Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Jeremáyà 23:1-40

23  “Ègbé ni fún àwọn olùṣọ́ àgùntàn tí wọ́n ń pa àwọn àgùntàn pápá ìjẹko mi run, tí wọ́n sì ń tú wọn ká!”+ ni àsọjáde Jèhófà.  Nítorí náà, èyí ni ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí lòdì sí àwọn olùṣọ́ àgùntàn tí wọ́n ń ṣe olùṣọ́ àgùntàn àwọn ènìyàn mi: “Ẹ̀yin fúnra yín ti tú àwọn àgùntàn mi ká; ẹ sì ń fọ́n wọn ká ṣáá, ẹ kò sì yí àfiyèsí yín sí wọn.”+ “Kíyè sí i, èmi yóò yí àfiyèsí mi sí yín nítorí búburú ìbálò yín,”+ ni àsọjáde Jèhófà.  “Èmi fúnra mi yóò sì kó àṣẹ́kù àgùntàn mi jọpọ̀ láti gbogbo ilẹ̀ tí mo ti fọ́n wọn ká sí,+ ṣe ni èmi yóò mú wọn padà wá sí ilẹ̀ ìjẹko wọn,+ dájúdájú, wọn yóò sì máa so èso, wọn yóò sì di púpọ̀.+  Ṣe ni èmi yóò sì gbé àwọn olùṣọ́ àgùntàn dìde lórí wọn tí yóò ṣe olùṣọ́ àgùntàn wọn ní ti gidi;+ wọn kì yóò sì fòyà mọ́, bẹ́ẹ̀ ni ìpayà kankan kì yóò bá wọn mọ́,+ kì yóò sì sí ọ̀kankan tí yóò dàwátì,” ni àsọjáde Jèhófà.  “Wò ó! Àwọn ọjọ́ ń bọ̀,” ni àsọjáde Jèhófà, “ṣe ni èmi yóò gbé èéhù kan tí ó jẹ́ olódodo dìde fún Dáfídì.+ Dájúdájú, ọba kan yóò jẹ,+ yóò sì fi ọgbọ́n inú hùwà, yóò sì mú ìdájọ́ òdodo àti òdodo ṣẹ ní kíkún ní ilẹ̀ náà.+  A óò gba Júdà là ní ọjọ́ rẹ̀,+ Ísírẹ́lì alára yóò sì máa gbé nínú ààbò.+ Èyí sì ni orúkọ rẹ̀ tí a óò máa fi pè é, Jèhófà Ni Òdodo Wa.”+  “Nítorí náà, wò ó! àwọn ọjọ́ ń bọ̀,” ni àsọjáde Jèhófà, “wọn kì yóò sì tún wí pé, ‘Jèhófà ń bẹ láàyè, ẹni tí ó mú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gòkè wá láti ilẹ̀ Íjíbítì,’+  bí kò ṣe, ‘Jèhófà ń bẹ láàyè ẹni tí ó mú àwọn ọmọ ilé Ísírẹ́lì gòkè tí ó sì mú wọn wọlé wá láti ilẹ̀ àríwá àti láti gbogbo ilẹ̀ tí mo ti fọ́n wọn ká sí,’ dájúdájú, wọn yóò sì máa gbé lórí ilẹ̀ tiwọn.”+  Ní ti àwọn wòlíì, ìròbìnújẹ́ ti bá ọkàn-àyà mi nínú mi. Gbogbo egungun mi ti bẹ̀rẹ̀ sí mì. Mo ti dà bí ọkùnrin tí ó mutí para,+ àti bí abarapá ọkùnrin tí wáìnì ti ṣẹ́pá rẹ̀, nítorí Jèhófà àti nítorí àwọn ọ̀rọ̀ mímọ́ rẹ̀. 10  Nítorí àwọn panṣágà+ ni ó kún ilẹ̀ náà.+ Nítorí ègún, ilẹ̀ náà ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣọ̀fọ̀,+ ilẹ̀ ìjẹko inú aginjù ti gbẹ;+ ipa ọ̀nà ìgbésẹ̀ wọn jẹ́ búburú, agbára ńlá wọn kò sì tọ́. 11  “Nítorí pé àti wòlíì àti àlùfáà alára ti di eléèérí.+ Pẹ̀lúpẹ̀lù, mo ti rí ìwà búburú wọn nínú ilé tèmi,”+ ni àsọjáde Jèhófà. 12  “Nítorí náà, ọ̀nà wọn yóò di àwọn ibi yíyọ̀bọ̀rọ́+ fún wọn nínú ìṣúdùdù, èyí tí a ó tì wọ́n sí, tí wọn yóò sì ṣubú dájúdájú.”+ “Nítorí èmi yóò mú ìyọnu àjálù wá sórí wọn, ọdún tí a óò fún wọn ní àfiyèsí,”+ ni àsọjáde Jèhófà. 13  “Mo sì ti rí àìbẹ́tọ̀ọ́mu nínú àwọn wòlíì Samáríà.+ Wọ́n ti ṣe bí àwọn wòlíì tí Báálì+ ru lọ́kàn sókè, wọ́n sì ń mú kí àwọn ènìyàn mi, àní Ísírẹ́lì, rìn gbéregbère.+ 14  Mo sì ti rí àwọn ohun ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀+ nínú àwọn wòlíì Jerúsálẹ́mù, ṣíṣe panṣágà+ àti rírìn nínú èké;+ wọ́n sì ti fún ọwọ́ àwọn aṣebi lókun kí olúkúlùkù wọn má bàa padà+ nínú ìwà búburú rẹ̀. Sí mi, gbogbo wọn dà bí Sódómù,+ àti àwọn olùgbé rẹ̀ bí Gòmórà.”+ 15  Nítorí náà, èyí ni ohun tí Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wí lòdì sí àwọn wòlíì: “Kíyè sí i, èmi yóò mú kí wọ́n jẹ iwọ, dájúdájú, èmi yóò fún wọn ni omi onímájèlé mu.+ Nítorí láti ọ̀dọ̀ àwọn wòlíì Jerúsálẹ́mù ni ìpẹ̀yìndà+ ti jáde lọ sí gbogbo ilẹ̀.” 16  Èyí ni ohun tí Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wí: “Ẹ má fetí sí ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì tí ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún yín.+ Wọ́n ń sọ yín di asán.+ Ìran ọkàn-àyà tiwọn ni wọ́n ń sọ+—kì í ṣe láti ẹnu Jèhófà.+ 17  Wọ́n ń sọ léraléra fún àwọn tí ń ṣàìbọ̀wọ̀ fún mi pé, ‘Jèhófà ti sọ pé: “Àlàáfíà ni ẹ óò ní.”’+ Àti sí olúkúlùkù ẹni tí ń rìn nínú agídí ọkàn-àyà rẹ̀,+ wọ́n wí pé, ‘Ìyọnu àjálù kankan kì yóò já lù yín.’+ 18  Nítorí, ta ni ó ti dúró ní àwùjọ tímọ́tímọ́+ Jèhófà kí ó lè rí i, kí ó sì gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀?+ Ta ni ó ti fún ọ̀rọ̀ rẹ̀ ní àfiyèsí kí ó lè gbọ́ ọ?+ 19  Wò ó! Ìjì ẹlẹ́fùúùfù Jèhófà, ìhónú pàápàá, yóò jáde lọ dájúdájú, àní àfẹ́yíká ìjì líle.+ Orí àwọn ẹni burúkú ni yóò ti fẹ́ ní àfẹ́yíká.+ 20  Ìbínú Jèhófà kì yóò yí padà títí yóò fi mú kí èrò ọkàn-àyà rẹ̀ di ṣíṣe+ àti títí yóò fi mú kí ó ṣẹ.+ Ní apá ìgbẹ̀yìn àwọn ọjọ́, ẹ ó fi òye gbà á rò.+ 21  “Èmi kò rán àwọn wòlíì, síbẹ̀, àwọn fúnra wọn sáré. Èmi kò bá wọn sọ̀rọ̀, síbẹ̀, àwọn fúnra wọn sọ tẹ́lẹ̀.+ 22  Ṣùgbọ́n ká ní wọ́n dúró ní àwùjọ tímọ́tímọ́+ mi ni, nígbà náà, wọn ì bá mú kí àwọn ènìyàn mi gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, wọn ì bá sì mú wọn yí padà kúrò ní ọ̀nà búburú wọn àti kúrò nínú búburú ìbálò wọn.”+ 23  “Ọlọ́run tí ó wà nítòsí ha ni mí,” ni àsọjáde Jèhófà, “tí kì í sì í ṣe Ọlọ́run tí ó jìnnà réré?”+ 24  “Tàbí ẹnì kankan ha lè fi ara pa mọ́ sí ibi ìlùmọ́ kí èmi fúnra mi má sì rí i?”+ ni àsọjáde Jèhófà. “Èmi kò ha kún ọ̀run àti ilẹ̀ ayé ní ti gidi?”+ ni àsọjáde Jèhófà. 25  “Mo ti gbọ́ ohun tí àwọn wòlíì tí ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ èké ní orúkọ+ mi wí, pé, ‘Mo ti lá àlá! Mo ti lá àlá!’+ 26  Báwo ni yóò ti wà pẹ́ tó ní ọkàn-àyà àwọn wòlíì tí ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ èké, tí wọ́n sì jẹ́ wòlíì àgálámàṣà ọkàn-àyà wọn?+ 27  Wọ́n ń ronú mímú kí àwọn ènìyàn mi gbàgbé orúkọ mi nípasẹ̀ àwọn àlá wọn tí ẹnì kìíní wọn ń rọ́ fún ẹnì kejì,+ gan-an gẹ́gẹ́ bí àwọn baba wọn ti gbàgbé orúkọ mi nípasẹ̀ Báálì.+ 28  Wòlíì tí ó bá lá àlá, jẹ́ kí ó rọ́ àlá náà; ṣùgbọ́n ẹni náà tí ó ní ọ̀rọ̀ mi, kí ó sọ ọ̀rọ̀ mi jáde ní òtítọ́.”+ “Kí ni èérún pòròpórò ní í ṣe pẹ̀lú ọkà?”+ ni àsọjáde Jèhófà. 29  “Ọ̀rọ̀ mi kò ha dà bí iná,”+ ni àsọjáde Jèhófà, “àti bí ọmọ owú tí ń fọ́ àpáta gàǹgà túútúú?”+ 30  “Nítorí náà, kíyè sí i, mo dojú ìjà kọ àwọn wòlíì,”+ ni àsọjáde Jèhófà, “àwọn tí ń jí ọ̀rọ̀ mi gbé lọ, olúkúlùkù láti ọ̀dọ̀ alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀.”+ 31  “Kíyè sí i, mo dojú ìjà kọ àwọn wòlíì,” ni àsọjáde Jèhófà, “àwọn tí ń lo ahọ́n wọn kí wọ́n lè sọ jáde pé, ‘Àsọjáde kan!’”+ 32  “Kíyè sí i, mo dojú ìjà kọ àwọn wòlíì tí ń lá àlá èké,” ni àsọjáde Jèhófà, “tí ń rọ́ wọn, tí wọ́n sì ń mú kí àwọn ènìyàn mi rìn gbéregbère nítorí èké wọn+ àti nítorí ìṣògo wọn.”+ “Ṣùgbọ́n èmi fúnra mi kò rán wọn tàbí pàṣẹ fún wọn. Nítorí náà, wọn kì yóò ṣe àwọn ènìyàn yìí láǹfààní kankan,”+ ni àsọjáde Jèhófà. 33  “Nígbà tí àwọn ènìyàn yìí tàbí wòlíì tàbí àlùfáà bá sì béèrè lọ́wọ́ rẹ, pé, ‘Kí ni ẹrù ìnira Jèhófà?’+ ìwọ yóò sì sọ fún wọn pé, ‘“Ẹ̀yin ni—ẹrù ìnira mà ni yín o!+ Dájúdájú, èmi yóò sì pa yín tì,”+ ni àsọjáde Jèhófà.’ 34  Ní ti wòlíì tàbí àlùfáà tàbí àwọn ènìyàn tí ó bá sọ pé, ‘Ẹrù ìnira Jèhófà!’ Ṣe ni èmi yóò yí àfiyèsí sórí ọkùnrin yẹn pẹ̀lú àti sórí agbo ilé rẹ̀.+ 35  Èyí ni ohun tí olúkúlùkù yín ń sọ fún ọmọnìkejì rẹ̀ àti olúkúlùkù fún arákùnrin rẹ̀, ‘Kí ni ohun tí Jèhófà fi dáhùn? Kí sì ni ohun tí Jèhófà sọ?’+ 36  Ṣùgbọ́n ẹ má ṣe mẹ́nu kan ẹrù ìnira+ Jèhófà mọ́,+ nítorí ohun tí ẹrù ìnira náà dà fún olúkúlùkù ni ọ̀rọ̀ ara rẹ̀,+ ẹ sì ti yí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run alààyè,+ Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, Ọlọ́run wa, padà. 37  “Èyí ni ohun tí ìwọ yóò sọ fún wòlíì náà, ‘Kí ni Jèhófà fi dá ọ lóhùn? Kí sì ni Jèhófà sọ?+ 38  Bí ó bá sì jẹ́ “Ẹrù ìnira Jèhófà!” ni ohun tí ẹ ń sọ ṣáá, nítorí náà, èyí ni ohun tí Jèhófà wí: “Nítorí sísọ tí ẹ ń sọ pé, ‘Ọ̀rọ̀ yìí ni ẹrù ìnira gan-an tí ó jẹ́ ti Jèhófà,’ nígbà tí mo ń ránṣẹ́ sí yín ṣáá, pé, ‘Ẹ má sọ pé: “Ẹrù ìnira Jèhófà!”’ 39  nítorí náà, èmi rèé! Dájúdájú, èmi yóò sì fi yín fún àìnáání, pátápátá,+ èmi yóò sì kọ̀ yín tì àti ìlú ńlá tí mo fi fún ẹ̀yin àti àwọn baba ńlá yín—kúrò níwájú mi.+ 40  Ṣe ni èmi yóò mú ẹ̀gàn wá sórí yín fún àkókò tí ó lọ kánrin àti ìtẹ́lógo fún àkókò tí ó lọ kánrin, èyí tí a kì yóò gbàgbé.”’”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé