Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Jeremáyà 33:1-26

33  Ọ̀rọ̀ Jèhófà sì bẹ̀rẹ̀ sí tọ Jeremáyà wá ní ìgbà kejì, nígbà tí a ṣì sé e mọ́ Àgbàlá Ẹ̀ṣọ́,+ pé:  “Èyí ni ohun tí Jèhófà, Olùṣẹ̀dá+ ilẹ̀ ayé wí, Jèhófà, Aṣẹ̀dá+ rẹ̀ láti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in,+ Jèhófà ni orúkọ rẹ̀,+  ‘Ké pè mí, èmi yóò sì dá ọ lóhùn,+ pẹ̀lú ìmúratán sì ni èmi yóò fi sọ fún ọ nípa àwọn ohun ńlá tí kò ṣeé finú mòye, àwọn tí ìwọ kò tíì mọ̀.’”+  “Nítorí èyí ni ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí nípa àwọn ilé inú ìlú ńlá yìí àti nípa ilé àwọn ọba Júdà tí a bì wó ní tìtorí ohun àfiṣe-odi ìsàgatì àti ní tìtorí idà;+  nípa àwọn tí ń bọ̀ láti bá àwọn ará Kálídíá jà àti láti fi òkú àwọn ènìyàn tí mo ti ṣá balẹ̀ nínú ìbínú mi àti nínú ìhónú mi kún ibi gbogbo,+ àti ní tìtorí gbogbo àwọn tí ìwà búburú wọn ti mú mi fi ojú mi pa mọ́ kúrò nínú ìlú ńlá yìí,+  ‘Kíyè sí i, èmi yóò mú ìkọ́fẹ àti ìlera gòkè wá fún un;+ ṣe ni èmi yóò sì mú wọn lára dá, èmi yóò sì ṣí ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà àti òtítọ́ payá fún wọn.+  Dájúdájú, èmi yóò sì mú àwọn òǹdè Júdà àti òǹdè Ísírẹ́lì+ padà wá, èmi yóò sì gbé wọn ró bí ti ìbẹ̀rẹ̀.+  Ṣe ni èmi yóò sì wẹ̀ wọ́n mọ́ gaara kúrò nínú gbogbo ìṣìnà wọn èyí tí wọ́n fi ṣẹ̀ mí,+ èmi yóò sì dárí gbogbo ìṣìnà wọn jì, èyí tí wọ́n fi ṣẹ̀ mí àti èyí tí wọ́n fi ré ìlànà mi kọjá.+  Dájúdájú, òun yóò sì di orúkọ ayọ̀ ńláǹlà fún mi,+ ìyìn àti ẹwà sí gbogbo orílẹ̀-èdè ilẹ̀ ayé tí yóò gbọ́ nípa gbogbo oore tí èmi yóò ṣe fún wọn.+ Dájúdájú, wọn yóò sì wà nínú ìbẹ̀rùbojo,+ ṣìbáṣìbo+ yóò sì bá wọn ní tìtorí gbogbo oore náà àti ní tìtorí gbogbo àlàáfíà tí èmi yóò fún un.’”+ 10  “Èyí ni ohun tí Jèhófà wí, ‘Ní ibí yìí tí ẹ óò ti máa wí pé ó ṣófo láìsí ènìyàn àti láìsí ẹran agbéléjẹ̀, nínú àwọn ìlú ńlá Júdà àti ní àwọn ojú pópó Jerúsálẹ́mù tí a sọ di ahoro+ láìsí ènìyàn àti láìsí olùgbé àti láìsí ẹran agbéléjẹ̀, a ó ṣì gbọ́+ 11  ìró ayọ̀ ńláǹlà àti ìró ayọ̀ yíyọ̀,+ ohùn ọkọ ìyàwó àti ohùn ìyàwó, ohùn àwọn tí ń wí pé: “Ẹ gbé Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun lárugẹ, nítorí tí Jèhófà jẹ́ ẹni rere;+ nítorí tí inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ wà fún àkókò tí ó lọ kánrin!”’+ “‘Wọn yóò máa mú ọrẹ ẹbọ ìdúpẹ́ wá sínú ilé Jèhófà,+ nítorí èmi yóò mú àwọn òǹdè ilẹ̀ náà padà wá gan-an bí ti ìbẹ̀rẹ̀,’+ ni Jèhófà wí.” 12  “Èyí ni ohun tí Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wí, ‘Ní ibi ahoro yìí tí kò ní ènìyàn àti ẹran agbéléjẹ̀ pàápàá,+ àti nínú gbogbo àwọn ìlú ńlá rẹ̀, ilẹ̀ ìjẹko àwọn olùṣọ́ àgùntàn tí ń mú kí agbo ẹran dùbúlẹ̀ yóò ṣì wà.’+ 13  “‘Nínú àwọn ìlú ńlá ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá, nínú àwọn ìlú ńlá ilẹ̀ pẹ̀tẹ́lẹ̀+ àti nínú àwọn ìlú ńlá gúúsù+ àti ní ilẹ̀ Bẹ́ńjámínì+ àti ní àwọn àyíká Jerúsálẹ́mù+ àti nínú àwọn ìlú ńlá Júdà,+ agbo ẹran yóò ṣì kọjá lábẹ́ ọwọ́ ẹni tí ń ṣe kíkà,’+ ni Jèhófà wí.” 14  “‘Wò ó! Àwọn ọjọ́ ń bọ̀,’+ ni àsọjáde Jèhófà, ‘dájúdájú, èmi yóò sì mú ọ̀rọ̀ rere tí mo sọ+ nípa ilé Ísírẹ́lì+ àti nípa ilé Júdà ṣẹ. 15  Ní àwọn ọjọ́ wọnnì àti ní àkókò yẹn, èmi yóò mú kí èéhù òdodo rú jáde fún Dáfídì,+ dájúdájú, òun yóò sì mú ìdájọ́ òdodo àti òdodo ṣẹ ní kíkún ní ilẹ̀ náà.+ 16  Ní àwọn ọjọ́ wọnnì, a ó gba Júdà là,+ Jerúsálẹ́mù alára yóò sì máa gbé nínú ààbò.+ Ohun tí a ó sì máa pè é ni, Jèhófà Ni Òdodo Wa.’”+ 17  “Nítorí èyí ni ohun tí Jèhófà wí, ‘A kì yóò ké ọkùnrin kan kúrò nínú ọ̀ràn ti Dáfídì láti máa jókòó sórí ìtẹ́ ilé Ísírẹ́lì.+ 18  Àti ní ti àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Léfì, a kì yóò ké ọkùnrin kan kúrò níwájú mi láti máa rú odindi ọrẹ ẹbọ sísun àti láti máa fi ọrẹ ẹbọ ọkà rú èéfín àti láti máa rú ẹbọ nígbà gbogbo.’”+ 19  Ọ̀rọ̀ Jèhófà sì tọ Jeremáyà wá síwájú sí i, pé: 20  “Èyí ni ohun tí Jèhófà wí, ‘Bí ẹ bá lè ba májẹ̀mú mi ti ọ̀sán àti májẹ̀mú mi ti òru jẹ́, àní kí ọ̀sán àti òru má ṣe sí ní àkókò wọn,+ 21  bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ni a lè ba májẹ̀mú èmi pẹ̀lú Dáfídì ìránṣẹ́ mi jẹ́,+ tí kò fi ní ní ọmọ tí ń ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba lórí ìtẹ́ rẹ̀;+ bákàn náà ni pẹ̀lú àwọn ọmọ Léfì, àwọn àlùfáà, àwọn òjíṣẹ́ mi.+ 22  Gan-an bí a kò ti lè ka ẹgbẹ́ ọmọ ogun ọ̀run, tí a kò sì lè díwọ̀n iyanrìn òkun,+ bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò sọ irú-ọmọ Dáfídì ìránṣẹ́ mi àti àwọn ọmọ Léfì tí wọ́n ń ṣe ìránṣẹ́ fún mi di púpọ̀.’”+ 23  Ọ̀rọ̀ Jèhófà sì ń bá a lọ láti tọ Jeremáyà wá, pé: 24  “Ìwọ kò ha rí ohun tí àwọn kan lára àwọn ènìyàn yìí ń sọ, pé, ‘Ìdílé méjì tí Jèhófà yàn,+ òun yóò kọ̀ wọ́n pẹ̀lú’? Àwọn ènìyàn mi ni wọ́n sì ń hùwà àìlọ́wọ̀ sí,+ tí kì yóò fi máa bá a lọ mọ́ láti jẹ́ orílẹ̀-èdè níwájú wọn. 25  “Èyí ni ohun tí Jèhófà wí, ‘Bí kì í bá ṣe òtítọ́ pé mo ti yan májẹ̀mú mi ti ọ̀sán àti òru kalẹ̀,+ àwọn ìlànà àgbékalẹ̀ ọ̀run àti ilẹ̀ ayé,+ 26  bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú, èmi ì bá kọ irú-ọmọ Jékọ́bù àti ti Dáfídì ìránṣẹ́ mi,+ tí èmi kò fi ní mú àwọn olùṣàkóso lórí irú-ọmọ Ábúráhámù, Ísákì àti Jékọ́bù láti inú irú-ọmọ rẹ̀. Nítorí èmi yóò kó òǹdè wọn jọ,+ èmi yóò sì ṣe ojú àánú sí wọn.’”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé