níwájú àwọn tí ń wá ọkàn wọn; èmi yóò sì mú ìyọnu àjálù wá sórí wọn, ìbínú mi jíjófòfò,”+ ni àsọjáde Jèhófà. “Ṣe ni èmi yóò sì rán idà tọ̀ wọ́n lẹ́yìn títí èmi yóò fi pa wọ́n run pátápátá.”+ 38  “Dájúdájú, èmi yóò gbé ìtẹ́ mi kalẹ̀ ní Élámù,+ èmi yóò sì pa ọba àti àwọn ọmọ aládé run kúrò níbẹ̀,” ni àsọjáde Jèhófà. 39  “Dájúdájú, yóò sì ṣẹlẹ̀ ní apá ìgbẹ̀yìn àwọn ọjọ́+ pé èmi yóò kó àwọn òǹdè Élámù jọ,”+ ni àsọjáde Jèhófà.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé