Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Jeremáyà 40:1-16

40  Ọ̀rọ̀ tí ó tọ Jeremáyà wá láti ọ̀dọ̀ Jèhófà lẹ́yìn tí Nebusárádánì+ olórí ẹ̀ṣọ́ rán an láti Rámà,+ nígbà tí ó mú un nígbà tí a fi pawọ́pẹ́ dè é ní àárín gbogbo ìgbèkùn Jerúsálẹ́mù àti ti Júdà, tí a kó lọ ní ìgbèkùn sí Bábílónì.+  Nígbà náà ni olórí ẹ̀ṣọ́ mú Jeremáyà, ó sì wí fún un pé: “Jèhófà Ọlọ́run rẹ tìkára rẹ̀ ni ó sọ ìyọnu àjálù yìí lòdì sí ibí yìí,+  kí Jèhófà lè mú un ṣẹ, kí ó sì ṣe gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ, nítorí pé ẹ tí dẹ́ṣẹ̀ sí Jèhófà, ẹ kò sì ṣègbọràn sí ohùn rẹ̀. Nǹkan yìí sì ti ṣẹlẹ̀ sí yín.+  Wàyí o, wò ó! Mo tú ọ sílẹ̀ lónìí kúrò nínú pawọ́pẹ́ tí ó wà ní ọwọ́ rẹ. Bí ó bá dára ní ojú rẹ láti bá mi lọ sí Bábílónì, ká lọ, èmi yóò sì fi ojú mi sára rẹ.+ Ṣùgbọ́n bí ó bá burú ní ojú rẹ láti bá mi lọ sí Bábílónì, fà sẹ́yìn. Wò ó! Gbogbo ilẹ̀ náà pátá wà níwájú rẹ. Ibikíbi tí ó bá dára tí ó sì tọ̀nà ní ojú rẹ láti lọ, lọ sí ibẹ̀.”+  Síbẹ̀, òun kò tíì fẹ́ padà, nígbà tí Nebusárádánì wí pé: “Padà sọ́dọ̀ Gẹdaláyà+ ọmọkùnrin Áhíkámù+ ọmọkùnrin Ṣáfánì,+ ẹni tí ọba Bábílónì ti fàṣẹ yàn lórí ìlú ńlá Júdà, sì máa gbé pẹ̀lú rẹ̀ ní àárín àwọn ènìyàn náà; tàbí ibikíbi tí ó bá tọ̀nà ní ojú rẹ láti lọ, lọ.”+ Nígbà náà ni olórí ẹ̀ṣọ́ fún un ní oúnjẹ́ tí a yọ̀ǹda àti ẹ̀bùn, ó sì jẹ́ kí ó máa lọ.+  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Jeremáyà wá sọ́dọ̀ Gẹdaláyà+ ọmọkùnrin Áhíkámù ní Mísípà,+ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí gbé pẹ̀lú rẹ̀ ní àárín àwọn ènìyàn tí ó ṣẹ́ kù ní ilẹ̀ náà.  Nígbà tí ó ṣe, gbogbo olórí ẹgbẹ́ ológun tí ó wà ní pápá,+ àwọn àti àwọn ọkùnrin wọn, wá gbọ́ pé ọba Bábílónì ti fàṣẹ yan Gẹdaláyà ọmọkùnrin Áhíkámù lórí ilẹ̀ náà àti pé ó ti fàṣẹ yàn án lórí àwọn ọkùnrin àti àwọn obìnrin àti àwọn ọmọ kéékèèké àti àwọn kan lára àwọn ènìyàn rírẹlẹ̀ ní ilẹ̀ náà, tí a kò tíì kó lọ ní ìgbèkùn sí Bábílónì.+  Nítorí náà, wọ́n wá sọ́dọ̀ Gẹdaláyà ní Mísípà, àní Íṣímáẹ́lì+ ọmọkùnrin Netanáyà àti Jóhánánì+ àti Jónátánì, àwọn ọmọkùnrin Káréà, àti Seráyà ọmọkùnrin Táńhúmétì àti àwọn ọmọkùnrin Éfáì ará Nétófà+ àti Jesanáyà+ ọmọkùnrin ará Máákátì,+ àwọn àti àwọn ènìyàn wọn.+  Gẹdaláyà+ ọmọkùnrin Áhíkámù+ ọmọkùnrin Ṣáfánì+ sì tẹ̀ síwájú láti búra+ fún àwọn àti àwọn ènìyàn wọn, pé: “Ẹ má fòyà láti sin àwọn ará Kálídíà. Ẹ máa bá a lọ láti gbé ní ilẹ̀ yìí, kí ẹ sì máa sin ọba Bábílónì, nǹkan yóò sì lọ dáadáa fún yín.+ 10  Ní tèmi, kíyè sí i, èmi ń gbé ní Mísípà,+ láti lè dúró níwájú àwọn ará Kálídíà tí yóò wá bá wa. Ní ti ẹ̀yin fúnra yín, ẹ kó wáìnì+ jọ àti èso ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn àti òróró, kí ẹ sì fi wọ́n sínú àwọn ohun èlò yín, kí ẹ sì máa gbé nínú àwọn ìlú ńlá yín tí ẹ gbà.” 11  Gbogbo Júù tí ó sì wà ní Móábù àti láàárín àwọn ọmọ Ámónì àti ní Édómù àti àwọn tí wọ́n wà ní gbogbo ilẹ̀ yòókù,+ àwọn pẹ̀lú gbọ́ pé ọba Bábílónì ti fi àṣẹ́kù sílẹ̀ fún Júdà àti pé ó ti fàṣẹ yan Gẹdaláyà+ ọmọkùnrin Áhíkámù ọmọkùnrin Ṣáfánì lé wọn lórí. 12  Gbogbo Júù sì bẹ̀rẹ̀ sí padà bọ̀ láti gbogbo ibi tí a fọ́n wọn ká sí, wọ́n sì ń bá a lọ láti wá sí ilẹ̀ Júdà sọ́dọ̀ Gẹdaláyà ní Mísípà.+ Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí kó wáìnì àti èso ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn jọ ní ìwọ̀n púpọ̀ rẹpẹtẹ. 13  Ní ti Jóhánánì+ ọmọkùnrin Káréà+ àti gbogbo olórí ẹgbẹ́ ológun tí ó wà ní pápá,+ wọ́n wá sọ́dọ̀ Gẹdaláyà ní Mísípà. 14  Wọ́n sì tẹ̀ síwájú láti wí fún un pé: “Ìwọ kò ha mọ̀ rárá pé Báálísì, ọba àwọn ọmọ Ámónì,+ fúnra rẹ̀ ti rán Íṣímáẹ́lì+ ọmọkùnrin Netanáyà+ láti kọlu ọkàn rẹ lọ́nà tí ó lè yọrí sí ikú?” Ṣùgbọ́n Gẹdaláyà ọmọkùnrin Áhíkámù kò gbà wọ́n gbọ́.+ 15  Jóhánánì+ ọmọkùnrin Káréà fúnra rẹ̀ sì wí fún Gẹdaláyà, ní ibi ìlùmọ́ ní Mísípà pé: “Mo fẹ́ láti lọ, nísinsìnyí, kí èmi sì ṣá Íṣímáẹ́lì ọmọkùnrin Netanáyà balẹ̀, níwọ̀n bí kò ti sí ẹnì kankan tí yóò mọ̀.+ Èé ṣe tí òun yóò fi kọlu ọkàn rẹ lọ́nà tí ó lè yọrí sí ikú, èé sì ti ṣe tí gbogbo àwọn ti Júdà tí a ń kó pa pọ̀ sọ́dọ̀ rẹ yóò fi tú ká tí àṣẹ́kù Júdà yóò sì fi ṣègbé?”+ 16  Ṣùgbọ́n Gẹdaláyà+ ọmọkùnrin Áhíkámù+ sọ fún Jóhánánì ọmọkùnrin Káréà pé: “Má ṣe nǹkan yìí, nítorí èké ni ìwọ ń sọ nípa Íṣímáẹ́lì.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé