Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Jeremáyà 45:1-5

45  Ọ̀rọ̀ tí Jeremáyà wòlíì sọ fún Bárúkù+ ọmọkùnrin Neráyà, nígbà tí ó kọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sínú ìwé láti ẹnu Jeremáyà+ ní ọdún kẹrin Jèhóákímù+ ọmọkùnrin Jòsáyà, ọba Júdà, pé:  “Èyí ni ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí nípa rẹ, ìwọ Bárúkù,  ‘Ìwọ wí pé: “Mo gbé wàyí,+ nítorí pé Jèhófà ti fi ẹ̀dùn-ọkàn kún ìrora mi! Agara ti dá mi nítorí ìmí ẹ̀dùn mi, èmi kò sì rí ibi ìsinmi kankan.”’+  “Èyí ni ohun tí ìwọ yóò sọ fún un, ‘Èyí ni ohun tí Jèhófà wí: “Wò ó! Ohun ti mo kọ́ ni èmi yóò ya lulẹ̀, ohun tí mo sì gbìn ni èmi yóò fà tu, àní gbogbo ilẹ̀ náà.+  Ṣùgbọ́n ní tìrẹ, ìwọ ń wá àwọn ohun ńláńlá fún ara rẹ.+ Má ṣe wá wọn mọ́.”’+ “‘Nítorí kíyè sí i, èmi yóò mú ìyọnu àjálù wá sórí gbogbo ẹran ara,’+ ni àsọjáde Jèhófà, ‘èmi yóò sì fi ọkàn rẹ fún ọ bí ohun ìfiṣèjẹ ní gbogbo ibi tí ìwọ bá lọ.’”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé