Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Jeremáyà 24:1-10

24  Jèhófà sì fi hàn mí, sì wò ó! apẹ̀rẹ̀ méjì tí ọ̀pọ̀tọ́ wà nínú wọn ni a gbé kalẹ̀ níwájú tẹ́ńpìlì Jèhófà, lẹ́yìn tí Nebukadirésárì ọba Bábílónì ti mú Jekonáyà+ ọmọkùnrin Jèhóákímù,+ ọba Júdà lọ sí ìgbèkùn àti àwọn ọmọ aládé Júdà àti àwọn oníṣẹ́ ọnà+ àti àwọn olùkọ́ odi ààbò, láti Jerúsálẹ́mù, kí ó lè kó wọn wá sí Bábílónì.+  Ní ti apẹ̀rẹ̀ kìíní, àwọn ọ̀pọ̀tọ́ inú rẹ̀ dára gan-an, bí ọ̀pọ̀tọ́ àkọ́pọ́n;+ àti ní ti apẹ̀rẹ̀ kejì, àwọn ọ̀pọ̀tọ́ inú rẹ̀ burú gan-an, tí a kò fi lè jẹ wọ́n nítorí bí wọ́n ti burú tó.  Jèhófà sì ń bá a lọ láti wí fún mi pé: “Kí ni ìwọ rí, Jeremáyà?” Nítorí náà, mo wí pé: “Àwọn ọ̀pọ̀tọ́, àwọn ọ̀pọ̀tọ́ tí ó dára náà dára gan-an, àwọn tí ó sì burú náà burú gan-an, tí a kò fi lè jẹ wọ́n nítorí bí wọ́n ti burú tó.”+  Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Jèhófà tọ̀ mí wá, pé:  “Èyí ni ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí, ‘Bí ọ̀pọ̀tọ́ dáradára wọ̀nyí, bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò sì fi ojú rere wo àwọn ìgbèkùn Júdà, àwọn tí èmi yóò rán lọ kúrò ní ibí yìí sí ilẹ̀ àwọn ará Kálídíà,+ lọ́nà rere.+  Èmi yóò sì gbé ojú mi lé wọn lọ́nà rere,+ dájúdájú, èmi yóò sì mú wọn padà sí ilẹ̀ yìí.+ Èmi yóò sì gbé wọn ró, èmi kì yóò sì ya wọ́n lulẹ̀; èmi yóò sì gbìn wọ́n, èmi kì yóò sì fà wọ́n tu.+  Dájúdájú, èmi yóò sì fún wọn ní ọkàn-àyà láti mọ̀ mí,+ pé èmi ni Jèhófà; wọn yóò sì di ènìyàn mi,+ èmi fúnra mi yóò sì di Ọlọ́run wọn, nítorí wọn yóò fi gbogbo ọkàn-àyà wọn padà sọ́dọ̀ mi.+  “‘Àti bí ọ̀pọ̀tọ́ tí ó burú tí a kò lè jẹ nítorí bí wọ́n ti burú tó,+ èyí ní ti tòótọ́ ni ohun tí Jèhófà wí: “Bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò ṣe fi Sedekáyà+ ọba Júdà àti àwọn ọmọ aládé rẹ̀ àti àwọn àṣẹ́kù Jerúsálẹ́mù tí wọ́n ṣẹ́ kù ní ilẹ̀ yìí+ àti àwọn tí ń gbé ní ilẹ̀ Íjíbítì+  dájúdájú, èmi yóò fi wọ́n fún ìmìtìtì pẹ̀lú, fún ìyọnu àjálù, ní gbogbo ìjọba ilẹ̀ ayé,+ fún ẹ̀gàn àti fún ọ̀rọ̀ òwe, fún ìṣáátá+ àti fún ìfiré,+ ní gbogbo ibi tí èmi yóò fọ́n wọn ká sí.+ 10  Dájúdájú, èmi yóò rán idà,+ ìyàn+ àti àjàkálẹ̀ àrùn sí wọn,+ títí wọn yóò fi wá sí òpin wọn kúrò ní ilẹ̀ tí mo fi fún àwọn àti àwọn baba ńlá wọn.”’”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé