Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Jeremáyà 4:1-31

4  “Bí ìwọ yóò bá padà, Ísírẹ́lì,” ni àsọjáde Jèhófà, “o lè padà àní sọ́dọ̀ mi.+ Bí ìwọ yóò bá sì mú àwọn ohun ìríra rẹ kúrò ní tìtorí tèmi,+ nígbà náà, ìwọ kì yóò lọ gẹ́gẹ́ bí ìsáǹsá.  Dájúdájú, bí ìwọ yóò bá sì búra+ pé, ‘Bí Jèhófà ti ń bẹ láàyè ní òtítọ́,+ ní ìdájọ́ òdodo àti ní òdodo!’+ nígbà náà, nínú rẹ̀ ni àwọn orílẹ̀-èdè yóò ti bù kún ara wọn ní ti tòótọ́, nínú rẹ̀ sì ni wọn yóò ti máa ṣògo nípa ara wọn.”+  Nítorí pé èyí ni ohun tí Jèhófà wí fún àwọn ọkùnrin Júdà àti fún Jerúsálẹ́mù: “Ẹ tú ilẹ̀ adárafọ́gbìn fún ara yín, ẹ má sì máa fúnrúgbìn sáàárín ẹ̀gún.+  Ẹ dá ara yín ládọ̀dọ́ fún Jèhófà, kí ẹ sì gé adọ̀dọ́ ọkàn-àyà yín kúrò,+ ẹ̀yin ọkùnrin Júdà àti ẹ̀yin olùgbé Jerúsálẹ́mù; kí ìhónú mi má bàa jáde lọ bí iná, kí ó sì jó dájúdájú, tí kò ní sí ẹni tí yóò pa á, ní tìtorí búburú ìbálò yín.”+  Ẹ sọ ọ́ ní Júdà, ẹ sì kéde rẹ̀ fáyé gbọ́ àní ní Jerúsálẹ́mù,+ ẹ sọ ọ́ jáde, ẹ sì fun ìwo jákèjádò ilẹ̀ náà.+ Ẹ ké jáde kíkankíkan, kí ẹ sì wí pé: “Ẹ kó ara yín jọpọ̀, ẹ sì jẹ́ kí a wọnú àwọn ìlú ńlá olódi.+  Ẹ gbé àmì àfiyèsí sókè síhà Síónì. Ẹ ṣe ìpèsè fún ibi ààbò. Ẹ má ṣe dúró bọrọgidi.” Nítorí ìyọnu àjálù kan wà tí mo ń mú bọ̀ láti àríwá,+ àní ìfọ́yángá ńláǹlà.  Ó ti gòkè lọ bí kìnnìún láti inú ìgbòrò rẹ̀,+ ẹni tí ó sì ń run àwọn orílẹ̀-èdè ti ṣí kúrò;+ ó ti jáde lọ kúrò ní àyè rẹ̀ láti sọ ilẹ̀ rẹ di ohun ìyàlẹ́nu. Àwọn ìlú ńlá rẹ yóò di àwókù tí kì yóò fi ní olùgbé kankan mọ́.+  Ní tìtorí èyí, ẹ sán aṣọ àpò ìdọ̀họ.+ Ẹ lu igẹ̀ yín kí ẹ sì hu,+ nítorí ìbínú jíjófòfò Jèhófà kò tíì yí padà kúrò lórí wa.+  “Yóò sì ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ náà,” ni àsọjáde Jèhófà, “pé ọkàn-àyà ọba yóò ṣègbé,+ bákan náà ni ọkàn-àyà àwọn ọmọ aládé; dájúdájú, a ó sì jẹ́ kí ìyàlẹ́nu bá àwọn àlùfáà, àwọn wòlíì pàápàá yóò sì ṣe kàyéfì.”+ 10  Mo sì tẹ̀ síwájú láti sọ pé: “Págà, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ! Lóòótọ́, o ti tan àwọn ènìyàn yìí+ àti Jerúsálẹ́mù jẹ pátápátá, ní sísọ pé, ‘Àlàáfíà gan-an yóò di tiyín,’+ idà sì ti lọ títí dé ọkàn.” 11  Ní ìgbà yẹn, a ó sọ fún àwọn ènìyàn yìí àti fún Jerúsálẹ́mù pé: “Ẹ̀fúùfù ajó-nǹkan-gbẹ kan ń bẹ tí í ṣe ti àwọn ipa ọ̀nà àrìnkúnná tí ó gba aginjù+ kọjá lójú ọ̀nà tí ó lọ sọ́dọ̀ ọmọbìnrin àwọn ènìyàn mi;+ kì í ṣe fún fífẹ́ nǹkan tàbí fún fífọ nǹkan mọ́. 12  Ẹ̀fúùfù tí ó lágbára fẹ́ wá, àní láti inú ìwọ̀nyí sọ́dọ̀ mi. Nísinsìnyí, èmi fúnra mi pẹ̀lú yóò bá wọn sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìdájọ́ náà.+ 13  Wò ó! Bí àwọsánmà òjò ni yóò gòkè wá, àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀ sì dà bí ẹ̀fúùfù oníjì.+ Àwọn ẹṣin rẹ̀ yára ju idì lọ.+ Ègbé ni fún wa, nítorí pé a ti fi wá ṣe ìjẹ! 14  Wẹ ìwà búburú gbáà mọ́ kúrò nínú ọkàn-àyà rẹ, ìwọ Jerúsálẹ́mù, kí a lè gbà ọ́ là.+ Yóò ti pẹ́ tó tí àwọn ìrònú ìṣìnà rẹ yóò fi máa wà nínú rẹ?+ 15  Nítorí ohùn kan ń sọ̀rọ̀ láti Dánì,+ ó sì ń kéde ohun aṣenilọ́ṣẹ́ fáyé gbọ́ láti ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá Éfúráímù.+ 16  Ẹ mẹ́nu kàn án, bẹ́ẹ̀ ni, fún àwọn orílẹ̀-èdè. Ẹ kéde rẹ̀ fáyé gbọ́ ní ìlòdìsí Jerúsálẹ́mù.” “Àwọn olùṣọ́ ń bọ̀ láti ilẹ̀ jíjìnnàréré,+ wọn yóò sì fi ohùn wọn ké jáde lòdì sí àwọn ìlú ńlá Júdà gan-an. 17  Bí àwọn ẹ̀ṣọ́ pápá gbalasa ni wọ́n rí sí i láti ìhà gbogbo,+ nítorí pé ó ti ṣọ̀tẹ̀ àní sí èmi,”+ ni àsọjáde Jèhófà. 18  “Ọ̀nà rẹ àti ìbálò rẹ—sísan ìwọ̀nyí fún ọ yóò wà.+ Èyí ni ìyọnu àjálù tí yóò já lù ọ́, nítorí ó korò; nítorí ó ti lọ títí dé ọkàn-àyà rẹ.” 19  Ìwọ ìfun mi, ìfun mi! Mo wà nínú ìrora mímúná nínú ògiri ọkàn-àyà mi.+ Ọkàn-àyà mi ń ru gùdù nínú mi.+ Èmi kò lè dákẹ́, nítorí ìró ìwo ni ohun tí ọkàn mi gbọ́, àmì àfiyèsí oníròó ìdágìrì ogun.+ 20  Ìfọ́yángá lórí ìfọ́yángá ni ohun tí a ké jáde, nítorí gbogbo ilẹ̀ náà ni a ti fi ṣe ìjẹ.+ Lójijì, a ti fi àgọ́ mi ṣe ìjẹ,+ ní ìṣẹ́jú kan, aṣọ àgọ́ mi. 21  Yóò ti pẹ́ tó tí èmi yóò máa rí àmì àfiyèsí, tí èmi yóò máa gbọ́ ìró ìwo?+ 22  Nítorí òmùgọ̀ ni àwọn ènìyàn mi.+ Wọn kò fiyè sí mi.+ Aláìlọ́gbọ́n ọmọ ni wọ́n; wọn kì í sì í ṣe olóye.+ Ọlọ́gbọ́n ni wọ́n nínú ṣíṣe búburú, ṣùgbọ́n nínú ṣíṣe rere, dájúdájú, wọn kò ní ìmọ̀.+ 23  Mo rí ilẹ̀ náà, sì wò ó! ó ṣófo,+ ó sì ṣòfò; àti sí ọ̀run, ìmọ́lẹ̀ wọn kò sì sí mọ́.+ 24  Mo rí àwọn òkè ńlá, sì wò ó! wọ́n ń mì jìgìjìgì, gbogbo òkè kéékèèké pàápàá ni a sì mì.+ 25  Mo rí, sì wò ó! ará ayé kankan kò sí, gbogbo ẹ̀dá tí ń fò ní ojú ọ̀run sì ti fò lọ.+ 26  Mo rí, sì wò ó! ọgbà igi eléso pàápàá jẹ́ aginjù, gbogbo ìlú ńlá rẹ̀ gan-an ni a sì ti ya lulẹ̀.+ Nítorí Jèhófà ni, nítorí ìbínú rẹ̀ jíjófòfò ni. 27  Nítorí pé èyí ni ohun tí Jèhófà wí: “Ahoro ni gbogbo ilẹ̀ náà yóò dà,+ èmi kò ha sì ní mú kìkìdá ìparun pátápátá ṣẹ bí?+ 28  Ní tìtorí èyí, ilẹ̀ náà yóò ṣọ̀fọ̀,+ ọ̀run lókè yóò sì ṣókùnkùn dájúdájú.+ Nítorí pé mo ti sọ̀rọ̀, mo ti rò ó, èmi kò sì pèrò dà, bẹ́ẹ̀ sì ni èmi kì yóò yí padà kúrò nínú rẹ̀.+ 29  Nítorí ìró àwọn ẹlẹ́ṣin àti àwọn olùta ọrun, gbogbo ìlú ńlá náà pátá fẹsẹ̀ fẹ.+ Wọ́n ti wọnú ìgbòrò, wọ́n sì ti gòkè lọ sórí àwọn àpáta.+ Gbogbo ìlú ńlá ni a fi sílẹ̀, kò sì sí ènìyàn kankan tí ń gbé inú wọn.” 30  Nísinsìnyí tí a ti fi ọ́ ṣe ìjẹ, kí ni ìwọ yóò ṣe, níwọ̀n bí o ti máa ń fi aṣọ rírẹ̀dòdò wọ ara rẹ tẹ́lẹ̀, níwọ̀n bí o ti máa ń fi ohun ọ̀ṣọ́ wúrà ṣe ara rẹ lọ́ṣọ̀ọ́, níwọ̀n bí o ti máa ń fi tìróò sọ ojú rẹ di títóbi?+ Lásán ni o ń mú ara rẹ lẹ́wà ní ìrísí.+ Àwọn tí wọ́n ní ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ sí ọ ti pa ọ́ tì; wọ́n ń wá ọkàn rẹ gan-an.+ 31  Nítorí mo gbọ́ ohùn kan bí ti obìnrin aláìsàn, wàhálà bí ti obìnrin tí ń bí àkọ́bí rẹ̀ lọ́wọ́,+ ohùn ọmọbìnrin Síónì tí ń mí gúlegúle. Ó ń tẹ́ àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀ ṣáá pé:+ “Wàyí o, Mo gbé, nítorí pé ọ̀ràn àwọn olùpani ti sú ọkàn mi!”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé