Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Jeremáyà 43:1-13

43  Wàyí o, ó ṣẹlẹ̀ pé gbàrà tí Jeremáyà parí bíbá gbogbo ènìyàn náà sọ gbogbo ọ̀rọ̀ Jèhófà Ọlọ́run wọn, èyí tí Jèhófà Ọlọ́run wọn fi rán an sí wọn, àní gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí,+  Asaráyà ọmọkùnrin Hóṣáyà+ àti Jóhánánì+ ọmọkùnrin Káréà àti gbogbo ọkùnrin oníkùgbù+ tẹ̀ síwájú láti sọ fún Jeremáyà pé: “Èké ni ìwọ ń sọ.+ Jèhófà Ọlọ́run wa kò rán ọ, pé, ‘Má ṣe wọ Íjíbítì láti ṣe àtìpó níbẹ̀.’+  Ṣùgbọ́n Bárúkù+ ọmọkùnrin Neráyà ń dẹ ọ́ sí wa fún ète àtifi wá lé àwọn ará Kálídíà lọ́wọ́, láti fi ikú pa wá tàbí láti mú wa lọ ní ìgbèkùn sí Bábílónì.”+  Jóhánánì ọmọkùnrin Káréà àti gbogbo olórí ẹgbẹ́ ológun àti gbogbo ènìyàn náà kò sì ṣègbọràn sí ohùn Jèhófà,+ láti máa gbé ní ilẹ̀ Júdà nìṣó.+  Nítorí náà, Jóhánánì ọmọkùnrin Káréà àti gbogbo olórí ẹgbẹ́ ológun mú gbogbo àṣẹ́kù Júdà tí ó ti padà láti gbogbo orílẹ̀-èdè èyí tí a fọ́n wọn ká sí, láti máa gbé fún ìgbà díẹ̀ ní ilẹ̀ Júdà,+  àní àwọn abarapá ọkùnrin àti àwọn aya àti àwọn ọmọ kéékèèké àti àwọn ọmọbìnrin ọba+ àti olúkúlùkù ọkàn tí Nebusárádánì+ olórí ẹ̀ṣọ́ fi sílẹ̀ pẹ̀lú Gẹdaláyà+ ọmọkùnrin Áhíkámù+ ọmọkùnrin Ṣáfánì,+ àti Jeremáyà wòlíì àti Bárúkù+ ọmọkùnrin Neráyà.  Nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, wọ́n wá sí ilẹ̀ Íjíbítì,+ nítorí wọn kò ṣègbọràn sí ohùn Jèhófà; ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ wọ́n wá dé Tápánẹ́sì.+  Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Jèhófà tọ Jeremáyà wá ní Tápánẹ́sì, pé:  “Kó àwọn òkúta títóbi ní ọwọ́ rẹ, kí o sì kó wọn pa mọ́ sínú àpòrọ́ erùpẹ̀ ní ọ̀dẹ̀dẹ̀ onípèpéle tí a fi bíríkì ṣe tí ó wà ní ẹnu ọ̀nà ilé Fáráò ní Tápánẹ́sì lójú àwọn ọkùnrin Júù.+ 10  Kí o sì wí fún wọn pé, ‘Èyí ni ohun tí Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí: “Kíyè sí i, èmi yóò ránṣẹ́, dájúdájú, èmi yóò mú Nebukadirésárì ọba Bábílónì,+ ìránṣẹ́ mi,+ ṣe ni èmi yóò sì gbé ìtẹ́ rẹ̀ lé òkúta wọ̀nyí gan-an tí mo fi pa mọ́, dájúdájú, òun yóò sì na àgọ́ rẹ̀ onídàńsákì lé wọn lórí. 11  Òun yóò sì wọlé, yóò sì kọlu ilẹ̀ Íjíbítì.+ Ẹnì yòówù tí ó bá yẹ fún ìyọnu àjàkálẹ̀ tí ń ṣekú pani, yóò jẹ́ fún ìyọnu àjàkálẹ̀ tí ń ṣekú pani, ẹnì yòówù tí ó bá yẹ fún oko òǹdè, yóò jẹ́ fún oko òǹdè, ẹnì yòówù tí ó bá sì yẹ fún idà, yóò jẹ́ fún idà.+ 12  Ṣe ni èmi yóò mú kí iná jó nínú ilé àwọn ọlọ́run Íjíbítì;+ dájúdájú, òun yóò sì fi iná sun wọ́n, yóò sì kó wọn lọ ní òǹdè, yóò sì da ilẹ̀ Íjíbítì bora, gan-an gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́ àgùntàn ti ń da ẹ̀wù ara rẹ̀ bora,+ ní tòótọ́ yóò sì jáde kúrò níbẹ̀ ní àlàáfíà. 13  Dájúdájú, òun yóò sì fọ́ àwọn ọwọ̀n Bẹti-ṣémẹ́ṣì sí wẹ́wẹ́, èyí tí ó wà ní ilẹ̀ Íjíbítì; ilé àwọn ọlọ́run Íjíbítì ni òun yóò sì fi iná sun.”’”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé