Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Jeremáyà 35:1-19

35  Ọ̀rọ̀ tí ó tọ Jeremáyà wá láti ọ̀dọ̀ Jèhófà ní ọjọ́ Jèhóákímù+ ọmọkùnrin Jòsáyà, ọba Júdà, pé:  “Lọ sí ilé àwọn ọmọ Rékábù,+ kí o sì bá wọn sọ̀rọ̀, kí o sì mú wọn wá sínú ilé Jèhófà, sí ọ̀kan nínú àwọn yàrá ìjẹun; kí o sì fún wọn ní wáìnì mu.”  Bẹ́ẹ̀ ni mo mú Jaasánáyà ọmọkùnrin Jeremáyà ọmọkùnrin Habasináyà àti àwọn arákùnrin rẹ̀, àti gbogbo ọmọ rẹ̀, àti gbogbo agbo ilé àwọn ọmọ Rékábù,  mo sì mú wọn wá sínú ilé Jèhófà, sínú yàrá ìjẹun+ àwọn ọmọ Hánánì ọmọkùnrin Igidáláyà, ènìyàn Ọlọ́run tòótọ́, èyí tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ yàrá ìjẹun àwọn ọmọ aládé tí ó wà lókè yàrá ìjẹun Maaseáyà ọmọkùnrin Ṣálúmù,+ olùṣọ́nà.  Nígbà náà ni mo gbé àwọn ife tí ó kún fún wáìnì àti àwọn gàásì síwájú àwọn ọmọ ilé ọmọ Rékábù, mo sì wí fún wọn pé: “Ẹ mu wáìnì.”  Ṣùgbọ́n wọ́n wí pé: “Àwa kì yóò mu wáìnì, nítorí pé Jónádábù ọmọkùnrin Rékábù,+ baba ńlá wa, ni ẹni tí ó gbé àṣẹ yẹn kà wá lórí, pé, ‘Ẹ kò gbọ́dọ̀ mu wáìnì, ẹ̀yin tàbí àwọn ọmọ yín, fún àkókò tí ó lọ kánrin.+  Ẹ kò sì gbọ́dọ̀ kọ́ ilé kankan, ẹ kò sì gbọ́dọ̀ fún irúgbìn kankan; ẹ kò sì gbọ́dọ̀ gbin ọgbà àjàrà kankan, bẹ́ẹ̀ sì ni kò gbọ́dọ̀ di tiyín. Ṣùgbọ́n inú àgọ́ ni kí ẹ máa gbé ní gbogbo ọjọ́ yín, kí ẹ bàa lè wà láàyè nìṣó fún ọjọ́ púpọ̀ lórí ilẹ̀ tí ẹ ti ń ṣe àtìpó.’+  Bẹ́ẹ̀ ni a ń bá a nìṣó ní ṣíṣègbọràn sí ohùn Jèhónádábù ọmọkùnrin Rékábù baba ńlá wa nínú ohun gbogbo tí ó pa láṣẹ+ fún wa nípa ṣíṣàìmu wáìnì ní gbogbo ọjọ́ wa, àwa, àwọn aya wa, àwọn ọmọkùnrin wa àti àwọn ọmọbìnrin wa,+  àti nípa ṣíṣàìkọ́ ilé láti máa gbé inú rẹ̀, kí ọgbà àjàrà tàbí pápá tàbí irúgbìn kankan má bàa di tiwa. 10  A sì ń bá a lọ láti máa gbé inú àgọ́ àti láti máa ṣègbọràn àti láti máa ṣe gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí Jónádábù+ baba ńlá wa pa láṣẹ fún wa.+ 11  Ṣùgbọ́n ó ṣẹlẹ̀ nígbà tí Nebukadirésárì ọba Bábílónì gòkè wá láti gbéjà ko ilẹ̀+ náà pé a bẹ̀rẹ̀ sí wí pé, ‘Ẹ wá, ẹ sì jẹ́ kí a wọnú Jerúsálẹ́mù nítorí ẹgbẹ́ ológun àwọn ará Kálídíà àti nítorí ẹgbẹ́ ológun àwọn ará Síríà, ẹ sì jẹ́ kí a máa gbé ní Jerúsálẹ́mù.’”+ 12  Ọ̀rọ̀ Jèhófà sì bẹ̀rẹ̀ sí tọ Jeremáyà wá, pé: 13  “Èyí ni ohun tí Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí, ‘Lọ, kí o sì wí fún àwọn ènìyàn Júdà, àti fún àwọn olùgbé Jerúsálẹ́mù pé: “Ẹ kò ha gba ìgbani-níyànjú léraléra pé kí ẹ ṣègbọràn sí ọ̀rọ̀ mi?”+ ni àsọjáde Jèhófà. 14  “Mímú ọ̀rọ̀ Jèhónádábù ọmọkùnrin Rékábù+ ṣẹ, èyí tí ó pa láṣẹ fún àwọn ọmọ rẹ̀ ti wáyé, pé kí wọ́n má ṣe mu wáìnì, wọn kò sì mu ọ̀kankan títí di òní yìí, nítorí pé wọ́n ti ṣègbọràn sí àṣẹ baba ńlá wọn.+ Ní tèmi, mo ti bá yín sọ̀rọ̀, tí mo ń dìde ní kùtùkùtù, tí mo sì ń sọ̀rọ̀,+ ṣùgbọ́n ẹ kò ṣègbọràn sí mi.+ 15  Mo sì ń rán gbogbo ìránṣẹ́ mi wòlíì sí yín ṣáá,+ tí mo ń dìde ní kùtùkùtù, tí mo sì ń rán wọn, pé, ‘Ẹ jọ̀wọ́, ẹ yí padà, olúkúlùkù kúrò ní ọ̀nà búburú rẹ̀,+ kí ẹ sì ṣe ìbálò yín ní rere,+ ẹ má sì tọ àwọn ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn láti sìn wọ́n.+ Ẹ sì máa bá a lọ láti gbé ní ilẹ̀ tí mo ti fi fún ẹ̀yin àti fún àwọn baba ńlá yín.’+ Ṣùgbọ́n ẹ kò dẹ etí yín sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ sì ni ẹ kò fetí sí mi.+ 16  Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Jèhónádábù ọmọkùnrin Rékábù+ ti mú àṣẹ baba ńlá wọn tí ó pa fún wọn ṣẹ;+ ṣùgbọ́n ní ti àwọn ènìyàn yìí, wọn kò fetí sí mi.”’”+ 17  “Nítorí náà, èyí ni ohun tí Jèhófà, Ọlọ́run àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí, ‘Kíyè sí i, èmi yóò mú gbogbo ìyọnu àjálù tí mo ti sọ lòdì sí Júdà àti gbogbo olùgbé Jerúsálẹ́mù wá sórí wọn,+ nítorí ìdí náà pé mo ti bá wọn sọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n wọn kò fetí sílẹ̀, mo sì ń pè wọ́n ṣáá ṣùgbọ́n wọn kò dáhùn.’”+ 18  Jeremáyà sì wí fún agbo ilé àwọn ọmọ Rékábù pé: “Èyí ni ohun tí Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí, ‘Nítorí ìdí náà pé ẹ ṣègbọràn sí àṣẹ Jèhónádábù+ baba ńlá yín, tí ẹ sì ń bá a lọ láti máa pa gbogbo àṣẹ rẹ̀ mọ́, tí ẹ sì ń ṣe gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí ó pa láṣẹ fún yín,+ 19  nítorí náà, èyí ni ohun tí Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, wí: “A kì yóò ké ọkùnrin kan tí yóò máa dúró+ níwájú mi nígbà gbogbo kúrò lọ́dọ̀ Jónádábù ọmọkùnrin Rékábù.”’”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé