Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Jeremáyà 26:1-24

26  Ní ìbẹ̀rẹ̀ ìṣàkóso ọba Jèhóákímù+ ọmọkùnrin Jòsáyà, ọba Júdà, ọ̀rọ̀ yìí wá láti ọ̀dọ̀ Jèhófà, pé:  “Èyí ni ohun tí Jèhófà wí, ‘Dúró nínú àgbàlá ilé Jèhófà,+ kí o sì sọ̀rọ̀ nípa gbogbo ìlú ńlá Júdà tí ń wọlé láti tẹrí ba ní ilé Jèhófà, gbogbo ọ̀rọ̀ tí èmi yóò pa láṣẹ fún ọ láti sọ fún wọn.+ Má ṣe mú ọ̀rọ̀ kankan kúrò.+  Bóyá wọn yóò fetí sílẹ̀ kí olúkúlùkù wọn sì padà ní ọ̀nà búburú rẹ̀,+ dájúdájú, èmi yóò sì pèrò dà ní ti ìyọnu àjálù tí mo ń rò láti mú ṣẹ ní kíkún sórí wọn nítorí búburú ìbálò wọn.+  Kí o sì wí fún wọn pé: “Èyí ni ohun tí Jèhófà wí, ‘Bí ẹ kò bá ní fetí sí mi nípa rírìn nínú òfin mi+ tí mo ti fi síwájú yín,+  nípa fífetí sí ọ̀rọ̀ àwọn ìránṣẹ́ mi wòlíì, tí mo ń rán sí yín, àní tí mo ń dìde ní kùtùkùtù, tí mo sì ń rán wọn, àwọn tí ẹ kò fetí sí,+  Ṣe ni èmi, ẹ̀wẹ̀, yóò ṣe ilé yìí bí èyí tí ó wà ní Ṣílò,+ èmi yóò sì ṣe ìlú ńlá yìí ní ìfiré sí gbogbo orílẹ̀-èdè ilẹ̀ ayé.’”’”+  Àwọn àlùfáà àti àwọn wòlíì àti gbogbo ènìyàn náà sì bẹ̀rẹ̀ sí gbọ́ tí Jeremáyà ń sọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ní ilé Jèhófà.+  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, nígbà tí Jeremáyà parí sísọ gbogbo ohun tí Jèhófà pa láṣẹ pé kí ó sọ fún gbogbo àwọn ènìyàn náà, nígbà náà ni àwọn àlùfáà àti àwọn wòlíì àti gbogbo àwọn ènìyàn náà gbá a mú, wọ́n wí pé: “Dájúdájú, ìwọ yóò kú.+  Èé ṣe tí o fi sọ tẹ́lẹ̀ ní orúkọ Jèhófà, pé, ‘Bí èyí tí ó wà ní Ṣílò+ ni ilé yìí yóò dà, ìlú ńlá yìí gan-an yóò sì pa run di ahoro tí kò fi ní sí olùgbé’?” Gbogbo àwọn ènìyàn náà sì ń péjọ pọ̀ yí Jeremáyà ká ní ilé Jèhófà. 10  Nígbà tí ó ṣe, àwọn ọmọ aládé Júdà wá gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí gòkè wá láti ilé ọba sí ilé Jèhófà,+ wọ́n sì jókòó ní ibi àtiwọ ẹnubodè tuntun ti Jèhófà.+ 11  Àwọn àlùfáà àti àwọn wòlíì sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún àwọn ọmọ aládé àti fún gbogbo àwọn ènìyàn náà pé: “Ìdájọ́ ikú tọ́ sí ọkùnrin yìí,+ nítorí ó sọ tẹ́lẹ̀ nípa ìlú ńlá yìí, gan-an gẹ́gẹ́ bí ẹ ti fi etí ara yín gbọ́ ọ.”+ 12  Látàrí ìyẹn, Jeremáyà sọ fún gbogbo ọmọ aládé àti fún gbogbo àwọn ènìyàn náà pé: “Jèhófà ni ó rán mi láti sọ tẹ́lẹ̀ nípa ilé yìí àti nípa ìlú ńlá yìí, gbogbo ọ̀rọ̀ tí ẹ ti gbọ́.+ 13  Wàyí o, ẹ ṣe ọ̀nà yín àti ìbálò yín ní rere,+ ẹ sì ṣègbọràn sí ohùn Jèhófà Ọlọ́run yín, Jèhófà yóò sì pèrò dà ní ti ìyọnu àjálù tí ó ti sọ lòdì sí yín.+ 14  Ní tèmi, èmi rèé ní ọwọ́ yín.+ Ẹ ṣe sí mi gẹ́gẹ́ bí ohun tí ó dára àti gẹ́gẹ́ bí ohun tí ó tọ́ ní ojú yín.+ 15  Kìkì kí ẹ mọ̀ dájú pé, bí ẹ bá fi ikú pa mí, ẹ̀jẹ̀ aláìmọwọ́-mẹsẹ̀ ni ẹ mú wá sórí ara yín àti sórí ìlú ńlá yìí àti sórí àwọn olùgbé rẹ̀,+ nítorí lóòótọ́ ni Jèhófà rán mi sí yín pé kí n sọ gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ní etí yín.”+ 16  Nígbà náà ni àwọn ọmọ aládé+ àti gbogbo àwọn ènìyàn náà sọ fún àwọn àlùfáà àti fún àwọn wòlíì pé: “Ìdájọ́ ikú kò tọ́ sí ọkùnrin yìí,+ nítorí ó bá wa sọ̀rọ̀ ní orúkọ Jèhófà Ọlọ́run wa.”+ 17  Síwájú sí i, àwọn kan lára àwọn àgbà ọkùnrin ilẹ̀ náà dìde, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún gbogbo ìjọ àwọn ènìyàn náà pé:+ 18  “Ó ṣẹlẹ̀ pé, Míkà+ ti Móréṣétì+ pàápàá ń sọ tẹ́lẹ̀ ní ọjọ́ Hesekáyà ọba Júdà,+ ó sì ń bá a lọ láti sọ fún gbogbo ènìyàn Júdà pé, ‘Èyí ni ohun tí Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wí: “Síónì ni a ó túlẹ̀ rẹ̀ bí pápá lásán-làsàn,+ Jerúsálẹ́mù pàápàá yóò sì di òkìtì àwókù lásán-làsàn,+ òkè ńlá Ilé náà yóò sì wà fún àwọn ibi gíga igbó.”’+ 19  Hesekáyà ọba Júdà, àti gbogbo àwọn ti Júdà ha fi ikú pa á rárá bí? Òun kò ha bẹ̀rù Jèhófà tí ó sì tẹ̀ síwájú láti tu Jèhófà lójú,+ tí Jèhófà fi pèrò dà ní ti ìyọnu àjálù tí ó ti sọ lòdì sí wọn?+ Nítorí náà, a ń fa ìyọnu àjálù ńláǹlà lẹ́sẹ̀ lòdì sí ọkàn wa.+ 20  “Ọkùnrin kan báyìí sì tún wà tí ó ń sọ tẹ́lẹ̀ ní orúkọ Jèhófà, Úríjà ọmọkùnrin Ṣemáyà láti Kiriati-jéárímù ni.+ Ó sì ń sọ tẹ́lẹ̀ ṣáá lòdì sí ìlú ńlá yìí àti lòdì sí ilẹ̀ yìí ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo ọ̀rọ̀ Jeremáyà. 21  Jèhóákímù+ Ọba àti gbogbo àwọn ọkùnrin alágbára ńlá rẹ̀ àti gbogbo ọmọ aládé sì wá gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀, ọba sì bẹ̀rẹ̀ sí wá ọ̀nà láti fi ikú pa á.+ Nígbà tí Úríjà wá gbọ́ nípa rẹ̀, lójú-ẹsẹ̀, àyà fò ó,+ ó fẹsẹ̀ fẹ, ó sì wá sí Íjíbítì. 22  Ṣùgbọ́n Jèhóákímù Ọba rán àwọn ọkùnrin lọ sí Íjíbítì, Élínátánì ọmọkùnrin Ákíbórì+ àti àwọn ọkùnrin mìíràn pẹ̀lú rẹ̀ lọ sí Íjíbítì. 23  Wọ́n sì ń bá a lọ láti mú Úríjà jáde kúrò ní Íjíbítì, wọ́n sì mú un wá sọ́dọ̀ Jèhóákímù Ọba, ẹni tí ó fi idà ṣá a balẹ̀,+ tí ó sì gbé òkú rẹ̀ jù sínú itẹ́ òkú ọmọ àwọn ènìyàn náà.” 24  Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ọwọ́ Áhíkámù+ ọmọkùnrin Ṣáfánì+ ni ó wà pẹ̀lú Jeremáyà, kí a má bàa fi í lé àwọn ènìyàn náà lọ́wọ́ láti ṣe ikú pa á.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé