Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Jeremáyà 27:1-22

27  Ní ìbẹ̀rẹ̀ ìjọba Jèhóákímù ọmọkùnrin Jòsáyà,+ ọba Júdà, ọ̀rọ̀ yìí tọ Jeremáyà wá láti ọ̀dọ̀ Jèhófà, pé:  “Èyí ni ohun tí Jèhófà wí fún mi, ‘Ṣe àwọn ọ̀já àti àwọn ọ̀pá àjàgà fún ara rẹ,+ kí o sì fi wọ́n sí ọrùn rẹ.+  Kí o sì fi wọ́n ránṣẹ́ sí ọba Édómù+ àti sí ọba Móábù+ àti sí ọba àwọn ọmọ Ámónì+ àti sí ọba Tírè+ àti sí ọba Sídónì+ nípa ọwọ́ àwọn ońṣẹ́ tí ń bọ̀ ní Jerúsálẹ́mù sọ́dọ̀ Sedekáyà ọba Júdà.  Kí o sì pàṣẹ fún wọn pé kí wọ́n jíṣẹ́ fún àwọn ọ̀gá wọn, pé: “‘“Èyí ni ohun tí Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì+ wí; èyí ni ohun tí ẹ óò sọ fún àwọn ọ̀gá yín,  ‘Èmi ni mo ṣe ilẹ̀ ayé,+ aráyé+ àti àwọn ẹranko+ tí ó wà lórí ilẹ̀ nípasẹ̀ agbára ńlá mi+ àti nípasẹ̀ apá mi nínà jáde;+ mo sì ti fi fún ẹni tí ó tọ́ ní ojú mi.+  Wàyí o, èmi fúnra mi ti fi gbogbo ilẹ̀ yìí lé ọwọ́ Nebukadinésárì ọba Bábílónì,+ ìránṣẹ́ mi;+ àní àwọn ẹranko inú pápá ni mo ti fi fún un láti máa sìn ín.+  Gbogbo orílẹ̀-èdè sì ní láti máa sin òun pàápàá+ àti ọmọ rẹ̀ àti ọmọ-ọmọ rẹ̀, títí àkókò ilẹ̀ tirẹ̀ pàápàá yóò fi dé,+ ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè àti àwọn ọba ńláńlá yóò sì lò ó bí ìránṣẹ́.’+  “‘“‘Yóò sì ṣẹlẹ̀ pé, orílẹ̀-èdè àti ìjọba tí kò bá sìn ín, àní Nebukadinésárì ọba Bábílónì; àti ẹni náà tí kò bá fi ọrùn rẹ̀ sábẹ́ àjàgà ọba Bábílónì, èmi yóò yí àfiyèsí mi sára orílẹ̀-èdè yẹn pẹ̀lú idà+ àti pẹ̀lú ìyàn+ àti pẹ̀lú àjàkálẹ̀ àrùn,’+ ni àsọjáde Jèhófà, ‘títí èmi yóò fi pa wọ́n rẹ́ nípa ọwọ́ rẹ̀.’+  “‘“‘Ní tiyín, ẹ má fetí sí àwọn wòlíì+ yín àti sí àwọn woṣẹ́woṣẹ́ yín àti sí àwọn alálàá+ yín àti sí àwọn pidánpidán yín àti sí àwọn oníṣẹ́ oṣó+ yín, àwọn tí ń sọ fún yín pé: “Ẹ kò ní sin ọba Bábílónì.”+ 10  Nítorí èké ni wọ́n ń sọ ní àsọtẹ́lẹ̀ fún yín, fún ète mímú yín lọ jìnnà réré kúrò lórí ilẹ̀ yín; dájúdájú, èmi yóò fọ́n yín ká, ṣíṣègbé ni ẹ óò sì ṣègbé.+ 11  “‘“‘Àti ní ti orílẹ̀-èdè tí ó bá mú ọrùn rẹ̀ wá sábẹ́ àjàgà ọba Bábílónì tí ó sì sìn ín ní ti gidi, èmi yóò jẹ́ kí ó sinmi lórí ilẹ̀ rẹ̀ pẹ̀lú,’ ni àsọjáde Jèhófà, ‘yóò sì ro ó, dájúdájú, yóò sì máa gbé inú rẹ̀.’”’”+ 12  Sedekáyà+ ọba Júdà pàápàá ni mo bá sọ̀rọ̀ ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí,+ pé: “Mú ọrùn rẹ wá sábẹ́ àjàgà ọba Bábílónì, kí o sì sin òun àti àwọn ènìyàn rẹ̀, kí o sì máa wà láàyè.+ 13  Èé ṣe tí ìwọ fúnra rẹ àti àwọn ènìyàn rẹ yóò fi kú nípasẹ̀ idà,+ nípasẹ̀ ìyàn+ àti nípasẹ̀ àjàkálẹ̀ àrùn+ gẹ́gẹ́ bí ohun tí Jèhófà sọ sí àwọn orílẹ̀-èdè tí kò sin ọba Bábílónì? 14  Má sì fetí sí ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì tí ń sọ fún yín pé, ‘Ẹ kò ní sin ọba Bábílónì,’+ nítorí èké ni wọ́n ń sọ ní àsọtẹ́lẹ̀ fún yín.+ 15  “‘Nítorí èmi kò rán wọn,’ ni àsọjáde Jèhófà, ‘ṣùgbọ́n wọ́n ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ èké ní orúkọ mi, kí èmi lè fọ́n yín ká,+ ẹ óò sì ṣègbé,+ ẹ̀yin àti àwọn wòlíì tí ń sọ tẹ́lẹ̀ fún yín.’”+ 16  Àwọn àlùfáà àti gbogbo àwọn ènìyàn yìí ni mo bá sọ̀rọ̀, pé: “Èyí ni ohun tí Jèhófà wí, ‘Ẹ má fetí sí ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì yín tí ń sọ tẹ́lẹ̀ fún yín, pé: “Wò ó! Àwọn nǹkan èlò ilé Jèhófà ni a óò kó padà láti Bábílónì ní àìpẹ́ sí ìsinsìnyí!”+ Nítorí èké ni wọ́n ń sọ ní àsọtẹ́lẹ̀ fún yín.+ 17  Ẹ má fetí sí wọn. Ẹ sin ọba Bábílónì kí ẹ sì máa wà láàyè.+ Èé ṣe tí ìlú ńlá yìí yóò fi di ibi ìparundahoro?+ 18  Ṣùgbọ́n bí wọ́n bá jẹ́ wòlíì, tí ọ̀rọ̀ Jèhófà sì wà pẹ̀lú wọn, kí wọ́n jọ̀wọ́ fi taratara bẹ Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun,+ kí àwọn nǹkan èlò tí ó ṣẹ́ kù sílẹ̀ ní ilé Jèhófà àti ní ilé ọba Júdà àti ní Jerúsálẹ́mù má ṣe wá sí Bábílónì.’ 19  “Nítorí èyí ni ohun tí Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wí nípa àwọn ọwọ̀n+ àti nípa òkun+ àti àwọn kẹ̀kẹ́ ẹrù+ àti nípa ìyókù nǹkan èlò tí ó ṣẹ́ kù sílẹ̀ nínú ìlú ńlá yìí,+ 20  tí Nebukadinésárì ọba Bábílónì kò kó nígbà tí ó mú Jekonáyà+ ọmọkùnrin Jèhóákímù, ọba Júdà, lọ ní ìgbèkùn, láti Jerúsálẹ́mù lọ sí Bábílónì, pa pọ̀ pẹ̀lú gbogbo ọ̀tọ̀kùlú Júdà àti Jerúsálẹ́mù;+ 21  nítorí èyí ni ohun tí Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, wí nípa àwọn nǹkan èlò tí ó ṣẹ́ kù sílẹ̀ ní ilé Jèhófà àti ní ilé ọba Júdà àti Jerúsálẹ́mù,+ 22  ‘“Bábílónì ni a óò kó wọn wá,+ ibẹ̀ sì ni wọn yóò máa wà nìṣó títí di ọjọ́ tí èmi yóò yí àfiyèsí mi sí wọn,”+ ni àsọjáde Jèhófà. “Dájúdájú, èmi yóò mú wọn gòkè wá, èmi yóò sì mú wọn padà bọ̀ sí ibí yìí.”’”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé