Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Jeremáyà 28:1-17

28  Ó sì ṣẹlẹ̀ ní ọdún yẹn, ní ìbẹ̀rẹ̀ ìjọba Sedekáyà+ ọba Júdà, ní ọdún kẹrin, ní oṣù karùn-ún, pé Hananáyà+ ọmọkùnrin Ásúrì, wòlíì tí ó wá láti Gíbéónì,+ sọ fún mi ní ilé Jèhófà, lójú àwọn àlùfáà àti lójú àwọn ènìyàn náà pé:  “Èyí ni ohun tí Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí, dájúdájú, ‘èmi yóò ṣẹ́ àjàgà ọba Bábílónì.+  Ní ọdún méjì sí i, gbogbo nǹkan èlò ilé Jèhófà, èyí tí Nebukadinésárì ọba Bábílónì+ kó láti ibí yìí kí ó lè kó wọn lọ sí Bábílónì, ni èmi yóò kó padà wá.’”  “‘Jekonáyà+ ọmọkùnrin Jèhóákímù,+ ọba Júdà, àti gbogbo ìgbèkùn Júdà tí ó wá sí Bábílónì+ ni èmi yóò sì mú padà wá sí ibí yìí,’ ni àsọjáde Jèhófà, ‘nítorí èmi yóò ṣẹ́ àjàgà+ ọba Bábílónì.’”  Jeremáyà wòlíì sì ń bá a lọ láti sọ fún Hananáyà wòlíì lójú àwọn àlùfáà àti lójú gbogbo ènìyàn tí wọ́n dúró ní ilé Jèhófà;+  bẹ́ẹ̀ ni, Jeremáyà wòlíì bẹ̀rẹ̀ sí wí pé: “Àmín!+ Bẹ́ẹ̀ ni kí Jèhófà ṣe! Kí Jèhófà fìdí ọ̀rọ̀ rẹ tí ó ti sọ tẹ́lẹ̀ múlẹ̀ nípa mímú àwọn nǹkan èlò ilé Jèhófà àti gbogbo ìgbèkùn láti Bábílónì padà wá sí ibí yìí!+  Bí ó ti wù kí ó rí, jọ̀wọ́, gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí tí mo ń sọ ní etí rẹ àti ní etí gbogbo ènìyàn.+  Ní ti àwọn wòlíì tí ó wà ṣáájú mi àti ṣáájú rẹ láti ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn,+ àwọn pẹ̀lú a máa sọ tẹ́lẹ̀ nípa ọ̀pọ̀ ilẹ̀ àti nípa àwọn ìjọba ńlá, nípa ogun àti ìyọnu àjálù àti àjàkálẹ̀ àrùn.+  Ní ti wòlíì tí ó bá sọ tẹ́lẹ̀ nípa àlàáfíà,+ nígbà tí ọ̀rọ̀ wòlíì yẹn bá ṣẹ, wòlíì tí Jèhófà rán ní tòótọ́ yóò di mímọ̀.”+ 10  Látàrí ìyẹn, Hananáyà wòlíì mú ọ̀pá àjàgà náà kúrò ní ọrùn Jeremáyà wòlíì, ó sì ṣẹ́ ẹ.+ 11  Hananáyà+ sì ń bá a lọ láti sọ lójú gbogbo àwọn ènìyàn náà pé: “Èyí ni ohun tí Jèhófà wí,+ ‘Báyìí gan-an ni èmi yóò ṣẹ́ àjàgà Nebukadinésárì ọba Bábílónì láàárín ọdún méjì gbáko sí i kúrò ní ọrùn gbogbo orílẹ̀-èdè.’”+ Jeremáyà wòlíì sì bá ọ̀nà rẹ̀ lọ.+ 12  Lẹ́yìn náà, ọ̀rọ̀ Jèhófà tọ Jeremáyà wá,+ lẹ́yìn tí Hananáyà wòlíì ti ṣẹ́ ọ̀pá àjàgà kúrò ní ọrùn Jeremáyà wòlíì, pé: 13  “Lọ, kí o sì wí fún Hananáyà pé, ‘Èyí ni ohun tí Jèhófà wí: “Ọ̀pá àjàgà+ igi ni o ṣẹ́, dípò rẹ̀ kí o ṣe ọ̀pá àjàgà irin.”+ 14  Nítorí èyí ni ohun tí Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, wí: “Àjàgà irin ni èmi yóò fi sí ọrùn gbogbo orílẹ̀-èdè wọ̀nyí, láti sin Nebukadinésárì ọba Bábílónì;+ wọn yóò sì sìn ín.+ Àní àwọn ẹranko inú pápá ni èmi yóò fi fún un.”’”+ 15  Jeremáyà wòlíì sì ń bá a lọ láti sọ fún Hananáyà+ wòlíì pé: “Jọ̀wọ́, fetí sílẹ̀, ìwọ Hananáyà! Jèhófà kò rán ọ, ṣùgbọ́n ìwọ fúnra rẹ ti mú kí àwọn ènìyàn yìí ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú èké.+ 16  Nítorí náà, èyí ni ohun tí Jèhófà wí, ‘Wò ó! Èmi yóò rán ọ lọ kúrò lórí ilẹ̀. Ní ọdún yìí ni ìwọ yóò kú,+ nítorí ìwọ ti sọ ìdìtẹ̀ gbáà lòdì sí Jèhófà.’”+ 17  Bẹ́ẹ̀ ni Hananáyà wòlíì kú ní ọdún yẹn, ní oṣù keje.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé