Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Jeremáyà 36:1-32

36  Wàyí o, ó ṣẹlẹ̀ ní ọdún kẹrin Jèhóákímù+ ọmọkùnrin Jòsáyà, ọba Júdà, pé ọ̀rọ̀ yìí tọ Jeremáyà wá láti ọ̀dọ̀ Jèhófà, pé:  “Mú àkájọ ìwé kan fún ara rẹ,+ kí o sì kọ gbogbo ọ̀rọ̀+ tí mo ti bá ọ sọ lòdì sí Ísírẹ́lì àti lòdì sí Júdà+ àti lòdì sí gbogbo orílẹ̀-èdè,+ láti ọjọ́ tí mo ti bá ọ sọ̀rọ̀, láti ọjọ́ Jòsáyà, títí di òní yìí sínú rẹ̀.+  Bóyá àwọn ará ilé Júdà yóò fetí sí gbogbo ìyọnu àjálù tí mo ń ronú láti mú wá sórí wọn,+ kí olúkúlùkù wọn lè padà ní ọ̀nà búburú rẹ̀,+ kí n lè dárí ìṣìnà wọn àti ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì ní ti gidi.”+  Jeremáyà sì tẹ̀ síwájú láti pe Bárúkù+ ọmọkùnrin Neráyà, kí Bárúkù lè kọ̀wé láti ẹnu Jeremáyà gbogbo ọ̀rọ̀ Jèhófà tí Ó ti sọ fún un, sórí àkájọ ìwé náà.+  Nígbà náà, Jeremáyà pàṣẹ fún Bárúkù, pé: “A ti sé mi mọ́. Èmi kò lè wọ ilé Jèhófà.+  Kí ìwọ fúnra rẹ sì wọ ibẹ̀, kí o sì ka àwọn ọ̀rọ̀ Jèhófà+ láti inú àkájọ tí o ti kọ láti ẹnu mi sókè ní etí àwọn ènìyàn náà ní ilé Jèhófà ní ọjọ́ ààwẹ̀;+ àti pẹ̀lú, kí o kà wọ́n sókè ní etí gbogbo Júdà tí ń wọlé bọ̀ láti àwọn ìlú ńlá wọn.+  Bóyá ìbéèrè wọn fún ojú rere yóò wá síwájú Jèhófà,+ wọn yóò sì padà, olúkúlùkù kúrò ní ọ̀nà búburú rẹ̀,+ nítorí títóbi ni ìbínú àti ìhónú tí Jèhófà ti sọ̀rọ̀ rẹ̀ lòdì sí àwọn ènìyàn yìí.”+  Bárúkù+ ọmọkùnrin Neráyà sì tẹ̀ síwájú láti ṣe gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí Jeremáyà wòlíì ti pa láṣẹ fún un, láti ka àwọn ọ̀rọ̀ Jèhófà láti inú ìwé náà+ sókè ní ilé Jèhófà.+  Wàyí o, ó ṣẹlẹ̀ ní ọdún karùn-ún Jèhóákímù+ ọmọkùnrin Jòsáyà, ọba Júdà, ní oṣù kẹsàn-án,+ pé gbogbo ènìyàn Jerúsálẹ́mù àti gbogbo ènìyàn tí ń wọlé bọ̀ láti àwọn ìlú ńlá Júdà sí Jerúsálẹ́mù pòkìkí ààwẹ̀ níwájú Jèhófà.+ 10  Bárúkù sì bẹ̀rẹ̀ sí ka àwọn ọ̀rọ̀ Jeremáyà sókè láti inú ìwé náà ní ilé Jèhófà, ní yàrá ìjẹun+ Gemaráyà+ ọmọkùnrin Ṣáfánì+ adàwékọ,+ ní àgbàlá òkè, ní ibi àtiwọ ẹnubodè tuntun ti ilé Jèhófà,+ ní etí gbogbo àwọn ènìyàn náà. 11  Mikáyà ọmọkùnrin Gemaráyà ọmọkùnrin Ṣáfánì+ sì wá gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ Jèhófà láti inú ìwé náà. 12  Látàrí ìyẹn, ó sọ̀ kalẹ̀ lọ sí ilé ọba, sí yàrá ìjẹun akọ̀wé, sì wò ó! ibẹ̀ ni gbogbo ọmọ aládé jókòó sí, Élíṣámà+ akọ̀wé àti Deláyà+ ọmọkùnrin Ṣemáyà àti Élínátánì+ ọmọkùnrin Ákíbórì+ àti Gemaráyà+ ọmọkùnrin Ṣáfánì+ àti Sedekáyà ọmọkùnrin Hananáyà àti gbogbo ọmọ aládé yòókù. 13  Mikáyà+ sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún wọn nípa gbogbo ọ̀rọ̀ tí ó gbọ́ nígbà tí Bárúkù ka ìwé náà sókè ní etí àwọn ènìyàn.+ 14  Nígbà náà ni gbogbo àwọn ọmọ aládé rán Jéhúdì+ ọmọkùnrin Netanáyà ọmọkùnrin Ṣelemáyà ọmọkùnrin Kúúṣì sí Bárúkù,+ pé: “Àkájọ náà nínú èyí tí o ti kà sókè ní etí àwọn ènìyàn—mú un dání kí o sì máa bọ̀.” Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Bárúkù ọmọkùnrin Neráyà mú àkájọ náà ní ọwọ́ rẹ̀, ó sì wọlé tọ̀ wọ́n wá.+ 15  Nígbà náà ni wọ́n wí fún un pé: “Jọ̀wọ́, jókòó, kí o sì kà á sókè ní etí wa.” Nítorí náà, Bárúkù+ kà á sókè ní etí wọn. 16  Wàyí o, ó ṣẹlẹ̀ pé gbàrà tí wọ́n gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ náà, wọ́n wo ara wọn tìbẹ̀rùbojo-tìbẹ̀rùbojo; wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí wí fún Bárúkù pé: “Láìkùnà, àwa yóò sọ gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fún ọba.”+ 17  Wọ́n sì béèrè lọ́wọ́ Bárúkù, pé: “Jọ̀wọ́, sọ fún wa, Báwo ni o ṣe kọ gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí láti ẹnu rẹ̀?”+ 18  Nígbà náà ni Bárúkù wí fún wọn pé: “Ẹnu rẹ̀ ni ó fi ń polongo gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fún mi, mo sì ń fi yíǹkì kọ ọ́ sínú ìwé.”+ 19  Níkẹyìn, àwọn ọmọ aládé wí fún Bárúkù pé: “Lọ, fi ara rẹ pa mọ́, ìwọ àti Jeremáyà, tí ẹnì kankan kò fi ní mọ ibi tí ẹ wà.”+ 20  Lẹ́yìn náà, wọ́n wọlé tọ ọba lọ, ní àgbàlá,+ àkájọ náà ni wọ́n sì tọ́jú pa mọ́ sí yàrá ìjẹun+ Élíṣámà+ akọ̀wé; wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ gbogbo ọ̀rọ̀ náà ní etí ọba. 21  Nítorí náà, ọba rán Jéhúdì+ jáde lọ láti mú àkájọ náà wá. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ó mú un wá láti yàrá ìjẹun Élíṣámà+ akọ̀wé.+ Jéhúdì sì bẹ̀rẹ̀ sí kà á sókè ní etí ọba àti ní etí gbogbo àwọn ọmọ aládé tí ó dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọba. 22  Ọba sì wà ní ìjókòó ní ilé ìgbà òtútù,+ ní oṣù kẹsàn-án,+ pẹ̀lú àdògán+ tí ń jó níwájú rẹ̀. 23  Ó sì wá ṣẹlẹ̀ pé gbàrà tí Jéhúdì ka abala ojú ìwé mẹ́ta tàbí mẹ́rin, ó bẹ̀rẹ̀ sí fi ọ̀bẹ akọ̀wé ya á sọ́tọ̀ọ̀tọ̀, ó sì sọ ọ́ sínú iná tí ó wà nínú àdògán títí gbogbo àkájọ náà fi wọ inú iná tí ó wà nínú àdògán náà.+ 24  Wọn kò sì ní ìbẹ̀rùbojo kankan;+ bẹ́ẹ̀ sì ni ọba àti gbogbo ìránṣẹ́ rẹ̀, tí wọ́n ń fetí sí gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, kò gbọn ẹ̀wù wọn ya.+ 25  Àní Élínátánì+ àti Deláyà+ àti Gemaráyà+ pàápàá rọ ọba pé kí ó má fi iná sun àkájọ náà, ṣùgbọ́n kò fetí sí wọn.+ 26  Síwájú sí i, ọba pàṣẹ fún Jéráméélì ọmọkùnrin ọba àti Seráyà ọmọkùnrin Ásíríẹ́lì àti Ṣelemáyà ọmọkùnrin Ábídélì pé kí wọ́n mú Bárúkù akọ̀wé àti Jeremáyà wòlíì wá.+ Ṣùgbọ́n Jèhófà fi wọ́n pa mọ́.+ 27  Ọ̀rọ̀ Jèhófà sì tọ Jeremáyà wá síwájú sí i lẹ́yìn tí ọba ti sun àkájọ náà tí ó ní ọ̀rọ̀ tí Bárúkù+ kọ láti ẹnu Jeremáyà+ nínú, pé: 28  “Tún mú àkájọ fún ara rẹ, òmíràn, kí o sì kọ gbogbo ọ̀rọ̀ àkọ́kọ́ tí ó wà lórí àkájọ àkọ́kọ́, èyí tí Jèhóákímù ọba Júdà sun sórí rẹ̀.+ 29  Kí o sì wí lòdì sí Jèhóákímù ọba Júdà pé, ‘Èyí ni ohun tí Jèhófà wí: “Ìwọ sun àkájọ yìí,+ o sì wí pé, ‘Èé ṣe tí o fi kọ̀wé sórí rẹ̀,+ pé: “Láìkùnà, ọba Bábílónì yóò wá, ṣe ni yóò sì run ilẹ̀ yìí, yóò sì mú kí ènìyàn àti ẹranko kásẹ̀ nílẹ̀ nínú rẹ̀”?’+ 30  Nítorí náà, èyí ni ohun tí Jèhófà wí lòdì sí Jèhóákímù ọba Júdà, ‘Kì yóò ní ẹnì kankan tí yóò jókòó sórí ìtẹ́ Dáfídì,+ òkú òun alára yóò sì di ohun tí a sọ síta+ fún ooru ní ọ̀sán àti fún ìrì dídì wínníwínní ní òru. 31  Dájúdájú, èmi yóò béèrè ìjíhìn lọ́wọ́ rẹ̀+ àti lọ́wọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ àti lọ́wọ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ nítorí ìṣìnà wọn,+ èmi yóò sì mú gbogbo ìyọnu àjálù tí mo sọ lòdì sí wọn, ṣùgbọ́n tí wọn kò fetí sílẹ̀,+ wá sórí wọn àti sórí àwọn olùgbé Jerúsálẹ́mù àti sórí àwọn ènìyàn Júdà.’”’”+ 32  Jeremáyà alára sì mú àkájọ mìíràn, ó sì fi fún Bárúkù ọmọkùnrin Neráyà, akọ̀wé,+ ẹni tí ó tẹ̀ síwájú láti kọ̀wé sínú rẹ̀ láti ẹnu+ Jeremáyà gbogbo ọ̀rọ̀ inú ìwé tí Jèhóákímù ọba Júdà fi iná sun;+ ọ̀rọ̀ púpọ̀ bí ìwọnnì ni a sì fi kún un.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé