Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Jeremáyà 48:1-47

48  Sí Móábù,+ èyí ni ohun tí Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, wí:+ “Ègbé ni fún Nébò,+ nítorí a ti fi ṣe ìjẹ! A ti kó ìtìjú bá Kíríátáímù,+ a ti gbà á. A ti kó ìtìjú bá ibi gíga ààbò, a sì ti kó ìpayà bá a.+  Kò sí ìyìn mọ́ fún Móábù.+ Wọ́n ti gbìrò ìyọnu àjálù sí i ní Hẹ́ṣíbónì+ pé: ‘Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a ké e kúrò ní jíjẹ́ orílẹ̀-èdè.’+ “Ìwọ, pẹ̀lú, Mádíménì, dákẹ́ jẹ́ẹ́. Idà ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.  Ìró igbe ẹkún ń bẹ láti Hórónáímù,+ ìfiṣèjẹ àti ìwópalẹ̀ ńláǹlà.  A ti wó Móábù palẹ̀.+ Àwọn ọmọ rẹ̀ kéékèèké ti mú kí a gbọ́ igbe.  Nítorí ní ọ̀nà tí ó gòkè lọ sí Lúhítì,+ pẹ̀lú ẹkún sísun ni ènìyàn ń gòkè lọ—ẹkún sísun wà. Nítorí ní ọ̀nà tí ó sọ̀ kalẹ̀ láti Hórónáímù, igbe ẹkún tí ń kó wàhálà báni wà nítorí ìwópalẹ̀+ tí àwọn ènìyàn ti gbọ́.  “Ẹ fẹsẹ̀ fẹ; ẹ pèsè àsálà fún ọkàn yín,+ kí ẹ sì dà bí igi júnípà ní aginjù.+  Nítorí ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ wà nínú iṣẹ́ rẹ àti nínú àwọn ìṣúra rẹ, ìwọ alára ni a óò kó lẹ́rú.+ Dájúdájú, Kémóṣì+ yóò jáde lọ sí ìgbèkùn,+ àwọn àlùfáà rẹ̀ àti àwọn ọmọ aládé rẹ̀ ní àkókò kan náà.+  Afiniṣèjẹ yóò sì wọlé wá sórí gbogbo ìlú ńlá,+ kì yóò sì sí ìlú ńlá kankan tí yóò bọ́.+ Pẹ̀tẹ́lẹ̀ rírẹlẹ̀ yóò sì ṣègbé dájúdájú, ilẹ̀ títẹ́jú pẹrẹsẹ yóò sì pa rẹ́ ráúráú, ohun tí Jèhófà ti wí.  “Ẹ fi àmì ojú ọ̀nà fún Móábù, nítorí ní àwókù ni òun yóò jáde lọ;+ àwọn ìlú ńlá rẹ̀ yóò sì di ohun ìyàlẹ́nu, láìsí ẹnì kankan tí ń gbé inú wọn.+ 10  “Ègún ni fún ẹni tí ń ṣe iṣẹ́ àfiránni Jèhófà lọ́nà àìnáání;+ ègún sì ni fún ẹni tí ń fawọ́ idà sẹ́yìn kúrò nínú ẹ̀jẹ̀! 11  “Àwọn ọmọ Móábù ti wà ní ìdẹ̀rùn láti ìgbà èwe wọn,+ wọ́n sì wà láìní ìyọlẹ́nu lórí gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀ wọn.+ A kò sì tíì dà wọ́n láti inú ohun èlò kan sínú ohun èlò mìíràn, wọn kò sì tíì lọ sí ìgbèkùn. Ìdí nìyẹn tí ìtọ́wò wọn fi dúró jẹ́ẹ́ láàárín wọn, ìtasánsán wọn pàápàá kò sì tíì yí padà. 12  “‘Nítorí náà, wò ó! àwọn ọjọ́ ń bọ̀,’ ni àsọjáde Jèhófà, ‘ṣe ni èmi yóò rán amóhun-èlò-dago sí wọn, wọn yóò sì mú wọn dago dájúdájú;+ wọn yóò sì sọ àwọn ohun èlò wọn di òfìfo, ìṣà wọn títóbi ni wọn yóò sì fọ́ túútúú. 13  Ojú yóò sì ti àwọn ọmọ Móábù nítorí Kémóṣì,+ gan-an gẹ́gẹ́ bí ojú ti ti ilé Ísírẹ́lì nítorí Bẹ́tẹ́lì, ìgbọ́kànlé wọn.+ 14  Kí ni ó mú yín dá a láṣà pé: “Àwa jẹ́ alágbára ńlá+ àti ọkùnrin tí ó ní ìmí fún ogun”?’ 15  “‘A ti fi Móábù ṣe ìjẹ, ẹnì kan sì ti gòkè lọ lòdì sí ìlú ńlá rẹ̀.+ Àní àwọn ọ̀dọ́kùnrin wọn ààyò jù lọ ti sọ̀ kalẹ̀ lọ fún ìfikúpa,’+ ni àsọjáde Ọba, orúkọ ẹni tí ń jẹ́ Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun.+ 16  “Àjálù sórí àwọn ọmọ Móábù sún mọ́lé ní ti gidi, ìyọnu àjálù wọn gan-an sì ń ṣe kánkán gidi gan-an.+ 17  Gbogbo àwọn tí ó wà yí wọn ká yóò bá wọn kẹ́dùn, àní gbogbo àwọn tí ó mọ orúkọ wọn.+ Ẹ wí pé, ‘Ẹ wò bí a ti ṣẹ́ ọ̀pá okun, ọ̀pá ẹwà!’+ 18  “Sọ̀ kalẹ̀ kúrò nínú ògo, sì jókòó nínú òùngbẹ, ìwọ obìnrin olùgbé, ọmọbìnrin+ Díbónì;+ nítorí ẹni tí ó fi Móábù ṣe ìjẹ ti gòkè wá láti gbéjà kò ọ́. Ní tòótọ́, òun yóò run àwọn ibi olódi rẹ.+ 19  “Dúró jẹ́ẹ́, kí o sì fojú wá ọ̀nà, ìwọ obìnrin olùgbé Áróérì.+ Béèrè lọ́wọ́ ọkùnrin tí ń sá lọ àti lọ́wọ́ obìnrin tí ń sá àsálà. Wí pé, ‘Kí ni a ti mú kí ó ṣẹlẹ̀?’+ 20  A ti kó ìtìjú bá Móábù, nítorí a ti kó ìpayà bá a.+ Ẹ hu kí ẹ sì ké jáde. Ẹ sọ ní Áánónì+ pé a ti fi Móábù ṣe ìjẹ. 21  Ìdájọ́ pàápàá sì ti wá sí ilẹ̀ tí ó wà ní ẹkùn ìpínlẹ̀ títẹ́jú pẹrẹsẹ,+ sí Hólónì àti sí Jáhásì+ àti lòdì sí Mẹ́fáátì,+ 22  àti lòdì sí Díbónì+ àti lòdì sí Nébò+ àti lòdì sí Bẹti-dibilátáímù, 23  àti lòdì sí Kíríátáímù+ àti lòdì sí Bẹti-gámúlì àti lòdì sí Bẹti-méónì+ 24  àti lòdì sí Kéríótì+ àti lòdì sí Bósírà+ àti lòdì sí gbogbo ìlú ńlá tí ó wà ní ilẹ̀ Móábù, àwọn tí ó jìnnà réré àti àwọn tí ó wà nítòsí. 25  “‘A ti ké ìwo Móábù lulẹ̀,+ a sì ti ṣẹ́ apá òun fúnra rẹ̀,’+ ni àsọjáde Jèhófà. 26  ‘Ẹ mú kí ó mu àmupara,+ nítorí ó ti gbé àgbéré ńláǹlà sí Jèhófà;+ Móábù sì ti yíràá ní ṣíṣe pàtápàtá nínú èébì rẹ̀,+ ó sì ti di ohun ìyọṣùtì sí, àní òun alára. 27  “‘Ísírẹ́lì kò ha sì di ohun ìyọṣùtì sí lójú rẹ bí?+ Tàbí a ha rí i láàárín àwọn olè paraku bí?+ Nítorí ìwọ ń mi orí rẹ nígbàkúùgbà tí o bá sọ̀rọ̀ lòdì sí i. 28  “‘Ẹ fi àwọn ìlú ńlá sílẹ̀ kí ẹ sì máa gbé lórí àpáta gàǹgà,+ ẹ̀yin olùgbé Móábù, kí ẹ sì dà bí àdàbà tí ń kọ́ ìtẹ́ rẹ̀ sí ẹkùn ilẹ̀ tí ó wà ní ẹnu ibi jíjinkòtò.’”+ 29  “A ti gbọ́ nípa ìgbéraga Móábù+—onírera gan-an ni—nípa ipò gíga rẹ̀ àti nípa ìgbéraga rẹ̀ àti nípa ìrera rẹ̀ àti nípa ìgafíofío ọkàn-àyà rẹ̀.”+ 30  “‘Èmi fúnra mi ti mọ ìbínú kíkan rẹ̀,’ ni àsọjáde Jèhófà, ‘kì í sì í ṣe bí yóò ti rí nìyẹn; ọ̀rọ̀ òfìfo+ rẹ̀—wọn kì yóò rí bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ ní ti gidi.+ 31  Ìdí nìyẹn tí ó fi jẹ́ pé lórí Móábù ni èmi yóò hu, Móábù látòkè délẹ̀ ni èmi yóò sì ké jáde fún.+ Àwọn ọkùnrin Kiri-hérésì+ ni ènìyàn yóò sì kédàárò fún. 32  “‘Ẹkún sísun tí ó ju ti Jásérì+ lọ ni èmi yóò fi sunkún fún ọ, ìwọ àjàrà Síbúmà.+ Àwọn ọ̀mùnú rẹ tí ń gbẹ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀ ti sọdá òkun. Dé òkun—dé Jásérì+—ni wọ́n ti dé. Afiniṣèjẹ pàápàá ti balẹ̀ sórí èso ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn+ rẹ àti sórí ìkójọ èso àjàrà rẹ.+ 33  Ayọ̀ yíyọ̀ àti ìdùnnú ni a ti mú kúrò nínú ọgbà igi eléso àti kúrò ní ilẹ̀ Móábù.+ Mo sì ti mú kí wáìnì pàápàá kasẹ̀ nílẹ̀ ní ibi ìfúntí wáìnì.+ Kò sí ẹni tí yóò máa fi igbe tẹ̀ ẹ́. Igbe náà kì yóò jẹ́ igbe.’”+ 34  “‘Láti igbe tí ó dún ní Hẹ́ṣíbónì+ títí lọ dé Éléálè,+ títí lọ dé Jáhásì+ ni ohùn wọn dé,+ láti Sóárì+ títí lọ dé Hórónáímù,+ dé Ẹgilati-ṣẹ́líṣíyà;+ nítorí àní omi Nímúrímù+ pàápàá yóò di ahoro lásán. 35  Ṣe ni èmi yóò sì mú kí ó kásẹ̀ nílẹ̀ ní Móábù,’ ni àsọjáde Jèhófà, ‘ẹni tí ń mú ọrẹ ẹbọ wá sí ibi gíga àti ẹni tí ń rú èéfín ẹbọ sí ọlọ́run rẹ̀.+ 36  Ìdí nìyẹn tí ọkàn-àyà mi yóò fi ru gùdù fún Móábù alára, gẹ́gẹ́ bí fèrè;+ ọkàn-àyà mi pàápàá yóò sì ru gùdù fún àwọn ọkùnrin Kiri-hérésì,+ gẹ́gẹ́ bí fèrè. Ìdí nìyẹn tí ọ̀pọ̀ yanturu ohun tí ó ti pèsè yóò fi ṣègbé dájúdájú.+ 37  Nítorí gbogbo orí ni ó pá,+ gbogbo irùngbọ̀n ni a sì gé mọ́lẹ̀.+ Ojú ọgbẹ́ wà ní gbogbo ọwọ́,+ aṣọ àpò ìdọ̀họ sì wà ní ìgbáròkó!’”+ 38  “‘Lórí gbogbo òrùlé ní Móábù àti ní àwọn ojúde ìlú—gbogbo rẹ̀—ìpohùnréré ẹkún wà;+ nítorí mo ti fọ́ Móábù gẹ́gẹ́ bí ohun èlò tí a kò ní inú dídùn sí,’+ ni àsọjáde Jèhófà. 39  ‘Wo bi àyà rẹ̀ ti já tó! Ẹ hu! Ẹ wo bí Móábù ti yí ẹ̀yìn rẹ̀! Ìtìjú ti bá a.+ Móábù sì ti di ohun ìyọṣùtì sí àti ohun ìjayà sí gbogbo àwọn tí ó wà yí i ká.’” 40  “Nítorí èyí ni ohun tí Jèhófà wí, ‘Wò ó! Gẹ́gẹ́ bí idì tí ń kù gìrì mọ́ nǹkan,+ ẹnì kan yóò na ìyẹ́ apá rẹ̀ pẹ̀lú bo Móábù.+ 41  Ní tòótọ́, a ó gba àwọn ìlú náà, àwọn ibi lílágbára tirẹ̀ ni a ó sì gbà dájúdájú. Ọkàn-àyà àwọn alágbára ńlá Móábù ní ọjọ́ yẹn yóò sì dà bí ọkàn-àyà aya kan tí ó ní wàhálà ìbímọ.’”+ 42  “‘Dájúdájú, a ó sì pa Móábù rẹ́ ráúráú kí ó má bàa jẹ́ àwọn ènìyàn kan mọ́,+ nítorí pé Jèhófà ni ó ti gbé àgbéré ńláǹlà sí.+ 43  Ìbẹ̀rùbojo àti ibi jíjinkòtò àti pańpẹ́ wà lórí rẹ, ìwọ olùgbé Móábù,’+ ni àsọjáde Jèhófà. 44  ‘Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń sá lọ nítorí ìbẹ̀rùbojo yóò já sínú ibi jíjinkòtò; ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ń gòkè bọ̀ láti ibi jíjinkòtò ni pańpẹ́ yóò mú.’+ “‘Nítorí èmi yóò mú ọdún tí a óò fún wọn ní àfiyèsí wá sórí rẹ̀, sórí Móábù,’+ ni àsọjáde Jèhófà. 45  ‘Nínú òjìji Hẹ́ṣíbónì ni àwọn tí ń sá lọ ti dúró jẹ́ẹ́ láìní agbára. Nítorí iná yóò jáde lọ láti Hẹ́ṣíbónì+ dájúdájú, àti ọwọ́ iná láti àárín Síhónì;+ yóò sì jẹ ẹ̀bátí Móábù run, àti àtàrí àwọn ọmọ ìrọ́kẹ̀kẹ̀.’+ 46  “‘Ègbé ni fún ọ, ìwọ Móábù!+ Àwọn ènìyàn Kémóṣì+ ti ṣègbé. Nítorí a ti mú àwọn ọmọkùnrin rẹ ní òǹdè àti àwọn ọmọbìnrin rẹ ní òǹdè. 47  Dájúdájú, èmi yóò kó àwọn òǹdè Móábù jọ ní apá ìgbẹ̀yìn àwọn ọjọ́,’+ ni àsọjáde Jèhófà. ‘Títí dé ìhín ni ìdájọ́ lórí Móábù.’”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé