Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Jeremáyà 34:1-22

34  Ọ̀rọ̀ tí ó tọ Jeremáyà wá láti ọ̀dọ̀ Jèhófà, nígbà tí Nebukadirésárì ọba Bábílónì+ àti gbogbo ẹgbẹ́ ológun rẹ̀+ àti gbogbo ìjọba ilẹ̀ ayé, àgbègbè ìṣàkóso abẹ́ ọwọ́ rẹ̀,+ àti gbogbo ènìyàn ń bá Jerúsálẹ́mù àti gbogbo ìlú ńlá rẹ̀ jà,+ pé:  “Èyí ni ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí, ‘Lọ, kí o sì wí fún Sedekáyà ọba Júdà,+ bẹ́ẹ̀ ni, kí o wí fún un pé: “Èyí ni ohun tí Jèhófà wí, ‘Kíyè sí i, èmi yóò fi ìlú ńlá yìí lé ọba Bábílónì lọ́wọ́,+ òun yóò sì fi iná sun ún.+  Ìwọ alára kì yóò sì sá àsálà kúrò ní ọwọ́ rẹ̀, nítorí a óò mú ọ dájúdájú, a ó sì fi ọ́ lé ọwọ́ rẹ̀.+ Ojú ìwọ fúnra rẹ yóò sì rí ojú ọba Bábílónì pàápàá,+ ẹnu tirẹ̀ yóò sì bá àní ẹnu rẹ sọ̀rọ̀, ìwọ yóò sì lọ sí Bábílónì.’  Bí ó ti wù kí ó rí, gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà, ìwọ Sedekáyà ọba Júdà,+ ‘Èyí ni ohun tí Jèhófà wí nípa rẹ: “Ìwọ kì yóò tipa idà kú.  Ìwọ yóò kú ní àlàáfíà;+ bí ìfinásun sì ti wáyé fún àwọn baba rẹ, àwọn ọba ìṣáájú tí wọ́n wà ṣáájú rẹ,+ bẹ́ẹ̀ ni wọn yóò ṣe ìfinásun+ fún ọ, ‘Págà, ọ̀gá!’+ sì ni wọn yóò sọ nínú ìdárò+ fún ọ, nítorí ‘èmi fúnra mi ti sọ ọ̀rọ̀ náà gan-an,’ ni àsọjáde Jèhófà.”’”’”  Jeremáyà wòlíì sì tẹ̀ síwájú láti bá Sedekáyà ọba Júdà sọ gbogbo ọ̀rọ̀+ wọ̀nyí ní Jerúsálẹ́mù,  nígbà tí ẹgbẹ́ ológun ọba Bábílónì ń bá Jerúsálẹ́mù jà àti gbogbo ìlú ńlá Júdà tí ó ṣẹ́ kù,+ Lákíṣì,+ àti Ásékà;+ nítorí àwọn, èyíinì ni àwọn ìlú ńlá olódi,+ ni ó ṣẹ́ kù sílẹ̀ nínú àwọn ìlú ńlá Júdà.+  Ọ̀rọ̀ tí ó tọ Jeremáyà wá láti ọ̀dọ̀ Jèhófà lẹ́yìn tí Sedekáyà Ọba bá gbogbo ènìyàn tí ó wà ní Jerúsálẹ́mù dá májẹ̀mú láti pòkìkí ìdásílẹ̀ lómìnira fún wọn,+  láti jẹ́ kí olúkúlùkù, ìránṣẹ́kùnrin rẹ̀ àti olúkúlùkù, ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀, ọkùnrin Hébérù+ àti obìnrin Hébérù, lọ ní òmìnira, láti má lò wọ́n bí ìránṣẹ́ mọ́, èyíinì ni, Júù, tí í ṣe arákùnrin rẹ̀.+ 10  Nítorí náà, gbogbo ọmọ aládé+ ṣègbọràn, àti gbogbo ènìyàn tí ó ti wọnú májẹ̀mú náà láti jẹ́ kí olúkúlùkù, ìránṣẹ́kùnrin rẹ̀ àti olúkúlùkù, ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀, lọ ní òmìnira, láti má lò wọ́n bí ìránṣẹ́ mọ́, wọ́n sì ń bá a lọ láti ṣègbọràn, wọ́n sì jẹ́ kí wọ́n lọ.+ 11  Ṣùgbọ́n wọ́n yíjú padà+ lẹ́yìn ìyẹn, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí mú àwọn ìránṣẹ́kùnrin àti àwọn ìránṣẹ́bìnrin tí wọ́n ti jẹ́ kí ó lọ lómìnira padà wá, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí tẹ̀ wọ́n lórí ba bí ìránṣẹ́kùnrin àti bí ìránṣẹ́bìnrin.+ 12  Nítorí náà, ọ̀rọ̀ Jèhófà tọ Jeremáyà wá láti ọ̀dọ̀ Jèhófà, pé: 13  “Èyí ni ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí, ‘Èmi fúnra mi bá àwọn baba ńlá+ yín dá májẹ̀mú ní ọjọ́ tí mo mú wọn jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì,+ kúrò ní ilé ìránṣẹ́,+ pé: 14  “Ní òpin ọdún méje, kí olúkúlùkù yín jẹ́ kí arákùnrin rẹ̀ lọ,+ ọkùnrin Hébérù,+ tí a tà fún ọ+ tí ó sì ti sìn ọ́ fún ọdún mẹ́fà; kí o sì jẹ́ kí ó lọ ní òmìnira kúrò lọ́dọ̀ rẹ.” Ṣùgbọ́n àwọn baba ńlá yín kò fetí sí mi, bẹ́ẹ̀ sì ni wọn kò dẹ etí wọn sílẹ̀.+ 15  Ẹ̀yin fúnra yín sì yíjú padà lónìí, ẹ sì ń ṣe ohun dídúró ṣánṣán ní ojú mi ní pípòkìkí ìdásílẹ̀ lómìnira, olúkúlùkù fún alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀, ẹ sì dá májẹ̀mú kan níwájú mi+ nínú ilé tí a fi orúkọ mi pè.+ 16  Lẹ́yìn náà, ẹ yí padà,+ ẹ sì sọ orúkọ mi di aláìmọ́,+ olúkúlùkù yín sì mú ìránṣẹ́kùnrin rẹ̀ àti olúkúlùkù, ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ padà wá, àwọn tí ẹ jẹ́ kí ó lọ ní òmìnira lọ́nà tí ó wu ọkàn wọn, ẹ sì tẹ̀ wọ́n lórí ba láti di ìránṣẹ́kùnrin àti ìránṣẹ́bìnrin yín.’+ 17  “Nítorí náà, èyí ni ohun tí Jèhófà wí, ‘Ẹ̀yin fúnra yín kò ṣègbọràn sí mi ní bíbá a lọ láti pòkìkí ìdásílẹ̀ lómìnira,+ olúkúlùkù fún arákùnrin rẹ̀ àti olúkúlùkù fún alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀. Kíyè sí i, èmi yóò pòkìkí ìdásílẹ̀ lómìnira fún yín,’+ ni àsọjáde Jèhófà, ‘sí idà,+ sí àjàkálẹ̀ àrùn+ àti sí ìyàn,+ dájúdájú, èmi yóò sì fi yín fún ìmìtìtì lójú gbogbo ìjọba ilẹ̀ ayé.+ 18  Ṣe ni èmi yóò sì fi àwọn ènìyàn tí wọ́n ń dọ́gbọ́n yẹ májẹ̀mú mi sílẹ̀,+ ní ti pé wọn kò mú ọ̀rọ̀ májẹ̀mú mi ṣẹ, èyí tí wọ́n dá níwájú mi pẹ̀lú ọmọ màlúù tí wọ́n gé sí méjì+ kí wọ́n lè kọjá láàárín àwọn ègé rẹ̀;+ 19  èyíinì ni, àwọn ọmọ aládé Júdà àti àwọn ọmọ aládé Jerúsálẹ́mù,+ àwọn òṣìṣẹ́ láàfin àti àwọn àlùfáà àti gbogbo ènìyàn ilẹ̀ náà tí wọ́n ń kọjá láàárín àwọn ègé ọmọ màlúù— 20  bẹ́ẹ̀ ni, ṣe ni èmi yóò fi wọ́n lé àwọn ọ̀tá wọn lọ́wọ́ àti lé ọwọ́ àwọn tí ń wá ọkàn wọn;+ òkú wọn yóò sì di oúnjẹ fún àwọn ẹ̀dá tí ń fò ní ojú ọ̀run àti fún àwọn ẹranko ilẹ̀ ayé.+ 21  Sedekáyà ọba Júdà+ àti àwọn ọmọ aládé rẹ̀ ni èmi yóò sì fi lé àwọn ọ̀tá wọn lọ́wọ́ àti lé ọwọ́ àwọn tí ń wá ọkàn wọn àti lé ọwọ́ ẹgbẹ́ ológun ọba Bábílónì+ tí ó fà sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ yín.’+ 22  “‘Kíyè sí i, èmi yóò pàṣẹ,’ ni àsọjáde Jèhófà, ‘ó sì dájú pé èmi yóò mú wọn padà wá sí ìlú ńlá yìí,+ wọn yóò bá a jà, wọn yóò gbà á, wọn yóò sì fi iná sun ún;+ àwọn ìlú ńlá Júdà ni èmi yóò sì sọ di ahoro láìní olùgbé.’”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé