Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Jeremáyà 46:1-28

46  Èyí ni ohun tí ó tọ Jeremáyà wòlíì wá bí ọ̀rọ̀ Jèhófà nípa àwọn orílẹ̀-èdè:+  Sí Íjíbítì,+ nípa ẹgbẹ́ ológun Fáráò Nékò ọba Íjíbítì,+ tí ó wà lẹ́bàá Odò Yúfírétì ní Kákémíṣì,+ ẹni tí Nebukadirésárì ọba Bábílónì ṣẹ́gun ní ọdún kẹrin Jèhóákímù+ ọmọkùnrin Jòsáyà, ọba Júdà:  “Ẹ to asà àti apata ńlá ní ẹsẹẹsẹ, ẹ sì sún mọ́ ìjà ogun.+  Ẹ fi ìjánu sí ẹṣin, kí ẹ sì gùn ún, ẹ̀yin ẹlẹ́ṣin, kí ẹ sì dúró ti ẹ̀yin ti àṣíborí. Ẹ dán aṣóró. Ẹ fi ẹ̀wù tí a fi àdàrọ irin ṣe wọ ara yín.+  “‘Èé ṣe tí mo fi rí wọn nínú ìpayà? Wọ́n ń yí padà, àwọn alágbára ńlá wọn ni a sì fọ́ sí wẹ́wẹ́; wọ́n sì ti sá lọ dájúdájú, wọn kò sì tíì yíjú padà.+ Jìnnìjìnnì wà yí ká,’+ ni àsọjáde Jèhófà.  ‘Kí ẹni yíyára má gbìyànjú láti sá lọ, kí alágbára ńlá má sì gbìyànjú láti sá àsálà.+ Lókè níhà àríwá,+ lẹ́bàá bèbè Odò Yúfírétì, wọ́n ti kọsẹ̀, wọ́n sì ti ṣubú.’+  “Ta ni ẹni yìí tí ń gòkè bọ̀ gẹ́gẹ́ bí Odò Náílì, bí àwọn odò tí omi wọn ń bi ara wọn síwá-sẹ́yìn?+  Íjíbítì alára ń gòkè bọ̀ gẹ́gẹ́ bí Odò Náílì,+ àti pé bí àwọn odò, ṣe ni omi náà ń bì síwá-sẹ́yìn.+ Ó sì wí pé, ‘Èmi yóò gòkè lọ. Èmi yóò bo ilẹ̀ ayé. Lọ́gán ni èmi yóò pa ìlú ńlá náà run àti àwọn tí ń gbé inú rẹ̀.’+  Ẹ gòkè lọ, ẹ̀yin ẹṣin; kí ẹ sì sá eré àsápajúdé, ẹ̀yin kẹ̀kẹ́ ẹṣin! Kí àwọn alágbára ńlá sì jáde lọ, Kúṣì+ àti Pútì,+ tí wọ́n ń di apata mú, àti àwọn Lúdímù,+ tí wọ́n ń di ọrun mú tí wọ́n sì ń fà á. 10  “Ọjọ́ yẹn sì jẹ́ ti Olúwa Ọba Aláṣẹ, Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, ọjọ́ ẹ̀san fún gbígbẹ̀san ara rẹ̀ lára àwọn elénìní rẹ̀.+ Dájúdájú, idà yóò sì jẹ run, yóò sì tẹ́ ara rẹ̀ lọ́rùn, yóò sì mu ẹ̀jẹ̀ wọn yó, nítorí Olúwa Ọba Aláṣẹ,+ Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, ní ẹbọ+ kan ní ilẹ̀ àríwá lẹ́bàá Odò Yúfírétì.+ 11  “Gòkè lọ sí Gílíádì kí o sì mú básámù+ wá, ìwọ wúńdíá ọmọbìnrin Íjíbítì.+ Lásán ni o sọ ọ̀nà ìmúniláradá di púpọ̀. Kò sí ìmúbọ̀sípò fún ọ.+ 12  Àwọn orílẹ̀-èdè ti gbọ́ nípa àbùkù rẹ,+ igbe ẹkún rẹ sì ti kún ilẹ̀ náà.+ Nítorí wọ́n ti kọsẹ̀, alágbára ńlá kọsẹ̀ lára alágbára ńlá.+ Wọ́n ti jọ ṣubú lulẹ̀, àwọn méjèèjì.” 13  Ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ fún Jeremáyà wòlíì nípa wíwá tí Nebukadirésárì ọba Bábílónì yóò wá láti ṣá ilẹ̀ Íjíbítì balẹ̀:+ 14  “Ẹ sọ ọ́ ní Íjíbítì, ẹ sì kéde rẹ̀ fáyé gbọ́ ní Mígídólì,+ ẹ sì kéde rẹ̀ fáyé gbọ́ ní Nófì+ àti ní Tápánẹ́sì.+ Pé, ‘Ẹ dúró, ní ṣíṣe ìmúrasílẹ̀ fún ara yín pẹ̀lú,+ nítorí ó dájú pé idà yóò jẹ gbogbo ohun tí ó wà ní àyíká rẹ run.+ 15  Èé ṣe tí a fi gbá àwọn alágbára rẹ lọ?+ Wọn kò mú ìdúró, nítorí Jèhófà fúnra rẹ̀ ti tì wọ́n dànù.+ 16  Wọ́n ń kọsẹ̀ ní iye púpọ̀. Wọ́n tún ṣubú ní tòótọ́. Wọ́n sì ń sọ, èkínní fún èkejì pé: “Dìde, sì jẹ́ kí a padà sọ́dọ̀ àwọn ènìyàn wa àti sí ilẹ̀ àwọn ìbátan wa nítorí idà tí ń hanni léèmọ̀.”’ 17  Ibẹ̀ ni wọ́n ti pòkìkí pé, ‘Fáráò ọba Íjíbítì jẹ́ ariwo lásán.+ Ó ti jẹ́ kí ìgbà àjọyọ̀ kọjá lọ.’+ 18  “‘Bí mo ti ń bẹ láàyè,’ ni àsọjáde Ọba, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun,+ ‘bí Tábórì+ láàárín àwọn òkè ńláńlá àti bí Kámẹ́lì+ lẹ́bàá òkun ni òun yóò wọlé. 19  Di kìkì ẹrù àdì-lọ-sí ìgbèkùn fún ara rẹ,+ ìwọ obìnrin olùgbé, ọmọbìnrin+ Íjíbítì. Nítorí Nófì+ pàápàá yóò di ohun ìyàlẹ́nu lásán, ní tòótọ́, a ó sì sọ iná sí i, kí ó má bàa ní olùgbé.+ 20  Íjíbítì dà bí ẹgbọrọ abo màlúù tí ó lẹ́wà gan-an ní ìrísí. Láti àríwá, àní ẹ̀fọn kan yóò wá bá a dájúdájú.+ 21  Pẹ̀lúpẹ̀lù, àwọn ọmọ ogun rẹ̀ tí ó háyà ní àárín rẹ̀ dà bí ọmọ màlúù àbọ́sanra.+ Ṣùgbọ́n àwọn pẹ̀lú ti bìlà;+ wọ́n ti jùmọ̀ sá lọ. Wọn kò lè mú ìdúró kankan.+ Nítorí ọjọ́ àjálù wọn gan-an ti wọlé wá sórí wọn, àkókò láti fún wọn ní àfiyèsí.’+ 22  “‘Ohùn rẹ̀ dà bí ti ejò tí ń lọ;+ nítorí pẹ̀lú ìmí ni àwọn ènìyàn yóò lọ, pẹ̀lú àáké ni wọn yóò sì wọlé tọ̀ ọ́ wá ní ti gidi, bí àwọn tí ń kó igi jọ. 23  Dájúdájú, wọn yóò gé igbó rẹ̀ lulẹ̀,’+ ni àsọjáde Jèhófà, ‘nítorí pé inú rẹ̀ kò ṣeé wọ̀. Nítorí wọ́n ti pọ̀ níye ju eéṣú lọ,+ wọn kò sì ní iye. 24  Dájúdájú, ojú yóò ti ọmọbìnrin+ Íjíbítì. Ní tòótọ́, a ó fi í lé àwọn ènìyàn àríwá lọ́wọ́.’+ 25  “Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, wí pé, ‘Kíyè sí i, èmi yóò yí àfiyèsí mi sí Ámọ́nì+ láti Nóò+ àti sí Fáráò àti sí Íjíbítì àti sí àwọn ọlọ́run rẹ̀+ àti sí àwọn ọba rẹ̀,+ àní sí Fáráò àti sí gbogbo àwọn tí wọ́n ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú rẹ̀.’+ 26  “‘Dájúdájú, èmi yóò sì fi wọ́n lé àwọn tí ń wá ọkàn wọn àti lé Nebukadirésárì ọba Bábílónì+ àti lé àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́; àti lẹ́yìn ìgbà náà, a óò máa gbé inú rẹ̀ bí ti ìgbà láéláé,’+ ni àsọjáde Jèhófà. 27  “‘Ní ti ìwọ, má fòyà, ìwọ Jékọ́bù ìránṣẹ́ mi, kí ìpayà má sì bá ọ, ìwọ Ísírẹ́lì.+ Nítorí kíyè sí i, èmi yóò gbà ọ́ là láti ibi jíjìnnàréré àti àwọn ọmọ rẹ láti ilẹ̀ oko òǹdè wọn.+ Dájúdájú, Jékọ́bù yóò padà, kì yóò sì ní ìyọlẹ́nu kankan, yóò wà ní ìdẹ̀rùn, láìsí ẹnì kankan tí ń fa ìwárìrì.+ 28  Ní ti ìwọ, má fòyà, ìwọ Jékọ́bù ìránṣẹ́ mi,’ ni àsọjáde Jèhófà, ‘nítorí èmi wà pẹ̀lú rẹ.+ Nítorí èmi yóò ṣe ìparun pátápátá láàárín gbogbo orílẹ̀-èdè tí èmi fọ́n ọ ká sí,+ ṣùgbọ́n èmi kì yóò ṣe ìparun pátápátá sí ọ.+ Síbẹ̀, ṣe ni èmi yóò nà ọ́ dé ìwọ̀n tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu,+ èmi kò sì ní ṣàìfi ìyà jẹ ọ́.’”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé