Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Jeremáyà 42:1-22

42  Nígbà náà ni gbogbo olórí ẹgbẹ́ ológun àti Jóhánánì+ ọmọkùnrin Káréà àti Jesanáyà+ ọmọkùnrin Hóṣáyà+ àti gbogbo ènìyàn náà, láti orí ẹni tí ó kéré jù lọ àní dé orí ẹni tí ó tóbi jù lọ, wá  wọ́n sì wí fún Jeremáyà wòlíì pé: “Jọ̀wọ́, jẹ́ kí ìbéèrè wa fún ojú rere wá síwájú rẹ, sì gbàdúrà nítorí wa sí Jèhófà Ọlọ́run rẹ,+ nítorí gbogbo àṣẹ́kù yìí, nítorí a ti ṣẹ́ wa kù, ìwọ̀nba nínú ọ̀pọ̀,+ gan-an gẹ́gẹ́ bí ojú rẹ ti rí wa.  Kí Jèhófà Ọlọ́run rẹ sì sọ fún wa, ọ̀nà tí ó yẹ kí a rìn àti ohun tí ó yẹ kí a ṣe.”+  Látàrí ìyẹn, Jeremáyà wòlíì wí fún wọn pé: “Mo ti gbọ́. Kíyè sí i, èmi yóò gbàdúrà sí Jèhófà Ọlọ́run yín gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ yín;+ dájúdájú, yóò sì ṣẹlẹ̀ pé gbogbo ọ̀rọ̀ tí Jèhófà bá fi dá yín lóhùn ni èmi yóò sọ fún yín.+ Èmi kì yóò ṣẹ́ ọ̀rọ̀ kankan kù láìsọ ọ́ fún yín.”+  Àwọn, ní tiwọn, sì wí fún Jeremáyà pé: “Kí Jèhófà jẹ́ ẹlẹ́rìí tòótọ́ àti aṣeégbíyèlé lòdì sí wa+ bí kì í bá ṣe gẹ́gẹ́ bí gbogbo ọ̀rọ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ fi rán ọ sí wa ni àwa yóò ṣe gẹ́lẹ́.+  Yálà ó dára tàbí ó burú, ohùn Jèhófà Ọlọ́run wa, ọ̀dọ̀ ẹni tí a rán ọ lọ, ni àwa yóò ṣègbọràn sí, fún ète pé kí nǹkan lè lọ dáadáa pẹ̀lú wa nítorí pé a ṣègbọràn sí ohùn Jèhófà Ọlọ́run wa.”+  Wàyí o, ó ṣẹlẹ̀ ní òpin ọjọ́ mẹ́wàá pé ọ̀rọ̀ Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí tọ Jeremáyà wá.+  Nítorí náà, ó pe Jóhánánì ọmọkùnrin Káréà àti gbogbo olórí ẹgbẹ́ ológun tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ àti gbogbo àwọn ènìyàn náà láti orí ẹni tí ó kéré jù lọ dé orí ẹni tí ó tóbi jù lọ;+  ó sì ń bá a lọ láti wí fún wọn pé: “Èyí ni ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì, ẹni tí ẹ rán mi sí láti mú kí ìbéèrè yín fún ojú rere wá síwájú rẹ̀,+ wí, 10  ‘Láìkùnà, bí ẹ bá ń bá a nìṣó ní gbígbé ní ilẹ̀ yìí,+ dájúdájú, èmi pẹ̀lú yóò gbé yín ró, èmi kì yóò sì ya yín lulẹ̀, ṣe ni èmi yóò gbìn yín, èmi kì yóò sì fà yín tu;+ nítorí ó dájú pé èmi yóò kẹ́dùn nítorí ìyọnu àjálù tí mo ti fà fún yín.+ 11  Ẹ má fòyà nítorí ọba Bábílónì, ẹni tí ẹ ń bẹ̀rù.’+ “‘Ẹ má fòyà nítorí rẹ̀,’+ ni àsọjáde Jèhófà, ‘nítorí èmi wà pẹ̀lú yín, láti gbà yín là àti láti dá yín nídè kúrò ní ọwọ́ rẹ̀.+ 12  Èmi yóò sì fi àánú fún yín, dájúdájú, òun yóò sì ṣàánú fún yín, yóò sì dá yín padà sí ilẹ̀ yín.+ 13  “‘Ṣùgbọ́n bí ẹ bá ń wí pé: “Rárá; àwa kì yóò gbé ní ilẹ̀ yìí!” láti ṣàìgbọràn sí ohùn Jèhófà Ọlọ́run yín,+ 14  pé: “Rárá, ṣùgbọ́n ilẹ̀ Íjíbítì ni àwa yóò wọ̀ lọ,+ níbi tí àwa kì yóò ti rí ogun, a kì yóò sì gbọ́ ìró ìwo, ebi oúnjẹ kì yóò sì pa wá; ibẹ̀ sì ni àwa yóò máa gbé”;+ 15  nísinsìnyí pàápàá, gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà, ìwọ àṣẹ́kù Júdà. Èyí ni ohun tí Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, wí: “Bí ó bá jẹ́ àforí-àfọrùn ni ẹ gbé ojú yín lé àtiwọ Íjíbítì, tí ẹ sì wọ ibẹ̀ ní tòótọ́ láti máa ṣe àtìpó níbẹ̀,+ 16  yóò sì ṣẹlẹ̀ pé idà náà gan-an tí ẹ ń fòyà rẹ̀ yóò dé bá yín níbẹ̀ ní ilẹ̀ Íjíbítì,+ àti ìyàn náà gan-an èyí tí ń kó jìnnìjìnnì bá yín, yóò sì ti ibẹ̀ máa tọ̀ yín lẹ́yìn pẹ́kípẹ́kí lọ sí Íjíbítì;+ ibẹ̀ sì ni ẹ óò kú sí.+ 17  Yóò sì ṣẹlẹ̀ pé, gbogbo ènìyàn tí ó ti gbé ojú wọn lé àtiwọ Íjíbítì láti máa ṣe àtìpó níbẹ̀ yóò di àwọn tí yóò kú nípa idà, nípa ìyàn àti nípa àjàkálẹ̀ àrùn;+ wọn kì yóò sì wá ní olùlàájá tàbí olùsálà, nítorí ìyọnu àjálù tí èmi yóò mú wá sórí wọn.”’+ 18  “Nítorí èyí ni ohun tí Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí, ‘Gan-an gẹ́gẹ́ bí ìbínú mi àti ìhónú mi ti tú jáde sórí àwọn olùgbé Jerúsálẹ́mù,+ bẹ́ẹ̀ ni ìhónú mi yóò tú jáde sórí yín nítorí wíwọ̀ tí ẹ wọ Íjíbítì, dájúdájú, ẹ ó sì di ègún àti ohun ìyàlẹ́nu àti ìfiré àti ẹ̀gàn,+ ẹ kì yóò sì rí ibí yìí mọ́.’+ 19  “Jèhófà ti sọ̀rọ̀ lòdì sí yín, ẹ̀yin àṣẹ́kù Júdà. Ẹ má wọ Íjíbítì.+ Kí ẹ mọ̀ dájú pé mo ti jẹ́rìí lòdì sí yín lónìí.+ 20  pé ẹ ti gbé ìgbésẹ̀ ìṣìnà lòdì sí ọkàn yín;+ nítorí ẹ̀yin fúnra yín ti rán mi sí Jèhófà Ọlọ́run yín, pé, ‘Gbàdúrà nítorí wa sí Jèhófà Ọlọ́run wa; ní ìbámu pẹ̀lú ohun gbogbo tí Jèhófà Ọlọ́run wa sì sọ, sọ fún wa bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, dájúdájú, àwa yóò sì ṣe bẹ́ẹ̀.’+ 21  Mo sì sọ fún yín lónìí, ṣùgbọ́n ó dájú pé ẹ kì yóò ṣègbọràn sí ohùn Jèhófà Ọlọ́run yín tàbí ohunkóhun tí ó fi rán mi sí yín.+ 22  Wàyí o, kí ẹ mọ̀ dájú pé nípasẹ̀ idà,+ nípasẹ̀ ìyàn àti nípasẹ̀ àjàkálẹ̀ àrùn ni ẹ óò kú ní ibi tí ẹ ní inú dídùn láti wọ̀ lọ ṣe àtìpó.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé