Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Jeremáyà 37:1-21

37  Sedekáyà+ Ọba tí í ṣe ọmọkùnrin Jòsáyà+ sì bẹ̀rẹ̀ sí jọba ní ipò Konáyà+ ọmọkùnrin Jèhóákímù,+ ẹni tí Nebukadirésárì ọba Bábílónì fi jẹ ọba ní ilẹ̀ Júdà.+  Òun fúnra rẹ̀ àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ àti àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà kò sì fetí sí ọ̀rọ̀ Jèhófà+ tí ó sọ nípasẹ̀ Jeremáyà wòlíì.+  Sedekáyà Ọba sì rán Jéhúkálì+ ọmọkùnrin Ṣelemáyà àti Sefanáyà+ ọmọkùnrin Maaseáyà+ àlùfáà sí Jeremáyà wòlíì, pé: “Jọ̀wọ́, gbàdúrà nítorí wa sí Jèhófà Ọlọ́run wa.”+  Jeremáyà sì ń wọlé, ó sì ń jáde lọ ní àárín àwọn ènìyàn náà,+ níwọ̀n bí wọn kò tíì fi í sí àtìmọ́lé.  Ẹgbẹ́ ológun kan tí ó jẹ́ ti Fáráò sì jáde wá láti Íjíbítì;+ àwọn ará Kálídíà tí ó sàga ti Jerúsálẹ́mù sì wá gbọ́ ìròyìn nípa wọn. Nítorí náà, wọ́n fà sẹ́yìn kúrò ní Jerúsálẹ́mù.+  Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Jèhófà tọ Jeremáyà wòlíì wá, pé:  “Èyí ni ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí, ‘Èyí ni ohun tí ẹ óò wí fún ọba Júdà, ẹni tí ó rán yín sí mi láti wádìí lọ́dọ̀ mi:+ “Wò ó! Ẹgbẹ́ ológun Fáráò tí ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ yín fún ète láti pèsè ìrànwọ́ yóò ní láti padà lọ sí ilẹ̀ wọn, Íjíbítì.+  Dájúdájú, àwọn ará Kálídíà yóò sì padà wá, wọn yóò sì bá ìlú ńlá yìí jà, wọn yóò gbà á, wọn yóò sì fi iná sun ún.”+  Èyí ni ohun tí Jèhófà wí: “Ẹ má tan ọkàn yín jẹ,+ pé, ‘Láìkùnà, àwọn ará Kálídíà yóò lọ kúrò lọ́dọ̀ wa,’ nítorí pé wọn kì yóò lọ. 10  Nítorí bí ẹ bá ṣá gbogbo ẹgbẹ́ ológun àwọn ará Kálídíà tí ń bá yín jà balẹ̀,+ tí àwọn ọkùnrin tí a gún ní àgúnyọ sì ṣẹ́ kù lára wọn,+ olúkúlùkù wọn yóò dìde nínú àgọ́ rẹ̀, wọn yóò sì fi iná sun ìlú ńlá yìí ní ti gidi.”’” 11  Ó sì ṣẹlẹ̀ nígbà tí ẹgbẹ́ ológun àwọn ará Kálídíà fà sẹ́yìn kúrò ní Jerúsálẹ́mù+ nítorí ẹgbẹ́ ológun Fáráò,+ 12  pé Jeremáyà bẹ̀rẹ̀ sí jáde ní Jerúsálẹ́mù láti lọ sí ilẹ̀ Bẹ́ńjámínì+ láti gba ìpín rẹ̀ níbẹ̀ ní àárín àwọn ènìyàn náà. 13  Ó sì ṣẹlẹ̀ nígbà tí ó wà ní Ẹnubodè Bẹ́ńjámínì+ pé onípò àṣẹ tí ó ní iṣẹ́ àbójútó, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Íríjà ọmọkùnrin Ṣelemáyà ọmọkùnrin Hananáyà, wà níbẹ̀. Lójú-ẹsẹ̀, ó di Jeremáyà wòlíì mú, ó wí pé: “Ọ̀dọ̀ àwọn ará Kálídíà ni ìwọ ń yapa lọ!” 14  Ṣùgbọ́n Jeremáyà wí pé: “Èké ni!+ Èmi kò yapa lọ sọ́dọ̀ àwọn ará Kálídíà.” Ṣùgbọ́n kò fetí sí i. Bẹ́ẹ̀ ni Íríjà di Jeremáyà mú, ó sì mú un wá sọ́dọ̀ àwọn ọmọ aládé. 15  Ìkannú àwọn ọmọ aládé+ sì bẹ̀rẹ̀ sí ru sí Jeremáyà,+ wọ́n sì gbá a,+ wọ́n sì fi í sínú ilé ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀,+ nínú ilé Jèhónátánì+ akọ̀wé, nítorí èyí ni wọ́n fi ṣe àtìmọ́lé.+ 16  Nígbà tí Jeremáyà dé sínú ilé ìkùdu+ àti sínú yàrá abẹ́ ilẹ̀ náà, Jeremáyà wá ń bá a lọ láti máa gbé ibẹ̀ fún ọjọ́ púpọ̀. 17  Sedekáyà Ọba sì ránṣẹ́, ó sì mú un wá, ọba sì bẹ̀rẹ̀ sí bi í ní àwọn ìbéèrè nínú ilé rẹ̀ ní ibi ìlùmọ́.+ Ó sì ń bá a lọ láti wí pé: “Ọ̀rọ̀ ha wà láti ọ̀dọ̀ Jèhófà?” Jeremáyà sì fèsì pé: “Dájúdájú, ó wà!” Ó sì wí síwájú sí i pé: “Ọwọ́ ọba Bábílónì ni a ó fi ọ́ lé!”+ 18  Nígbà náà ni Jeremáyà sọ fún Sedekáyà Ọba pé: “Ọ̀nà wo ni mo gbà dẹ́ṣẹ̀ sí ọ àti sí àwọn ìránṣẹ́ rẹ àti sí àwọn ènìyàn yìí,+ tí ẹ fi fi mí sínú àtìmọ́lé? 19  Àwọn wòlíì rẹ wá dà báyìí, àwọn tí ó sọ tẹ́lẹ̀ fún ọ, pé, ‘Ọba Bábílónì kì yóò wá gbéjà kò yín, kì yóò sì gbéjà ko ilẹ̀ yìí’?+ 20  Wàyí o, jọ̀wọ́, fetí sílẹ̀, ìwọ olúwa mi ọba. Jọ̀wọ́, jẹ́ kí ìbéèrè mi fún ojú rere+ wá síwájú rẹ, má sì ṣe dá mi padà sí ilé Jèhónátánì+ akọ̀wé, kí èmi má bàa kú sí ibẹ̀.”+ 21  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Sedekáyà Ọba pàṣẹ, wọ́n sì fi Jeremáyà sínú ìhámọ́ ní Àgbàlá Ẹ̀ṣọ́;+ a sì ń fún un ní ìṣù búrẹ́dì ribiti kan lójoojúmọ́ láti ojú pópó àwọn olùṣe búrẹ́dì,+ títí gbogbo búrẹ́dì ìlú ńlá náà fi tán pátápátá.+ Jeremáyà sì ń bá a lọ láti máa gbé ní Àgbàlá Ẹ̀ṣọ́.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé