Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Jeremáyà 44:1-30

44  Ọ̀rọ̀ tí ó tọ Jeremáyà wá fún gbogbo Júù tí ń gbé ní ilẹ̀ Íjíbítì,+ àwọn tí ń gbé ní Mígídólì+ àti ní Tápánẹ́sì+ àti ní Nófì+ àti ní ilẹ̀ Pátírọ́sì,+ pé:  “Èyí ni ohun tí Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí, ‘Ẹ̀yin fúnra yín ti rí gbogbo ìyọnu àjálù tí mo mú wá sórí Jerúsálẹ́mù+ àti sórí gbogbo àwọn ìlú ńlá Júdà, sì kíyè sí i, ibi ìparundahoro ni wọ́n ní òní yìí, kò sì sí olùgbé kankan nínú wọn.+  Ó jẹ́ nítorí ìwà búburú wọn tí wọ́n hù láti mú mi bínú nípa lílọ rú èéfín ẹbọ+ àti ṣíṣe iṣẹ́ ìsìn sí àwọn ọlọ́run mìíràn tí àwọn fúnra wọn kò mọ̀, yálà ẹ̀yin tàbí àwọn baba ńlá yín.+  Mo sì ń rán gbogbo ìránṣẹ́ mi wòlíì sí yín ṣáá, tí mo ń dìde ní kùtùkùtù, tí mo sì ń ránṣẹ́,+ pé: “Ẹ jọ̀wọ́, ẹ má ṣe irú ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí yìí tí mo kórìíra.”+  Ṣùgbọ́n wọn kò fetí sílẹ̀,+ bẹ́ẹ̀ ni wọn kò dẹ etí wọn sílẹ̀ láti yí padà kúrò nínú ìwà búburú wọn nípa ṣíṣàìrú èéfín ẹbọ sí àwọn ọlọ́run mìíràn.+  Nítorí náà, ìhónú mi, àti ìbínú mi ni a tú jáde, ó sì jó ní àwọn ìlú ńlá Júdà àti ní àwọn ojú pópó Jerúsálẹ́mù;+ wọ́n sì wá jẹ́ ibi ìparundahoro, ahoro, bí o ti rí ní òní yìí.’+  “Wàyí o, èyí ni ohun tí Jèhófà, Ọlọ́run àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí, ‘Èé ṣe tí ẹ fi ń fa ìyọnu àjálù ńláǹlà wá bá ọkàn yín,+ láti ké ọkùnrin àti obìnrin, ọmọ àti ọmọ ẹnu ọmú,+ kúrò nínú yín, kúrò ní àárín Júdà, tí ẹ kò fi ṣẹ́ àṣẹ́kù sílẹ̀ fún ara yín;  nípa fífi iṣẹ́ ọwọ́ yín mú mi bínú, nípa rírú èéfín ẹbọ sí àwọn ọlọ́run mìíràn+ ní ilẹ̀ Íjíbítì, èyí tí ẹ ń wọ̀ lọ láti ṣe àtìpó; fún ète mímú kí a ké yín kúrò àti fún ète pé kí ẹ lè di ohun ìfiré àti ohun ẹ̀gàn láàárín gbogbo orílẹ̀-èdè ilẹ̀ ayé?+  Ẹ ha ti gbàgbé ìwà búburú àwọn baba ńlá yín+ àti ìwà búburú àwọn ọba Júdà+ àti ìwà búburú àwọn aya wọn+ àti ìwà búburú tiyín àti ìwà búburú àwọn aya yín,+ tí wọ́n ti ṣe ní ilẹ̀ Júdà àti ní àwọn ojú pópó Jerúsálẹ́mù? 10  Àti títí di òní yìí, wọn kò ṣe bí ẹni tí a tẹ̀ mọ́lẹ̀,+ àyà kò sì fò wọ́n,+ bẹ́ẹ̀ ni wọn kò rìn nínú òfin mi+ àti nínú àwọn ìlànà àgbékalẹ̀ mi tí mo gbé kalẹ̀ síwájú yín àti síwájú àwọn baba ńlá yín.’+ 11  “Nítorí náà, èyí ni ohun tí Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí, ‘Kíyè sí i, èmi dojú mi kọ ọ́ fún ìyọnu àjálù àti fún kíké gbogbo Júdà kúrò.+ 12  Dájúdájú, èmi yóò kó àṣẹ́kù Júdà tí ó gbé ojú wọn lé àtiwọ ilẹ̀ Íjíbítì láti máa ṣe àtìpó níbẹ̀,+ ó sì dájú pé gbogbo wọn yóò wá sí òpin wọn ní ilẹ̀ Íjíbítì.+ Wọn yóò tipa idà ṣubú; wọn yóò sì tipa ìyàn+ wá sí òpin wọn, láti orí ẹni tí ó kéré jù lọ àní títí dé orí ẹni tí ó tóbi jù lọ; nípa idà àti nípa ìyàn ni wọn yóò kú. Wọn yóò sì di ègún, ohun ìyàlẹ́nu àti ìfiré àti ẹ̀gàn.+ 13  Ṣe ni èmi yóò sì béèrè ìjíhìn lọ́wọ́ àwọn tí ń gbé ní ilẹ̀ Íjíbítì, gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti fi idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀ àrùn béèrè ìjíhìn lọ́wọ́ Jerúsálẹ́mù.+ 14  Kì yóò sì wá sí olùsálà tàbí olùlàájá fún àṣẹ́kù Júdà tí ń wọ ibẹ̀ lọ láti ṣe àtìpó, ní ilẹ̀ Íjíbítì,+ àní láti padà sí ilẹ̀ Júdà tí wọ́n ń gbé ìfẹ́ tí ó gba gbogbo ọkàn wọn sókè sí láti padà sí, kí wọ́n lè máa gbé ibẹ̀;+ nítorí wọn kì yóò padà, àyàfi àwọn olùsálà mélòó kan.’” 15  Gbogbo ọkùnrin tí wọ́n sì mọ̀ pé àwọn aya wọn ti ń rú èéfín ẹbọ sí àwọn ọlọ́run mìíràn,+ àti gbogbo aya tí wọ́n dúró bí ìjọ títóbi, àti gbogbo ènìyàn tí ń gbé ní ilẹ̀ Íjíbítì,+ ní Pátírọ́sì,+ sì tẹ̀ síwájú láti dá Jeremáyà lóhùn, pé: 16  “Ní ti ọ̀rọ̀ tí o bá wa sọ ní orúkọ Jèhófà, àwa kì yóò fetí sí ọ;+ 17  ṣùgbọ́n ṣíṣe ni àwa yóò ṣe gbogbo ọ̀rọ̀ tí ó ti ẹnu wa jáde,+ láti rú èéfín ẹbọ sí ‘ọbabìnrin ọ̀run’+ àti láti da ọrẹ ẹbọ ohun mímu jáde sí i,+ gan-an gẹ́gẹ́ bí àwa+ àti àwọn baba ńlá wa,+ àwọn ọba wa+ àti àwọn ọmọ aládé wa ti ṣe ní àwọn ìlú ńlá Júdà àti ní àwọn ojú pópó Jerúsálẹ́mù, nígbà tí a máa ń jẹ oúnjẹ ní àjẹtẹ́rùn, tí nǹkan sì dára fún wa, a kò sì rí ìyọnu àjálù kankan rárá.+ 18  Láti ìgbà tí a sì ti ṣíwọ́ rírú èéfín ẹbọ sí ‘ọbabìnrin ọ̀run’+ àti dída ọrẹ ẹbọ ohun mímu jáde sí i ni a ti ṣaláìní ohun gbogbo, àti nípasẹ̀ idà àti nípasẹ̀ ìyàn sì ni a ti wá sí òpin wa.+ 19  “Pẹ̀lúpẹ̀lù, nígbà tí a ń rú èéfín ẹbọ sí ‘ọbabìnrin ọ̀run’+ tí a sì ṣe tán láti da ọrẹ ẹbọ ohun mímu jáde sí i,+ a ha ń ṣe àkàrà ìrúbọ sí i, láìbéèrè lọ́wọ́ àwọn ọkọ wa, láti gbẹ́ ère rẹ̀, àti láti da ọrẹ ẹbọ ohun mímu jáde sí i?”+ 20  Ẹ̀wẹ̀, Jeremáyà wí fún gbogbo àwọn ènìyàn náà, fún àwọn abarapá ọkùnrin àti fún àwọn aya àti fún gbogbo àwọn ènìyàn náà, àwọn tí ń fi ọ̀rọ̀ dá a lóhùn, pé: 21  “Ní ti èéfín ẹbọ tí ẹ rú ní àwọn ìlú ńlá Júdà àti ní àwọn ojú pópó Jerúsálẹ́mù,+ ẹ̀yin+ àti àwọn baba ńlá yín,+ àwọn ọba yín+ àti àwọn ọmọ aládé yín+ àti àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà, kì í ha ṣe èyí ni Jèhófà rántí tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí wá sí ọkàn-àyà rẹ̀?+ 22  Níkẹyìn, Jèhófà kò tún lè fara dà á mọ́ nítorí búburú ìbálò yín,+ nítorí àwọn ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí tí ẹ ti ṣe, bẹ́ẹ̀ ni ilẹ̀ yín sì wá di ibi ìparundahoro àti ohun ìyàlẹ́nu àti ìfiré, láìní olùgbé, bí ó ti rí ní òní yìí.+ 23  Nítorí òtítọ́ náà pé ẹ rú èéfín ẹbọ+ àti pé ẹ dẹ́ṣẹ̀ sí Jèhófà,+ ẹ kò sì ṣègbọràn sí ohùn Jèhófà,+ ẹ kò sì rìn nínú òfin+ rẹ̀ àti nínú àwọn ìlànà àgbékalẹ̀ rẹ̀ àti nínú àwọn ìránnilétí rẹ̀, ìdí nìyẹn tí ìyọnu àjálù yìí fi já lù yín bí ó ti rí ní òní yìí.”+ 24  Jeremáyà sì ń bá a lọ láti sọ fún gbogbo àwọn ènìyàn náà àti fún gbogbo àwọn obìnrin náà pé: “Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà, gbogbo Júdà tí ó wà ní ilẹ̀ Íjíbítì.+ 25  Èyí ni ohun tí Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí, ‘Ní ti ẹ̀yín àti àwọn aya yín,+ ẹ̀yin obìnrin yìí pẹ̀lú fi ẹnu yín sọ̀rọ̀, (ẹ sì ti fi ọwọ́ yín mú un ṣẹ,) pé: “Láìkùnà, àwa yóò pa ẹ̀jẹ́ wa tí a ti jẹ́ mọ́,+ láti rú èéfín ẹbọ sí ‘ọbabìnrin ọ̀run’+ àti láti da ọrẹ ẹbọ ohun mímu jáde sí i.”+ Láìkùnà, ẹ̀yin obìnrin yìí yóò mú ẹ̀jẹ́ yín ṣẹ, láìkùnà, ẹ ó sì pa ẹ̀jẹ́ yín mọ́.’ 26  “Nítorí náà, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà, gbogbo Júdà tí ń gbé ní ilẹ̀ Íjíbítì,+ ‘“Kíyè sí i, èmi fúnra mi ti fi orúkọ mi ńlá búra,”+ ni Jèhófà wí, “pé orúkọ mi kì yóò jẹ́ ohun tí a óò máa pè jáde láti ẹnu èyíkéyìí nínú àwọn ọkùnrin Júdà,+ pé, ‘Bí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ ti ń bẹ láàyè!’+ ní gbogbo ilẹ̀ Íjíbítì. 27  Kíyè sí i, mo wà lójúfò sí wọn fún ìyọnu àjálù kì í sì í ṣe fún rere;+ gbogbo àwọn ọkùnrin Júdà tí ó sì wà ní ilẹ̀ Íjíbítì yóò tipa idà àti ìyàn wá sí òpin wọn dájúdájú, títí wọn yóò fi kásẹ̀ nílẹ̀.+ 28  Àti ní ti àwọn tí wọ́n bá sá àsálà kúrò lọ́wọ́ idà, wọn yóò padà láti ilẹ̀ Íjíbítì sí ilẹ̀ Júdà, ní iye tí ó kéré;+ àti gbogbo àṣẹ́kù Júdà, tí ń bọ̀ wá sí ilẹ̀ Íjíbítì láti máa ṣe àtìpó níbẹ̀, yóò sì mọ ọ̀rọ̀ ẹni tí ó ṣẹ dájúdájú, èyí tí ó ti ẹnu mi jáde tàbí èyí tí ó ti ẹnu wọn jáde.”’”+ 29  “‘Èyí sì ni àmì fún yín,’+ ni àsọjáde Jèhófà, ‘pé èmi yóò yí àfiyèsí mi sí yín ní ibí yìí, kí ẹ lè mọ̀ pé láìkùnà, àwọn ọ̀rọ̀ mi yóò ṣẹ sí yín lára fún ìyọnu àjálù:+ 30  Èyí ni ohun tí Jèhófà wí: “Kíyè sí i, èmi yóò fi Fáráò Hófírà, ọba Íjíbítì,+ lé àwọn ọ̀tá rẹ̀ àti lé àwọn tí ń wá ọkàn rẹ̀ lọ́wọ́,+ gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti fi Sedekáyà ọba Júdà lé Nebukadirésárì ọba Bábílónì lọ́wọ́, ọ̀tá rẹ̀ àti ẹni tí ń wá ọkàn rẹ̀.”’”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé