Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Jeremáyà 3:1-25

3  Àsọjáde kan wà: “Bí ọkùnrin kan bá lé aya rẹ̀ lọ, tí obìnrin náà sì lọ kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀ tí ó sì di ti ọkùnrin mìíràn, ó ha yẹ kí ọkùnrin náà tún padà sọ́dọ̀ rẹ̀?”+ A kò ha ti sọ ilẹ̀ yẹn di eléèérí dájúdájú bí?+ “Ìwọ alára sì ti bá ọ̀pọ̀ alábàákẹ́gbẹ́ ṣe kárùwà;+ ó ha sì yẹ kí o padà sọ́dọ̀ mi bí?”+ ni àsọjáde Jèhófà.  “Gbé ojú rẹ sókè sí àwọn ipa ọ̀nà àrìnkúnná, kí o sì rí i.+ Ibo ni a kò ti fipá bá ọ lò pọ̀?+ Ẹ̀gbẹ́ ọ̀nà ni o jókòó sí dè wọ́n, bí ọmọ ilẹ̀ Arébíà nínú aginjù;+ o sì ń bá a lọ láti fi ìṣe kárùwà rẹ àti ìwà búburú rẹ sọ ilẹ̀ náà di eléèérí.+  Nítorí náà, a fawọ́ ọ̀pọ̀ yanturu ọ̀wààrà òjò sẹ́yìn,+ òjò ìgbà ìrúwé pàápàá kò rọ̀.+ Iwájú orí rẹ ti di ti aya tí ń ṣe iṣẹ́ kárùwà. Ìwọ ti kọ̀ láti mọ ìtẹ́lógo lára.+  Ìwọ ha ti pè mí láti ìsinsìnyí lọ pé, ‘Baba mi,+ ìwọ ni ọ̀rẹ́ àfinúhàn ìgbà èwe mi!+  Ó ha yẹ kí ẹnì kan fìbínú hàn fún àkókò tí ó lọ kánrin, tàbí kí ó máa ṣọ́ ohun kan títí láé?’+ Wò ó! Ìwọ ti sọ̀rọ̀, o sì ń bá a lọ láti ṣe ohun búburú, o sì borí.”+  Jèhófà sì tẹ̀ síwájú láti sọ fún mi ní ọjọ́ Jòsáyà Ọba+ pé: “‘O ha rí ohun tí Ísírẹ́lì aláìṣòótọ́ ṣe bí?+ Ó ń lọ sórí gbogbo òkè ńlá gíga+ àti sábẹ́ gbogbo igi gbígbẹ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀,+ kí ó lè ṣe iṣẹ́ kárùwà níbẹ̀.+  Lẹ́yìn tí ó sì ti ṣe gbogbo nǹkan wọ̀nyí, mo ń sọ ṣáá pé kí ó padà àní sọ́dọ̀ mi, ṣùgbọ́n kò padà;+ Júdà sì ń wo arábìnrin rẹ̀ aládàkàdekè.+  Nígbà tí mo wá rí ìyẹn, nítorí ìdí náà pé Ísírẹ́lì aláìṣòótọ́ ti ṣe panṣágà, mo lé e lọ,+ mo sì ń bá a lọ láti fi ìwé ẹ̀rí ìkọ̀sílẹ̀ rẹ̀ kíkún fún un,+ síbẹ̀, Júdà arábìnrin rẹ̀ tí ń ṣe àdàkàdekè kò fòyà, ṣùgbọ́n òun alára pẹ̀lú bẹ̀rẹ̀ sí lọ ṣe iṣẹ́ kárùwà.+  Iṣẹ́ kárùwà rẹ̀ sì ṣẹlẹ̀ nítorí ojú ìwòye ṣeréṣeré tí ó ní, ó ń bá a lọ láti sọ ilẹ̀ náà di eléèérí,+ ó sì ń bá àwọn òkúta àti àwọn igi ṣe panṣágà;+ 10  àní látàrí gbogbo èyí, Júdà arábìnrin rẹ̀ aládàkàdekè kò fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ̀ padà sọ́dọ̀ mi,+ kìkì lọ́nà èké,’+ ni àsọjáde Jèhófà.” 11  Jèhófà sì ń bá a lọ láti sọ fún mi pé: “Ísírẹ́lì aláìṣòótọ́ ti fi ọkàn rẹ̀ hàn ní olódodo ju Júdà aládàkàdekè.+ 12  Lọ, kí o sì pòkìkí ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sí àríwá+ pé: “‘“Padà, ìwọ Ísírẹ́lì ọ̀dàlẹ̀,” ni àsọjáde Jèhófà.’+ ‘“Èmi kì yóò jẹ́ kí ojú mi sọ̀ kalẹ̀ tìbínú-tìbínú sórí yín,+ nítorí adúróṣinṣin ni mí,”+ ni àsọjáde Jèhófà.’ ‘“Èmi kì yóò máa fìbínú hàn fún àkókò tí ó lọ kánrin.+ 13  Kìkì pé kí o fiyè sí ìṣìnà rẹ, nítorí Jèhófà Ọlọ́run rẹ ni ìwọ ré ìlànà rẹ̀ kọjá.+ Ìwọ sì ń bá a lọ láti tú àwọn ọ̀nà rẹ ká fún àwọn àjèjì+ lábẹ́ gbogbo igi gbígbẹ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀,+ ṣùgbọ́n ohùn mi ni ẹ kò fetí sí,” ni àsọjáde Jèhófà.’” 14  “Ẹ padà, ẹ̀yin ọ̀dàlẹ̀ ọmọ,”+ ni àsọjáde Jèhófà. “Nítorí èmi fúnra mi ti di ọkọ olówó orí yín;+ dájúdájú, èmi yóò gbà yín, ọ̀kan nínú ìlú ńlá kan àti méjì nínú ìdílé kan, ṣe ni èmi yóò mú yín wá sí Síónì.+ 15  Dájúdájú, èmi yóò fi àwọn olùṣọ́ àgùntàn fún yín ní ìbámu pẹ̀lú ọkàn-àyà mi,+ wọn yóò sì fi ìmọ̀ àti ìjìnlẹ̀ òye bọ́ yín dájúdájú.+ 16  Yóò sì ṣẹlẹ̀ pé, ẹ ó di púpọ̀ dájúdájú, ẹ ó sì so èso ní ilẹ̀ náà ní àwọn ọjọ́ wọnnì,” ni àsọjáde Jèhófà.+ “Wọn kì yóò tún sọ pé, ‘Àpótí májẹ̀mú Jèhófà!’+ bẹ́ẹ̀ ni kì yóò tún wá sí ọkàn-àyà mọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò rántí rẹ̀ mọ́+ tàbí kí wọ́n sàárò rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò tún ṣe é mọ́. 17  Ní àkókò yẹn, wọn yóò pe Jerúsálẹ́mù ní ìtẹ́ Jèhófà;+ a ó sì kó gbogbo orílẹ̀-èdè jọpọ̀ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀,+ sí orúkọ Jèhófà ní Jerúsálẹ́mù,+ wọn kì yóò sì tún tọ agídí ọkàn-àyà búburú wọn lẹ́yìn mọ́.”+ 18  “Ní àwọn ọjọ́ wọnnì, wọn yóò rìn, ilé Júdà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ilé Ísírẹ́lì,+ wọn yóò sì jọ+ jáde kúrò ní ilẹ̀ àríwá sí ilẹ̀ tí mo fi fún àwọn baba ńlá yín gẹ́gẹ́ bí ohun ìní àjogúnbá.+ 19  Èmi fúnra mi sì wí pé, ‘Wo bí mo ti bẹ̀rẹ̀ sí gbé ọ sáàárín àwọn ọmọ tí mo sì fi ilẹ̀ fífanimọ́ra fún ọ,+ ohun ìní àjogúnbá ti ohun ọ̀ṣọ́ ẹgbẹ́ ọmọ ogun àwọn orílẹ̀-èdè!’ Mo sì sọ síwájú sí i pé, ‘“Baba mi!”+ ni ẹ ó pè mí, ẹ kì yóò sì yí padà ní títọ̀ mí lẹ́yìn.’ 20  ‘Lóòótọ́, gẹ́gẹ́ bí aya kan ṣe ń fi àdàkàdekè lọ kúrò lọ́dọ̀ alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀,+ bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin, ilé Ísírẹ́lì, ṣe fi àdàkàdekè bá mi lò,’+ ni àsọjáde Jèhófà.” 21  Ní àwọn ipa ọ̀nà àrìnkúnná, a gbọ́ ìró kan, ẹkún sísun, ìpàrọwà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Nítorí wọ́n ti lọ́ ọ̀nà wọn po;+ wọ́n ti gbàgbé Jèhófà Ọlọ́run wọn.+ 22  “Ẹ padà, ẹ̀yin ọ̀dàlẹ̀ ọmọ.+ Èmi yóò mú ipò ìwà ọ̀dàlẹ̀ yín lára dá.”+ “Àwa rèé! A ti wá sọ́dọ̀ rẹ, nítorí ìwọ, Jèhófà, ni Ọlọ́run wa.+ 23  Lóòótọ́, àwọn òkè kéékèèké àti yánpọnyánrin orí àwọn òkè ńlá+ jẹ́ ti èké.+ Lóòótọ́, nínú Jèhófà Ọlọ́run wa ni ìgbàlà Ísírẹ́lì wà.+ 24  Ṣùgbọ́n ohun tí ń tini lójú+ fúnra rẹ̀ ti jẹ làálàá àwọn baba ńlá wa run láti ìgbà èwe wa, àwọn agbo ẹran wọn àti àwọn ọ̀wọ́ ẹran wọn, àwọn ọmọkùnrin wọn àti àwọn ọmọbìnrin wọn. 25  A dùbúlẹ̀ nínú ìtìjú wa,+ ìtẹ́lógo wa sì bò wá;+ nítorí Jèhófà Ọlọ́run wa ni a dẹ́ṣẹ̀ sí,+ àwa àti àwọn baba wa láti ìgbà èwe wa wá títí di òní yìí,+ a kò sì ṣègbọràn sí ohùn Jèhófà Ọlọ́run wa.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé