Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Jeremáyà 29:1-32

29  Ìwọ̀nyí sì ni ọ̀rọ̀ inú lẹ́tà tí Jeremáyà wòlíì fi ránṣẹ́ láti Jerúsálẹ́mù sí ìyókù àwọn àgbà ọkùnrin nínú àwọn ìgbèkùn àti sí àwọn àlùfáà àti sí àwọn wòlíì àti sí gbogbo àwọn ènìyàn náà, àwọn tí Nebukadinésárì kó lọ sí ìgbèkùn láti Jerúsálẹ́mù lọ sí Bábílónì,+  lẹ́yìn tí Jekonáyà+ ọba àti ìyáàfin+ àti àwọn òṣìṣẹ́ láàfin, àwọn ọmọ aládé Júdà àti Jerúsálẹ́mù,+ àti àwọn oníṣẹ́ ọnà àti àwọn olùkọ́ odi ààbò+ ti jáde lọ kúrò ní Jerúsálẹ́mù.  Nípa ọwọ́ Élásà ọmọkùnrin Ṣáfánì+ àti Gemaráyà ọmọkùnrin Hilikáyà, ẹni tí Sedekáyà+ ọba Júdà rán sí Bábílónì sí Nebukadinésárì ọba Bábílónì, pé:  “Èyí ni ohun tí Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, wí fún gbogbo ìgbèkùn, àwọn tí mo ti mú kí ó lọ ní ìgbèkùn+ láti Jerúsálẹ́mù sí Bábílónì,  ‘Ẹ kọ́ ilé, kí ẹ sì máa gbé inú wọn, ẹ gbin ọgbà kí ẹ sì máa jẹ èso wọn.+  Ẹ fẹ́ aya kí ẹ sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin;+ ẹ sì fẹ́ aya fún àwọn ọmọkùnrin yín kí ẹ sì fi àwọn ọmọbìnrin yín fún ọkọ, kí wọ́n lè bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin; kí wọ́n sì di púpọ̀ níbẹ̀, kí ẹ má sì kéré níye.  Pẹ̀lúpẹ̀lù, ẹ wá àlàáfíà ìlú ńlá tí mo mú kí a kó yín lọ ní ìgbèkùn, ẹ sì gbàdúrà nítorí rẹ̀ sí Jèhófà, nítorí nínú àlàáfíà rẹ̀, àlàáfíà yóò wà fún ẹ̀yin fúnra yín.+  Nítorí èyí ni ohun tí Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí: “Ẹ má ṣe jẹ́ kí àwọn wòlíì yín tí wọ́n wà láàárín yín àti àwọn woṣẹ́woṣẹ́ yín tàn yín jẹ,+ ẹ má sì fetí sí àlá wọn tí wọ́n ń lá.+  Nítorí ‘nínú èké ni wọ́n ń sọ tẹ́lẹ̀ fún yín ní orúkọ mi. Èmi kò rán wọn,’+ ni àsọjáde Jèhófà.”’” 10  “Nítorí èyí ni ohun tí Jèhófà wí, ‘Ní ìbámu pẹ̀lú lílo àádọ́rin ọdún pé ní Bábílónì,+ èmi yóò yí àfiyèsí mi sí yín, dájúdájú, èmi yóò fìdí ọ̀rọ̀ rere mi múlẹ̀ fún yín, láti mú yín padà wá sí ibí yìí.’+ 11  “‘Nítorí èmi fúnra mi mọ àwọn èrò tí mo ń rò nípa yín ní àmọ̀dunjú,’+ ni àsọjáde Jèhófà, ‘àwọn èrò àlàáfíà, kì í ṣe ti ìyọnu àjálù,+ láti fún yín ní ọjọ́ ọ̀la kan àti ìrètí kan.+ 12  Dájúdájú, ẹ ó sì pè mí, ẹ ó sì wá gbàdúrà sí mi, èmi yóò sì fetí sí yín.’+ 13  “‘Ní ti gidi, ẹ óò wá mi, ẹ ó sì rí mi,+ nítorí ẹ ó fi gbogbo ọkàn-àyà yín wá mi.+ 14  Dájúdájú, èmi yóò sì jẹ́ kí ẹ rí mi,’+ ni àsọjáde Jèhófà. ‘Èmi yóò sì kó ẹgbẹ́ àwọn òǹdè yín jọ, èmi yóò sì kó yín jọpọ̀ láti inú gbogbo orílẹ̀-èdè àti láti inú gbogbo ibi tí mo ti fọ́n yín ká sí,’+ ni àsọjáde Jèhófà. ‘Èmi yóò sí mú yín padà wá sí ibi tí mo ti mú kí ẹ lọ sí ìgbèkùn.’+ 15  “Ṣùgbọ́n ẹ ti wí pé, ‘Jèhófà ti gbé àwọn wòlíì dìde fún wa ní Bábílónì.’ 16  “Nítorí èyí ni ohun tí Jèhófà wí fún ọba tí ó jókòó sórí ìtẹ́ Dáfídì+ àti fún gbogbo àwọn ènìyàn tí ń gbé nínú ìlú ńlá yìí, àwọn arákùnrin yín tí kò jáde lọ pẹ̀lú yín sí ìgbèkùn,+ 17  ‘Èyí ni ohun tí Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wí: “Kíyè sí i, èmi yóò rán idà,+ ìyàn,+ àti àjàkálẹ̀ àrùn+ sí wọn, dájúdájú, èmi yóò ṣe wọ́n bí ọ̀pọ̀tọ́ fífọ́ tí a kò lè jẹ nítorí bí ó ti burú tó.”’+ 18  “‘Dájúdájú, èmi yóò fi idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀ àrùn lépa wọn, èmi yóò sì fi wọ́n fún ìmìtìtì lójú gbogbo ìjọba ilẹ̀ ayé,+ fún ègún àti fún ohun ìyàlẹ́nu àti fún ìsúfèé sí àti fún ẹ̀gàn láàárín gbogbo orílẹ̀-èdè tí èmi yóò fọ́n wọn ká sí,+ 19  nítorí òtítọ́ náà pé wọn kò fetí sí ọ̀rọ̀ mi,’ ni àsọjáde Jèhófà, ‘tí mo fi ránṣẹ́ sí wọn nípasẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ mi wòlíì, tí mo ń dìde ní kùtùkùtù, tí mo sì ń rán wọn.’+ “‘Ṣùgbọ́n ẹ kò fetí sílẹ̀,’+ ni àsọjáde Jèhófà. 20  “Ní tiyín, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà, gbogbo ẹ̀yin ìgbèkùn,+ àwọn tí mo ti rán lọ láti Jerúsálẹ́mù sí Bábílónì.+ 21  Èyí ni ohun tí Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, sọ nípa Áhábù ọmọkùnrin Koláyà àti sí Sedekáyà ọmọkùnrin Maaseáyà, àwọn tí ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ èké fún yín ní orúkọ mi,+ ‘Kíyè sí i, èmi yóò fi wọ́n lé Nebukadirésárì ọba Bábílónì lọ́wọ́, òun yóò sì ṣá wọn balẹ̀ lójú yín.+ 22  Àti láti ọ̀dọ̀ wọn, ó dájú pé ìfiré yóò wáyé lẹ́nu gbogbo ẹgbẹ́ àwọn ìgbèkùn Júdà pátá tí ó wà ní Bábílónì, pé: “Kí Jèhófà ṣe ọ́ bí Sedekáyà àti bí Áhábù,+ tí ọba Bábílónì yan nínú iná!”+ 23  nítorí ìdí náà pé wọ́n ń hu ìwà òpònú ní Ísírẹ́lì,+ wọ́n sì ń ṣe panṣágà ṣáá pẹ̀lú aya alábàákẹ́gbẹ́ wọn,+ wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ èké ní orúkọ mi, ọ̀rọ̀ tí èmi kò pa láṣẹ fún wọn.+ “‘“Èmi sì ni Ẹni tí ó mọ̀, èmi sì ni ẹlẹ́rìí,”+ ni àsọjáde Jèhófà.’” 24  “Ṣemáyà+ ti Néhélámù ni ìwọ yóò sì wí fún pé, 25  ‘Èyí ni ohun tí Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, wí: “Nítorí ìdí náà pé ìwọ fúnra rẹ ti fi àwọn lẹ́tà ránṣẹ́ ní orúkọ+ rẹ sí gbogbo àwọn ènìyàn tí wọ́n wà ní Jerúsálẹ́mù, àti sí Sefanáyà+ ọmọkùnrin Maaseáyà, àlùfáà, àti sí gbogbo àlùfáà, pé, 26  ‘Jèhófà fúnra rẹ̀ ti ṣe ọ́ ní àlùfáà dípò Jèhóádà àlùfáà, láti di alábòójútó títóbi lọ́lá nínú ilé Jèhófà+ fún ènìyàn èyíkéyìí tí ó ya wèrè+ tí ó sì ń hùwà bí wòlíì, kí o sì fi í sínú àbà àti sínú egìran;+ 27  ǹjẹ́ nísinsìnyí, èé ṣe tí ìwọ kò fi bá Jeremáyà ti Ánátótì+ wí lọ́nà mímúná, ẹni tí ó ń ṣe bí wòlíì fún yín?+ 28  Nítorí ìdí nìyẹn tí ó fi ránṣẹ́ sí wa ní Bábílónì, pé: “Ó ti pẹ́ jù! Ẹ kọ́ ilé, kí ẹ sì máa gbé inú wọn, ẹ gbin ọgbà kí ẹ sì máa jẹ èso wọn,+—”’”’” 29  Sefanáyà+ àlùfáà sì bẹ̀rẹ̀ sí ka lẹ́tà yìí ní etí Jeremáyà wòlíì. 30  Lẹ́yìn náà, ọ̀rọ̀ Jèhófà tọ Jeremáyà wá, pé: 31  “Ránṣẹ́ sí gbogbo ìgbèkùn,+ pé, ‘Èyí ni ohun tí Jèhófà wí nípa Ṣemáyà ti Néhélámù: “Nítorí ìdí náà pé Ṣemáyà ti sọ tẹ́lẹ̀ fún yín, ṣùgbọ́n èmi fúnra mi kò rán an, ó sì gbìyànjú láti mú kí ẹ ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú èké,+ 32  nítorí náà, èyí ni ohun tí Jèhófà wí, ‘Kíyè sí i, èmi yóò yí àfiyèsí mi sí Ṣemáyà+ ti Néhélámù àti sí àwọn ọmọ rẹ̀.’+ “‘“‘Òun kì yóò wá ní ọkùnrin kankan tí ń gbé ní àárín àwọn ènìyàn yìí;+ òun kì yóò sì rí ohun rere tí èmi yóò ṣe fún àwọn ènìyàn mi,’+ ni àsọjáde Jèhófà, ‘nítorí ó ti sọ̀rọ̀ ìdìtẹ̀ gbáà lòdì sí Jèhófà.’”’”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé