Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Jeremáyà 38:1-28

38  Ṣẹfatáyà ọmọkùnrin Mátánì àti Gẹdaláyà ọmọkùnrin Páṣúrì àti Júkálì+ ọmọkùnrin Ṣelemáyà àti Páṣúrì ọmọkùnrin Málíkíjà+ sì wá gbọ́ ọ̀rọ̀ tí Jeremáyà ń sọ fún gbogbo àwọn ènìyàn náà,+ pé:  “Èyí ni ohun tí Jèhófà wí, ‘Ẹni tí ó bá ń bá a lọ ní gbígbé inú ìlú ńlá yìí ni ẹni tí yóò tipa idà,+ ìyàn+ àti àjàkálẹ̀ àrùn kú.+ Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá jáde lọ sọ́dọ̀ àwọn ará Kálídíà ni ẹni tí yóò máa wà láàyè nìṣó tí yóò sì ni ọkàn rẹ̀ dájúdájú bí ohun ìfiṣèjẹ, tí yóò sì wà láàyè.’+  Èyí ni ohun tí Jèhófà wí, ‘Láìkùnà, a ó fi ìlú ńlá yìí lé ẹgbẹ́ ológun ọba Bábílónì lọ́wọ́, dájúdájú, òun yóò sì gbà á.’”+  Àwọn ọmọ aládé sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún ọba pé: “Jọ̀wọ́, jẹ́ kí a fi ikú pa ọkùnrin yìí,+ nítorí bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe ń sọ ọwọ́ àwọn ọkùnrin ogun tí wọ́n ṣẹ́ kù nínú ìlú ńlá yìí àti ọwọ́ gbogbo ènìyàn di aláìlera, nípa sísọ irú ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fún wọn.+ Nítorí ọkùnrin yìí kì í ṣe ẹni tí ń wá àlàáfíà àwọn ènìyàn yìí bí kò ṣe ìyọnu àjálù wọn.”  Nítorí náà, Sedekáyà Ọba wí pé: “Wò ó! Ó wà ní ọwọ́ yín. Nítorí kò sí nǹkan kan rárá nínú èyí tí ọba ti lè borí yín.”+  Wọ́n sì tẹ̀ síwájú láti mú Jeremáyà, wọ́n sì sọ ọ́ sínú ìkùdu Málíkíjà+ ọmọkùnrin ọba, èyí tí ó wà ní Àgbàlá Ẹ̀ṣọ́.+ Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n fi ìjàrá rọ Jeremáyà sísàlẹ̀. Wàyí o, nínú ìkùdu náà, kò sí omi, bí kò ṣe ẹrẹ̀; Jeremáyà sì bẹ̀rẹ̀ sí rì sínú ẹrẹ̀ náà.+  Ebedi-mélékì ará Etiópíà,+ ọkùnrin kan tí ó jẹ́ ìwẹ̀fà, tí ó sì wà ní ilé ọba, wá gbọ́ pé wọ́n ti fi Jeremáyà sínú ìkùdu; ọba sì jókòó sí Ẹnubodè Bẹ́ńjámínì.+  Nítorí náà, Ebedi-mélékì jáde kúrò ní ilé ọba, ó sì sọ fún ọba, pé:  “Olúwa mi ọba, àwọn ọkùnrin yìí ti ṣe ohun búburú nínú gbogbo ohun tí wọ́n ṣe sí Jeremáyà wòlíì, ẹni tí wọ́n sọ sínú ìkùdu,+ kí ó bàa lè kú sí ibi tí ó wà nítorí ìyàn náà.+ Nítorí kò sí búrẹ́dì mọ́ ní ìlú ńlá yìí.” 10  Nígbà náà ni ọba pàṣẹ fún Ebedi-mélékì ará Etiópíà, pé: “Mú ọgbọ̀n ọkùnrin sábẹ́ àbójútó rẹ láti ibí yìí, kí o sì gbé Jeremáyà wòlíì gòkè láti inú ìkùdu náà kí ó tó kú.”+ 11  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Ebedi-mélékì mú àwọn ọkùnrin tí wọ́n wà lábẹ́ àbójútó rẹ̀, ó sì wọnú ilé ọba sí ìsàlẹ̀ ibi ìṣúra,+ ó sì mú àwọn àkísà gbígbó àti àwọn ègé aṣọ gbígbó níbẹ̀, ó sì fi ìjàrá náà rọ̀ wọ́n sísàlẹ̀ sí Jeremáyà nínú ìkùdu náà.+ 12  Nígbà náà ni Ebedi-mélékì ará Etiópíà sọ fún Jeremáyà pé: “Jọ̀wọ́, fi àwọn àkísà gbígbó náà àti àwọn ègé aṣọ náà sáàárín abíyá rẹ àti ìjàrá náà.” Wàyí o, Jeremáyà ṣe bẹ́ẹ̀.+ 13  Níkẹyìn, wọ́n fi ìjàrá náà fa Jeremáyà jáde, wọ́n sì gbé e gòkè wá láti inú ìkùdu náà. Jeremáyà sì ń bá a lọ láti máa gbé nínú Àgbàlá Ẹ̀ṣọ́.+ 14  Sedekáyà Ọba sì bẹ̀rẹ̀ sí ránṣẹ́, ó sì mú Jeremáyà wòlíì wá sọ́dọ̀ ara rẹ̀+ ní ọ̀nà àbáwọlé kẹta,+ èyí tí ó wà ní ilé Jèhófà,+ nígbà náà ni ọba wí fún Jeremáyà pé: “Èmi ń béèrè ohun kan lọ́wọ́ rẹ. Má fi ohunkóhun pa mọ́ fún mi.”+ 15  Látàrí èyí, Jeremáyà wí fún Sedekáyà pé: “Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé mo sọ fún ọ, ìwọ kì yóò ha fi ikú pa mí láìkùnà? Bí ó bá sì ṣẹlẹ̀ pé mo fún ọ ní àmọ̀ràn, ìwọ kì yóò fetí sí mi.”+ 16  Látàrí ìyẹn, Sedekáyà Ọba búra fún Jeremáyà ní ibi ìlùmọ́, pé: “Bí Jèhófà ti ń bẹ láàyè, ẹni tí ó ṣe ọkàn yìí fún wa,+ èmi kì yóò fi ikú pa ọ́, èmi kì yóò sì fi ọ́ lé àwọn ènìyàn yìí tí ń wá ọkàn rẹ lọ́wọ́.”+ 17  Wàyí o, Jeremáyà wí fún Sedekáyà pé: “Èyí ni ohun tí Jèhófà, Ọlọ́run àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun,+ Ọlọ́run Ísírẹ́lì+ wí, ‘Láìkùnà, bí ìwọ bá jáde lọ sọ́dọ̀ àwọn ọmọ aládé ọba Bábílónì,+ dájúdájú, ọkàn rẹ yóò máa wà láàyè nìṣó, ìlú ńlá yìí ni a kì yóò sì fi iná sun, dájúdájú, ìwọ fúnra rẹ àti agbo ilé rẹ yóò sì máa wà láàyè nìṣó.+ 18  Ṣùgbọ́n bí ìwọ kò bá jáde lọ sọ́dọ̀ àwọn ọmọ aládé ọba Bábílónì, ìlú ńlá yìí pẹ̀lú ni a ó fi lé àwọn ará Kálídíà lọ́wọ́, dájúdájú, wọn yóò sì fi iná sun ún,+ ìwọ fúnra rẹ kì yóò sì sá àsálà kúrò ní ọwọ́ wọn.’”+ 19  Nígbà náà ni Sedekáyà Ọba wí fún Jeremáyà pé: “Jìnnìjìnnì àwọn Júù tí ó ti ya lọ sọ́dọ̀ àwọn ará Kálídíà bá mi,+ kí ó má bàa di pé wọ́n fi mi lé ọwọ́ wọn, kí wọ́n sì hùwà ìkà sí mi ní ti gidi.”+ 20  Ṣùgbọ́n Jeremáyà wí pé: “Wọn kì yóò ṣe irú ìfifúnni bẹ́ẹ̀. Jọ̀wọ́, ṣègbọràn sí ohùn Jèhófà nínú ohun tí mo ń sọ fún ọ, nǹkan yóò lọ dáadáa fún ọ,+ ọkàn rẹ yóò sì máa wà láàyè nìṣó. 21  Ṣùgbọ́n bí o bá kọ̀ láti jáde lọ,+ èyí ni ohun tí Jèhófà ti jẹ́ kí èmi rí: 22  Sì wò ó! gbogbo obìnrin tí ó ṣẹ́ kù sí ilé ọba Júdà+ ni a mú jáde wá sọ́dọ̀ àwọn ọmọ aládé ọba Bábílónì,+ wọ́n sì ń wí pé, ‘Àwọn ọkùnrin tí ó wà ní àlàáfíà pẹ̀lú rẹ ti dẹ ọ́ lọ,+ wọ́n sì ti borí rẹ.+ Wọ́n ti mú kí ẹsẹ̀ rẹ rì sínú ẹrọ̀fọ̀; wọ́n ti sá padà gba òdì-kejì.’+ 23  Gbogbo àwọn aya rẹ àti àwọn ọmọ rẹ ni wọn yóò sì mú jáde wá fún àwọn ará Kálídíà, ìwọ alára kì yóò sì sá àsálà kúrò ní ọwọ́ wọn,+ ṣùgbọ́n ọwọ́ ọba Bábílónì yóò gbá ọ mú, àti nítorí rẹ, ìlú ńlá yìí ni a ó fi iná sun.”+ 24  Sedekáyà sì tẹ̀ síwájú láti wí fún Jeremáyà pé: “Kí ẹnì kankan má ṣe mọ̀ nípa nǹkan wọ̀nyí, kí ìwọ má bàa kú. 25  Bí ó bá sì ṣẹlẹ̀ pé àwọn ọmọ aládé+ gbọ́ pé mo ti bá ọ sọ̀rọ̀, tí wọ́n sì wọlé wá bá ọ ní ti gidi, tí wọ́n sì wí fún ọ pé, ‘Jọ̀wọ́, sọ fún wa, Kí ni o bá ọba sọ? Má fi ohunkóhun pa mọ́ fún wa, àwa kì yóò sì fi ikú pa ọ́. Kí sì ni ohun tí ọba bá ọ sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀?’ 26  kí ìwọ wí fún wọn pẹ̀lú pé, ‘Ṣe ni mo ń jẹ́ kí ìbéèrè mi fún ojú rere wá síwájú ọba, kí ó má bàa dá mi padà sí ilé Jèhónátánì+ láti kú sí ibẹ̀.’” 27  Nígbà tí ó ṣe, gbogbo àwọn ọmọ aládé wọlé tọ Jeremáyà wá, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí béèrè ìbéèrè lọ́wọ́ rẹ̀. Ẹ̀wẹ̀, ó sọ fún wọn gẹ́gẹ́ bí gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí tí ọba ti pàṣẹ fún un.+ Nítorí náà, wọ́n dákẹ́ jẹ́ẹ́ níwájú rẹ̀, nítorí wọn kò gbọ́ ọ̀ràn náà. 28  Jeremáyà sì ń bá a lọ láti máa gbé ní Àgbàlá Ẹ̀ṣọ́+ títí di ọjọ́ tí a gba Jerúsálẹ́mù.+ Ó sì ṣẹlẹ̀ gẹ́lẹ́ nígbà tí a gba Jerúsálẹ́mù.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé