Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Jeremáyà 32:1-44

32  Ọ̀rọ̀ tí ó tọ Jeremáyà wá láti ọ̀dọ̀ Jèhófà ní ọdún kẹwàá Sedekáyà ọba Júdà,+ èyíinì ni, ọdún kejìdínlógún Nebukadirésárì.+  Àti ní àkókò yẹn, ẹgbẹ́ ológun ọba Bábílónì sàga ti Jerúsálẹ́mù;+ àti ní ti Jeremáyà wòlíì, ó ṣẹlẹ̀ pé ó wà lábẹ́ ìkálọ́wọ́kò ní Àgbàlá Ẹ̀ṣọ́+ tí ó wà ní ilé ọba Júdà;  nítorí pé Sedekáyà ọba Júdà ti ká a lọ́wọ́ kò,+ ní wíwí pé: “Èé ṣe tí o fi ń sọ tẹ́lẹ̀,+ pé, ‘Èyí ni ohun tí Jèhófà wí: “Kíyè sí i, èmi yóò fi ìlú ńlá yìí lé ọba Bábílónì lọ́wọ́, òun yóò sì gbà á dájúdájú;+  àti Sedekáyà alára, tí í ṣe ọba Júdà, kì yóò sì sá àsálà ní ọwọ́ àwọn ará Kálídíà, nítorí láìkùnà, a ó fi í lé ọba Bábílónì lọ́wọ́, ní ti gidi, ẹnu rẹ̀ yóò sì bá ẹnu ẹni tọ̀hún sọ̀rọ̀, ojú tirẹ̀ yóò sì rí ojú ẹni tọ̀hún pàápàá”’;+  ‘yóò sì mú Sedekáyà lọ sí Bábílónì, ibẹ̀ ni yóò sì wà títí èmi yóò fi yí àfiyèsí mi sí i,’+ ni àsọjáde Jèhófà; ‘bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ ń bá àwọn ará Kálídíà jagun, ẹ kì yóò kẹ́sẹ járí’?”+  Jeremáyà sì tẹ̀ síwájú láti wí pé: “Ọ̀rọ̀ Jèhófà ti tọ̀ mí wá, pé,  ‘Hánámélì rèé, ọmọkùnrin Ṣálúmù, arákùnrin rẹ láti ìdí ilé baba rẹ, tí ń wọlé bọ̀ wá bá ọ, pé: “Ra pápá mi tí ó wà ní Ánátótì+ fún ara rẹ, nítorí pé tìrẹ ni ẹ̀tọ́ ìtúnrà fún rírà á.”’”+  Nígbà tí ó ṣe, Hánámélì ọmọkùnrin arákùnrin mi láti ìdí ilé baba mi wọlé tọ̀ mí wá, ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Jèhófà, sí Àgbàlá Ẹ̀ṣọ́,+ ó sì ń bá a lọ láti wí fún mi pé: “Jọ̀wọ́, ra pápá mi tí ó wà ní Ánátótì,+ èyí tí ó wà ní ilẹ̀ Bẹ́ńjámínì,+ nítorí pé tìrẹ ni ẹ̀tọ́ ohun ìní àjogúnbá, tìrẹ sì ni agbára ìtúnrà. Rà á fún ara rẹ.” Látàrí ìyẹn, mo mọ̀ pé ó jẹ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà.+  Nítorí náà, mo tẹ̀ síwájú láti ra pápá tí ó wà ní Ánátótì+ lọ́wọ́ Hánámélì+ ọmọkùnrin arákùnrin mi láti ìdí ilé baba mi. Mo sì wọn owó fún un,+ ṣékélì méje àti ẹyọ fàdákà mẹ́wàá. 10  Lẹ́yìn náà, mo kọ ìwé àdéhùn,+ mo sì fi èdìdì sí i,+ mo sì gba àwọn ẹlẹ́rìí+ bí mo ti ń wọn+ owó náà lórí òṣùwọ̀n. 11  Lẹ́yìn náà, mo mú ìwé àdéhùn ọjà rírà, èyí tí a fi èdìdì dì ní ìbámu pẹ̀lú àṣẹ àti ìlànà,+ àti èyí tí a ṣí sílẹ̀; 12  mo sì wá fi ìwé àdéhùn ọjà rírà náà fún Bárúkù,+ ọmọkùnrin Neráyà,+ ọmọkùnrin Maseáyà, lójú Hánámélì ọmọkùnrin arákùnrin mi láti ìdí ilé baba mi àti lójú àwọn ẹlẹ́rìí, àwọn tí ó kọ̀wé sínú ìwé àdéhùn ọjà rírà náà,+ lójú gbogbo Júù tí wọ́n jókòó sí Àgbàlá Ẹ̀ṣọ́.+ 13  Wàyí o, mo pàṣẹ fún Bárúkù lójú wọn, pé: 14  “Èyí ni ohun tí Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí, ‘Ní mímú ìwé àdéhùn wọ̀nyí, ìwé àdéhùn ọjà rírà yìí, àní èyí tí a fi èdìdì dì, àti ìwé àdéhùn kejì tí a ṣí sílẹ̀,+ kí o sì fi wọ́n sínú ohun èlò amọ̀, kí wọ́n lè wà fún ọ̀pọ̀ ọjọ́.’ 15  Nítorí èyí ni ohun tí Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí, ‘Àwọn ilé àti pápá àti ọgbà àjàrà ni a ó rà síbẹ̀ ní ilẹ̀ yìí.’”+ 16  Mo sì bẹ̀rẹ̀ sí gbàdúrà+ sí Jèhófà lẹ́yìn tí mo ti fi ìwé àdéhùn ọjà rírà náà fún Bárúkù+ ọmọkùnrin Neráyà,+ pé: 17  “Págà, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ!+ Kíyè sí i, ìwọ fúnra rẹ ni ó ṣe ọ̀run àti ilẹ̀ ayé nípa agbára ńlá rẹ+ àti nípa apá rẹ nínà jáde.+ Gbogbo ọ̀ràn náà kò ṣe àgbàyanu jù fún ọ,+ 18  Ẹni tí ń ṣe inú-rere-onífẹ̀ẹ́ sí ẹgbẹẹgbẹ̀rún,+ ẹni tí ó sì ń san ìṣìnà baba padà sí oókan àyà àwọn ọmọ wọn lẹ́yìn wọn,+ Ọlọ́run tòótọ́, Ẹni ńlá,+ Ẹni tí ó ní agbára ńlá,+ Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun+ ni orúkọ rẹ̀,+ 19  ó pọ̀ ní ète,+ ó sì pọ̀ yanturu ní àwọn ìṣe,+ ìwọ ẹni tí ojú rẹ ṣí sí gbogbo ọ̀nà àwọn ọmọ ènìyàn,+ láti fi fún olúkúlùkù gẹ́gẹ́ bí àwọn ọ̀nà rẹ̀ àti gẹ́gẹ́ bí èso ìbálò rẹ̀;+ 20  ìwọ ẹni tí ó fi àwọn àmì àti àwọn iṣẹ́ ìyanu lélẹ̀ ní ilẹ̀ Íjíbítì títí di òní yìí àti ní Ísírẹ́lì àti láàárín àwọn ènìyàn,+ kí o lè ṣe orúkọ fún ara rẹ, gan-an bí ti ọjọ́ òní yìí.+ 21  Ìwọ sì tẹ̀ síwájú láti mú àwọn ènìyàn rẹ Ísírẹ́lì jáde wá láti ilẹ̀ Íjíbítì,+ pẹ̀lú àwọn iṣẹ́ àmì àti pẹ̀lú àwọn iṣẹ́ ìyanu+ àti pẹ̀lú ọwọ́ líle àti pẹ̀lú apá nínà jáde àti pẹ̀lú ẹ̀rù ńláǹlà.+ 22  “Nígbà tí ó ṣe, o fún wọn ní ilẹ̀ yìí tí o búra fún àwọn baba ńlá wọn láti fi fún wọn,+ ilẹ̀ tí ń ṣàn fún wàrà àti oyin.+ 23  Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí wọlé wá, wọ́n sì gbà á,+ ṣùgbọ́n wọn kò ṣègbọràn sí ohùn rẹ, wọn kò sì rìn nínú òfin rẹ.+ Gbogbo ohun tí o pàṣẹ fún wọn pé kí wọ́n ṣe ni wọn kò ṣe,+ tí o fi mú kí gbogbo ìyọnu àjálù yìí já lù wọ́n.+ 24  Wò ó! Pẹ̀lú ohun àfiṣe-odi ìsàgatì+ ni àwọn ènìyàn wá sí ìlú ńlá náà láti gbà á,+ ìlú ńlá náà gan-an ni a ó sì fi lé àwọn ará Kálídíà tí ń bá a jà lọ́wọ́,+ nítorí idà+ àti ìyàn+ àti àjàkálẹ̀ àrùn;+ ohun tí ìwọ sì sọ ti ṣẹlẹ̀, sì kíyè sí i, ìwọ rí i.+ 25  Síbẹ̀, ìwọ fúnra rẹ, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, ti wí fún mi pé, ‘Fi owó ra pápá náà+ fún ara rẹ kí o sì gba àwọn ẹlẹ́rìí,’+ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìlú ńlá náà ni a ó fi lé àwọn ará Kálídíà lọ́wọ́.”+ 26  Látàrí ìyẹn, ọ̀rọ̀ Jèhófà tọ Jeremáyà wá, pé: 27  “Èmi rèé, Jèhófà, Ọlọ́run gbogbo ẹran ara.+ Ọ̀ràn èyíkéyìí ha wà tí ó ṣe àgbàyanu jù fún mi bí?+ 28  Nítorí náà, èyí ni ohun tí Jèhófà wí, ‘Kíyè sí i, èmi yóò fi ìlú ńlá yìí lé àwọn ará Kálídíà lọ́wọ́ àti lé Nebukadirésárì ọba Bábílónì lọ́wọ́, òun yóò sì gbà á.+ 29  Àwọn ará Kálídíà tí ń bá ìlú ńlá yìí jà yóò wọlé wá, wọn yóò sì sọ iná sí ìlú ńlá yìí,+ wọn yóò sì sun ún kanlẹ̀ àti àwọn ilé tí wọ́n ti ń rú èéfín ẹbọ lórí òrùlé wọn sí Báálì tí wọ́n sì ti da ọrẹ ẹbọ ohun mímu jáde sí àwọn ọlọ́run mìíràn fún ète mímú mi bínú.’+ 30  “‘Nítorí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àti àwọn ọmọ Júdà jẹ́ olùṣe kìkì ohun tí ó burú ní ojú mi, láti ìgbà èwe wọn wá;+ nítorí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tilẹ̀ ń mú mi bínú nípa iṣẹ́ ọwọ́ wọn,’+ ni àsọjáde Jèhófà. 31  ‘Nítorí ìlú ńlá yìí, láti ọjọ́ tí wọ́n ti tẹ̀ ẹ́ dó, títí di òní yìí, ti jẹ́ kìkì okùnfà ìbínú nínú mi àti okùnfà ìhónú nínú mi,+ láti mú un kúrò níwájú mi,+ 32  ní tìtorí gbogbo ìwà búburú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì+ àti ti àwọn ọmọ Júdà+ tí wọ́n ti hù láti mú mi bínú,+ àwọn, àwọn ọba wọn,+ àwọn ọmọ aládé wọn,+ àwọn àlùfáà wọn+ àti àwọn wòlíì wọn,+ àti àwọn ènìyàn Júdà àti àwọn olùgbé Jerúsálẹ́mù. 33  Wọ́n sì ń yí ẹ̀yìn wọn sí mi, kì í sì í ṣe ojú wọn;+ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a ń kọ́ wọn, a ń dìde ní kùtùkùtù, a sì ń kọ́ wọn, ṣùgbọ́n kò sí ọ̀kankan nínú wọn tí ń fetí sílẹ̀ láti gba ìbáwí.+ 34  Wọ́n sì fi ohun ìríra wọn sínú ilé tí a fi orúkọ tèmi pè, láti sọ ọ́ di ẹlẹ́gbin.+ 35  Síwájú sí i, wọ́n kọ́ àwọn ibi gíga Báálì+ tí ó wà ní àfonífojì ọmọ Hínómù,+ láti mú àwọn ọmọkùnrin wọn àti àwọn ọmọbìnrin wọn la iná kọjá+ fún Mólékì,+ ohun kan tí èmi kò pa láṣẹ fún wọn,+ bẹ́ẹ̀ sì ni kò wá sí ọkàn-àyà mi láti ṣe ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí yìí,+ fún ète mímú Júdà ṣẹ̀.’+ 36  “Ǹjẹ́ nítorí náà, èyí ni ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí nípa ìlú ńlá yìí tí ẹ ń sọ pé dájúdájú a ó fi lé ọba Bábílónì lọ́wọ́ nípa idà àti nípa ìyàn àti nípa àjàkálẹ̀ àrùn,+ 37  ‘Kíyè sí i, èmi yóò kó wọn jọpọ̀ láti inú gbogbo ilẹ̀ tí èmi yóò ti fọ́n wọn ká sí nínú ìbínú mi àti nínú ìhónú mi àti nínú ìkannú ńláǹlà mi;+ ṣe ni èmi yóò sì mú wọn padà wá sí ibí yìí láti máa gbé nínú ààbò.+ 38  Wọn yóò sì jẹ́ ènìyàn mi dájúdájú,+ èmi alára yóò sì jẹ́ Ọlọ́run wọn.+ 39  Ṣe ni èmi yóò sì fún wọn ní ọkàn-àyà+ kan àti ọ̀nà kan láti bẹ̀rù mi nígbà gbogbo, fún rere wọn àti ti àwọn ọmọ wọn lẹ́yìn wọn.+ 40  Dájúdájú, èmi yóò sì bá wọn dá májẹ̀mú tí ó wà fún àkókò tí ó lọ kánrin,+ pé èmi kì yóò yí padà kúrò lẹ́yìn wọn, kí n lè ṣe wọ́n ní rere;+ ìbẹ̀rù mi ni èmi yóò sì fi sínú ọkàn-àyà wọn, kí wọ́n má bàa yà kúrò lọ́dọ̀ mi.+ 41  Ṣe ni èmi yóò sì yọ ayọ̀ ńláǹlà lórí wọn, láti ṣe wọ́n ní rere,+ èmi yóò sì fi gbogbo ọkàn-àyà mi àti gbogbo ọkàn mi gbìn wọ́n sí ilẹ̀ yìí+ lóòótọ́.’” 42  “Nítorí èyí ni ohun tí Jèhófà wí, ‘Gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti mú gbogbo ìyọnu àjálù yìí wá sórí àwọn ènìyàn yìí, bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò mú gbogbo oore tí mo sọ nípa wọn wá sórí wọn.+ 43  Dájúdájú, a ó sì ra pápá ní ilẹ̀ yìí,+ tí ẹ óò máa sọ nípa rẹ̀ pé: “Ahoro+ ni láìsí ènìyàn àti ẹran agbéléjẹ̀. A ti fi lé àwọn ará Kálídíà lọ́wọ́.”’+ 44  “‘Àwọn ènìyàn yóò fi owó ra pápá, àkọsílẹ̀ yóò sì wà nínú ìwé àdéhùn+ àti fífi èdìdì sí àti gbígba àwọn ẹlẹ́rìí+ ní ilẹ̀ Bẹ́ńjámínì+ àti ní àwọn àyíká Jerúsálẹ́mù+ àti ní àwọn ìlú ńlá Júdà+ àti ní àwọn ìlú ńlá ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá àti ní àwọn ìlú ńlá ilẹ̀ pẹ̀tẹ́lẹ̀+ àti ní àwọn ìlú ńlá gúúsù,+ nítorí pé èmi yóò mú àwọn òǹdè wọn padà wá,’+ ni àsọjáde Jèhófà.”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé