Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Jeremáyà 39:1-18

39  Ní ọdún kẹsàn-án Sedekáyà ọba Júdà, ní oṣù kẹwàá,+ Nebukadirésárì ọba Bábílónì àti gbogbo ẹgbẹ́ ológun rẹ̀ wá sí Jerúsálẹ́mù, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí sàga tì í.+  Ní ọdún kọkànlá Sedekáyà, ní oṣù kẹrin, ní ọjọ́ kẹsàn-án oṣù náà, wọ́n ya wọ inú ìlú ńlá náà.+  Gbogbo ọmọ aládé ọba Bábílónì sì bẹ̀rẹ̀ sí wọlé, wọ́n sì jókòó ní Ẹnubodè Àárín,+ àwọn yìí ni, Nẹgali-ṣárésà, Samugari-nébò, Sásékímù, Rábúsárísì, Nẹgali-ṣárésà tí í ṣe Rábúmágì àti gbogbo ìyókù àwọn ọmọ aládé ọba Bábílónì.  Wàyí o, ó ṣẹlẹ̀ pé, gbàrà tí Sedekáyà ọba Júdà àti gbogbo ọkùnrin ogun rí wọ́n, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí fẹsẹ̀ fẹ,+ wọ́n sì jáde kúrò nínú ìlú ńlá náà ní òru gba ti ọ̀nà ọgbà ọba,+ gba ẹnubodè tí ó wà láàárín ògiri onílọ̀ọ́po-méjì; wọ́n sì ń gba ti ọ̀nà Árábà+ jáde.  Ẹgbẹ́ ológun àwọn ará Kálídíà sì ń lépa wọn lọ,+ wọ́n sì lé Sedekáyà bá ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ aṣálẹ̀ ti Jẹ́ríkò.+ Nígbà náà ni wọ́n mú un, wọ́n sì mú un gòkè wá sọ́dọ̀ Nebukadirésárì ọba Bábílónì ní Ríbúlà+ ní ilẹ̀ Hámátì+ kí ó lè kéde àwọn ìpinnu ìdájọ́ sórí rẹ̀.+  Ọba Bábílónì sì tẹ̀ síwájú láti pa+ àwọn ọmọ Sedekáyà ní Ríbúlà lójú rẹ̀,+ gbogbo ọ̀tọ̀kùlú Júdà sì ni ọba Bábílónì pa.+  Ó sì fọ́ ojú Sedekáyà,+ lẹ́yìn èyí tí ó fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ bàbà dè é, láti mú un wá sí Bábílónì.  Ilé ọba àti ilé àwọn ènìyàn náà sì ni àwọn ará Kálídíà fi iná sun,+ wọ́n sì bi àwọn ògiri Jerúsálẹ́mù wó.+  Ìyókù àwọn ènìyàn tí ó sì ṣẹ́ kù nínú ìlú ńlá náà, àti àwọn olùyapa tí ó ya lọ sọ́dọ̀ rẹ̀, àti ìyókù àwọn ènìyàn tí ó ṣẹ́ kù ni Nebusárádánì+ olórí ẹ̀ṣọ́+ kó lọ ní ìgbèkùn sí Bábílónì.+ 10  Nebusárádánì olórí ẹ̀ṣọ́ sì jẹ́ kí àwọn kan lára àwọn ènìyàn náà, àwọn ẹni rírẹlẹ̀, tí kò ní nǹkan kan, ṣẹ́ kù ní ilẹ̀ Júdà;+ ó sì wá fún wọn ní ọgbà àjàrà àti iṣẹ́ ìsìn àpàpàǹdodo ní ọjọ́ náà.+ 11  Síwájú sí i, Nebukadirésárì ọba Bábílónì pàṣẹ ní ti Jeremáyà nípasẹ̀ Nebusárádánì olórí ẹ̀ṣọ́, pé: 12  “Mú un, kí o sì fojú sí i lára, má sì ṣe nǹkan kan tí ó burú sí i rárá.+ Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí òun bá ṣe wí fún ọ, bẹ́ẹ̀ ni kí o ṣe fún un.”+ 13  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Nebusárádánì+ olórí ẹ̀ṣọ́ àti Nebuṣásíbánì tí í ṣe Rábúsárísì, àti Nẹgali-ṣárésà tí í ṣe Rábúmágì àti gbogbo ènìyàn sàràkí-sàràkí ti ọba Bábílónì ránṣẹ́; 14  àní wọ́n tẹ̀ síwájú láti ránṣẹ́, wọ́n sì mú Jeremáyà jáde kúrò ní Àgbàlá Ẹ̀ṣọ́,+ wọ́n sì fi í lé Gẹdaláyà+ ọmọkùnrin Áhíkámù+ ọmọkùnrin Ṣáfánì+ lọ́wọ́, láti mú un wá sí ilé rẹ̀, kí ó lè máa gbé ní àárín àwọn ènìyàn náà. 15  Ọ̀rọ̀ Jèhófà sì tọ Jeremáyà wá nígbà tí a sé e mọ́ Àgbàlá Ẹ̀ṣọ́,+ pé: 16  “Lọ, kí o sì wí fún Ebedi-mélékì+ ará Etiópíà pé, ‘Èyí ni ohun tí Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, wí: “Kíyè sí i, èmi yóò mú ọ̀rọ̀ mi ṣẹ sórí ìlú ńlá yìí ní ti ìyọnu àjálù kì í sì í ṣe fún rere,+ dájúdájú, yóò sì ṣẹlẹ̀ ní ìṣojú rẹ ní ọjọ́ yẹn.”’+ 17  “‘Ṣe ni èmi yóò sì dá ọ nídè ní ọjọ́ yẹn,’+ ni àsọjáde Jèhófà, ‘a kì yóò sì fi ọ́ lé àwọn ènìyàn tí ìwọ ń fòyà wọn lọ́wọ́.’+ 18  “‘Nítorí, láìkùnà, èmi yóò pèsè àsálà fún ọ, ìwọ kì yóò sì tipa idà ṣubú; dájúdájú, ìwọ yóò sì ni ọkàn rẹ bí ohun ìfiṣèjẹ,+ nítorí pé o ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú mi,’+ ni àsọjáde Jèhófà.”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé