Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Jeremáyà 30:1-24

30  Ọ̀rọ̀ tí ó tọ Jeremáyà wá láti ọ̀dọ̀ Jèhófà, pé:  “Èyí ni ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí, ‘Kọ gbogbo ọ̀rọ̀ tí èmi yóò bá ọ sọ fún ara rẹ sínú ìwé kan.+  Nítorí, “wò ó! àwọn ọjọ́ ń bọ̀,” ni àsọjáde Jèhófà, “dájúdájú, èmi yóò kó àwọn òǹdè ènìyàn mi, Ísírẹ́lì àti Júdà jọ,”+ ni Jèhófà wí, “èmi yóò sì mú wọn padà wá sí ilẹ̀ tí mo fi fún àwọn baba ńlá wọn, dájúdájú, wọn yóò sì tún gbà á padà.”’”+  Ìwọ̀nyí sì ni ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ fún Ísírẹ́lì àti fún Júdà.  Nítorí èyí ni ohun tí Jèhófà wí: “Ìró ìwárìrì ni a ti gbọ́, ìbẹ̀rùbojo,+ kò sì sí àlàáfíà.  Ẹ jọ̀wọ́, ẹ béèrè, kí ẹ sì rí i bóyá ọkùnrin ń bímọ. Èé ṣe tí mo fi rí olúkúlùkù abarapá ọkùnrin pẹ̀lú ọwọ́ rẹ̀ ní abẹ́nú rẹ̀ bí obìnrin tí ó fẹ́ bímọ,+ tí gbogbo ojú sì di ràndánràndán?+  Págà! Nítorí ọjọ́ yẹn jẹ́ ọjọ́ ńlá,+ tí kò fi sí òmíràn bí rẹ̀,+ ó sì jẹ́ àkókò wàhálà fún Jékọ́bù.+ Ṣùgbọ́n a ó gbà á là, àní kúrò nínú rẹ̀.”  “Yóò sì ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ yẹn,” ni àsọjáde Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, “pé èmi yóò ṣẹ́ àjàgà ẹnì kan kúrò ní ọrùn rẹ, ọ̀já rẹ ni èmi yóò fà já sí méjì,+ àwọn àjèjì kì yóò sì lò ó bí ìránṣẹ́ mọ́.  Dájúdájú, wọn yóò sì máa sin Jèhófà Ọlọ́run wọn àti Dáfídì ọba wọn,+ ẹni tí èmi yóò gbé dìde fún wọn.”+ 10  “Ní tìrẹ, má fòyà, ìwọ Jékọ́bù ìránṣẹ́ mi,” ni àsọjáde Jèhófà, “má sì jẹ́ kí ìpayà bá ọ, Ísírẹ́lì.+ Nítorí kíyè sí i, èmi yóò gbà ọ́ là láti ibi jíjìnnàréré àti àwọn ọmọ rẹ láti ilẹ̀ oko òǹdè wọn.+ Dájúdájú, Jékọ́bù yóò padà, yóò sì bọ́ lọ́wọ́ ìyọlẹ́nu, yóò sì wà ní ìdẹ̀rùn, kì yóò sì sí ẹni tí ń fa ìwárìrì.”+ 11  “Nítorí mo wà pẹ̀lú rẹ,” ni àsọjáde Jèhófà, “láti gbà ọ́ là;+ ṣùgbọ́n èmi yóò ṣe ìparun pátápátá láàárín gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí mo tú ọ ká sí.+ Bí ó ti wù kí ó rí, nínú ọ̀ràn tìrẹ, èmi kì yóò ṣe ìparun pátápátá.+ Ṣe ni èmi yóò tọ́ ọ sọ́nà dé ìwọ̀n tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu, níwọ̀n bí èmi kò ti ní ṣàìfi ìyà jẹ ọ́.”+ 12  Nítorí èyí ni ohun tí Jèhófà wí: “Kò sí ìwòsàn fún ìwópalẹ̀ rẹ.+ Bárakú ni ọgbẹ́ rẹ.+ 13  Kò sí ẹni tí ń gba ẹjọ́ rẹ rò, fún egbò rẹ.+ Kò sí ọ̀nà ìmúniláradá, kò sí ìmúbọ̀sípò, fún ọ.+ 14  Gbogbo àwọn tí ń fi ìgbónájanjan nífẹ̀ẹ́ rẹ ni àwọn tí ó gbàgbé rẹ.+ Ìwọ kọ́ ni wọ́n ń wá. Nítorí mo fi ẹgba ọ̀tá lù ọ́,+ pẹ̀lú ìnàlẹ́gba ẹni tí ó níkà,+ ní tìtorí ọ̀pọ̀ yanturu ìṣìnà rẹ;+ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ ti di púpọ̀ níye.+ 15  Èé ṣe tí o fi ké jáde ní tìtorí ìwópalẹ̀ rẹ?+ Ìrora rẹ kò ṣeé wò sàn ní tìtorí ọ̀pọ̀ yanturu ìṣìnà rẹ; ẹ̀ṣẹ̀ rẹ ti di púpọ̀ níye.+ Mo ti ṣe nǹkan wọ̀nyí sí ọ. 16  Nítorí náà, gbogbo àwọn tí ń jẹ ọ́ run ni a ó jẹ run;+ àti ní ti gbogbo elénìní rẹ, oko òǹdè ni gbogbo wọn yóò lọ.+ Gbogbo àwọn tí ń kó ọ ní ìkógun yóò wá wà fún ìkógun dájúdájú, gbogbo àwọn tí ń kó ọ lẹ́rù lọ ni èmi yóò sì fi fún ìkólẹ́rù lọ.”+ 17  “Nítorí èmi yóò mú kí ara rẹ kọ́fẹ, èmi yóò sì mú ọ lára dá kúrò nínú ọgbẹ́ rẹ,”+ ni àsọjáde Jèhófà. “Nítorí obìnrin tí a lé lọ ni wọn ń pè ọ́:+ ‘Èyíinì ni Síónì, tí ẹnikẹ́ni kò wá.’”+ 18  Èyí ni ohun tí Jèhófà wí: “Kíyè sí i, èmi yóò kó àwọn òǹdè àgọ́ Jékọ́bù jọ,+ èmi yóò sì ṣe ojú àánú sí àwọn àgọ́ ìjọsìn rẹ̀. A ó sì tún ìlú ńlá náà kọ́ ní ti gidi sórí òkìtì rẹ̀;+ ibi tí ó sì tọ́ sí i ni ilé gogoro ibùgbé rẹ̀ yóò jókòó sí.+ 19  Àti láti ọ̀dọ̀ wọn, ìdúpẹ́ yóò jáde lọ dájúdájú, àti ìró àwọn tí ń rẹ́rìn-ín.+ Dájúdájú, èmi yóò sọ wọ́n di púpọ̀, wọn kì yóò sì kéré níye;+ èmi yóò sì mú wọn pọ̀ súà níye, wọn kì yóò sì di aláìjámọ́ pàtàkì.+ 20  Àwọn ọmọ rẹ̀ yóò sì dà bí ti ìgbà àtijọ́, àti níwájú mi, àpéjọ tirẹ̀ yóò fìdí múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in.+ Ṣe ni èmi yóò yí àfiyèsí mi sí gbogbo àwọn aninilára rẹ̀.+ 21  Dájúdájú, ọlọ́lá ọba rẹ̀ yóò wá jẹ́ láti ọ̀dọ̀ rẹ̀,+ láti àárín rẹ̀ sì ni olùṣàkóso rẹ̀ yóò ti jáde lọ;+ dájúdájú, èmi yóò mú un sún mọ́ tòsí, yóò sì tọ̀ mí wá.”+ “Nítorí nísinsìnyí, ta wá ni ẹni yìí tí ó ti fi ọkàn-àyà rẹ̀ jẹ́jẹ̀ẹ́ láti tọ̀ mí wá?”+ ni àsọjáde Jèhófà. 22  “Dájúdájú, ẹ óò di ènìyàn mi,+ èmi fúnra mi yóò sì di Ọlọ́run yín.”+ 23  Wò ó! Ìjì ẹlẹ́fùúùfù ti Jèhófà, ìhónú pàápàá, ti jáde lọ, ìjì líle tí ń gbá nǹkan lọ.+ Yóò fẹ́ yí ká sórí àwọn ẹni burúkú.+ 24  Ìbínú jíjófòfò Jèhófà kì yóò yí padà títí yóò fi ní ìmúṣẹ ní kíkún àti títí yóò fi mú èrò ọkàn-àyà rẹ̀ ṣẹ.+ Ní apá ìgbẹ̀yìn àwọn ọjọ́, ẹ ó gbà á yẹ̀wò.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé