Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Jeremáyà 47:1-7

47  Èyí ni ohun tí ó jẹ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà sí Jeremáyà wòlíì nípa àwọn Filísínì+ kí Fáráò tó bẹ̀rẹ̀ sí ṣá Gásà balẹ̀.+  Èyí ni ohun tí Jèhófà wí: “Wò ó! Omi ń gòkè bọ̀+ láti àríwá,+ ó sì ti di àkúnya ọ̀gbàrá. Wọn yóò sì kún bo ilẹ̀ náà àti ohun tí ó kún inú rẹ̀, ìlú ńlá náà àti àwọn tí ń gbé inú rẹ̀.+ Dájúdájú, àwọn ènìyàn náà yóò ké jáde, olúkúlùkù ẹni tí ń gbé ilẹ̀ náà yóò sì hu.+  Pẹ̀lú ìró kíkilẹ̀ pátákò àwọn akọ ẹṣin rẹ̀,+ pẹ̀lú dídún kẹ̀kẹ́ ẹṣin ogun rẹ̀,+ ìrọ́gììrì àgbá kẹ̀kẹ́ rẹ̀,+ dájúdájú, àwọn baba kì yóò yíjú padà wo àwọn ọmọ, nítorí rírọ tí ọwọ́ wọn rọ jọwọrọ,  ní tìtorí ọjọ́ tí ń bọ̀ láti fi gbogbo Filísínì+ ṣe ìjẹ, láti ké kúrò ní Tírè+ àti ní Sídónì+ olúkúlùkù olùlàájá tí ń ranni lọ́wọ́.+ Nítorí Jèhófà ń fi àwọn Filísínì+ ṣe ìjẹ, àwọn tí ó ṣẹ́ kù láti erékùṣù Káfítórì.+  Ìpárí+ yóò dé sí Gásà.+ A ti pa Áṣíkẹ́lónì+ lẹ́nu mọ́. Ìwọ àṣẹ́kù pẹ̀tẹ́lẹ̀ rírẹlẹ̀ wọn, yóò ti pẹ́ tó tí ìwọ yóò máa kọ ara rẹ lábẹ?+  “Àháà, idà Jèhófà!+ Yóò ti pẹ́ tó tí ìwọ yóò gbé jẹ́ẹ́? Kí a tì ọ́ bọnú àkọ̀ rẹ.+ Gba ìsinmi, kí o sì dákẹ́ jẹ́ẹ́.  “Báwo ni ó ṣe lè gbé jẹ́ẹ́, nígbà tí Jèhófà fúnra rẹ̀ ti pa àṣẹ fún un? Ó wà fún Áṣíkẹ́lónì àti fún etí òkun.+ Ibẹ̀ ni ó yàn fún un pé kí ó wà.”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé