Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Jeremáyà 25:1-38

25  Ọ̀rọ̀ tí ó tọ Jeremáyà wá nípa gbogbo àwọn ènìyàn Júdà ní ọdún kẹrin Jèhóákímù+ ọmọkùnrin Jòsáyà, ọba Júdà, èyíinì ni, ọdún kìíní Nebukadirésárì ọba Bábílónì;  èyí tí Jeremáyà wòlíì sọ nípa gbogbo àwọn ènìyàn Júdà àti nípa gbogbo àwọn olùgbé Jerúsálẹ́mù, pé:  “Láti ọdún kẹtàlá Jòsáyà+ ọmọkùnrin Ámọ́nì, ọba Júdà, títí di òní yìí, ọdún mẹ́tàlélógún yìí, ọ̀rọ̀ Jèhófà ti tọ̀ mí wá, mo sì ń bá yín sọ̀rọ̀ ṣáá, mo ń dìde ní kùtùkùtù, mo sì ń sọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n ẹ kò fetí sílẹ̀.+  Jèhófà sì rán gbogbo ìránṣẹ́ rẹ̀, àwọn wòlíì sí yín, ó ń dìde ní kùtùkùtù, ó sì ń rán wọn, ṣùgbọ́n ẹ kò fetí sílẹ̀,+ bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò dẹ etí yín sílẹ̀ láti fetí sílẹ̀,+  wọ́n ń wí pé, ‘Ẹ jọ̀wọ́, ẹ yí padà, olúkúlùkù kúrò nínú ọ̀nà búburú rẹ̀ àti kúrò nínú ìbálò búburú yín,+ kí ẹ sì máa gbé lórí ilẹ̀ tí Jèhófà fi fún ẹ̀yin àti àwọn baba ńlá yín láti ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn àti títí dé àkókò gígùn tí ń bẹ níwájú.+  Ẹ má sì tọ àwọn ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn láti sìn wọ́n àti láti tẹrí ba fún wọn, kí ẹ má bàa fi iṣẹ́ ọwọ́ yín mú mi bínú, kí n má sì mú ìyọnu àjálù wá bá yín.’+  “‘Ṣùgbọ́n ẹ kò fetí sí mi,’ ni àsọjáde Jèhófà, ‘fún ète fífi iṣẹ́ ọwọ́ yín mú mi bínú, sí ìyọnu àjálù yín.’+  “Nítorí náà, èyí ni ohun tí Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wí, ‘“Nítorí ìdí náà pé ẹ kò ṣègbọràn sí àwọn ọ̀rọ̀ mi,  kíyè sí i, èmi yóò ránṣẹ́, dájúdájú, èmi yóò mú gbogbo ìdílé àríwá,”+ ni àsọjáde Jèhófà, “àní èmi yóò ránṣẹ́ sí Nebukadirésárì ọba Bábílónì, ìránṣẹ́ mi,+ ṣe ni èmi yóò mú wọn wá láti gbéjà ko ilẹ̀ yìí,+ àti láti gbéjà ko àwọn olùgbé rẹ̀ àti láti gbéjà ko gbogbo orílẹ̀-èdè wọ̀nyí tí ó yí i ká;+ dájúdájú, èmi yóò yà wọ́n sọ́tọ̀ fún ìparun, èmi yóò sì sọ wọ́n di ohun ìyàlẹ́nu àti ohun ìsúfèé+ sí àti ibi ìparundahoro fún àkókò tí ó lọ kánrin.+ 10  Ìró ayọ̀ ńláǹlà àti ìró ayọ̀ yíyọ̀,+ ohùn ọkọ ìyàwó àti ohùn ìyàwó,+ ìró ọlọ ọlọ́wọ́+ àti ìmọ́lẹ̀ fìtílà sì ni èmi yóò pa run kúrò nínú wọn.+ 11  Gbogbo ilẹ̀ yìí yóò sì di ibi ìparundahoro, ohun ìyàlẹ́nu, orílẹ̀-èdè wọ̀nyí yóò sì ní láti sin ọba Bábílónì fún àádọ́rin ọdún.”’+ 12  “‘Yóò sì wá ṣẹlẹ̀ pé, nígbà tí àádọ́rin ọdún bá ti pé,+ èmi yóò béèrè fún ìjíhìn lọ́wọ́ ọba Bábílónì àti lọ́wọ́ orílẹ̀-èdè yẹn,’+ ni àsọjáde Jèhófà, ‘ní ti ìṣìnà wọn, àní lòdì sí ilẹ̀ àwọn ará Kálídíà,+ ṣe ni èmi yóò sọ ọ́ di ahoro fún àkókò tí ó lọ kánrin.+ 13  Dájúdájú, èmi yóò sì mú gbogbo ọ̀rọ̀ mi tí mo sọ lòdì sí ilẹ̀ yẹn wá sórí rẹ̀, àní gbogbo ohun tí a kọ sínú ìwé yìí tí Jeremáyà ti sọ tẹ́lẹ̀ lòdì sí gbogbo orílẹ̀-èdè.+ 14  Nítorí àwọn fúnra wọn pàápàá, ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè àti àwọn ọba ńláńlá,+ ti kó wọn nífà bí ìránṣẹ́;+ dájúdájú, èmi yóò san án padà fún wọn gẹ́gẹ́ bí ìgbòkègbodò wọn àti gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọwọ́ wọn.’”+ 15  Nítorí èyí ni ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí fún mi: “Gba ife wáìnì ìhónú yìí ní ọwọ́ mi, kí o sì mú kí gbogbo orílẹ̀-èdè tí èmi yóò rán ọ sí mu ún.+ 16  Wọn yóò sì mu, wọn yóò sì mì síwá-sẹ́yìn, wọn yóò sì ṣe bí ayírí nítorí idà tí èmi yóò rán sáàárín wọn.”+ 17  Mo sì ń bá a lọ láti gba ife náà ní ọwọ́ Jèhófà, mo sì mú kí gbogbo orílẹ̀-èdè tí Jèhófà rán mi sí mu ún:+ 18  èyíinì ni, Jerúsálẹ́mù àti àwọn ìlú ńlá Júdà àti àwọn ọba rẹ̀, àwọn ọmọ aládé rẹ̀, láti sọ wọ́n di ibi ìparundahoro, ohun ìyàlẹ́nu,+ ohun ìsúfèé sí àti ìfiré, gan-an bí ó ti rí ní òní yìí;+ 19  Fáráò, ọba Íjíbítì àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ àti àwọn ọmọ aládé rẹ̀ àti gbogbo ènìyàn rẹ̀;+ 20  àti gbogbo àwùjọ onírúurú ènìyàn, àti gbogbo ọba ilẹ̀ Úsì,+ àti gbogbo ọba ilẹ̀ Filísínì+ àti Áṣíkẹ́lónì+ àti Gásà+ àti Ékírónì+ àti àṣẹ́kù Áṣídódì;+ 21  Édómù+ àti Móábù+ àti àwọn ọmọkùnrin Ámónì;+ 22  àti gbogbo ọba Tírè+ àti gbogbo ọba Sídónì+ àti àwọn ọba erékùṣù tí ó wà ní ẹkùn ilẹ̀ òkun; 23  àti Dédánì+ àti Témà+ àti Búsì àti gbogbo àwọn tí ó gé irun wọn mọ́lẹ̀ ní ẹ̀bátí;+ 24  àti gbogbo ọba àwọn ará Arébíà+ àti gbogbo ọba àwùjọ onírúurú ènìyàn tí ń gbé ní aginjù; 25  àti gbogbo ọba Símírì àti gbogbo ọba Élámù+ àti gbogbo ọba àwọn ará Mídíà;+ 26  àti gbogbo ọba àríwá tí ó wà nítòsí àti àwọn tí ó jìnnà réré, ọ̀kan tẹ̀ lé èkejì, àti gbogbo ìjọba yòókù ní ilẹ̀ ayé, àwọn tí ó wà lórí ilẹ̀; ọba Ṣéṣákì+ alára yóò mu lẹ́yìn wọn. 27  “Ìwọ yóò sì wí fún wọn pé, ‘Èyí ni ohun tí Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, wí: “Ẹ mu, ẹ sì mu àmupara, kí ẹ sì bì, kí ẹ sì ṣubú, tí ẹ kò fi ní lè dìde+ nítorí idà tí èmi yóò rán sáàárín yín.”’+ 28  Yóò sì ṣẹlẹ̀ pé, bí wọ́n bá kọ̀ láti gba ife náà ní ọwọ́ rẹ láti mu, kí o sọ fún wọn pẹ̀lú pé, ‘Èyí ni ohun tí Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wí: “Láìkùnà, ẹ ó mu.+ 29  Nítorí, wò ó! orí ìlú ńlá tí a fi orúkọ mi pè ni èmi yóò ti bẹ̀rẹ̀ mímú ìyọnu àjálù wá,+ ẹ̀yin fúnra yín yóò ha sì lọ lọ́nàkọnà láìfaragba ìyà?”’+ “‘Ẹ kì yóò lọ láìfaragba ìyà, nítorí idà kan wà tí èmi yóò pè wá sórí gbogbo àwọn olùgbé ilẹ̀ ayé,’ ni àsọjáde Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun. 30  “Ní tìrẹ, ìwọ yóò sọ àsọtẹ́lẹ̀ gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fún wọn, ìwọ yóò sì wí fún wọn pé, ‘Láti ibi gíga lókè ni Jèhófà fúnra rẹ̀ yóò ti ké ramúramù,+ àti láti ibùgbé rẹ̀ mímọ́ ni yóò ti fọ ohùn rẹ̀ jáde.+ Láìkùnà, òun yóò ké ramúramù sórí ibi gbígbé rẹ̀. Igbe bí ti àwọn tí ń tẹ ìfúntí wáìnì ni òun yóò kọ lórin lòdì sí gbogbo àwọn olùgbé ilẹ̀ ayé.’+ 31  “‘Dájúdájú, ariwo kan yóò dún títí lọ dé ibi jíjìnnà jù lọ ní ilẹ̀ ayé, nítorí ìjà kan wà tí Jèhófà ní pẹ̀lú àwọn orílẹ̀-èdè.+ Òun alára yóò wọnú ìdájọ́ pẹ̀lú gbogbo ẹran ara.+ Ní ti àwọn ẹni burúkú, òun yóò fi wọ́n fún idà,’+ ni àsọjáde Jèhófà. 32  “Èyí ni ohun tí Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wí, ‘Wò ó! Ìyọnu àjálù kan ń jáde lọ láti orílẹ̀-èdè dé orílẹ̀-èdè,+ ìjì líle sì ni a ó ru dìde láti apá jíjìnnàréré jù lọ ní ilẹ̀ ayé.+ 33  Àwọn tí Jèhófà pa yóò sì wà dájúdájú ní ọjọ́ yẹn láti ìpẹ̀kun kan ilẹ̀ ayé títí lọ dé ìpẹ̀kun kejì ilẹ̀ ayé.+ A kì yóò pohùn réré ẹkún nítorí wọn, bẹ́ẹ̀ ni a kì yóò kó wọn jọpọ̀ tàbí kí a sin wọ́n.+ Bí ajílẹ̀ lórí ilẹ̀ ni wọn yóò dà.’+ 34  “Ẹ hu, ẹ̀yin olùṣọ́ àgùntàn, kí ẹ sì ké jáde!+ Ẹ yíràá,+ ẹ̀yin ọlọ́lá ọba inú agbo ẹran,+ nítorí ọjọ́ pípa yín àti títú yín ká ti pé,+ ẹ ó sì já bọ́ bí ohun èlò fífani-lọ́kàn-mọ́ra!+ 35  Ibi ìsásí sì ti ṣègbé fún àwọn olùṣọ́ àgùntàn, ọ̀nà àsálà sì ti ṣègbé fún àwọn ọlọ́lá ọba nínú agbo ẹran.+ 36  Fetí sílẹ̀! Igbe ẹkún àwọn olùṣọ́ àgùntàn, àti híhu àwọn ọlọ́lá ọba nínú agbo ẹran, nítorí Jèhófà ń fi pápá ìjẹko wọn ṣe ìjẹ. 37  Ibi gbígbé tí ó kún fún àlàáfíà sì ti di aláìlẹ́mìí nítorí ìbínú jíjófòfò Jèhófà.+ 38  Ó ti fi ibi kọ́lọ́fín rẹ̀ sílẹ̀ bí ẹgbọrọ kìnnìún onígọ̀gọ̀,+ nítorí ilẹ̀ wọn ti di ohun ìyàlẹ́nu nítorí idà tí ń hanni léèmọ̀ àti nítorí ìbínú rẹ̀ jíjófòfò.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé